Àwọn Ọba Kìíní 18:1-46

  • Èlíjà pàdé Ọbadáyà àti Áhábù (1-18)

  • Èlíjà àti àwọn wòlíì Báálì ní Kámẹ́lì (19-40)

    • ‘Wọ́n ń ṣiyèméjì’ (21)

  • Ọ̀dá ọlọ́dún mẹ́ta àti ààbọ̀ dópin (41-46)

18  Nígbà tó yá, Jèhófà bá Èlíjà sọ̀rọ̀ ní ọdún kẹta+ pé: “Lọ fara han Áhábù, màá sì rọ òjò sórí ilẹ̀.”+  Torí náà, Èlíjà lọ rí Áhábù, nígbà tí ìyàn ṣì mú gidigidi+ ní Samáríà.  Láàárín àkókò náà, Áhábù pe Ọbadáyà, ẹni tó ń bójú tó agbo ilé. (Ọbadáyà bẹ̀rù Jèhófà gidigidi,  nígbà tí Jésíbẹ́lì+ ń pa àwọn wòlíì Jèhófà,* Ọbadáyà kó ọgọ́rùn-ún [100] wòlíì, ó fi wọ́n pa mọ́ ní àádọ́ta-àádọ́ta sínú ihò, ó sì ń fún wọn ní oúnjẹ àti omi.)  Áhábù wá sọ fún Ọbadáyà pé: “Lọ káàkiri ilẹ̀ yìí, sí gbogbo ìsun omi àti gbogbo àfonífojì. Bóyá a lè rí koríko tútù, tí a máa fún àwọn ẹṣin àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* wa, kí gbogbo àwọn ẹran wa má bàa kú.”  Nítorí náà, wọ́n pín ilẹ̀ tí wọ́n máa lọ láàárín ara wọn. Áhábù gba ọ̀nà kan lọ, Ọbadáyà sì gba ọ̀nà míì lọ.  Bí Ọbadáyà ṣe ń lọ lójú ọ̀nà, Èlíjà wá pàdé rẹ̀. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni ó dá a mọ̀, ó dojú bolẹ̀, ó sì sọ pé: “Ṣé ìwọ rèé, olúwa mi Èlíjà?”+  Ó dá a lóhùn pé: “Èmi ni. Lọ sọ fún olúwa rẹ pé: ‘Èlíjà ti dé.’”  Àmọ́ Ọbadáyà sọ pé: “Kí ni ẹ̀ṣẹ̀ mi tí o fi fẹ́ fa ìránṣẹ́ rẹ lé ọwọ́ Áhábù láti pa mí? 10  Bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti wà láàyè, kò sí orílẹ̀-èdè tàbí ìjọba tí olúwa mi kò tíì ránṣẹ́ sí pé kí wọ́n wá ọ. Lẹ́yìn tí wọ́n bá sọ pé, ‘Kò sí níbí,’ ńṣe ló máa ní kí ìjọba náà tàbí orílẹ̀-èdè náà búra pé wọn kò rí ọ.+ 11  Ìwọ wá ń sọ pé, ‘Lọ sọ fún olúwa rẹ pé: “Èlíjà ti dé.”’ 12  Nígbà tí mo bá kúrò lọ́dọ̀ rẹ, ẹ̀mí Jèhófà yóò gbé ọ lọ+ sí ibi tí mi ò mọ̀, tí mo bá wá sọ fún Áhábù, tí kò sì rí ọ, ó dájú pé yóò pa mí. Bẹ́ẹ̀, ìránṣẹ́ rẹ ti ń bẹ̀rù Jèhófà láti ìgbà èwe rẹ̀ wá. 13  Ṣé wọn ò tíì sọ ohun tí mo ṣe fún olúwa mi nígbà tí Jésíbẹ́lì ń pa àwọn wòlíì Jèhófà ni, bí mo ṣe kó ọgọ́rùn-ún (100) lára àwọn wòlíì Jèhófà pa mọ́, ní àádọ́ta-àádọ́ta sínú ihò, tí mo sì ń fún wọn ní oúnjẹ àti omi?+ 14  Ní báyìí, o wá ń sọ pé, ‘Lọ sọ fún olúwa rẹ pé: “Èlíjà ti dé.”’ Ó dájú pé yóò pa mí.” 15  Àmọ́, Èlíjà sọ pé: “Bí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun tí mò ń sìn* ti wà láàyè, òní ni màá fi ara mi han ọba.” 16  Torí náà, Ọbadáyà lọ pàdé Áhábù, ó sì sọ fún un, Áhábù sì wá pàdé Èlíjà. 17  Bí Áhábù ṣe rí Èlíjà báyìí, ó sọ fún un pé: “Ṣé ìwọ rèé, ìwọ tí o kó wàhálà ńlá* bá Ísírẹ́lì?” 18  Ó fèsì pé: “Èmi kọ́ ló kó wàhálà bá Ísírẹ́lì, ìwọ àti ilé bàbá rẹ ni, ẹ pa àwọn àṣẹ Jèhófà tì, ẹ sì ń tẹ̀ lé àwọn Báálì.