Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ ÌGBÀGBỌ́ WỌN | JÓNÁTÁNÌ

Wọ́n Di Ọ̀rẹ́ Tímọ́tímọ́

Wọ́n Di Ọ̀rẹ́ Tímọ́tímọ́

Wọ́n ti jagun tán, gbogbo Àfonífojì Élà pa rọ́rọ́. Atẹ́gùn ọ̀sán rọra ń fẹ́ lu aṣọ àgọ́ àwọn ọmọ ogun, Sọ́ọ̀lù Ọba wá pe ìpàdé àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Jónátánì, ọmọkùnrin rẹ̀ àgbà wà níbẹ̀, ọ̀dọ́kùnrin kan tó jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn náà wà níbẹ̀, tó ń fayọ̀ ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i. Dáfídì ni ọ̀dọ́kùnrin yẹn, ó nítara, ara ẹ̀ sì yá gágá. Sọ́ọ̀lù fara balẹ̀ tẹ́tí sí ohun tó ń sọ, gbogbo ọ̀rọ̀ ẹ̀ ló ń fiyè sí lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan. Àmọ́ báwo lohun tó ṣẹlẹ̀ ṣe rí lára Jónátánì? Ọjọ́ pẹ́ tó ti ń jagun fún Jèhófà, ọ̀pọ̀ ogun ló sì ti ṣẹ́. Àmọ́ lọ́jọ́ tá à ń wí yìí, òun kọ́ ló ṣẹ́gun, ọ̀dọ́kùnrin yìí ló ṣẹ́gun. Dáfídì rẹ́yìn Gòláyátì akíkanjú! Ṣé Jónátánì wá ń jowú torí bí wọ́n ṣe ń yin Dáfídì ni?

Ohun tí Jónátánì ṣe lè yà ẹ́ lẹ́nu. Bíbélì sọ pé: “Gbàrà tí Dáfídì bá Sọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ tán, Jónátánì àti Dáfídì wá di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, Jónátánì sì bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ bí ara rẹ̀.” Jónátánì kó àwọn ohun ìjà rẹ̀ fún Dáfídì, tó fi mọ́ ọrun tó fi máa ń ta ọfà, ẹ̀bùn ńlá sì nìyẹn, torí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ Jónátánì sí tafàtafà tó já fáfá. Yàtọ̀ síyẹn, Jónátánì àti Dáfídì dá májẹ̀mú, wọ́n bára wọn ṣe àdéhùn tó sọ wọ́n di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ tí ò ní dalẹ̀ ara wọn.​—1 Sámúẹ́lì 18:1-5.

Báwọn méjèèjì ṣe di ọ̀rẹ́ nìyẹn, ọ̀rẹ́ wọn sì wà lára àwọn ọ̀rẹ́ tó dáa jù lọ tí Bíbélì sọ̀rọ̀ rẹ̀. Àwọn tó bá nígbàgbọ́ mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì káwọn ní ọ̀rẹ́. Tá a bá fọgbọ́n yan àwọn tá a máa mú lọ́rẹ̀ẹ́, tá a sì jẹ́ adúrótini tí kì í dalẹ̀ ọ̀rẹ́, ó máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára lásìkò tí ìfẹ́ wọ́n lóde yìí. (Òwe 27:17) Ẹ jẹ́ ká wá wo ohun tá a lè kọ́ lára Jónátánì tó bá dọ̀rọ̀ ká lọ́rẹ̀ẹ́.

Ohun Tó Pilẹ̀ Ọ̀rẹ́ Wọn

Kí ló jẹ́ káwọn méjèèjì yára di ọ̀rẹ́ bẹ́yẹn? Ohun tí wọ́n fi pilẹ̀ ọ̀rẹ́ wọn ni. Wò ó báyìí ná. Nǹkan ò rọrùn fún Jónátánì rárá lásìkò yẹn. Sọ́ọ̀lù Ọba tó jẹ́ bàbá rẹ̀ ti yí pa dà di èèyàn burúkú, kódà, ńṣe lọ̀rọ̀ ẹ̀ tún ń burú sí i. Bẹ́ẹ̀ sì rèé nígbà kan, onírẹ̀lẹ̀ ni, ó máa ń ṣègbọràn, ó sì nígbàgbọ́. Àmọ́ ní báyìí, ó ti di onínúfùfù àti aláìgbọràn.​—1 Sámúẹ́lì 15:17-19, 26.

