Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ KỌKÀNLÁ

Ó Ṣọ́nà, Ó sì Ní Sùúrù

Ó Ṣọ́nà, Ó sì Ní Sùúrù

1, 2. Iṣẹ́ tí kò rọrùn wo ni Èlíjà ní láti ṣe? Ọ̀nà wo ni òun àti Áhábù gbà yàtọ̀ síra?

ÈLÍJÀ fẹ́ dá wà níbì kan tó ti lè gbàdúrà sí Baba rẹ̀ ọ̀run. Àmọ́, ṣe ni àwọn èrò tó yí i ká ṣẹ̀ṣẹ̀ rí i pé òun ni wòlíì tòótọ́ tó pe iná sọ̀ kalẹ̀ látọ̀run, ọ̀pọ̀ nínú wọn sì ń fẹ́ kí i láti fi wá ojú rere rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, kí Èlíjà tó gun orí Òkè Ńlá Kámẹ́lì lọ láti lọ gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run ní ìdákọ́ńkọ́, ó ní iṣẹ́ kan láti ṣe. Iṣẹ́ náà kò sì rọrùn rárá. Ó ní láti bá Áhábù Ọba sọ̀rọ̀.

2 Ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ ló wà láàárín Áhábù àti Èlíjà. Aṣọ ìgúnwà ni Áhábù apẹ̀yìndà, oníwọra àti dọ̀bọ̀sìyẹsà wọ̀. Àmọ́ Èlíjà wọ aṣọ kẹ́jẹ́bú tí àwọn wòlíì máa ń wọ̀. Bóyá awọ onírun ni wọ́n tiẹ̀ fi ṣe é tàbí kó jẹ́ aṣọ tí wọ́n fi irun ràkúnmí tàbí ti ewúrẹ́ hun. Onígboyà èèyàn, tó jẹ́ adúróṣinṣin, tó sì nígbàgbọ́ ni Èlíjà. Àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ látàárọ̀ títí dìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn sì ti jẹ́ kí ìwà àwọn méjèèjì hàn kedere.

3, 4. (a) Báwo ni ìtìjú ńlá ṣe bá Áhábù àtàwọn olùjọsìn Báálì yòókù lọ́jọ́ náà? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa rí ìdáhùn sí?

3 Ìtìjú ńlá bá Áhábù àtàwọn olùjọsìn Báálì yòókù lọ́jọ́ tá à ń wí yìí. Ẹ̀sìn ìbọ̀rìṣà tí Áhábù àti aya rẹ̀, Jésíbẹ́lì Ayaba, ń gbé lárugẹ ní ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì ti tẹ́ pátápátá. Àṣírí tú pé kò sí Báálì kan níbì kankan, pé ẹ̀tàn lásán ni. Bí àwọn tó ń bọ òrìṣà tí kò lẹ́mìí yìí ṣe ké pè é tó, tí wọ́n jó ijó àjó-sínwín, tí wọ́n ń fọ̀bẹ ya ara wọn débi pé ẹ̀jẹ̀ ń dà lára wọn, Báálì ò tan iná lásánlàsàn ran pẹpẹ wọn. Nígbà tí Èlíjà ní kí wọ́n pa àádọ́ta-lé-nírínwó [450] wòlíì Báálì tí ikú tọ́ sí, Báálì ò lè gbà wọ́n sílẹ̀. Àmọ́ òrìṣà yìí tún kùnà láti ṣe nǹkan míì, ìyẹn ló sì wá tẹ́ ẹ pátápátá. Ó ju ọdún mẹ́ta lọ tí àwọn wòlíì Báálì fi ké pè é pé kó rọ òjò láti fòpin sí ọ̀dá tó wà nílẹ̀ Ísírẹ́lì, síbẹ̀ Báálì ò rọ òjò. Àmọ́ Jèhófà máa tó fòpin sí ọ̀dá náà láti fi hàn pé òun ni Olódùmarè.—1 Ọba 16:30–17:1; 18:1-40.

