TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ ÌGBÀGBỌ́ WỌN | MÍRÍÁMÙ
“Ẹ Kọrin sí Jèhófà”!
Ọmọdébìnrin náà fara pa mọ́ síbi tí ẹnikẹ́ni ò ti lè rí i, ó tẹjú mọ́ ibì kan láàárín àwọn esùsú tó wà níbẹ̀. Ó lẹ̀ mọ́ ibi tó wà, ara ẹ̀ ń wárìrì bí omi Odò Náìlì ṣe rọra ń ṣàn kọjá. Àkókò ń lọ, síbẹ̀ kò kúrò, ó ṣáà tẹjú mọ́ àárín esùsú náà, kò sì wo tàwọn kòkòrò tó ń kùn yùnmù yí i ká. Apẹ̀rẹ̀ kan tí wọ́n fi ọ̀dà kùn kí omi má bàa wọnú ẹ̀ wà níbi tó tẹjú mọ́ láàárín esùsú yẹn; inú ẹ̀ ni wọ́n gbé àbúrò ẹ̀ ọkùnrin sí. Bí ọmọ náà ṣe dá wà nínú apẹ̀rẹ̀ yẹn láìsí ẹnikẹ́ni tó lè ràn án lọ́wọ́ ń bà á nínú jẹ́. Ṣùgbọ́n ó mọ̀ pé ohun tó tọ́ làwọn òbí òun ṣe; ọ̀nà kan ṣoṣo tí wọ́n lè gbà dáàbò bo ọmọ náà nìyẹn lọ́wọ́ wàhálà tó ń ṣẹlẹ̀ lákòókò yẹn.
Ohun tí ọmọbìnrin yẹn ṣe gba ìgboyà gan-an, ó sì tún máa lo ìgboyà tó jùyẹn lọ láìpẹ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ṣì kéré, ó fi hàn pé òun nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. Kò ní pẹ́ tó fi máa ṣe ohun tó fi hàn pé ó nígbàgbọ́, á sì lo ànímọ́ yẹn jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀. Tó bá ti darúgbó lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, ìgbàgbọ́ tó ní á tọ́ ọ sọ́nà ní àkókò tó jẹ́ mánigbàgbé nínú ìtàn àwọn èèyàn ẹ̀. Ìgbàgbọ́ yìí tún máa ràn án lọ́wọ́ lásìkò kan tó ṣe àṣìṣe tó burú jáì. Ta ni ẹni tá à ń sọ̀rọ̀ ẹ̀? Kí la sì lè rí kọ́ nínú bó ṣe lo ìgbàgbọ́?
Míríámù Ọmọ Ẹrú
Bíbélì ò sọ orúkọ ọmọ náà fún wa, ṣùgbọ́n ẹni tá a mọ̀ ni. Míríámù ni, òun ni àkọ́bí àwọn Hébérù kan tó ń jẹ́ Ámúrámù àti Jókébédì, ẹrú sì ni wọ́n nílẹ̀ Íjíbítì. (Nọ́ńbà 26:59) Mósè lorúkọ àbúrò rẹ̀ ọkùnrin. Mósè ni wọ́n bí tẹ̀ lé Áárónì, tó jẹ́ nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́ta nígbà yẹn. A ò lè sọ ọjọ́ orí Míríámù, àmọ́ ó jọ pé kò tíì pé ọmọ ọdún mẹ́wàá nígbà yẹn.
Àkókò tí nǹkan nira gan-an fáwọn Hébérù ni wọ́n bí Míríámù. Torí pé ẹ̀rù àwọn Hébérù ń ba àwọn ará Íjíbítì, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í lo àwọn Hébérù yìí ní ìlò ẹrú, wọ́n sì ń pọ́n wọn lójú. Nígbà tí àwọn ẹrú náà ń pọ̀ sí i, tí wọ́n sì ń lágbára sí i, ẹ̀rù ba àwọn ará Íjíbítì, torí náà wọ́n túbọ̀ máyé nira fún wọn. Ni Fáráò bá pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo ọmọkùnrin àwọn Hébérù tí wọ́n bá ti ń gbẹ̀bí wọn. Àwọn obìnrin méjì tó ń gbẹ̀bí fáwọn Hébérù ni Ṣífúrà àti Púà. Ó dájú pé Míríámù mọ bí wọ́n ṣe lo ìgbàgbọ́, tí wọ́n sì dá ẹ̀mí àwọn ọmọ náà sí dípò kí wọ́n pa wọ́n.—Ẹ́kísódù 1:8-22.