Bí Sọ́ọ̀lù ṣe dìdàkudà yìí á ti máa kó ìrònú bá Jónátánì gan-an, torí òun àti bàbá rẹ̀ sún mọ́ra. (1 Sámúẹ́lì 20:2) Ó ṣeé ṣe kí Jónátánì máa ronú ìpalára tí Sọ́ọ̀lù máa ṣe fún orílẹ̀-èdè tí Jèhófà yàn. Ṣé àìgbọràn ọba yìí ò ní kó àwọn èèyàn náà ṣìnà, kí wọ́n má sì rí ojúure Jèhófà? Kò sí àní-àní pé àkókò yẹn ò rọrùn fún Jónátánì, ọkùnrin tó nígbàgbọ́ yìí.

Ìyẹn lè jẹ́ ká rí ohun tó fa Jónátánì sún mọ́ Dáfídì tó jẹ́ ọ̀dọ́. Jónátánì rí i pé ìgbàgbọ́ Dáfídì lágbára gan-an. Ẹ má gbàgbé pé Dáfídì ò bẹ̀rù bíi tàwọn ọmọ ogun Sọ́ọ̀lù, ó nígboyà láìka bí Gòláyátì ṣe rí fàkìà fakia tó. Ó gbà pé bóun ṣe gbẹ́kẹ̀ lé orúkọ Jèhófà máa jẹ́ kóun lágbára ju Gòláyátì àti gbogbo ohun ìjà tó kó wá sójú ogun.​—1 Sámúẹ́lì 17:45-47.

Irú èrò kan náà ni Jónátánì ní lọ́dún mélòó kan ṣáájú ìgbà yẹn. Ó dá òun náà lójú pé òun àti ẹni tó ń bá òun gbé ohun ìjà máa lè dojú kọ àwùjọ àwọn ọmọ ogun tó dira ogun, káwọn sì borí. Kí ló mú kó gbà bẹ́ẹ̀? Jónátánì sọ pé, “Kò sí ohun tó lè dí Jèhófà lọ́wọ́.” (1 Sámúẹ́lì 14:6) Torí náà, àwọn ohun kan wà tó mú kí ọ̀rọ̀ Jónátánì àti Dáfídì jọra, ìyẹn ni pé wọ́n nígbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an. Ohun tó dáa jù lọ tó lè mú kí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ náà nìyẹn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé akíkanjú ọmọ ọba ni Jónátánì, ó sì ti ń sún mọ́ àádọ́ta (50) ọdún, nígbà tó jẹ́ pé olùṣọ́ àgùntàn onírẹ̀lẹ̀ tó ṣeé ṣe kó má tíì pé ẹni ogún (20) ọdún ni Dáfídì, síbẹ̀ àwọn méjèèjì ò ka irú ẹni tí wọ́n jẹ́ àtọjọ́ orí wọn tó yàtọ̀ síra sí. *