4 Ṣùgbọ́n ìgbà wo ni Jèhófà máa fòpin sí ọ̀dá náà? Kí ni Èlíjà á máa ṣe kó tó dìgbà yẹn? Kí la sì lè kọ́ lára ọkùnrin tó nígbàgbọ́ yìí? Bí a ṣe ń bá ìtàn náà lọ, a máa rí ìdáhùn.—Ka 1 Àwọn Ọba 18:41-46.

Kò Dákẹ́ Àdúrà

5. Kí ni Èlíjà sọ fún Áhábù pé kó ṣe? Ǹjẹ́ ó jọ pé Áhábù kọ́gbọ́n nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn?

5 Èlíjà tọ Áhábù lọ ó sì sọ fún un pé: “Gòkè lọ, kí o jẹ, kí o sì mu; nítorí ìró ìkùrìrì eji wọwọ ń bẹ.” Ǹjẹ́ ọba burúkú yìí ti kọ́gbọ́n nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn? Lóòótọ́, ìtàn yẹn ò sọ ní tààràtà pé kò tíì kọ́gbọ́n, àmọ́ a ò rí i níbẹ̀ pé ó ronú pìwà dà. Kò ní kí Èlíjà bá òun bẹ Jèhófà pé kó dárí ji òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Áhábù kàn “gòkè lọ láti jẹ àti láti mu.” (1 Ọba 18:41, 42) Kí ni Èlíjà ṣe ní tiẹ̀?

6, 7. Kí ni Èlíjà gbàdúrà pé kó ṣẹlẹ̀? Kí nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀?

6 Bíbélì sọ pé: “Ní ti Èlíjà, ó gòkè lọ sí orí Kámẹ́lì, ó sì ń bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀, ó sì ń gbé ojú sáàárín eékún rẹ̀.” Bí Áhábù ṣe lọ jẹun, Èlíjà ráyè lọ gbàdúrà sí Jèhófà, Baba rẹ̀ ọ̀run. Kíyè sí ipò ìrẹ̀lẹ̀ tí ibí yìí sọ pé Èlíjà wà. Ó wólẹ̀, ó tẹ orí rẹ̀ ba débí tí ojú rẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ máa kan eékún rẹ̀. Kí nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ohun tó ń ṣe kò ṣòro láti mọ̀. Bíbélì sọ fún wa nínú Jákọ́bù 5:18 pé Èlíjà gbàdúrà pé kí ọ̀dá náà dópin. Ó jọ pé irú àdúrà bẹ́ẹ̀ ló ń gbà lórí Òkè Ńlá Kámẹ́lì yìí.

Àwọn àdúrà tí Èlíjà gbà fi hàn pé ó ń wù ú kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ

7 Ṣáájú àkókò yìí, Jèhófà ti sọ pé: “Mo ti pinnu láti rọ òjò sórí ilẹ̀.” (1 Ọba 18:1) Torí náà, ṣe ni Èlíjà ń gbàdúrà pé kí ìfẹ́ Jèhófà ṣẹ bí Jésù ṣe kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn.—Mát. 6:9, 10.

8. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ lára Èlíjà nípa àdúrà gbígbà?

8 A lè rí ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ kọ́ lára Èlíjà nípa àdúrà gbígbà. Ohun tó jẹ Èlíjà lógún jù ni bí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe máa ṣẹ. Tí àwa náà bá ń gbàdúrà, ó yẹ ká máa rántí pé: “Ohun yòówù tí ì báà jẹ́ tí a bá béèrè ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ [Ọlọ́run], ó ń gbọ́ tiwa.” (1 Jòh. 5:14) Nítorí náà, ó yẹ ká mọ ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́ kó bàa lè máa gbọ́ àdúrà wa. Ìdí pàtàkì nìyẹn tó fi yẹ ká jẹ́ kó mọ́ wa lára láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lójoojúmọ́. Ó dájú pé Èlíjà tún fẹ́ kí ọ̀dá náà dópin nítorí ìyà tó ń jẹ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè rẹ̀. Ńṣe lá máa dúpẹ́ gan-an látọkàn wá bó ṣe rí i pé Jèhófà ṣe iṣẹ́ ìyanu lọ́jọ́ yẹn. Tí àwa náà bá ń gbàdúrà, ó yẹ ká máa dúpẹ́ ká sì máa fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì jẹ wá lógún.—Ka 2 Kọ́ríńtì 1:11; Fílípì 4:6.