Míríámù rí báwọn òbí rẹ̀ náà ṣe lo ìgbàgbọ́. Lẹ́yìn tí Ámúrámù àti Jókébédì bí ọmọ wọn kẹta, ọmọ náà rẹwà, àmọ́ wọ́n kọ́kọ́ gbé e pa mọ́ fún oṣù mẹ́ta. Wọn ò bẹ̀rù àṣẹ tí ọba pa, kí wọ́n wá torí ẹ̀ pa ọmọ tí wọ́n bí. (Hébérù 11:23) Ṣùgbọ́n kò rọrùn láti gbé ọmọ pa mọ́, torí náà, ó gba pé kí wọ́n ṣe ìpinnu kan tó nira gan-an. Jókébédì ní láti gbé ọmọ náà síbi tí ẹni tó lè dáàbò bò ó tó sì máa tọ́ ọ dàgbà á ti rí i. Ẹ wo bó ti ní láti gbàdúrà kíkankíkan tó bó ṣe ń fi esùsú ṣe apẹ̀rẹ̀, tó fi ọ̀dà bítúmẹ́nì dídì àti ọ̀dà bítúmẹ́nì rírọ̀ kùn ún kí omi má bàa wọnú rẹ̀, lẹ́yìn náà tó gbé ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n sínú apẹ̀rẹ̀ náà, tó sì wá gbé e sínú Odò Náílì! Ó dájú pé òun ló ní kí Míríámù dúró síbẹ̀ kó lè rí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ọmọ náà.—Ẹ́kísódù 2:1-4.
Míríámù Dáàbò Bo Mósè
Torí náà, Míríámù dúró síbẹ̀. Nígbà tó yá, ó gbúròó àwọn èèyàn kan tó ń bọ̀. Àwọn obìnrin mélòó kan ni. Wọn kì í sì í ṣe èèyàn lásán nílẹ̀ Íjíbítì. Ọmọbìnrin Fáráò àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ obìnrin ni, wọ́n wá wẹ̀ nínú Odò Náílì. Ó ṣeé ṣe kí àyà Míríámù kọ́kọ́ já. Ṣé ó tiẹ̀ máa rò ó pé ọmọbìnrin Fáráò á tẹ àṣẹ ọba lójú, á sì dá ẹ̀mí ọmọ náà sí? Ó dájú pé Míríámù gbàdúrà kíkankíkan sí Jèhófà lásìkò yẹn.
Ọmọbìnrin Fáráò ló kọ́kọ́ rí apẹ̀rẹ̀ tó wà láàárín esùsú náá. Ó wá rán ẹrúbìnrin ẹ̀ pé kó lọ gbé e wá. Àkọsílẹ̀ yẹn wá sọ nípa ọmọbìnrin Fáráò pé: “Nígbà tó ṣí apẹ̀rẹ̀ náà, ó rí ọmọ náà, ọmọ náà sì ń sunkún.” Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn tètè yé e pé ọ̀kan lára àwọn obìnrin Hébérù ló ń gbìyànjú láti dá ẹ̀mí ọmọ ẹ̀ sí. Ṣùgbọ́n, àánú ọmọ tó rẹwà náà ṣe ọmọbìnrin Fáráò. (Ẹ́kísódù 2:5, 6) Míríámù tó ń wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ rí i lójú obìnrin náà pé ó wù ú kó ran ọmọ náà lọ́wọ́. Ó rí i pé àkókò yẹn gan-an ló yẹ kóun lo ìgbàgbọ́ tóun ní nínú Jèhófà. Ó lo ìgboyà, ó sì bá ọmọbìnrin Fáráò àtàwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ sọ̀rọ̀.