Májẹ̀mú tí àwọn méjèèjì dá jẹ́ kí okùn ọ̀rẹ́ wọn yi gan-an. Lọ́nà wo? Ẹ má gbàgbé pé Dáfídì mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ kí òun dà lọ́jọ́ iwájú, ó mọ̀ pé òun ni ọba kàn ní Ísírẹ́lì. Ṣé ó wá fi ọ̀rọ̀ yẹn pa mọ́ fún Jónátánì? Bóyá ni! Tí àwọn méjì bá máa ṣe ọ̀rẹ́ tó nítumọ̀ bíi tiwọn, tí okùn ọ̀rẹ́ wọn á sì yi, kò yẹ kí wọ́n máa fi nǹkan pa mọ́ fúnra wọn tàbí kí wọ́n máa parọ́ fúnra wọn. Ṣe ló yẹ kí wọ́n máa bára wọn sọ̀rọ̀ dáadáa. Báwo lẹ rò pé ó ṣe máa rí lára Jónátánì tó bá mọ̀ pé Dáfídì ni ọba kàn? Tó bá lọ jẹ́ pé Jónátánì ti ń rò ó pé lọ́jọ́ kan, òun máa di ọba, tóun á sì tún àwọn nǹkan tí bàbá òun ti bà jẹ́ ṣe ńkọ́? Bíbélì ò sọ nǹkan kan nípa bóyá inú Jónátánì ò dùn pé ọba ò ní kan òun, tó wá ń pa á mọ́ra. Ohun tó ṣe pàtàkì tí Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ ni pé Jónátánì jẹ́ adúróṣinṣin, ó sì nígbàgbọ́. Ó rí i pé ẹ̀mí Jèhófà wà lára Dáfídì. (1 Sámúẹ́lì 16:1, 11-13) Torí náà, Jónátánì mú ìlérí tó ṣe ṣẹ, kò sì wo Dáfídì bí ẹni tó ń bá òun du ipò, àmọ́ ó ń wò ó bí ọ̀rẹ́. Ohun tó wu Jónátánì ò ju pé kí ìfẹ́ Jèhófà ṣẹ.

Ohun tó mú kí ọ̀rọ̀ Jónátánì àti Dáfídì jọra ni ìgbàgbọ́ tó lágbára tí wọ́n ní nínú Jèhófà àti ìfẹ́ tó jinlẹ̀ tí wọ́n ní sí i

Ibi ire gbáà ni ọ̀rẹ́ táwọn méjèèjì ń ṣe já sí. Kí la rí kọ́ lára ìgbàgbọ́ tí Jónátánì ní? Ó yẹ kí gbogbo àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run rí bó ṣe ṣe pàtàkì tó pé kí wọ́n lọ́rẹ̀ẹ́. Kò pọn dandan kí àwa àti ọ̀rẹ́ wa jẹ́ ọjọ́ orí kan náà, tàbí ká jọ wá láti ibì kan náà, àmọ́ tí àwọn ọ̀rẹ́ wa bá nígbàgbọ́ tó jinlẹ̀, àǹfààní ńlá ni wọ́n máa ṣe wá. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jónátánì àti Dáfídì fún ara wọn lókun, tí wọ́n sì gbé ara wọn ró. Ìyẹn sì ràn wọ́n lọ́wọ́ gan-an nígbà tí ọ̀rẹ́ tí wọ́n ń bára wọn ṣe gbé wọn pàdé àwọn àdánwò tó lágbára.

Ta Ni Wọ́n Máa Jẹ́ Olóòótọ́ Sí?

Níbẹ̀rẹ̀, Sọ́ọ̀lù nífẹ̀ẹ́ Dáfídì gan-an, ó sì fi ṣe olórí ogun rẹ̀. Àmọ́ kò pẹ́ tí Sọ́ọ̀lù dẹni tó ní ìwà burúkú kan tí Jónátánì ò gbà kó jọba lọ́kàn rẹ̀ ní tiẹ̀, ìyẹn ni owú. Ṣe ni Dáfídì ń ṣẹ́gun àwọn Filísínì tó jẹ́ ọ̀tá Ísírẹ́lì lọ ràì. Ìyẹn mú káwọn èèyàn máa kókìkí Dáfídì, kí wọ́n sì gba tiẹ̀. Kódà, àwọn obìnrin kan ní Ísírẹ́lì kọ ọ́ lórin pé: “Sọ́ọ̀lù ti pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀tá,àmọ́ Dáfídì pa ẹgbẹẹgbàárùn-ún ọ̀tá.” Inú Sọ́ọ̀lù ò dùn sí orin tí wọ́n ń kọ yẹn. Bíbélì sọ pé, “Láti ọjọ́ yẹn lọ, ìgbà gbogbo ni Sọ́ọ̀lù ń wo Dáfídì tìfuratìfura.” (1 Sámúẹ́lì 18:7, 9) Ẹ̀rù ń bà á pé Dáfídì lè fẹ́ gba ipò ọba mọ́ òun lọ́wọ́. Ìwà òmùgọ̀ ló hù yẹn. Lóòótọ́, Dáfídì mọ̀ pé òun lóun máa di ọba lẹ́yìn Sọ́ọ̀lù, àmọ́ kò rò ó rí pé kóun gbapò lọ́wọ́ ọba tí Jèhófà fòróró yàn nígbà tí ọba náà ṣì wà lórí oyè!