+ 19  Ní báyìí, pe gbogbo Ísírẹ́lì jọ sọ́dọ̀ mi lórí Òkè Kámẹ́lì+ àti ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé àádọ́ta (450) wòlíì Báálì àti ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) wòlíì òpó òrìṣà,*+ tó ń jẹun lórí tábìlì Jésíbẹ́lì.” 20  Torí náà, Áhábù ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn èèyàn Ísírẹ́lì, ó sì kó àwọn wòlíì náà jọ sórí Òkè Kámẹ́lì. 21  Lẹ́yìn náà Èlíjà wá bá gbogbo àwọn èèyàn náà, ó sì sọ pé: “Ìgbà wo lẹ máa ṣiyèméjì* dà?+ Tó bá jẹ́ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́, ẹ tẹ̀ lé e;+ àmọ́ tó bá jẹ́ pé Báálì ni, ẹ tẹ̀ lé e!” Àwọn èèyàn náà kò sì fèsì kankan. 22  Ni Èlíjà bá sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Èmi nìkan ló kù nínú àwọn wòlíì Jèhófà,+ nígbà tí àwọn wòlíì Báálì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé àádọ́ta (450) ọkùnrin. 23  Ẹ jẹ́ kí wọ́n fún wa ní akọ ọmọ màlúù méjì, kí wọ́n mú akọ ọmọ màlúù kan, kí wọ́n gé e sí wẹ́wẹ́, kí wọ́n sì kó o sórí igi, ṣùgbọ́n kí wọ́n má fi iná sí i. Èmi náà á ṣètò akọ ọmọ màlúù kejì, màá sì kó o sórí igi, ṣùgbọ́n mi ò ní fi iná sí i. 24  Lẹ́yìn náà, kí ẹ pe orúkọ ọlọ́run yín,+ èmi náà á pe orúkọ Jèhófà. Ọlọ́run tí ó bá fi iná dáhùn ni Ọlọ́run tòótọ́.”+ Gbogbo àwọn èèyàn náà bá dáhùn pé: “Ohun tí o sọ dáa.” 25  Èlíjà wá sọ fún àwọn wòlíì Báálì pé: “Ẹ mú akọ ọmọ màlúù kan, kí ẹ sì kọ́kọ́ ṣètò rẹ̀, nítorí pé ẹ̀yin ni ó pọ̀ jù. Kí ẹ wá pe orúkọ ọlọ́run yín, ṣùgbọ́n kí ẹ má fi iná sí i.” 26  Torí náà, wọ́n mú akọ ọmọ màlúù tí wọ́n yàn, wọ́n ṣètò rẹ̀, wọ́n sì ń pe orúkọ Báálì láti àárọ̀ títí di ọ̀sán, wọ́n ń sọ pé: “Báálì, dá wa lóhùn!” Ṣùgbọ́n wọn ò gbọ́ ohùn kankan, ẹnì kankan ò sì dá wọn lóhùn.+ Wọ́n sì ń tiro yí ká pẹpẹ tí wọ́n ṣe. 27  Lọ́wọ́ ọ̀sán, Èlíjà bẹ̀rẹ̀ sí í fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ pé: “Ẹ fi gbogbo ohùn yín pè é! Ṣebí ọlọ́run ni!+ Bóyá ó ti ronú lọ tàbí kó jẹ́ pé ó ti lọ yàgbẹ́.* Ó sì lè jẹ́ pé ńṣe ló sùn lọ, tó sì yẹ kí ẹnì kan jí i!” 28  Wọ́n ń fi gbogbo ohùn wọn kígbe, wọ́n sì ń fi ọ̀bẹ àti aṣóró ya ara wọn bí àṣà wọn, títí ẹ̀jẹ̀ fi tú jáde sí gbogbo ara wọn. 29  Nígbà tí ọ̀sán ti pọ́n, tí wọ́n sì ń ṣe wọ́nranwọ̀nran* títí di ìgbà tí a máa ń fi ọrẹ ọkà rúbọ, àmọ́ wọn kò gbọ́ ohùn kankan, ẹnì kankan kò dá wọn lóhùn, kò sì sí ẹni tó ń fiyè sí wọn.+ 30  Níkẹyìn, Èlíjà sọ fún gbogbo àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ sún mọ́ mi.” Nítorí náà, gbogbo àwọn èèyàn náà sún mọ́ ọn. Lẹ́yìn náà, ó tún pẹpẹ Jèhófà tí wọ́n ti ya lulẹ̀ ṣe.+ 31  Ni Èlíjà bá kó òkúta méjìlá (12), tó jẹ́ iye ẹ̀yà àwọn ọmọ Jékọ́bù, ẹni tí Jèhófà sọ fún pé: “Ísírẹ́lì ni orúkọ rẹ yóò máa jẹ́.”+ 32  Ó fi àwọn òkúta náà mọ pẹpẹ kan+ fún ògo orúkọ Jèhófà. Ó sì gbẹ́ kòtò kan yí pẹpẹ náà ká, àyè tó wà níbẹ̀ fẹ̀ tó ibi tí wọ́n lè fún irúgbìn òṣùwọ̀n síà* méjì sí. 33  Lẹ́yìn ìyẹn, ó to àwọn igi, ó gé akọ ọmọ màlúù náà sí wẹ́wẹ́, ó sì kó o sórí àwọn igi náà.