Àkọsílẹ̀ Lúùkù 10:1-42

  • Jésù rán 70 èèyàn jáde (1-12)

  • Àwọn ìlú tí kò ronú pìwà dà gbé (13-16)

  • Àwọn 70 náà pa dà dé (17-20)

  • Jésù yin Baba rẹ̀ torí ó ṣojúure sí àwọn onírẹ̀lẹ̀ (21-24)

  • Àpèjúwe ará Samáríà tó jẹ́ aládùúgbò rere (25-37)

  • Jésù lọ sọ́dọ̀ Màtá àti Màríà (38-42)

10  Lẹ́yìn àwọn nǹkan yìí, Olúwa yan àwọn àádọ́rin (70) míì, ó sì rán wọn jáde ṣáájú rẹ̀ ní méjì-méjì+ sínú gbogbo ìlú àti ibi tí òun fúnra rẹ̀ máa lọ.  Ó wá sọ fún wọn pé: “Òótọ́ ni, ìkórè pọ̀, àmọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ò tó nǹkan. Torí náà, ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè pé kó rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde láti bá a kórè.+  Ẹ lọ! Ẹ wò ó! Mò ń rán yín jáde bí ọ̀dọ́ àgùntàn sí àárín ìkookò.+  Ẹ má ṣe gbé àpò owó, àpò oúnjẹ tàbí bàtà,+ ẹ má sì kí ẹnikẹ́ni* lójú ọ̀nà.  Ibikíbi tí ẹ bá ti wọ ilé kan, ẹ kọ́kọ́ sọ pé: ‘Àlàáfíà fún ilé yìí o.’+  Tí ọ̀rẹ́ àlàáfíà bá sì wà níbẹ̀, àlàáfíà yín máa wá sórí rẹ̀. Àmọ́ tí kò bá sí, ó máa pa dà sọ́dọ̀ yín.  Torí náà, ẹ dúró sínú ilé yẹn,+ kí ẹ jẹ, kí ẹ sì mu ohun tí wọ́n bá pèsè,+ torí owó iṣẹ́ tọ́ sí òṣìṣẹ́.+ Ẹ má ṣe máa ti ilé kan bọ́ sí òmíràn.  “Bákan náà, ibikíbi tí ẹ bá ti wọ ìlú kan, tí wọ́n sì gbà yín, ẹ jẹ ohun tí wọ́n bá gbé síwájú yín,  kí ẹ wo àwọn aláìsàn tó wà níbẹ̀ sàn, kí ẹ sì sọ fún wọn pé: ‘Ìjọba Ọlọ́run ti sún mọ́ ọ̀dọ̀ yín.’+ 10  Àmọ́ ibikíbi tí ẹ bá ti wọ ìlú kan, tí wọn ò sì gbà yín, ẹ lọ sí àwọn ọ̀nà rẹ̀ tó bọ́ sí gbangba, kí ẹ sì sọ pé: 11  ‘A nu eruku tó lẹ̀ mọ́ wa lẹ́sẹ̀ pàápàá látinú ìlú yín kúrò lòdì sí yín.+ Síbẹ̀, ẹ fi èyí sọ́kàn pé Ìjọba Ọlọ́run ti sún mọ́lé.’ 12  Mò ń sọ fún yín pé Sódómù máa lè fara dà á ní ọjọ́ yẹn ju ìlú yẹn lọ.+ 13  “O gbé, ìwọ Kórásínì! O gbé, ìwọ Bẹtisáídà! torí ká ní àwọn iṣẹ́ agbára tó ṣẹlẹ̀ nínú yín bá ṣẹlẹ̀ ní Tírè àti Sídónì ni, tipẹ́tipẹ́ ni wọ́n á ti ronú pìwà dà, tí wọ́n á jókòó pẹ̀lú aṣọ ọ̀fọ̀* àti eérú.+ 14  Torí náà, Tírè àti Sídónì máa lè fara dà á lásìkò ìdájọ́ jù yín lọ. 15  Àti ìwọ, Kápánáúmù, ṣé a máa gbé ọ ga dé ọ̀run ni? Inú Isà Òkú* nísàlẹ̀ lo máa lọ! 16  “Ẹnikẹ́ni tó bá fetí sí yín, fetí sí mi.