Sọ́ọ̀lù wá dá a bí ọgbọ́n, kí Dáfídì lè kú sógun, àmọ́ irọ́ ni, kò rí i ṣe. Ṣe ni Dáfídì kàn ń ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá lọ, àwọn èèyàn sì túbọ̀ ń gba tiẹ̀. Ohun tí Sọ́ọ̀lù wá gbìyànjú àtiṣe ni pé kó kó agbo ilé rẹ̀ sòdí, látorí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ dórí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tó dàgbà jù, kí gbogbo wọn lè gbìmọ̀ pọ̀ láti pa Dáfídì! Ẹ wo bó ṣe máa ká Jónátánì lára tó pé bàbá òun lè ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀! (1 Sámúẹ́lì 18:25-30; 19:1) Jónátánì nífẹ̀ẹ́ bàbá rẹ̀, kò sì fẹ́ dalẹ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀. Níbi tọ́rọ̀ dé yìí, ta ló máa wá jẹ́ olóòótọ́ sí?

Jónátánì sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀, ó ní: “Kí ọba má ṣàìdáa sí Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ̀, nítorí kò ṣẹ̀ ọ́, àwọn ohun tó ṣe fún ọ sì ti ṣe ọ́ láǹfààní. Ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wewu kó lè pa Filísínì náà, tí Jèhófà sì mú kí gbogbo Ísírẹ́lì ṣẹ́gun lọ́nà tó kàmàmà. O rí i, inú rẹ sì dùn gan-an. Kí ló wá dé tí o fẹ́ fi pa Dáfídì láìnídìí?” Ó yani lẹ́nu pé Sọ́ọ̀lù gbọ́ ti Jónátánì nírú àsìkò yìí, kódà ó búra pé òun ò ní ṣèpalára kankan fún Dáfídì. Àmọ́ Sọ́ọ̀lù ò mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Nígbà tó yá, tí ọwọ́ Dáfídì tún mókè sí i lójú ogun, ìbínú mú kí Sọ́ọ̀lù jowú rẹ̀ débi pé ó ju ọ̀kọ̀ lù ú! (1 Sámúẹ́lì 19:4-6, 9, 10) Àmọ́ Dáfídì yẹ̀ ẹ́, ó sì sá kúrò ní ààfin Sọ́ọ̀lù.

Ṣé ó ti ṣe ẹ́ rí pé o ò mọ ti ẹni tó ò bá ṣe? Ó máa ń dunni gan-an. Nírú àsìkò yẹn, àwọn kan máa gbà ẹ́ nímọ̀ràn pé ti ìdílé ẹni ló yẹ kéèyàn fi sákọ̀ọ́kọ́. Àmọ́ Jónátánì mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ kọ́ ló ṣe yẹ kí ọ̀rọ̀ rí. Ó mọ̀ pé ìránṣẹ́ tó dúró ṣinṣin sí Jèhófà ni Dáfídì, ó sì máa ń ṣègbọràn. Báwo ló ṣe máa wá fi Dáfídì sílẹ̀ lọ máa gbè sẹ́yìn Sọ́ọ̀lù bàbá rẹ̀? Torí pé Jónátánì náà jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, ó ṣe ìpinnu tó tọ́. Ó fìgboyà gbèjà Dáfídì. Síbẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ni Jónátánì fẹ́ jẹ́ adúróṣinṣin sí, kò dalẹ̀ bàbá rẹ̀ náà torí ó bá a sọ òótọ́ ọ̀rọ̀ dípò kó tì í lẹ́yìn pé kó ṣe ohun tó fẹ́ ṣe. Kálukú wa máa jàǹfààní ẹ̀ tá a bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jónátánì bó ṣe fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin.