A ò lè sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ẹrú kan tó jẹ́ Hébérù tó bá gbójú-gbóyà lọ bá ọmọ ọba sọ̀rọ̀. Síbẹ̀, Míríámù bi ọmọbìnrin Fáráò tààràtà pé: “Ṣé kí n lọ bá ọ pé obìnrin Hébérù kan tó máa bá ọ tọ́jú ọmọ náà wá?” Ìbéèrè tó mọ́gbọ́n dání gan-an nìyẹn. Ọmọbìnrin Fáráò mọ̀ pé òun ò ní lè tọ́jú ọmọ náà. Ó sì lè ronú pé bóyá á kúkú sàn kí ọmọ náà dàgbà láàárín àwọn èèyàn ẹ̀, lẹ́yìn náà, òun á mú un wá sílé òun, òun á sì sọ ọ́ di ọmọ òun. Ìyẹn á sì lè jẹ́ kóun tọ́ ọ dáadáa, kóun sì rán an níléèwé. Ó dájú pé inú Míríámù dùn gan-an nígbà tí ọmọbìnrin Fáráò sọ pé: “Lọ pè é wá!”—Ẹ́kísódù 2:7, 8.
Míríámù lo ìgboyà bó ṣe ń ṣọ́ àbúrò rẹ̀ kí ohunkóhun máa bàa ṣe é
Míríámù sáré lọ bá àwọn òbí ẹ̀ tí wọ́n ti ń ṣàníyàn. Ẹ wo bí inú ẹ̀ á ṣe dùn tó bó ṣe ń ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ fún màmá ẹ̀. Ó dá Jókébédì lójú pé Jèhófà lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ náà. Torí náà, kíá ló tẹ̀ lé Míríámù lọ sọ́dọ̀ ọmọbìnrin Fáráò. Nígbà tí ọmọbìnrin Fáráò sọ fún Jókébédì pé: “Gbé ọmọ yìí lọ kí o máa bá mi tọ́jú rẹ̀, màá sì sanwó fún ọ,” inú ẹ̀ dùn, ọkàn ẹ̀ sì balẹ̀. Ṣùgbọ́n ó ṣeé ṣe kó má jẹ́ kó hàn lójú òun.—Ẹ́kísódù 2:9.
Míríámù kọ́ ẹ̀kọ́ tó pọ̀ nípa Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ lọ́jọ́ yẹn. Ó kẹ́kọ̀ọ́ pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn rẹ̀, ó sì máa ń tẹ́tí sí àdúrà wọn. Ó tún kẹ́kọ̀ọ́ pé kì í ṣe àwọn àgbàlagbà tàbí àwọn ọkùnrin nìkan ló máa ń nígboyà àti ìgbàgbọ́. Jèhófà máa ń tẹ́tí sí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́. (Sáàmù 65:2) Ó sì yẹ kí gbogbo àwa tá à ń sìn ín lónìí, lọ́mọdé lágbà, lọ́kùnrin àti lóbìnrin máa rántí èyí láwọn àkókò líle koko yìí.
Míríámù, Ẹ̀gbọ́n Tó Ní Sùúrù
Jókébédì tọ́ ọmọ náà, ó sì bójú tó o. Torí pé Míríámù ló ṣe ohun tó gbẹ̀mí àbúrò rẹ̀ là, ó dájú pé á fẹ́ràn rẹ̀ gan-an. Ó ṣeé ṣe kí òun náà kọ́ ọ ní ọ̀rọ̀ sísọ, inú ẹ̀ á sì dùn nígbà tó kọ́kọ́ pe orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀. Nígbà tí Mósè dàgbà díẹ̀, àkókò ti wá tó láti gbé e lọ sọ́dọ̀ ọmọbìnrin Fáráò. (Ẹ́kísódù 2:10) Ó dájú pé bí Mósè ò ṣe ní sí lọ́dọ̀ àwọn òbí àtẹ̀gbọ́n rẹ̀ mọ́ yìí máa dùn wọ́n gan-an. Míríámù á sì ti máa hára gàgà láti mọ bí Mósè, gẹ́gẹ́ bí orúkọ tí ọmọbìnrin Fáráò fún un, ṣe máa rí tó bá dàgbà di géńdé! Ṣé á ṣì máa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà bó ṣe ń dàgbà nílé ọba ilẹ̀ Íjíbítì?