+ Ẹnikẹ́ni tí kò bá sì kà yín sí, kò ka èmi náà sí. Bákan náà, ẹnikẹ́ni tí kò bá kà mí sí, kò ka Ẹni tó rán mi náà sí.”+ 17  Lẹ́yìn náà, àwọn àádọ́rin (70) náà pa dà dé tayọ̀tayọ̀, wọ́n ń sọ pé: “Olúwa, àwọn ẹ̀mí èṣù pàápàá tẹrí ba fún wa torí pé a lo orúkọ rẹ.”+ 18  Ó wá sọ fún wọn pé: “Mo rí i tí Sátánì já bọ́+ bíi mànàmáná láti ọ̀run. 19  Ẹ wò ó! Mo ti fún yín ní àṣẹ láti fi ẹsẹ̀ tẹ àwọn ejò àti àkekèé mọ́lẹ̀ àti àṣẹ lórí gbogbo agbára ọ̀tá,+ kò sì ní sí ohunkóhun tó máa pa yín lára. 20  Ṣùgbọ́n, ẹ má yọ̀ torí pé a mú kí àwọn ẹ̀mí tẹrí ba fún yín, àmọ́ ẹ yọ̀ torí pé a ti kọ orúkọ yín sílẹ̀ ní ọ̀run.”+ 21  Ní wákàtí yẹn gan-an, ó yọ̀ gidigidi nínú ẹ̀mí mímọ́, ó sì sọ pé: “Baba, Olúwa ọ̀run àti ayé, mo yìn ọ́ ní gbangba, torí pé o rọra fi àwọn nǹkan yìí pa mọ́ fún àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn amòye,+ o sì ti ṣí wọn payá fún àwọn ọmọdé. Bẹ́ẹ̀ ni, Baba, torí pé ohun tí o fọwọ́ sí nìyí.+ 22  Baba mi ti fa ohun gbogbo lé mi lọ́wọ́, kò sẹ́ni tó mọ ẹni tí Ọmọ jẹ́, àfi Baba, kò sì sẹ́ni tó mọ ẹni tí Baba jẹ́, àfi Ọmọ+ àti ẹnikẹ́ni tí Ọmọ bá fẹ́ ṣí i payá fún.”+ 23  Ó wá yíjú sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ó sì sọ fún wọn láwọn nìkan pé: “Aláyọ̀ ni àwọn ojú tó rí àwọn ohun tí ẹ̀ ń rí.+ 24  Torí mò ń sọ fún yín pé, ó wu ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì àti àwọn ọba pé kí wọ́n rí àwọn ohun tí ẹ̀ ń rí, àmọ́ wọn ò rí i,+ ó wù wọ́n kí wọ́n gbọ́ àwọn ohun tí ẹ̀ ń gbọ́, àmọ́ wọn ò gbọ́ ọ.” 25  Wò ó! ọkùnrin kan tó mọ Òfin dunjú dìde láti dán an wò, ó sì sọ pé: “Olùkọ́, kí ló yẹ kí n ṣe kí n lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”+ 26  Ó sọ fún un pé: “Kí la kọ sínú Òfin? Kí lo kà níbẹ̀?” 27  Ọkùnrin náà dáhùn pé: “‘Kí o fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara* rẹ àti gbogbo okun rẹ àti gbogbo èrò rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà* Ọlọ́run rẹ,’+ kí o sì ‘nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.’”+ 28  Ó sọ fún un pé: “Ìdáhùn rẹ tọ́; máa ṣe bẹ́ẹ̀, o sì máa rí ìyè.”