Ohun Tí Ìdúróṣinṣin Rẹ̀ Yọrí Sí

Jónátánì tún gbìyànjú láti mú kí àlàáfíà pa dà wà láàárín Sọ́ọ̀lù àti Dáfídì, àmọ́ Sọ́ọ̀lù ò gbọ́ tiẹ̀ lọ́tẹ̀ yìí. Dáfídì wá yọ́ lọ bá Jónátánì, ó sọ fún un pé ẹ̀rù ń ba òun torí ẹ̀mí òun wà nínú ewu. Ó sọ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ àgbà yìí pé, “Ìṣísẹ̀ kan péré ló wà láàárín èmi àti ikú!” Jónátánì gbà fún Dáfídì pé òun máa fọgbọ́n mọ èrò bàbá òun lórí ọ̀rọ̀ yìí, òun á sì jábọ̀ fún Dáfídì. Jónátánì sọ pé òun máa ta ọfà sí tòsí ibi tí Dáfídì fara pa mọ́ sí láti fún un lábọ̀. Ohun tí Jónátánì bi Dáfídì ò ju pé kó búra sí ìlérí yìí pé: “Má ṣe dáwọ́ ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí o ní sí agbo ilé mi dúró, kódà nígbà tí Jèhófà bá gbá gbogbo àwọn ọ̀tá Dáfídì kúrò lórí ilẹ̀.” Dáfídì gbà, ó ní òun á máa bójú tó agbo ilé Jónátánì, òun á sì máa dáàbò bò wọ́n.​—1 Sámúẹ́lì 20:3, 13-27.

Jónátánì gbìyànjú àtisọ ọ̀rọ̀ Dáfídì dáadáa létí Sọ́ọ̀lù, àmọ́ ṣe ni inú bí ọba! Ó pe Jónátánì ní “ọmọ ọlọ̀tẹ̀ obìnrin,” ó sì sọ pé ṣe ló dójú ti ẹbí àwọn bó ṣe ń gbè sẹ́yìn Dáfídì. Ó tiẹ̀ tún gbìyànjú láti sọ̀rọ̀ tó máa jẹ́ kó dà bíi pé ire Jónátánì lòun ń wá, ó ní: “Ní gbogbo ìgbà tí ọmọ Jésè bá fi wà láàyè lórí ilẹ̀, ìwọ àti ipò ọba rẹ kò ní lè fìdí múlẹ̀.” Àmọ́ Jónátánì ò ríyẹn rò, ṣe ló tún bẹ bàbá rẹ̀, ó ní: “Kí nìdí tí wọ́n á fi pa á? Kí ló ṣe?” Ni orí Sọ́ọ̀lù bá kanrin! Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Sọ́ọ̀lù ti dàgbà, akíkanjú ọkùnrin ogun ṣì ni. Ṣe ló ju ọ̀kọ̀ lu ọmọ rẹ̀! Bó ti wù kó jẹ́ akíkanjú tó, ọ̀kọ̀ náà ò ba Jónátánì. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn dun Jónátánì gan-an, ojú tì í, ó sì fìbínú kúrò níbẹ̀.​—1 Sámúẹ́lì 20:24-34.

