Rúùtù 1:1-22

  • Élímélékì àti ìdílé rẹ̀ kó lọ sí Móábù (1, 2)

  • Náómì, Ọ́pà àti Rúùtù di opó (3-6)

  • Rúùtù kò fi Náómì àti Jèhófà sílẹ̀ (7-17)

  • Náómì pa dà sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, Rúùtù tẹ̀ lé e (18-22)

1  Ó ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí àwọn onídàájọ́+ ń ṣe àbójútó* ní Ísírẹ́lì, ìyàn mú ní ilẹ̀ náà. Ọkùnrin kan àti ìyàwó rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjì kúrò ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù+ ní Júdà, wọ́n sì lọ ń gbé ní ilẹ̀* Móábù.+  Élímélékì* ni orúkọ ọkùnrin náà, Náómì* ni orúkọ ìyàwó rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì sì ń jẹ́ Málónì* àti Kílíónì.* Ará Éfúrátà ni wọ́n, ìyẹn Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tó wà ní Júdà. Nígbà tí wọ́n dé ilẹ̀ Móábù, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ibẹ̀.  Nígbà tó yá, Élímélékì ọkọ Náómì kú, ó wá ku obìnrin náà àti àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì.  Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ náà fẹ́ ìyàwó láàárín àwọn ará Móábù. Ọ̀kan ń jẹ́ Ọ́pà, èkejì sì ń jẹ́ Rúùtù.+ Nǹkan bí ọdún mẹ́wàá ni wọ́n fi gbé ibẹ̀.  Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ méjèèjì, Málónì àti Kílíónì kú. Bí obìnrin náà ò ṣe ní ọkọ àti ọmọ mọ́ nìyẹn.  Òun àti ìyàwó àwọn ọmọ rẹ̀ wá gbéra, wọ́n sì fi ilẹ̀ Móábù sílẹ̀, torí ó ti gbọ́ ní Móábù pé Jèhófà ti ṣíjú àánú wo àwọn èèyàn rẹ̀, ó sì ti ń fún wọn ní oúnjẹ.*  Bó ṣe di pé ó fi ibi tó ń gbé ní Móábù sílẹ̀ nìyẹn, ìyàwó àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì sì tẹ̀ lé e. Bí wọ́n ṣe ń lọ ní ojú ọ̀nà tó lọ sí ilẹ̀ Júdà,  Náómì sọ fún ìyàwó àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì pé: “Ẹ pa dà, kí kálukú yín lọ sí ilé ìyá rẹ̀. Kí Jèhófà ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sí yín+ bí ẹ ṣe ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sí àwọn ọkọ yín tó ti kú àti sí èmi náà.  Kí Jèhófà fi* kálukú yín lọ́kàn balẹ̀* ní ilé ọkọ tí ẹ máa fẹ́.”+ Ó fi ẹnu kò wọ́n lẹ́nu, wọ́n sì bú sẹ́kún. 10  Wọ́n sì ń sọ fún un pé: “Rárá o, a máa bá ọ lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn rẹ.” 11  Ṣùgbọ́n Náómì sọ pé: “Ẹ pa dà, ẹ̀yin ọmọ mi. Kí nìdí tí ẹ ó fi bá mi lọ? Ṣé mo ṣì lè bí àwọn ọmọ tó máa fẹ́ yín ni?+ 12  Ẹ pa dà, ẹ̀yin ọmọ mi. Ẹ máa lọ, torí mo ti dàgbà ju ẹni tó lè fẹ́ ọkọ. Ká tiẹ̀ wá sọ pé mo lè rí ọkọ fẹ́ ní alẹ́ òní, tí mo sì bímọ, 13  ṣé ẹ máa wá dúró títí wọ́n á fi dàgbà? Ṣé ẹ ò wá ní lọ́kọ nítorí wọn ni? Rárá o, ẹ̀yin ọmọ mi, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí yín bà mí nínú jẹ́ gan-an torí Jèhófà ti bínú sí mi.”+ 14  Ni wọ́n bá tún bú sẹ́kún. Lẹ́yìn èyí, Ọ́pà fi ẹnu ko ìyá ọkọ rẹ̀ lẹ́nu, ó sì pa dà. Àmọ́ Rúùtù kò fi í sílẹ̀. 15  Torí náà, Náómì sọ pé: “Wò ó! Ìyàwó àbúrò ọkọ rẹ ti pa dà sọ́dọ̀ àwọn èèyàn rẹ̀ àti àwọn ọlọ́run rẹ̀. Ìwọ náà pa dà.” 16  Àmọ́ Rúùtù sọ pé: “Má rọ̀ mí pé kí n fi ọ́ sílẹ̀, pé kí n má ṣe bá ọ lọ; torí ibi tí o bá lọ ni èmi yóò lọ, ibi tí o bá sùn ni èmi yóò sùn. Àwọn èèyàn rẹ ni yóò jẹ́ èèyàn mi, Ọlọ́run rẹ ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run mi.+ 17  Ibi tí o bá kú sí ni èmi yóò kú sí, ibẹ̀ sì ni wọn yóò sin mí sí. Kí Jèhófà fi ìyà jẹ mí gan-an bí ohunkóhun yàtọ̀ sí ikú bá yà wá.” 18  Nígbà tí Náómì rí i pé Rúùtù kò fẹ́ fi òun sílẹ̀, kò rọ̀ ọ́ mọ́ pé kó pa dà. 19  Àwọn méjèèjì sì ń lọ títí wọ́n fi dé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.+ Gbàrà tí wọ́n dé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, òkìkí wọn kàn káàkiri ìlú náà, àwọn obìnrin ibẹ̀ sì ń sọ pé: “Ṣé Náómì nìyí?” 20  Ó sì ń fèsì pé: “Ẹ má pè mí ní Náómì* mọ́. Márà* ni kí ẹ máa pè mí, torí Olódùmarè ti mú kí ayé mi korò gan-an.+ 21  Ọwọ́ mi kún nígbà tí mo lọ, àmọ́ Jèhófà mú kí n pa dà lọ́wọ́ òfo. Kí nìdí tí ẹ fi ń pè mí ní Náómì, nígbà tó jẹ́ pé Jèhófà ló kẹ̀yìn sí mi, Olódùmarè ló sì fa àjálù tó bá mi?”+ 22  Bí Náómì ṣe pa dà láti ilẹ̀ Móábù+ nìyẹn, òun àti Rúùtù ará Móábù, ìyàwó ọmọ rẹ̀. Wọ́n dé sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè ọkà bálì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “ṣe ìdájọ́.”
Tàbí “agbègbè.”
Ó túmọ̀ sí “Ọba Ni Ọlọ́run Mi.”
Ó túmọ̀ sí “Adùn Mi.”
Ó ṣeé ṣe kó wá látinú ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí ẹni “tó tètè máa ń rẹ̀ tàbí ẹni tó máa ń ṣàìsàn.”
Ó túmọ̀ sí “Dákúdájí; Ẹni Tó Ń Kú Lọ.”
Ní Héb., “búrẹ́dì.”
Ní Héb., “ibi ìsinmi.”
Tàbí “fi ẹ̀bùn fún kálukú yín.”
Ó túmọ̀ sí “Adùn Mi.”
Ó túmọ̀ sí “Ìkorò.”