Ó Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Ó sì Ń Ṣọ́nà

9. Kí ni Èlíjà sọ pé kí ẹmẹ̀wà òun ṣe? Nǹkan méjì wo la fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí nínú ohun tí Èlíjà ṣe?

9 Ó dá Èlíjà lójú pé Jèhófà máa fòpin sí ọ̀dá tó wà nílẹ̀, kò kàn mọ ìgbà tí Jèhófà máa fòpin sí i ni. Kí ni Èlíjà wá ń ṣe kó tó dìgbà náà? Ohun tí Bíbélì sọ ni pé: “Ó sọ fún ẹmẹ̀wà rẹ̀ pé: ‘Jọ̀wọ́, gòkè lọ. Wo ìhà òkun.’ Nítorí náà, ó gòkè lọ, ó sì wò ó, ó sì wá sọ pé: ‘Kò sí nǹkan kan rárá.’ Ó sì ń bá a lọ láti sọ pé, ‘Padà lọ,’ fún ìgbà méje.” (1 Ọba 18:43) Ó kéré tán a rí ohun méjì kọ́ látinú ohun tí Èlíjà ṣe. Àkọ́kọ́ ni pé ó dá a lójú pé Jèhófà yóò dá sí ọ̀rọ̀ náà. Èkejì sì ni pé ó ń ṣọ́nà. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa nǹkan méjì yìí.

Èlíjà ń hára gàgà láti rí àmì táá fi hàn pé Jèhófà kò ní pẹ́ rọ̀jò

10, 11. (a) Báwo ni Èlíjà ṣe fi hàn pé ó dá òun lójú pé ìlérí Jèhófà máa ṣẹ? (b) Kí nìdí tí àwa náà fi lè ní irú ìdánilójú tí Èlíjà ní?

10 Ìlérí Jèhófà dá Èlíjà lójú gan-an, ìyẹn ló ṣe ń hára gàgà láti rí àmì táá fi hàn pé kò ní pẹ́ rọ òjò. Ó wá ran ẹmẹ̀wà rẹ̀ lọ síbi tó ga, táá ti lè rí ojú sánmà dáadáa lórí òkè náà, kó lọ wò ó bóyá ó máa rí àmì pé òjò máa tó rọ̀. Nígbà tí ẹmẹ̀wà rẹ̀ pa dà dé, ohun tí kò mórí yá ló sọ. Ó ní: “Kò sí nǹkan kan rárá.” Ìyẹn ni pé ojú sánmà mọ́ fo, láìsí ìkùukùu kankan. Ǹjẹ́ èyí kò ṣe ọ́ ní kàyéfì? Rántí pé àìpẹ́ yìí ni Èlíjà ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ fún Áhábù Ọba pé: “Ìró ìkùrìrì eji wọwọ ń bẹ.” Kí ló jẹ́ kí wòlíì náà sọ bẹ́ẹ̀ nígbà tí òjò kankan ò ṣú rárá?

11 Èlíjà mọ̀ pé Jèhófà ti ní òun máa rọ òjò. Òun tó jẹ́ wòlíì àti aṣojú Jèhófà sì mọ̀ dájú pé Ọlọ́run máa mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ. Ó dá a lójú débi tó fi dà bíi pé ó tiẹ̀ ti ń gbọ́ tí òjò náà ń rọ̀. Èyí lè mú ká rántí ohun tí Bíbélì sọ nípa Mósè pé: “Ó ń bá a lọ ní fífẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin bí ẹni tí ń rí Ẹni tí a kò lè rí.” Ṣé bí ìwọ náà ṣe nígbàgbọ́ tó nínú Ọlọ́run nìyẹn? Ọlọ́run ti jẹ́ ká ní ọ̀pọ̀ ìdí tí a fi lè gba òun àti àwọn ìlérí rẹ̀ gbọ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀.—Héb. 11:1, 27.