Jónátánì fi hàn pé òun ò mọ tara òun nìkan

Nígbà tó di àárọ̀ ọjọ́ kejì, Jónátánì lọ sínú pápá, nítòsí ibi tí Dáfídì fara pa mọ́ sí. Bó ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ó ta ọfà kan, láti fìyẹn sọ fún Dáfídì pé Sọ́ọ̀lù ṣì fẹ́ gbẹ̀mí ẹ̀. Ó wá rán ìránṣẹ́ rẹ̀ pa dà sínú ìlú. Bó ṣe di pé ó ku òun àti Dáfídì nìyẹn, tí wọ́n sì ráyè sọ̀rọ̀ ní ṣókí. Àwọn méjèèjì sunkún, inú Jónátánì ò sì dùn bó ṣe ń dágbére fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ yìí. Bí Dáfídì ṣe di ìsáǹsá nìyẹn.​—1 Sámúẹ́lì 20:35-42.

Lójú àdánwò, Jónátánì fi hàn pé adúróṣinṣin lòun, pé òun ò mọ tara òun nìkan. Ó dájú pé inú Sátánì tó jẹ́ ọ̀tá gbogbo àwọn olóòótọ́ máa dùn ká sọ pé ipasẹ̀ Sọ́ọ̀lù ni Jónátánì tẹ̀ lé, tó sì ń wá ipò àti ògo fún ara rẹ̀. Ẹ má gbàgbé pé Sátánì máa ń fẹ́ rúná sí èrò ìmọtara-ẹni-nìkan tó máa ń wà lọ́kàn àwa èèyàn. Ó rí i ṣe fún Ádámù àti Éfà, àwọn òbí wa àkọ́kọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6) Àmọ́ kò rí i ṣe fún Jónátánì. Ẹ wo bíyẹn ṣe máa bí Sátánì nínú tó! Ṣé ìwọ náà ò ní gbà fún un tó bá gbé e wá? Àsìkò tá à ń gbé yìí lágbára, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má sí ẹni tí kì í fẹ́ mọ tara rẹ̀ nìkan. (2 Tímótì 3:1-5) Ṣé a máa kẹ́kọ̀ọ́ lára Jónátánì, bó ṣe jẹ́ adúróṣinṣin, tí kò sì mọ tara rẹ̀ nìkan?

Ọ̀rẹ́ tó ń dúró tini ni Jónátánì, ó fọgbọ́n sọ fún Dáfídì ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé ewu wà, kó lè sá fún ẹ̀mí rẹ̀

“Ẹni Ọ̀wọ́n Lo Jẹ́ sí Mi”

Ìkórìíra tí Sọ́ọ̀lù ní sí Dáfídì ti wá burú jáì. Jónátánì kàn ń wo bàbá ẹ̀ bó ṣe ń dìdàkudà ni, kò sóhun tó lè ṣe sí i. Sọ́ọ̀lù ń ṣe bí ẹni tí orí ẹ̀ ti yí, ó kó ọmọ ogun rẹpẹtẹ lẹ́yìn, wọ́n ń wá Dáfídì aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ kiri ìlú. (1 Sámúẹ́lì 24:1, 2, 12-15; 26:20) Ṣé Jónátánì náà dara pọ̀ mọ́ wọn? Ó wúni lórí pé Ìwé Mímọ́ ò dárúkọ Jónátánì níbì kankan mọ́ ara àwọn tó ń kóra wọn kiri yẹn. Ohun tó jẹ́ kíyẹn ṣeé ṣe ni bí Jónátánì ṣe jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà àti Dáfídì, tí ò sì fẹ́ da májẹ̀mú tó bá ọ̀rẹ́ rẹ̀ dá.

