Jẹ́nẹ́sísì 21:1-34

  • Wọ́n bí Ísákì (1-7)

  • Íṣímáẹ́lì ń fi Ísákì ṣe yẹ̀yẹ́ (8, 9)

  • Ó lé Hágárì àti Íṣímáẹ́lì lọ (10-21)

  • Ábúráhámù bá Ábímélékì dá májẹ̀mú (22-34)

21  Jèhófà rántí Sérà gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ, Jèhófà sì ṣe ohun tó ṣèlérí+ fún Sérà.  Sérà lóyún,+ ó sì bí ọmọkùnrin kan fún Ábúráhámù ní ọjọ́ ogbó rẹ̀ ní àkókò tí Ọlọ́run ṣèlérí fún un.+  Ábúráhámù pe orúkọ ọmọ tuntun tí Sérà bí fún un ní Ísákì.+  Ábúráhámù sì dádọ̀dọ́* Ísákì ọmọ rẹ̀ nígbà tó pé ọmọ ọjọ́ mẹ́jọ, bí Ọlọ́run ṣe pa á láṣẹ fún un.+  Ẹni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún ni Ábúráhámù nígbà tó bí Ísákì ọmọ rẹ̀.  Sérà wá sọ pé: “Ọlọ́run ti pa mí lẹ́rìn-ín; gbogbo ẹni tó bá gbọ́ nípa rẹ̀ á bá mi rẹ́rìn-ín.”*  Ó fi kún un pé: “Ta ni ì bá sọ fún Ábúráhámù pé, ‘Ó dájú pé Sérà yóò di ìyá ọlọ́mọ’? Síbẹ̀ mo bímọ fún un ní ọjọ́ ogbó rẹ̀.”  Ọmọ náà wá dàgbà, wọ́n sì gba ọmú lẹ́nu rẹ̀, Ábúráhámù sì se àsè ńlá ní ọjọ́ tí wọ́n gba ọmú lẹ́nu Ísákì.  Àmọ́ Sérà ń kíyè sí i pé ọmọ tí Hágárì+ ará Íjíbítì bí fún Ábúráhámù ń fi Ísákì ṣe yẹ̀yẹ́.+ 10  Ó wá sọ fún Ábúráhámù pé: “Lé ẹrúbìnrin yìí àti ọmọkùnrin rẹ̀ jáde, nítorí ọmọ ẹrúbìnrin yìí kò ní bá Ísákì ọmọ mi pín ogún!”+ 11  Àmọ́ ohun tó sọ nípa ọmọ yìí kò dùn mọ́ Ábúráhámù+ nínú rárá. 12  Ọlọ́run wá sọ fún Ábúráhámù pé: “Má ṣe jẹ́ kí ohun tí Sérà ń sọ fún ọ nípa ọmọ náà àti ẹrúbìnrin rẹ bà ọ́ nínú jẹ́. Fetí sí ohun tó sọ,* torí látọ̀dọ̀ Ísákì+ ni ọmọ* rẹ yóò ti wá. 13  Ní ti ọmọ ẹrúbìnrin+ náà, màá mú kí òun náà di orílẹ̀-èdè kan,+ torí ọmọ* rẹ ni.” 14  Ábúráhámù wá jí ní àárọ̀ kùtù, ó mú búrẹ́dì àti ìgò omi tí wọ́n fi awọ ṣe, ó sì fún Hágárì. Ó gbé e lé èjìká rẹ̀, ó sì ní kí òun àti ọmọ+ náà máa lọ. Hágárì kúrò níbẹ̀, ó sì ń rìn kiri nínú aginjù Bíá-ṣébà.+ 15  Nígbà tó yá, omi inú ìgò awọ náà tán, ó sì gbé ọmọ náà sábẹ́ igi kan nínú igbó. 16  Lẹ́yìn náà, ó lọ dá jókòó sí ìwọ̀n ibi tí ọfà lè dé téèyàn bá ta á, torí ó sọ pé: “Mi ò fẹ́ kí ọmọ náà kú níṣojú mi.” Torí náà, ó jókòó sí ọ̀ọ́kán, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ké, ó sì ń sunkún. 