12. Báwo ni Èlíjà ṣe fi hàn pé òun ń sọ́nà? Kí ló ṣe nígbà tó gbọ́ pé àwọsánmà kékeré kan ń gòkè bọ̀?

12 Tún kíyè sí i pé Èlíjà ń ṣọ́nà. Kì í ṣe ẹ̀ẹ̀kan tàbí ẹ̀ẹ̀mejì ló rán ẹmẹ̀wà rẹ̀ pé kó pa dà lọ wo ojú sánmà, ẹ̀ẹ̀méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni! A lè fojú inú wò ó pé lílọ bíbọ̀ yẹn máa dá ẹmẹ̀wà Èlíjà lágara, àmọ́ Èlíjà kò yéé rán an lọ, torí ó ń hára gàgà láti rí àmì pé òjò fẹ́ rọ̀. Nígbà keje tí ẹmẹ̀wà Èlíjà lọ wò ó, ó sọ fún Èlíjà pé: “Wò ó! Àwọsánmà kékeré kan bí àtẹ́lẹwọ́ ènìyàn ń gòkè bọ̀ láti inú òkun.” Tiẹ̀ fojú inú wo bí ìránṣẹ́ Èlíjà á ṣe na apá láti fi àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ júwe bí àwọsánmà tó yọ lójú ọ̀run lórí Òkun Ńlá yẹn ṣe kéré tó! Ohun tí ẹmẹ̀wà yìí rí lè má jọ ọ́ lójú. Àmọ́ lójú Èlíjà, ohun pàtàkì ni. Ló bá rán ẹmẹ̀wà yẹn níṣẹ́ kánjúkánjú, ó sọ pé: “Gòkè lọ, sọ fún Áhábù pé, ‘Di kẹ̀kẹ́! Kí o sì sọ̀ kalẹ̀ lọ kí eji wọwọ má bàa dá ọ dúró!’”—1 Ọba 18:44.

13, 14. (a) Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Èlíjà tó ń ṣọ́nà? (b) Kí làwọn ìdí tí kò fi yẹ ká fi iṣẹ́ ìsìn wa tó jẹ́ kánjúkánjú falẹ̀ lákòókò tá a wà yìí?

13 Èlíjà tún fi àpẹẹrẹ àtàtà kan lélẹ̀ fún wa. Àkókò tí a wà yìí náà jẹ́ àkókò tí Ọlọ́run máa tó mú ète rẹ̀ ṣẹ. Bí Èlíjà ṣe ń retí ìgbà tí ọ̀dá òjò máa dópin ni àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run náà ṣe ń retí òpin ètò nǹkan burúkú tí a wà yìí. (1 Jòh. 2:17) Torí náà, a gbọ́dọ̀ máa ṣọ́nà nìṣó bíi ti Èlíjà, títí dìgbà tí Jèhófà Ọlọ́run máa dá sí ọ̀rọ̀ ayé yìí. Jésù Ọmọ Ọlọ́run gba àwa ọmọlẹ́yìn rẹ̀ níyànjú pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ ọjọ́ tí Olúwa yín ń bọ̀.” (Mát. 24:42) Ṣé ohun tí Jésù wá ń sọ ni pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun ò ní róye pé òpin máa tó dé ni? Rárá o, torí ó ṣe ọ̀pọ̀ àlàyé nípa bí ayé ṣe máa rí tó bá kù díẹ̀ kí òpin dé. Gbogbo wa la sì lè ṣàkíyèsí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àmì tí Jésù fún wa nípa “ìparí ètò àwọn nǹkan.”—Ka Mátíù 24:3-7.