Ìdáhùn ìbéèrè yìí ṣe kedere nígbà tó yá. Ó dájú pé inú Míríámù dùn gan-an nígbà tó mọ̀ pé àbúrò òun dàgbà di géńdé, ó sì pinnu láti sin Ọlọ́run rẹ̀ dípò kó lo àǹfààní tó ní láti máa jayé ọba nínú ilé Fáráò! Nígbà tí Mósè pé ẹni ogójì (40) ọdún, ó gbèjà àwọn èèyàn ẹ̀. Ó pa ọmọ Íjíbítì kan torí pé ó fìyà jẹ ẹrú kan tó jẹ́ Hébérù. Mósè mọ̀ pé wọ́n lè torí ìyẹn pa òun, torí náà ó sá kúrò ní Íjíbítì.—Ẹ́kísódù 2:11-15; Ìṣe 7:23-29; Hébérù 11:24-26.
Ó ṣeé ṣe kí Míríámù má gbúròó àbúrò rẹ̀ mọ́ ní gbogbo ogójì ọdún tí Mósè fi gbé nílẹ̀ àjèjì. Ilẹ̀ Mídíánì ni Mósè sá lọ, ibẹ̀ sì jìn gan-an, iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn ló ń ṣe níbẹ̀. (Ẹ́kísódù 3:1; Ìṣe 7:29, 30) Míríámù fi sùúrù dúró títí tó fi darúgbó, ó sì rí bí ìyà tí wọ́n fi ń jẹ àwọn èèyàn ẹ̀ ṣe ń pọ̀ sí i.
Míríámù Wòlíì Obìnrin
Ó ṣeé ṣe kí Míríámù ti lé lẹ́ni ọgọ́rin (80) ọdún nígbà tí Ọlọ́run rán Mósè pa dà láti wá gba àwọn èèyàn Rẹ̀ sílẹ̀. Áárónì ló ṣe agbẹnusọ fún Mósè, àwọn àbúrò Míríámù méjèèjì yìí ni wọ́n sì lọ bá Fáráò kí wọ́n lè sọ fún un pé kó jẹ́ káwọn èèyàn Ọlọ́run lọ. Míríámù ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ ní gbogbo àsìkò tí Fáráò kọ̀ jálẹ̀ tí ò jẹ́ káwọn èèyàn náà lọ. Wọ́n ń pa dà lọ sọ́dọ̀ Fáráò ṣáá, bí Jèhófà ṣe ń mú ìyọnu mẹ́wàá wá sórí Íjíbítì láti kìlọ̀ fún wọn. Nígbà tó dorí ìyọnu tó kẹ́yìn, ìyẹn nígbà tí gbogbo ọmọkùnrin tó jẹ́ àkọ́bí nílẹ̀ Íjíbítì kú. Àkókò ti wá tó fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti jáde kúrò nílẹ̀ Íjíbítì! Ẹ wo bí Míríámù á ṣe máa ṣiṣẹ́ kára láti ran àwọn èèyàn ẹ̀ lọ́wọ́ nígbà tí Mósè mú wọn jáde kúrò nílẹ̀ Íjíbítì.—Ẹ́kísódù 4:14-16, 27-31; 7:1–12:51.
Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì há sáàárín Òkun Pupa àti àwọn ọmọ ogun Íjíbítì, Míríámù rí i tí àbúrò rẹ̀ dúró níwájú òkun náà, tó sì na ọ̀pá rẹ̀ sókè. Òkun náà pínyà! Bí Míríámù ṣe ń wo àbúrò rẹ̀ tó ń mú àwọn èèyàn náà gba orí ilẹ̀ gbígbẹ kọjá láàárín òkun, ó dájú pé ìgbàgbọ́ tó ní nínú Jèhófà máa lágbára ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ó mọ̀ pé Ọlọ́run tóun ń sìn lè ṣe ohun gbogbo, ó sì lè mú gbogbo ìlérí rẹ̀ ṣẹ!—Ẹ́kísódù 14:1-31.
Lẹ́yìn tí àwọn èèyàn náà ti sọdá láyọ̀, tí omi sì ya bo Fáráò àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀, Míríámù rí i pé Jèhófà lágbára ju àwọn ọmọ ogun tó lágbára jù lọ láyé. Èyí mú káwọn èèyàn náà kọ orin kan sí Jèhófà. Míríámù ló ṣáájú àwọn obìnrin tó ń kọrin sí Jèhófà pé: “Ẹ kọrin sí Jèhófà, torí ó ti di ẹni àgbéga. Ó taari ẹṣin àti ẹni tó gùn ún sínú òkun.”—Ẹ́kísódù 15:20, 21; Sáàmù 136:15.