Ìfẹ́ tí Jónátánì ní sí ọ̀rẹ́ rẹ̀ yìí ò yí pa dà. Nígbà tó yá, ó wá ọ̀nà láti tún pa dà fojú kan Dáfídì. Hóréṣì ni wọ́n ti ríra, ìtumọ̀ Hóréṣì ni “Ibi Tó Ní Igi.” Inú aṣálẹ̀ ni Hóréṣì wà, ní àgbègbè olókè tó ṣeé ṣe kó má ju nǹkan bíi máìlì mélòó kan sí gúúsù ìlà oòrùn ìlú Hébúrónì. Kí nìdí tí Jónátánì fi fẹ̀mí ẹ̀ wewu kó lè rí ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó ti di ìsáǹsá yìí? Bíbélì sọ fún wa pé torí kó lè ran Dáfídì lọ́wọ́ “kí ó lè túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà” ló ṣe wá a lọ.” (1 Sámúẹ́lì 23:16) Báwo ni Jónátánì ṣe ṣe é?

Jónátánì sọ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ ọ̀dọ́ yìí pé: “Má bẹ̀rù.” Ó fi dá a lójú pé: “Sọ́ọ̀lù bàbá mi kò ní rí ọ mú.” Kí ló mú kí Jónátánì sọ ọ̀rọ̀ ìdánilójú yìí? Ìdí ni pé ó ní ìgbàgbọ́ tó jinlẹ̀ nínú Jèhófà pé ohun tó ní lọ́kàn máa ṣẹ dandan ni. Ó wá ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ìwọ lo máa di ọba Ísírẹ́lì.” Ọlọ́run ti fi àsọtẹ́lẹ̀ yẹn rán wòlíì Sámúẹ́lì lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn, Jónátánì wá ń rán Dáfídì létí báyìí pé gbogbo ìgbà ni ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá sọ máa ń ṣeé gbára lé. Kí ni Jónátánì wá gbà pé ó máa jẹ́ ìpín tòun? Ó ní, “èmi ni màá di igbá kejì rẹ.” Àbẹ́ ò rí i pé onírẹ̀lẹ̀ gbáà ni ọkùnrin yìí! Ó gbà láti jẹ́ ìránṣẹ́ ọ̀dọ́kùnrin tó fi ọgbọ̀n (30) ọdún jù lọ yìí, ó sì gbà láti tì í lẹ́yìn! Jónátánì wá parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Sọ́ọ̀lù bàbá mi náà sì mọ̀ bẹ́ẹ̀.” (1 Sámúẹ́lì 23:17, 18) Sọ́ọ̀lù gan-an mọ̀ lọ́kàn ara ẹ̀ pé òun ò lè rọ́nà gbé e gbà, apá òun ò sì lè ká ẹni tí Jèhófà ti yàn pé kó di ọba lọ́la yìí!

Jónátánì fún Dáfídì níṣìírí lákòókò tó nílò rẹ̀

Ó dájú pé ọ̀pọ̀ ọdún ni Dáfídì á fi máa rántí ọjọ́ tóun àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ yìí pàdé. Àmọ́ ó dunni pé ìgbà tí wọ́n ríra gbẹ̀yìn nìyẹn. Ó ṣeni láàánú pé ìrètí Jónátánì wọmi, kò pa dà di igbá-kejì Dáfídì.

Jónátánì bá bàbá rẹ̀ lọ kógun ja àwọn Filísínì, àwọn tó jẹ́ pé wọn ò fi bò rárá pé ọ̀tá Ísírẹ́lì làwọn. Tayọ̀tayọ̀ ló fi ń kọ́wọ́ ti bàbá rẹ̀ lójú ogun, torí pé ìjọsìn rẹ̀ sí Jèhófà ló máa ń fi ṣáájú láìka àwọn àṣìṣe tí bàbá rẹ̀ ti ṣe sí. Ó fìgboyà jà fitafita lójú ogun bó ṣe máa ń ṣe tẹ́lẹ̀, àmọ́, Ísírẹ́lì ò rọ́wọ́ mú lójú ogun náà. Sọ́ọ̀lù ti bá ìwà burúkú rẹ̀ débi pé ó ti ń lọ́wọ́ sí iṣẹ́ òkùnkùn. Bí Òfin Ọlọ́run ṣe sọ, ẹjọ́ ikú ni wọ́n máa dá fún ẹni tó bá ń ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀, torí náà, Jèhófà ò bù kún Sọ́ọ̀lù mọ́. Àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́ta, títí kan Jónátánì, ló kú lójú ogun. Sọ́ọ̀lù náà fara gbọgbẹ́, ó sì para ẹ̀.​—1 Sámúẹ́lì 28:6-14; 31:2-6.

