Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn​—⁠Àwọn Ọkùnrin àti Obìnrin Tí Bíbélì Sọ̀rọ̀ Nípa Wọn

Àwọn àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ kó o túbọ̀ lóye ìtàn àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí Bíbélì sọ pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ tó lágbára gan-an. * Àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ wọn á jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ lágbára, á sì jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run.

^ Kó lè dà bíi pé o wà níbẹ̀ nígbà táwọn ẹni ìgbàgbọ́ yẹn gbé láyé, a fi àwọn àlàyé kan tí ò sí nínú Bíbélì kún àwọn ìtàn náà. Ṣe la fara balẹ̀ ṣèwádìí àwọn ohun tá a fi kún un yìí ká lè rí i dájú pé wọn ò ta ko àwọn àkọsílẹ̀ tó wà nínú Ìwé Mímọ́ àti àwọn nǹkan míì tí wọ́n ti ṣàwárí nípa àwọn èèyàn ayé ìgbà yẹn.

Ìgbà Ìṣẹ̀dá sí Ìgbà Ìkún Omi

Ébẹ́lì—“Bí Ó Tilẹ̀ Jẹ́ Pé Ó Kú, Ó Ń Sọ̀rọ̀ Síbẹ̀”

Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ lára Ébẹ́lì àti ìgbàgbọ́ rẹ̀ nígbà tó jẹ́ pé ìwọ̀nba nǹkan díẹ̀ ni Bíbélì sọ nípa rẹ̀?

Énọ́kù: “Ó Ti Wu Ọlọ́run Dáadáa”

Tó o bá ní bùkátà ìdílé tàbí tó o dojú kọ ìṣòro kan tó gba pé kó o ṣe ohun tó o mọ̀ pé ó tọ́, wàá rí ẹ̀kọ́ kọ́ látinú àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Énọ́kù.

Nóà “Bá Ọlọ́run Tòótọ́ Rìn”

Àwọn nǹkan wo ni kò ní jẹ́ kó rọrùn fún Nóà àti aya rẹ̀ láti tọ́ àwọn ọmọ wọn? Báwo ló ṣe jẹ́ pé ìgbàgbọ́ ló mú kí Nóà kan áàkì yẹn?

Ọlọ́run Pa Nóà “Mọ́ Láìséwu Pẹ̀lú Àwọn Méje Mìíràn”

Báwo ni Ọlọ́run ṣe dáàbò bo Nóà àti ìdílé rẹ̀ ní àkókò tó tí ì le jù nínú ìtàn ẹ̀dá?

Ìgbà Ìkún Omi sí Ìgbà Táwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Kúrò ní Íjíbítì

Ábúráhámù—“Baba Gbogbo Àwọn Tí Wọ́n Ní Ìgbàgbọ́”

Báwo ni ohun tí Ábúrámù ṣe ṣe fi hàn pé ó ní ìgbàgbọ́? Àwọn ọ̀nà wo ni wàá fẹ́ gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Ábúrámù?

Sárà: “O Jẹ́ Obìnrin Kan Tí Ó Lẹ́wà Ní Ìrísí”

Nílùú Íjíbítì, àwọn ìjòye Fáráò rí bí Sárà ṣe lẹ́wà tó. Ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà máa yà ẹ́ lẹ́nu.

Ọlọ́run Pè É Ní “Ìyá Ọba”

Kí nìdí tí orúkọ tuntun yìí fi tọ́ sí Sárà?

Rèbékà: “Mo Múra Tán Láti Lọ”

Yàtọ̀ sí ìgbàgbọ́, Rèbékà tún ní àwọn ànímọ́ rere mí ì.

“Ẹ jọ̀wọ́, Ẹ Fetí Sí Àlá Tí Mo Lá”

Wàhálà tó wà nínú ìdílé Jósẹ́fù jẹ́ ẹ̀kọ́ fáwọn ìdílé tó tún ìgbéyàwó ṣe.

“Itumo Ko Ha Je Ti Olorun?”

Ki lo ran Josefu lati fi igboya tumo ala olori agboti ati olori oluse buredi ati Farao? Bawo ni Josefu se jade lewon to si di eni nla laaarin ojo kan soso?

“Emi Ha Wa ni Ipo Olorun Bi?”

Nje owu, iwa odale tabi ikoriira ti da wahala sile ninu idile re ri? To ba ri bee, itan Josefu to wa ninu Bibeli maa ran e lowo.

Jóòbù​—“Mi Ò Ní Fi Ìwà Títọ́ Mi Sílẹ̀!”

Báwo ni ìtàn Jóòbù tó wà nínú Bíbélì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè kojú ìṣòro àti àjálù tàbí àwọn àdánwò ìgbàgbọ́ míì?

