Jẹ́nẹ́sísì 30:1-43

  • Bílíhà bí Dánì àti Náfútálì (1-8)

  • Sílípà bí Gádì àti Áṣérì (9-13)

  • Líà bí Ísákà àti Sébúlúnì (14-21)

  • Réṣẹ́lì bí Jósẹ́fù (22-24)

  • Agbo ẹran Jékọ́bù ń pọ̀ sí i (25-43)

30  Nígbà tí Réṣẹ́lì rí i pé òun ò bí ọmọ kankan fún Jékọ́bù, ó bẹ̀rẹ̀ sí í jowú ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ó sì ń sọ fún Jékọ́bù pé: “Fún mi ní ọmọ, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, màá kú.”  Ni inú bá bí Jékọ́bù sí Réṣẹ́lì, ó sì sọ pé: “Ṣé èmi ni Ọlọ́run tí kò fún ẹ lọ́mọ ni?”*  Torí náà, Réṣẹ́lì sọ pé: “Bílíhà+ ẹrúbìnrin mi nìyí. Bá a ní àṣepọ̀ kó lè bímọ fún mi,* kí èmi náà lè ní ọmọ nípasẹ̀ rẹ̀.”  Ló bá fún Jékọ́bù ní Bílíhà ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kó fi ṣe aya, Jékọ́bù sì bá a ní àṣepọ̀.+  Bílíhà lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún Jékọ́bù.  Réṣẹ́lì wá sọ pé: “Ọlọ́run ti ṣe onídàájọ́ mi, ó sì ti gbọ́ ohùn mi, ó wá fún mi ní ọmọkùnrin kan.” Ìdí nìyẹn tó fi pe orúkọ rẹ̀ ní Dánì.*+  Bílíhà, ìránṣẹ́ Réṣẹ́lì tún lóyún lẹ́ẹ̀kan sí i, nígbà tó yá, ó bí ọmọkùnrin kejì fún Jékọ́bù.  Réṣẹ́lì wá sọ pé: “Ìjàkadì gidi ni mo bá ẹ̀gbọ́n mi jà. Mo sì ti borí!” Torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Náfútálì.*+  Nígbà tí Líà rí i pé òun ò bímọ mọ́, ó mú Sílípà ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì fún Jékọ́bù pé kó fi ṣe aya.+ 10  Sílípà ìránṣẹ́ Líà sì bí ọmọkùnrin kan fún Jékọ́bù. 11  Líà wá sọ pé: “Ire wọlé dé!” Torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Gádì.*+ 12  Lẹ́yìn náà, Sílípà ìránṣẹ́ Líà bí ọmọkùnrin kejì fún Jékọ́bù. 13  Líà sì sọ pé: “Ayọ̀ mi kún! Ó dájú pé àwọn ọmọbìnrin máa pè mí ní aláyọ̀.”+ Torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Áṣérì.*+ 14  Nígbà ìkórè àlìkámà,* Rúbẹ́nì+ ń rìn nínú oko, ó sì rí máńdírékì. Ó mú un wá fún Líà ìyá rẹ̀. Réṣẹ́lì wá sọ fún Líà pé: “Jọ̀ọ́, fún mi lára àwọn máńdírékì tí ọmọ rẹ mú wá.” 15  Ló bá sọ fún un pé: “Ṣé ohun kékeré lo rò pé o ṣe nígbà tó o gba ọkọ mi?+ Ṣé o tún fẹ́ gba máńdírékì ọmọ mi ni?” Ni Réṣẹ́lì bá sọ pé: “Kò burú. Màá jẹ́ kó sùn tì ọ́ lálẹ́ òní tí o bá fún mi ní máńdírékì ọmọ rẹ.” 16  Nígbà tí Jékọ́bù ń bọ̀ láti oko ní ìrọ̀lẹ́, Líà lọ pàdé rẹ̀, ó sì sọ pé: “Èmi lo máa bá ní àṣepọ̀, torí mo ti fi àwọn máńdírékì ọmọ mi gbà ọ́ pátápátá.” Ó wá sùn tì í ní alẹ́ ọjọ́ yẹn. 17  Ọlọ́run fetí sí Líà, ó sì dá a lóhùn, ó lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin karùn-ún fún Jékọ́bù. 18  Líà sì sọ pé: “Ọlọ́run ti pín mi lérè,* torí mo ti fún ọkọ mi ní ìránṣẹ́ mi.” Torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Ísákà.