Jónátánì sọ pé: “Ìwọ lo máa di ọba Ísírẹ́lì, èmi ni màá di igbá kejì rẹ.”​—1 Sámúẹ́lì 23:17

Ẹ̀dùn ọkàn wá bá Dáfídì. Kẹ́ ẹ lè mọ̀ pé èèyàn tó lọ́kàn rere ni Dáfídì, ṣe ló tún ń ṣọ̀fọ̀ Sọ́ọ̀lù, ẹni tó kó o sí ìdààmú, tó sì fayé ni ín lára! Dáfídì kọrin arò fún Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tó wọni lọ́kàn jù nínú orin yẹn ni ohun tó sọ nípa ọ̀rẹ́ rẹ̀ ọ̀wọ́n tó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ fún un yìí. Ó ní: “Ẹ̀dùn ọkàn bá mi nítorí rẹ, Jónátánì arákùnrin mi; ẹni ọ̀wọ́n lo jẹ́ sí mi. Ìfẹ́ tí o ní sí mi lágbára ju ti obìnrin lọ.”​—2 Sámúẹ́lì 1:26.

Dáfídì ò gbàgbé ẹ̀jẹ́ tó jẹ́ fún Jónátánì. Ọdún mélòó kan lẹ́yìn ìyẹn, ó wá ọmọ Jónátánì tó ń jẹ́ Méfíbóṣétì rí kó lè máa tọ́jú ẹ̀. Aláàbọ̀ ara ni. (2 Sámúẹ́lì 9:1-13) Ó ṣe kedere pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni Dáfídì ti kọ́ lára Jónátánì tó bá dọ̀rọ̀ kéèyàn jẹ́ adúróṣinṣin, kó buyì kún àwọn míì, kó sì wuni látọkàn láti jẹ́ olóòótọ́ sí ọ̀rẹ́ ẹni, kódà tí ò bá tiẹ̀ rọrùn. Ṣé àwa náà máa fi àwọn ẹ̀kọ́ yẹn sọ́kàn? Ṣé a lè wá àwọn ọ̀rẹ́ bíi Jónátánì? Ṣé àwa náà lè jẹ́ ọ̀rẹ́ tòótọ́ bíi ti Jónátánì? Tá a bá ran àwọn ọ̀rẹ́ wa lọ́wọ́ kí wọ́n lè nígbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà, tá a fi ìdúróṣinṣin wa sí Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́, tá a sì jẹ́ adúróṣinṣin dípò ká máa wá àǹfààní tara wa nìkan, irú ọ̀rẹ́ tí Jónátánì jẹ́ làwa náà máa jẹ́. Àá sì lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ rẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 7 Nígbà tí Ìwé Mímọ́ máa kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa Jónátánì, ìyẹn nígbà tí Sọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí í jọba, ọ̀gágun ni nígbà yẹn, torí náà ó kéré tán, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ọmọ ogún (20) ọdún nígbà yẹn. (Númérì 1:3; 1 Sámúẹ́lì 13:2) Ogójì (40) ọdún ni Sọ́ọ̀lù fi jọba. Torí náà, nígbà tí Sọ́ọ̀lù kú, Jónátánì ti tó nǹkan bí ọgọ́ta (60) ọdún. Ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún ni Dáfídì nígbà tí Sọ́ọ̀lù kú. (1 Sámúẹ́lì 31:2; 2 Sámúẹ́lì 5:4) Ó ṣe kedere nígbà náà pé nǹkan bí ọgbọ̀n (30) ọdún ni Jónátánì fi ju Dáfídì lọ.