Ọlọ́run mí sí Míríámù láti ṣáájú àwọn obìnrin Ísírẹ́lì nínú orin ìṣẹ́gun tí wọ́n kọ ní Òkun Pupa
Míríámù ka ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn sí ohun tó ṣe pàtàkì gan-an, kò sì jẹ́ gbàgbé rẹ̀ láé. Ibi tí Bíbélì bá ìtàn náà dé nìyí tó fi pe Míríámù ní wòlíì obìnrin. Míríámù sì ni obìnrin àkọ́kọ́ tí Bíbélì pè bẹ́ẹ̀. Míríámù wà lára ìwọ̀nba àwọn obìnrin tó sin Jèhófà nírú ọ̀nà àkànṣe yìí.—Onídàájọ́ 4:4; 2 Àwọn Ọba 22:14; Àìsáyà 8:3; Lúùkù 2:36.
Bíbélì tipa bẹ́ẹ̀ rán wa létí pé Jèhófà ń wò wá, ó sì ṣe tán láti bù kún àwọn nǹkan tá à ń ṣe nínú ìjọsìn rẹ̀, títí kan bá a ṣe ń ní sùúrù tá a sì ń yin orúkọ rẹ̀ lógo. Bóyá ọmọdé ni wá tàbí àgbàlagbà, ọkùnrin tàbí obìnrin, a lè lo ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà. Irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ máa ń mú inú rẹ̀ dùn; kì í gbàgbé rẹ̀, ó sì máa san ẹni tó bá ní irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ lẹ́san. (Hébérù 6:10; 11:6) Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì pé ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Míríámù!
Míríámù Agbéraga
Ìbùkún wà nínú kéèyàn ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn, ewu sì tún wà níbẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Míríámù ni obìnrin tó gbajúmọ̀ jù láàárín àwọn obìnrin Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n kúrò lóko ẹrú. Ṣé ìyẹn á mú kó di agbéraga tàbí kó máa wá ipò ọlá? (Òwe 16:18) Ó ṣeni láàánú pé ohun tó ṣẹlẹ̀ fúngbà díẹ̀ nìyẹn.
Ní oṣù díẹ̀ lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò nílẹ̀ Íjíbítì, Mósè gba àwọn èèyàn kan tó wá láti ibi tó jìnnà lálejò. Jẹ́tírò bàbá ìyàwó Mósè ni, àmọ́ nígbà tó ń bọ̀, ó mú Sípórà ìyàwó Mósè àtàwọn ọmọ wọn ọkùnrin méjì dání. Ìgbà tí Mósè lo ogójì (40) ọdún nílẹ̀ Mídíánì ló fẹ́ ẹ. Sípórà ti kọ́kọ́ pa dà sọ́dọ̀ ìdílé rẹ̀ nílẹ̀ Mídíánì, bóyá torí kó lè lọ bẹ̀ wọ́n wò, àmọ́ bàbá rẹ̀ ti mú un wá síbi táwọn ọmọ Ísírẹ́lì pàgọ́ sí báyìí. (Ẹ́kísódù 18:1-5) Ẹ wo bó ṣe máa rí lára àwọn Hébérù yẹn nígbà táwọn ará Mídíánì náà dé sáàárín wọn! Ó ṣée ṣe kára ọ̀pọ̀ lára wọn ti wà lọ́nà láti mọ ìyàwó ọkùnrin tí Ọlọ́run yàn láti mú wọn kúrò nílẹ̀ Íjíbítì.