17  Ọlọ́run gbọ́ igbe ọmọ+ náà, áńgẹ́lì Ọlọ́run sì pe Hágárì láti ọ̀run, ó sì sọ fún un+ pé: “Ṣé kò sí o, Hágárì? Má bẹ̀rù, torí Ọlọ́run ti gbọ́ igbe ọmọ náà níbi tó wà yẹn. 18  Dìde, gbé ọmọ náà, kí o sì fi ọwọ́ rẹ dì í mú, torí màá mú kí ó di orílẹ̀-èdè ńlá.”+ 19  Ọlọ́run wá ṣí i lójú, ló bá rí kànga omi kan, ó wá lọ rọ omi kún ìgò awọ náà, ó sì fún ọmọ náà ní omi mu. 20  Ọlọ́run wà pẹ̀lú ọmọ+ náà bó ṣe ń dàgbà. Ó ń gbé inú aginjù, ó sì wá di tafàtafà. 21  Ó ń gbé inú aginjù Páránì,+ ìyá rẹ̀ sì fẹ́ ìyàwó fún un láti ilẹ̀ Íjíbítì. 22  Nígbà yẹn, Ábímélékì àti Fíkólì olórí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sọ fún Ábúráhámù pé: “Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ nínú gbogbo ohun tí ò ń ṣe.+ 23  Torí náà, fi Ọlọ́run búra fún mi báyìí, pé o ò ní hùwà ọ̀dàlẹ̀ sí èmi àti àwọn ọmọ mi àti àtọmọdọ́mọ mi àti pé o máa fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí èmi àti ilẹ̀ tí ò ń gbé bí mo ṣe fi hàn sí ọ.”+ 24  Torí náà, Ábúráhámù sọ pé: “Mo búra.” 25  Àmọ́ Ábúráhámù fẹjọ́ sun Ábímélékì nípa kànga omi tí àwọn ìránṣẹ́ Ábímélékì fipá gbà.+ 26  Ábímélékì fèsì pé: “Mi ò mọ ẹni tó ṣe èyí; o ò sọ ọ́ létí mi rí, òní yìí ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gbọ́.” 27  Ni Ábúráhámù bá mú àgùntàn àti màlúù, ó kó o fún Ábímélékì, àwọn méjèèjì sì jọ dá májẹ̀mú. 28  Nígbà tí Ábúráhámù ya abo ọ̀dọ́ àgùntàn méje sọ́tọ̀ kúrò lára agbo ẹran, 29  Ábímélékì bi Ábúráhámù pé: “Kí nìdí tí o fi ya abo ọ̀dọ́ àgùntàn méje yìí sọ́tọ̀?” 30  Ó fèsì pé: “Gba abo ọ̀dọ́ àgùntàn méje náà lọ́wọ́ mi, kó jẹ́ ẹ̀rí pé èmi ni mo gbẹ́ kànga yìí.” 31  Ìdí nìyẹn tó fi pe ibẹ̀ ní Bíá-ṣébà,*+ torí pé àwọn méjèèjì búra níbẹ̀. 32  Torí náà, wọ́n dá májẹ̀mú+ ní Bíá-ṣébà, lẹ́yìn náà, Ábímélékì àti Fíkólì olórí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbéra, wọ́n sì pa dà sí ilẹ̀ àwọn Filísínì.+ 33  Lẹ́yìn náà, ó gbin igi támáríkì kan sí Bíá-ṣébà, ó sì ké pe orúkọ Jèhófà,+ Ọlọ́run ayérayé+ níbẹ̀. 34  Ábúráhámù sì ń gbé ní ilẹ̀ àwọn Filísínì,* ó pẹ́ gan-an*+ níbẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “kọlà.”
Tàbí kó jẹ́, “á fi mí rẹ́rìn-ín.”
Ní Héb., “ohùn rẹ̀.”
Ní Héb., “èso.”
Ní Héb., “èso.”
Ó túmọ̀ sí “Kànga Ìbúra; Kànga Ohun Méje.”
Tàbí “gbé ní ilẹ̀ àwọn Filísínì bí àjèjì.”
Ní Héb., “ó lo ọjọ́ tó pọ̀.”