*+ 19  Líà tún lóyún lẹ́ẹ̀kan sí i, ó sì bí ọmọkùnrin kẹfà fún Jékọ́bù.+ 20  Líà wá sọ pé: “Ọlọ́run ti fún mi ní ẹ̀bùn, àní ó fún mi ní ẹ̀bùn tó dára. Ní báyìí, ọkọ mi yóò fàyè gbà mí,+ torí mo ti bí ọmọkùnrin mẹ́fà+ fún un.” Torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Sébúlúnì.*+ 21  Lẹ́yìn náà, ó bí ọmọbìnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Dínà.+ 22  Níkẹyìn, Ọlọ́run rántí Réṣẹ́lì, Ọlọ́run fetí sí i, ó sì dá a lóhùn torí ó jẹ́ kó lóyún.*+ 23  Ó lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan. Ó wá sọ pé: “Ọlọ́run ti mú ẹ̀gàn+ mi kúrò!” 24  Torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Jósẹ́fù,*+ ó sì sọ pé: “Jèhófà ti fún mi ní ọmọkùnrin míì.” 25  Lẹ́yìn tí Réṣẹ́lì bí Jósẹ́fù, Jékọ́bù sọ fún Lábánì lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé: “Jẹ́ kí n máa lọ, kí n lè pa dà síbi tí mo ti wá àti sí ilẹ̀+ mi. 26  Fún mi ní àwọn ìyàwó mi àti àwọn ọmọ mi, àwọn tí mo torí wọn sìn ọ́, kí n lè máa lọ, torí o mọ bí mo ṣe sìn ọ́ tó.”+ 27  Lábánì wá sọ fún un pé: “Tí mo bá ti rí ojúure rẹ, mo ti rí àmì tó fi hàn pé* torí rẹ ni Jèhófà ṣe ń bù kún mi.” 28  Ó tún sọ pé: “Sọ iye tí o fẹ́ gbà fún mi, màá sì fún ọ.”+ 29  Jékọ́bù fèsì pé: “O mọ bí mo ṣe sìn ọ́, o sì mọ bí mo ṣe tọ́jú agbo ẹran rẹ;+ 30  díẹ̀ lo ní kí n tó dé, àmọ́ agbo ẹran rẹ ti wá pọ̀ sí i, ó ti di púpọ̀ rẹpẹtẹ, Jèhófà sì ti bù kún ọ látìgbà tí mo ti dé. Ìgbà wo ni mo wá fẹ́ ṣe ohun tó máa jẹ́ ti agbo ilé mi?”+ 31  Ó wá bi í pé: “Kí ni kí n fún ọ?” Jékọ́bù fèsì pé: “Má ṣe fún mi ní nǹkan kan rárá! Àmọ́ tí o bá máa ṣe ohun kan ṣoṣo yìí fún mi, màá pa dà máa bójú tó agbo àgùntàn rẹ, màá sì máa ṣọ́ wọn.+ 32  Màá gba àárín gbogbo agbo ẹran rẹ kọjá lónìí. Kí o ya gbogbo àgùntàn aláwọ̀ tó-tò-tó àtàwọn tó ní oríṣiríṣi àwọ̀ sọ́tọ̀ àti gbogbo àgùntàn tí àwọ̀ rẹ̀ pọ́n rẹ́súrẹ́sú* láàárín àwọn ọmọ àgbò. Kí o sì ya èyíkéyìí tó bá ní oríṣiríṣi àwọ̀ àti àwọ̀ tó-tò-tó sọ́tọ̀ láàárín àwọn abo ewúrẹ́. Láti ìsinsìnyí lọ, àwọn yẹn ló máa jẹ́ èrè mi.+ 33  Kí òdodo* tí mò ń ṣe jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní ọjọ́ tí o bá wá wo àwọn tó jẹ́ èrè mi; tí o bá rí èyí tí kì í ṣe aláwọ̀ tó-tò-tó tí kò sì ní oríṣiríṣi àwọ̀ láàárín àwọn abo ewúrẹ́ àti èyí tí àwọ̀ rẹ̀ kò pọ́n rẹ́súrẹ́sú láàárín àwọn ọmọ àgbò lọ́dọ̀ mi, á jẹ́ pé mo jí i ni.” 34  Ni Lábánì bá fèsì pé: “Mo fara mọ́ ọn! Jẹ́ kó rí bí o ṣe sọ.”