Jóòbù​—Jèhófà Wò Ó Sàn

Kò sí ohun tó lè yẹ̀yẹ̀ Sátánì tó kọjá pé ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Jóòbù, kò sì sí ohun tó lè múnú Jèhófà tó nífẹ̀ẹ́ wa dénú dùn jùyẹn lọ!

Míríámù—“Ẹ Kọrin sí Jèhófà”!

Ọlọ́run mí sí wòlíì obìnrin kan tó ń jẹ́ Míríámù láti ṣáájú àwọn obìnrin Ísírẹ́lì nínú orin ìṣẹ́gun tí wọ́n kọ ní Òkun Pupa. Ohun tá a kọ́ lára Míríámù ni pé ká nígboyà, ká nígbàgbọ́, ká sì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀.

Ìgbà Táwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Kúrò ní Íjíbítì sí Ìgbà Ọba Àkọ́kọ́ ní Ísírẹ́lì

‘A Polongo Ráhábù Ní Olódodo Nípa Àwọn Iṣẹ́ Rẹ̀’

Báwo ni ìtàn Ráhábù ṣe fi dá wa lójú pé kò sẹ́ni tí kò já mọ́ nǹkan kan lójú Jèhófà? Kí la rí kọ́ nínú bó ṣe lo ìgbàgbọ́?

“Mo Dìde Gẹ́gẹ́ Bí Ìyá ní Ísírẹ́lì”

Kí ni ìtàn Dèbórà kọ́ wa nípa ohun tó túmọ̀ sí láti ní ìgbàgbọ́?

Rúùtù—“Ibi Tí O Bá Lọ Ni Èmi Yóò Lọ”

Kí nìdí tí Rúùtù fi gbà láti fi ìdílé rẹ̀ àti ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀? Àwọn ànímọ́ wo ni Rúùtù ní tí Jèhófà fi kà á sí ẹni tó ṣeyebíye?

Rúùtù—“Obìnrin Títayọ Lọ́lá”

Kí nìdí tí ìgbéyàwó Rúùtù àti Bóásì fi ṣe pàtàkì? Ẹ̀kọ́ wo ni Rúùtù àti Náómì kọ́ wa nípa ìdílé?

Hánà Sọ Ẹ̀dùn Ọkàn Rẹ̀ fún Ọlọ́run Nínú Àdúrà

Ìgbàgbọ́ tí Hánà ní nínú Jèhófà mú kó borí ìṣòro tó dà bíi pé kò ṣeé fara dà.

Sámúẹ́lì “Ń Bá A Lọ ní Dídàgbà Lọ́dọ̀ Jèhófà”

Kí ló ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa ìgbà tí Sámúẹ́lì wà lọ́mọdé? Kí ló mú kí ìgbàgbọ́ Sámúẹ́lì máa pọ̀ sí i nígbà tó wà ní àgọ́ ìjọsìn?

Sámúẹ́lì Lo Ìfaradà Bó Tilẹ̀ Jẹ́ Pé Wọ́n Já A Kulẹ̀

A lè rí àwọn ìnira àti ìjákulẹ̀ tó máa dán ìgbàgbọ́ wa wò. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ lára bí Sámúẹ́lì ṣe lo ìfaradà?

Ìgbà Ọba Àkọ́kọ́ ní Ísírẹ́lì sí Ìgbà Tá A Bí Jésù

Jónátánì​—“Kò Sí Ìdílọ́wọ́ fún Jèhófà”

Jónátánì mú ẹnì kan ṣoṣo dání lọ gbéjà ko àwọn ọmọ ogun tó dìhámọ́ra níbi tí wọ́n pabùdó sí, mánigbàgbé lohun tó sì tẹ̀yìn ẹ̀ yọ.

“Ti Jèhófà Ni Ìjà Ogun Náà”

Kí ló ran Dáfídì lọ́wọ́ láti pa Gòláyátì? Kí la rí kọ́ látinú ìtàn Dáfídì?

Dáfídì àti Jónátánì—Wọ́n Di Ọ̀rẹ́ Tímọ́tímọ́

Báwo ló ṣe di pé àwọn méjì tí wọn ò wá láti ilé kan náà, tí ọjọ́ orí wọn sì yàtọ̀ síra, di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ bẹ́ẹ̀? Báwo ni àpẹẹrẹ wọn ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ní ọ̀rẹ́ lóde òní?

Ábígẹ́lì Hùwà Ọlọgbọ́n

Kí la rí kọ́ látinú bí ilé ọkọ kò ṣe rọrùn fún Ábígẹ́lì?

Èlíjà Gbèjà Ìjọsìn Mímọ́

Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Èlíjà tá a bá bá àwọn èèyàn tí kò fara mọ́ ohun tí Bíbélì sọ pà dé?

Èlíjà Ṣọ́nà, Ó sì Ní Sùúrù

Báwo ni Èlíjà ṣe fi hàn pé òun ò fi ọ̀rọ̀ àdúrà gbígbà ṣeré bó ṣe ń dúró dé ìgbà tí Jèhófà máa mú ìlérí rẹ̀ ṣe?