Ṣé inú Míríámù náà dùn láti rí Sípórà? Ó ṣeé ṣe kí inú ẹ̀ dùn nígbà tó kọ́kọ́ rí i. Ṣùgbọ́n ó jọ pé nígbà tó yá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga. Ó lè ti máa bẹ̀rù, kó máa ronú pé Sípórà á gbapò òun, á sì di obìnrin tó gbajúmọ̀ jù lórílẹ̀-èdè náà. Lọ́rọ̀ kan ṣáá, Áárónì àti Míríámù sọ̀rọ̀ Sípórà láìdáa. Bí irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ sì ṣe máa ń rí, kò pẹ́ tó fi di àríwísí tó sì dá ìkórìíra sílẹ̀. Ọ̀rọ̀ Sípórà ni wọ́n kọ́kọ́ ń sọ, wọ́n ṣàròyé pé kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì, pé ọmọ ilẹ̀ Kúṣì ni. * Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọ́n bá a débi tí wọ́n fi ń sọ̀rọ̀ Mósè náà láìdáa. Míríámù àti Áárónì ń sọ pé: “Ṣé ẹnu Mósè nìkan ni Jèhófà gbà sọ̀rọ̀ ni? Ṣé kò gbẹnu tiwa náà sọ̀rọ̀ ni?”—Nọ́ńbà 12:1, 2.
Míríámù Di Adẹ́tẹ̀
Ọ̀rọ̀ tí Míríámù àti Áárónì sọ yẹn jẹ́ ká rí i pé ohun tí ò dáa ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbilẹ̀ lọ́kàn wọn. Bí Jèhófà ṣe ń lo Mósè ò tẹ́ wọn lọ́rùn mọ́, torí náà wọ́n ń fẹ́ ọlá àṣẹ àti agbára tó pọ̀ sí i fún ara wọn. Ṣé Mósè ń jẹ gàba lé wọn lórí tó sì ń gbéra ga ni? Òótọ́ ni pé ó ní àwọn àlébù tiẹ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe ẹni tó ń wá ipò ọlá, kò sì gbéra ga. Àkọsílẹ̀ tí Ọlọ́run mí sí sọ pé: “Ọkùnrin náà, Mósè, ló jẹ́ oníwà pẹ̀lẹ́ jù lọ nínú gbogbo èèyàn tó wà láyé.” Lédè kan ṣáá, Míríámù àti Áárónì ti kọjá àyè wọn, wọ́n sì ti fira wọn sínú ewu. Ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ pé, ‘Jèhófà ń fetí sílẹ̀.’—Nọ́ńbà 12:2, 3.
Ṣàdédé ni Jèhófà ní káwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà lọ síwájú àgọ́ ìpàdé. Nígbà tí wọ́n débẹ̀, ọwọ̀n ìkùukùu tó ṣàpẹẹrẹ pé Jèhófà wà níbẹ̀ sọ̀ kalẹ̀, ó sì dúró sẹ́nu ọ̀nà. Lẹ́yìn náà ni Jèhófà sọ̀rọ̀. Ó bá Míríámù àti Áárónì wí, ó sì rán wọn létí pé òun ní àjọṣe tó ṣàrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú Mósè àti pé iṣẹ́ pàtàkì ni òun gbé lé e lọ́wọ́. Jèhófà wá bi wọ́n pé: “Kí wá nìdí tí ẹ̀rù ò fi bà yín láti sọ̀rọ̀ tí kò dáa sí Mósè ìránṣẹ́ mi?” Ó dájú pé ṣe ni Míríámù àti Áárónì á máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ bí Jèhófà ṣe ń bá wọn sọ̀rọ̀. Jèhófà gbà pé òun fúnra òun ni wọ́n ń rín fín, kì í ṣe Mósè.—Nọ́ńbà 12:4-8.
Ó dájú pé Míríámù ló bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ burúkú yẹn kó tó di pé àbúrò ẹ̀ náà dara pọ̀ mọ́ ọn láti ṣàríwísí ìyàwó àbúrò wọn. Ìyẹn lè jẹ́ ká lóye ìdí tó fi jẹ́ pé Míríámù ni Jèhófà fìyà jẹ. Ṣe ni Jèhófà fi àrùn ẹ̀tẹ̀ kọ lù ú. Àrùn burúkú yẹn mú kí ara ẹ̀ “funfun bíi yìnyín.” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ Áárónì rẹ ara ẹ̀ sílẹ̀ níwájú Mósè, ó sì ń bẹ̀ ẹ́ pé kó bá àwọn bẹ Jèhófà. Ó ní: “Ìwà òmùgọ̀ gbáà la hù yìí.” Torí pé Mósè jẹ́ oníwà pẹ̀lẹ́, ó ké pe Jèhófà, ó ní: “Ọlọ́run, jọ̀ọ́ mú un lára dá! Jọ̀ọ́!” (Nọ́ńbà 12:9-13) Bí Mósè àti Áárónì ṣe banú jẹ́ tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ nítorí Míríámù fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ẹ̀gbọ́n wọn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣàṣìṣe.