+ 35  Ní ọjọ́ yẹn, ó ya àwọn òbúkọ abilà àtàwọn tó ní oríṣiríṣi àwọ̀ sọ́tọ̀ àti gbogbo abo ewúrẹ́ aláwọ̀ tó-tò-tó àtàwọn tó ní oríṣiríṣi àwọ̀. Ó ya gbogbo èyí tó ní funfun lára àtàwọn tí àwọ̀ wọn pọ́n rẹ́súrẹ́sú sọ́tọ̀ láàárín àwọn ọmọ àgbò, ó sì ní kí àwọn ọmọ rẹ̀ máa bójú tó wọn. 36  Lẹ́yìn ìyẹn, ó fi àyè tó fẹ̀ tó ìrìn àjò ọjọ́ mẹ́ta sí àárín òun àti Jékọ́bù, Jékọ́bù sì ń bójú tó èyí tó ṣẹ́ kù nínú agbo ẹran Lábánì. 37  Jékọ́bù wá fi igi tórásì, álímọ́ńdì àti igi adánra* tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gé ṣe ọ̀pá, ó bó àwọn ibì kan lára àwọn ọ̀pá náà sí funfun. 38  Ó wá kó àwọn ọ̀pá tó ti bó náà síwájú agbo ẹran, sínú àwọn kòtò omi, sínú àwọn ọpọ́n ìmumi, níbi tí àwọn agbo ẹran ti wá ń mumi, kí wọ́n lè gùn níwájú àwọn ọ̀pá náà tí wọ́n bá wá mumi. 39  Torí náà, àwọn ẹran náà máa ń gùn níwájú àwọn ọ̀pá náà, wọ́n sì ń bí àwọn ọmọ tó nílà lára, aláwọ̀ tó-tò-tó àtàwọn tó ní oríṣiríṣi àwọ̀. 40  Jékọ́bù wá ya àwọn ọmọ àgbò sọ́tọ̀, ó sì mú kí àwọn agbo ẹran náà kọjú sí àwọn tó jẹ́ abilà àti gbogbo àwọn tí àwọ̀ wọn pọ́n rẹ́súrẹ́sú lára àwọn ẹran Lábánì. Lẹ́yìn náà, ó kó àwọn ẹran tirẹ̀ sọ́tọ̀, kò sì kó wọn mọ́ ti Lábánì. 41  Nígbàkigbà tí àwọn ẹran tó sanra bá fẹ́ gùn, Jékọ́bù máa ń kó àwọn ọ̀pá náà sínú kòtò omi níwájú àwọn agbo ẹran náà, kí wọ́n lè gùn níwájú àwọn ọ̀pá náà. 42  Àmọ́ tí àwọn ẹran náà ò bá lókun, kò ní kó àwọn ọ̀pá náà síbẹ̀. Torí náà, àwọn tí kò lókun yẹn ló máa ń di ti Lábánì, àmọ́ àwọn tó sanra á di ti Jékọ́bù.+ 43  Ohun ìní rẹ̀ wá ń pọ̀ sí i, ó ní agbo ẹran tó pọ̀ rẹpẹtẹ, àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin, ó sì tún ní àwọn ràkúnmí àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “tí kò jẹ́ kí o ní èso ikùn ni?”
Ní Héb., “kó lè bímọ lórí orúnkún mi.”
Ó túmọ̀ sí “Onídàájọ́.”
Ó túmọ̀ sí “Ìjàkadì Mi.”
Ó túmọ̀ sí “Ire.”
Ó túmọ̀ sí “Ayọ̀; Ìdùnnú.”
Tàbí “wíìtì.”
Tàbí “pín mi lérè iṣẹ́.”
Ó túmọ̀ sí “Òun Ni Èrè.”
Ó túmọ̀ sí “Ó Fàyè Gbà Mí.”
Ní Héb., “Ọlọ́run fetí sí i, ó sì ṣí ilé ọlẹ̀ rẹ̀.”
Ìkékúrú Josifáyà, tó túmọ̀ sí “Kí Jáà Fi Kún Un (Bù sí I).”
Tàbí “ẹ̀rí ti fi hàn pé.”
Ìyẹn, oríṣi àwọ̀ búráùn kan.
Tàbí “òótọ́.”
Igi tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ fẹ̀, tí èèpo rẹ̀ sì máa ń bó.