+ 29  Àmọ́ ọkùnrin náà fẹ́ fi hàn pé olódodo ni òun,+ ó wá sọ fún Jésù pé: “Ta ni ọmọnìkejì mi gan-an?” 30  Jésù dáhùn pé: “Ọkùnrin kan ń sọ̀ kalẹ̀ lọ láti Jerúsálẹ́mù sí Jẹ́ríkò, ó sì bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọlọ́ṣà, wọ́n bọ́ ọ láṣọ, wọ́n lù ú, wọ́n sì fi sílẹ̀ lọ nígbà tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú. 31  Ó ṣẹlẹ̀ pé àsìkò yẹn ni àlùfáà kan ń sọ̀ kalẹ̀ lọ lójú ọ̀nà yẹn, àmọ́ nígbà tó rí ọkùnrin náà, ó gba ọ̀nà tó wà ní òdìkejì kọjá lọ. 32  Bákan náà, nígbà tí ọmọ Léfì kan dé ibẹ̀, tó sì rí i, ó gba ọ̀nà tó wà ní òdìkejì kọjá lọ. 33  Àmọ́ ará Samáríà+ kan tó ń rìnrìn àjò gba ọ̀nà yẹn ṣàdédé bá a pàdé, nígbà tó rí i, àánú rẹ̀ ṣe é. 34  Torí náà, ó sún mọ́ ọn, ó di àwọn ọgbẹ́ rẹ̀, ó sì da òróró àti wáìnì sí i. Ó wá gbé e sórí ẹran rẹ̀, ó gbé e lọ sí ilé ìgbàlejò kan, ó sì tọ́jú rẹ̀. 35  Lọ́jọ́ kejì, ó mú owó dínárì* méjì jáde, ó fún olùtọ́jú ilé náà, ó sì sọ pé: ‘Tọ́jú rẹ̀, ohunkóhun tí o bá sì ná lẹ́yìn èyí, màá san án pa dà fún ọ tí mo bá dé.’ 36  Lójú tìẹ, èwo nínú àwọn mẹ́ta yìí ló fi hàn pé òun jẹ́ ọmọnìkejì+ ọkùnrin tó bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọlọ́ṣà náà?” 37  Ó sọ pé: “Ẹni tó ṣàánú rẹ̀ ni.”+ Jésù wá sọ fún un pé: “Ìwọ náà, lọ ṣe ohun kan náà.”+ 38  Bí wọ́n ṣe ń lọ, ó wọ abúlé kan. Ibí ni obìnrin kan tó ń jẹ́ Màtá+ ti gbà á lálejò sínú ilé rẹ̀. 39  Ó tún ní arábìnrin kan tó ń jẹ́ Màríà, ẹni tó jókòó síbi ẹsẹ̀ Olúwa, tó sì ń fetí sí ohun tó ń sọ.* 40  Àmọ́ ní ti Màtá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tó ń ṣe gbà á lọ́kàn. Torí náà, ó wá bá Jésù, ó sì sọ pé: “Olúwa, ṣé o ò rí i bí arábìnrin mi ṣe fi èmi nìkan sílẹ̀ láti bójú tó àwọn nǹkan ni? Sọ fún un pé kó wá ràn mí lọ́wọ́.” 41  Olúwa dá a lóhùn pé: “Màtá, Màtá, ò ń ṣàníyàn, o sì ń ṣèyọnu nípa nǹkan tó pọ̀. 42  Nǹkan díẹ̀ tàbí ẹyọ kan ṣoṣo la nílò. Màríà ní tiẹ̀, yan ìpín rere,*+ a ò sì ní gbà á lọ́wọ́ rẹ̀.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “gbá ẹnikẹ́ni mọ́ra láti kí i.”
Ní Grk., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
Tàbí “Hédíìsì,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”
Ní Grk., “ọ̀rọ̀ rẹ̀.”
Tàbí “ìpín tó dáa jù.”