Àwọsánmà kékeré yẹn nìkan mú kí Èlíjà mọ̀ dájú pé Jèhófà ti fẹ́ rọ̀jò. Àmì àwọn ọjọ́ ìkẹyìn tí àwa náà ń rí tó láti mú wa rí i pé kò yẹ ká fi iṣẹ́ ìsìn wa tó jẹ́ kánjúkánjú falẹ̀

14 Bí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ohun tó para pọ̀ jẹ́ àmì náà ṣe ń ṣẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé òpin ò ní pẹ́ dé. Ǹjẹ́ èyí kò tó láti mú wa rí i pé kò yẹ ká máa fi iṣẹ́ ìsìn wa sí Jèhófà tó jẹ́ kánjúkánjú falẹ̀ rárá? Àwọsánmà kékeré tó yọ lójú ọ̀run yẹn nìkan ṣoṣo ṣáà ni Èlíjà rí tó fi mọ̀ dájú pé Jèhófà ti fẹ́ rọ̀jò. Ǹjẹ́ ìrètí wòlíì yìí sì já sí asán?

Jèhófà Mú Ìtura àti Ìbùkún Wá

15, 16. Àwọn nǹkan wo ló ń ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra wọn ní kíákíá? Kí ló ṣeé ṣe kí Èlíjà máa rò lọ́kàn nípa Áhábù?

15 Bíbélì sọ pé: “Ó sì ṣẹlẹ̀ láàárín àkókò náà pé àwọsánmà àti ẹ̀fúùfù mú ojú ọ̀run ṣókùnkùn, eji wọwọ ńláǹlà sì bẹ̀rẹ̀. Áhábù sì ń gun kẹ̀kẹ́ lọ, ó sì wá sí Jésíréélì.” (1 Ọba 18:45) Àwọn nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra wọn ní kíákíá. Bí ẹmẹ̀wà Èlíjà ṣe ń jíṣẹ́ rẹ̀ fún Áhábù lọ́wọ́, àwọsánmà kékeré yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ sí i títí tó fi ṣú bo ojú ọ̀run. Atẹ́gùn ńlá kan wá bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́. Ló bá di pé òjò rọ̀ nílẹ̀ Ísírẹ́lì lẹ́yìn ọ̀dá ọdún mẹ́ta àtààbọ̀. Ilẹ̀ tó ti gbẹ táútáú wá ń fa omi òjò yẹn mu. Bí òjò yẹn ṣe ń ya lulẹ̀ wìì-wìì, odò Kíṣónì kún àkúnya, ó sì dájú pé ó fọ ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì Báálì tí Èlíjà ní kí wọ́n pa kúrò nílẹ̀. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì aláìgbọràn wá láǹfààní láti jáwọ́ pátápátá kúrò nínú ìjọsìn Báálì tó ti sọ wọ́n di ẹlẹ́gbin.

“Eji wọwọ ńláǹlà sì bẹ̀rẹ̀”

16 Ó dájú pé Èlíjà pàápàá á máa retí pé kí wọ́n jáwọ́ nínú ìjọsìn Báálì pátápátá! Bóyá á máa rò ó lọ́kàn pé, kí ni Áhábù máa ṣe nípa àwọn ohun ìyanu tó rí pé ó ń ṣẹlẹ̀? Ǹjẹ́ Áhábù máa ronú pìwà dà kó sì jáwọ́ nínú ìjọsìn Báálì tó fi sọ ara rẹ̀ di ẹlẹ́gbin? Àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ náà tó láti mú kó ronú pìwà dà. Àmọ́ ṣá o, a ò mọ ohun tó wà lọ́kàn Áhábù lákòókò yẹn. Ohun tí ìtàn yìí kàn sọ ni pé ọba yẹn “ń gun kẹ̀kẹ́ lọ, ó sì wá sí Jésíréélì.” Ṣé ó tiẹ̀ rí ẹ̀kọ́ kankan kọ́? Ǹjẹ́ ó ti pinnu pé òun á yí pa dà? Àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà fi hàn pé kò tíì kọ́gbọ́n, kò sì tíì ṣe tán láti yí pa dà. Àmọ́ ṣá, ṣíṣe ṣì kù fún Áhábù àti Èlíjà lọ́jọ́ yẹn.