Ọlọ́run Tù Èlíjà Nínú

Kí ló ṣẹlẹ̀ tí ìdààmú ọkàn fi bá Èlíjà, débi pé ó gbàdúrà pé kí òun kú?

Èlíjà Fara Da Ìwà Ìrẹ́jẹ

Ṣé àwọn èèyàn ti rẹ́ ìwọ náà jẹ rí? Ṣé ó wù ẹ́ láti rí kí Ọlọ́run mú ọ̀ràn tọ́? Wo bó o ṣe lè fara wé Èlíjà tó jé olóòótọ́.

Èlíjà—Ó Fara Dà Á Dé Òpin

Bí Èlíjà ṣe jẹ́ olóòótọ́, tó sì nífaradà lè ràn wá lọ́wọ́ káwa náà lè jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára sí i lákòókò ìṣòro.

Jónà Kẹ́kọ̀ọ́ Nínú Àwọn Àṣìṣe Rẹ̀

Ǹjẹ́ iṣẹ́ tí Jèhófà ní kó o ṣe ti bà ọ́ lẹ́rù rí bíi ti Jónà? Kí ni ìtàn Jónà kọ́ wa nípa sùúrù àti àánú Jèhófà.

Jónà Kọ́ Ìdí Tó Fi Yẹ Kó Jẹ́ Aláàánú

Báwo ni ìtàn Jónà ṣe lè mú ká fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò irú ẹni tá a jẹ́ gan-an?

Ẹ́sítérì Gbèjà Àwọn Èèyàn Ọlọ́run

Ó máa ń gba pé ká ní ìgboyà àti ìgbàgbọ́ bíi ti Ẹ́sítérì ká tó lè fi ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ hàn.

Ẹ́sítérì Lo Ọgbọ́n àti Ìgboyà, Kò sì Mọ Tara Rẹ̀ Nìkan

Báwo ní Ẹ́sítérì ṣe fínnúfíndọ̀ lo ara rẹ̀ fún Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀?

Ìgbà Tá A Bí Jésù sí Ìgbà Táwọn Àpọ́sítélì Kú

Màríà—“Wò Ó! Ẹrúbìnrin Jèhófà!”

Kí ni ìdáhùn tí Màríà fún Gébúrẹ́lì fi hàn nípa irú ìgbàgbọ́ tó ní? Àwọn ànímọ́ pàtàkì míì wo ló tún fi hàn?

Màríà dé ‘ìparí èrò nínú ọkàn rẹ̀’

Ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù mú kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú àwọn ìlérí Jèhófà túbọ̀ lágbára sí i.

Ó fara da ọgbẹ́ ọkàn

Àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Màríà ìyá Jésù lè ràn wá lọ́wọ́ nígbà tí àwa náà bá dojú kọ ìbànújẹ́ tó fẹ́ dà bí “idà oró.”

Jósẹ́fù Dáàbò Bo Ìdílé Rẹ̀, Ó Pèsè fún Wọn, Ó sì Ní Ìfaradà

Báwo ni Jósẹ́fù ṣe dáàbò bo ìdílé rẹ̀? Kí nìdí tó fi ní láti kó Màríà àti Jésù lọ sí Íjíbítì?

“Màtá—“Mo Ti Gbà Gbọ́”

Kí ni Màtá ṣe tó fi hàn pé ó ní ìgbàgbọ́ tó wúni lórí kódà lásìkò tí ẹ̀dùn ọkàn bá a?

Màríà Magidalénì—“Mo Ti Rí Olúwa!”

Obìnrin olóòótọ́ náà láǹfààní láti sọ ìhìn rere fún àwọn míì.

Pétérù Borí Ìbẹ̀rù àti Iyè Méjì

Iyè méjì burú, ó lè ba ayé ẹni jẹ́. Àmọ́ Pétérù borí ìbẹ̀rù àti iyè méjì tó ní pé bóyá ni òun lè di ọmọ ẹ̀yìn Jésù.

Pétérù Dúró Ṣinṣin Nígbà Ìdánwò

Báwo ni ìgbàgbọ́ Pétérù àti ìdúróṣinṣin rẹ̀ ṣe jẹ́ kó tẹ́wọ́ gba ìtọ́sọ́nà lọ́dọ̀ Jésù?

Pétérù Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Ìdáríjì Lọ́dọ̀ Ọ̀gá Rẹ̀

Kí ni Jésù kọ́ Pétérù nípa ìdáríjì? Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun ti dárí ji Pétérù?

“Ọmọ Mi Olùfẹ́ Ọ̀wọ́n àti Olùṣòtítọ́ Nínú Olúwa”

Kí ló ran Tímótì tó jẹ́ onítìjú èèyàn lọ́wọ́ láti di alábòójútó tó dáńgájíá nínú ìjọ Kristẹni?