+ Ó wá sọ pé: “Ẹ pọn omi kún ìṣà mẹ́rin tí ó tóbi, kí ẹ sì dà á sórí ẹran ẹbọ sísun náà àti àwọn igi náà.” 34  Lẹ́yìn náà, ó sọ pé: “Ẹ ṣe é lẹ́ẹ̀kan sí i.” Torí náà, wọ́n ṣe é lẹ́ẹ̀kan sí i. Ó tún sọ pé: “Ẹ ṣe é nígbà kẹta.” Torí náà, wọ́n ṣe é nígbà kẹta. 35  Omi yí pẹpẹ náà ká, ó sì tún pọn omi kún kòtò náà. 36  Ní déédéé àkókò tí wọ́n máa ń fi ọrẹ ọkà ìrọ̀lẹ́ rúbọ,+ wòlíì Èlíjà wá síwájú, ó sì sọ pé: “Jèhófà, Ọlọ́run Ábúráhámù,+ Ísákì+ àti Ísírẹ́lì, jẹ́ kí wọ́n mọ̀ lónìí pé ìwọ ni Ọlọ́run Ísírẹ́lì àti pé ìránṣẹ́ rẹ ni mí, kí wọ́n sì mọ̀ pé ìwọ lo ní kí n ṣe gbogbo nǹkan yìí.+ 37  Dá mi lóhùn, Jèhófà! Dá mi lóhùn kí àwọn èèyàn yìí lè mọ̀ pé ìwọ, Jèhófà, ni Ọlọ́run tòótọ́ àti pé o fẹ́ yí ọkàn wọn pa dà sọ́dọ̀ rẹ.”+ 38  Ni iná Jèhófà bá bọ́ láti òkè, ó sì jó ẹran ẹbọ sísun+ náà àti àwọn igi, àwọn òkúta àti iyẹ̀pẹ̀ ibẹ̀ run, ó sì lá omi inú kòtò náà gbẹ.+ 39  Nígbà tí gbogbo àwọn èèyàn náà rí i, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ wọ́n dojú bolẹ̀, wọ́n sì sọ pé: “Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́! Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́!” 40  Ni Èlíjà bá sọ fún wọn pé: “Ẹ gbá àwọn wòlíì Báálì mú! Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìkankan lára wọn sá lọ!” Ní kíá, wọ́n gbá wọn mú, Èlíjà wá mú wọn lọ sí odò* Kíṣónì,+ ó sì pa wọ́n níbẹ̀.+ 41  Èlíjà wá sọ fún Áhábù pé: “Gòkè lọ, kí o jẹ, kí o sì mu, nítorí ìró òjò+ ń dún.” 42  Torí náà, Áhábù gòkè lọ kí ó lè jẹ, kí ó sì mu, àmọ́ Èlíjà lọ sí orí Òkè Kámẹ́lì, ó bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀, ó sì gbé orí rẹ̀ sáàárín eékún rẹ̀.+ 43  Lẹ́yìn náà, ó sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Jọ̀wọ́, gòkè lọ kí o sì wo apá ibi tí òkun wà.” Nítorí náà, ó gòkè lọ, ó wò ó, ó sì sọ pé: “Kò sí nǹkan kan.” Ìgbà méje ni Èlíjà sọ fún un pé, “Pa dà lọ.” 44  Ní ìgbà keje, ìránṣẹ́ náà sọ pé: “Wò ó! Mo rí ìkùukùu kékeré kan bí àtẹ́lẹwọ́ èèyàn tó ń gòkè bọ̀ láti inú òkun.” Èlíjà sì sọ pé: “Lọ sọ fún Áhábù pé, ‘Di kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ! Kí o sì sọ̀ kalẹ̀ lọ kí òjò má bàa dá ọ dúró!’” 45  Láàárín àkókò yìí, ojú ọ̀run ṣú dẹ̀dẹ̀, atẹ́gùn fẹ́, òjò ńlá sì rọ̀;+ Áhábù gun kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ó sì lọ sí Jésírẹ́lì.+ 46  Àmọ́, Jèhófà fún Èlíjà lágbára, ó wé* aṣọ rẹ̀ mọ́ ìbàdí, ó sì ń sáré lọ níwájú Áhábù títí dé Jésírẹ́lì.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “ké àwọn wòlíì Jèhófà kúrò.”
Ọ̀rọ̀ yìí ní Hébérù ń tọ́ka sí ìbaaka.
Ní Héb., “tí mo dúró síwájú rẹ̀.”
Tàbí “ìtanùlẹ́gbẹ́.”
Ní Héb., “tiro.”
Tàbí kó jẹ́, “ó ti rìnrìn àjò.”
Tàbí “ṣe bíi wòlíì.”
Síà kan jẹ́ Lítà 7.33. Wo Àfikún B14.
Tàbí “àfonífojì.”
Tàbí “sán.”