Jẹ́nẹ́sísì 16:1-16

  • Hágárì àti Íṣímáẹ́lì (1-16)

16  Sáráì ìyàwó Ábúrámù kò bí ọmọ kankan+ fún un, àmọ́ ó ní ìránṣẹ́ kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Íjíbítì, Hágárì+ ni orúkọ rẹ̀.  Sáráì wá sọ fún Ábúrámù pé: “Jọ̀ọ́, gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ! Jèhófà ò jẹ́ kí n bímọ. Jọ̀ọ́, bá ìránṣẹ́ mi ní àṣepọ̀. Bóyá mo lè ní ọmọ nípasẹ̀ rẹ̀.”+ Ábúrámù sì fetí sí ohun tí Sáráì sọ.  Lẹ́yìn tí Ábúrámù ti lo ọdún mẹ́wàá ní ilẹ̀ Kénáánì, Sáráì ìyàwó Ábúrámù mú Hágárì, ìránṣẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Íjíbítì, ó sì fún Ábúrámù ọkọ rẹ̀ kó fi ṣe aya.  Ábúrámù wá bá Hágárì ní àṣepọ̀, ó sì lóyún. Nígbà tó rí i pé òun ti lóyún, ó bẹ̀rẹ̀ sí í fojú àbùkù wo Sáráì ọ̀gá rẹ̀.  Torí náà, Sáráì sọ fún Ábúrámù pé: “Ìwọ lo fa ìyà tó ń jẹ mí. Èmi ni mo fa ìránṣẹ́ mi lé ọ lọ́wọ́,* àmọ́ nígbà tó rí i pé òun ti lóyún, ó wá ń fojú àbùkù wò mí. Kí Jèhófà ṣèdájọ́ èmi àti ìwọ.”  Ábúrámù wá sọ fún Sáráì pé: “Wò ó! O ní àṣẹ lórí ìránṣẹ́ rẹ. Ohun tí o bá rí i pé ó dáa jù ni kí o ṣe fún un.” Sáráì wá ni ín lára, ó sì sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.  Nígbà tó yá, áńgẹ́lì Jèhófà rí i níbi ìsun omi kan nínú aginjù, ìsun omi tó wà lójú ọ̀nà Ṣúrì.+  Ó sì sọ pé: “Hágárì, ìránṣẹ́ Sáráì, ibo lo ti ń bọ̀, ibo lo sì ń lọ?” Ó fèsì pé: “Mo sá kúrò lọ́dọ̀ Sáráì ọ̀gá mi ni.”  Áńgẹ́lì Jèhófà wá sọ fún un pé: “Pa dà sọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ, kí o sì tẹrí ba fún un.”* 10  Áńgẹ́lì Jèhófà wá sọ pé: “Èmi yóò mú kí ọmọ* rẹ pọ̀ gan-an débi pé wọn ò ní lè kà wọ́n.”+ 11  Áńgẹ́lì Jèhófà fi kún un pé: “O ti lóyún, wàá sì bí ọmọkùnrin kan, kí o pe orúkọ rẹ̀ ní Íṣímáẹ́lì,* torí Jèhófà ti gbọ́ nípa ìyà tó ń jẹ ọ́. 12  Ó máa dà bíi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ inú igbó.* Ó máa bá gbogbo èèyàn jà, gbogbo èèyàn á sì bá a jà, òdìkejì gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ ni á máa gbé.”* 13  Ó wá ké pe orúkọ Jèhófà, ẹni tó ń bá a sọ̀rọ̀, ó sì sọ pé: “Ọlọ́run tó ń ríran+ ni ọ́,” torí ó sọ pé: “Ṣé kì í ṣe pé mo ti rí ẹni tó ń rí mi lóòótọ́!” 14  Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń pe kànga náà ní Bia-laháí-róì.* (Ó wà láàárín Kádéṣì àti Bérédì.) 15  Hágárì wá bí ọmọkùnrin kan fún Ábúrámù, Ábúrámù sì pe orúkọ ọmọ tí Hágárì bí fún un ní Íṣímáẹ́lì.+ 16  Ẹni ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún (86) ni Ábúrámù nígbà tí Hágárì bí Íṣímáẹ́lì fún un.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “lé àyà rẹ.”
Ní Héb., “rẹ ara rẹ sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ rẹ̀.”
Ní Héb., “èso.”
Ó túmọ̀ sí “Ọlọ́run Ń Gbọ́.”
Tàbí oríṣi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ inú igbó kan tí wọ́n ń pè ní onager lédè Gẹ̀ẹ́sì. Àmọ́, àwọn kan gbà pé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà ni. Ó lè jẹ́ torí pé kì í gbára lé ẹnikẹ́ni.
Tàbí kó jẹ́, “kò ní sí àlàáfíà láàárín òun àti àwọn arákùnrin rẹ̀.”
Ó túmọ̀ sí “Kànga Ẹni Tó Wà Láàyè Tó Ń Rí Mi.”