Ọlọ́run Wo Míríámù Sàn
Jèhófà fi àánú hàn. Ó mú Míríámù lára dá torí pé ó ronú pìwà dà. Ṣùgbọ́n ó sọ pé kí wọ́n kọ́kọ́ sé e mọ́ ẹ̀yìn ibùdó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún ọjọ́ méje. Ó ti ní láti nira gan-an fún Míríámù láti ṣègbọràn, torí ojú á máa tì í bó ṣe ń jáde lọ sí ẹ̀yìn ibùdó. Ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ tó ní mú un lára dá. Ó mọ̀ dáadáa lọ́kàn rẹ̀ pé olódodo ni Jèhófà Bàbá òun, àti pé ṣe ló ń bá òun wí torí pé ó nífẹ̀ẹ́ òun. Torí náà, ó ṣe ohun tí Ọlọ́run ní kó ṣe. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò ṣí kúrò títí ọjọ́ méje tó fi dá wà náà fi kọjá. Lẹ́yìn náà, Míríámù tún lo ìgbàgbọ́ bó ṣe gbà láì janpata pé kí wọ́n mú òun “pa dà wọlé.”—Nọ́ńbà 12:14, 15.
Àwọn tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ló máa ń bá wí. (Hébérù 12:5, 6) Ó fẹ́ràn Míríámù, ó sì bá a wí torí pé ó gbéra ga. Ìbáwí yẹn ò rọrùn, ṣùgbọ́n ohun tó gbà á là nìyẹn. Torí pé ó fi ọkàn tó dáa gba ìbáwí náà, ó pa dà rí ojúure Ọlọ́run. Ó ṣì wà láàyè títí di apá iparí ìrìn àjò àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nínú aginjù. Nígbà tó kú ní Kádéṣì tó wà ní aginjù Síínì, ó ti ń sún mọ́ ẹni àádóje (130) ọdún. * (Nọ́ńbà 20:1) Ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn náà, ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí Míríámù mú kó sọ ohun tó dáa nípa iṣẹ́ ìsìn tó fòótọ́ ṣe. Ó rán àwọn èèyàn rẹ̀ létí nípasẹ̀ wòlíì Míkà pé: “Mo rà yín pa dà lóko ẹrú, mo rán Mósè, Áárónì àti Míríámù sí yín.”—Míkà 6:4.
Ìgbàgbọ́ tí Míríámù ní ràn án lọ́wọ́ láti fìrẹ̀lẹ̀ gba ìbáwí Jèhófà
A lè rí ohun púpọ̀ kọ́ nínú ìgbésí ayé Míríámù. Ó yẹ ká máa dáàbò bo àwọn tí kò lólùgbèjà, ká sì fìgboyà sọ òótọ́ ọ̀rọ̀ bó ṣe ṣe nígbà tó ṣì kéré. (Jémíìsì 1:27) Bíi ti Míríámù, ó yẹ ká fi tayọ̀tayọ̀ sọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn. (Róòmù 10:15) Bíi ti Míríámù, a gbọ́dọ̀ yẹra fún owú àti ìbínú kíkorò. (Òwe 14:30) Ó sì yẹ ká fìrẹ̀lẹ̀ gba ìbáwí Jèhófà bíi tiẹ̀. (Hébérù 12:5) Bí a bá ṣe ń ṣe gbogbo nǹkan yìí, ṣe là ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Míríámù.
^ ìpínrọ̀ 21 Ní ti Sípórà, ohun tí “ọmọ ilẹ̀ Kúṣì” túmọ̀ sí ni pé bíi ti àwọn ará Mídíánì yòókù, Arébíà ló ti wá, kì í ṣe Etiópíà.
^ ìpínrọ̀ 26 Nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, Míríámù tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n pátápátá ló kọ́kọ́ kú, lẹ́yìn náà ni Áárónì kú, Mósè tó jẹ́ àbígbẹ̀yìn ló kú kẹ́yìn. Àárín ọdún kan làwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì kú.