17, 18. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Èlíjà bó ṣe ń lọ sí Jésíréélì? (b) Kí ló yani lẹ́nu nípa bí Èlíjà ṣe sáré láti Kámẹ́lì dé Jésíréélì? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

17 Wòlíì Jèhófà yìí wá forí lé ọ̀nà tí Áhábù ń gbà lọ. Ìrìn ọ̀nà jíjìn ló fẹ́ rìn yìí, nínú òjò, nígbà tí ilẹ̀ ń ṣú lọ. Àmọ́ ohun àrà ọ̀tọ̀ kan ṣẹlẹ̀.

18 Bíbélì sọ pé: “Ọwọ́ Jèhófà sì wà lára Èlíjà, bẹ́ẹ̀ ni ó sì di ìgbáròkó rẹ̀ lámùrè, ó sì ń sáré lọ níwájú Áhábù dé iyàn-níyàn Jésíréélì.” (1 Ọba 18:46) Ó dájú pé ohun ìyanu ni “ọwọ́ Jèhófà” yìí ń mú kí Èlíjà ṣe yẹn. Torí pé Jésíréélì tí Èlíjà ń sáré lọ jìnnà tó ọgbọ̀n kìlómítà, ara Èlíjà sì ti ń dara àgbà. * Fojú inú wò ó ná bí Èlíjà ṣe ń di aṣọ gígùn tó wọ̀ lámùrè, tó dì í mọ́ ìgbáròkó rẹ̀ dáadáa kí ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì lè ṣeé gbé tìrọ̀rùntìrọ̀rùn. Tó wá bẹ̀rẹ̀ sí í sáré tete lọ lójú ọ̀nà tí omi ti rin gbingbin náà, débi tó fi bá kẹ̀kẹ́ ẹṣin ọba tó sì tún yà á sílẹ̀!

19. (a) Bí Ọlọ́run ṣe mú kí ara Èlíjà ta kébékébé mú wa rántí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wo? (b) Kí ni Èlíjà mọ̀ dájú bó ṣe ń sáré lọ sí Jésíréélì?

19 Ẹ ò rí i pé nǹkan ńlá ni Jèhófà fi jíǹkí Èlíjà yìí! Orí rẹ̀ ní láti yá gágá bó ṣe ń rí i pé ara òun ń ta kébékébé ju ti ìgbà tí òun wà lọ́dọ̀ọ́ pàápàá. Ìyẹn lè mú wa rántí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó mú kó dá wa lójú pé àwọn olóòótọ́ èèyàn yóò ní ìlera pípé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ iwájú. (Ka Aísáyà 35:6; Lúùkù 23:43) Bí Èlíjà ṣe ń sáré lọ lẹlẹ lójú ọ̀nà tí omi ti rin gbingbin náà, ó mọ̀ dájú pé inú Baba òun Jèhófà, tó jẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà, ń dùn sí òun!

20. Báwo la ṣe lè rí àwọn ìbùkún Jèhófà gbà?

20 Ó máa ń wu Jèhófà kó bù kún wa. Ẹ jẹ́ ká máa ṣe ohun tí a ó fi rí àwọn ìbùkún rẹ̀ gbà, ká máa sa gbogbo ipá wa láti rí i pé wọ́n tẹ̀ wá lọ́wọ́. Ǹjẹ́ kí àwa náà máa ṣọ́nà bíi ti Èlíjà, ká máa fara balẹ̀ kíyè sí àwọn ẹ̀rí tó ń fi hàn pé Jèhófà ti fẹ́ dá sí ọ̀rọ̀ ayé lákòókò eléwu tó jẹ́ kánjúkánjú yìí. A ní ọ̀pọ̀ ìdí tó fi yẹ ká ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú àwọn ìlérí Jèhófà “Ọlọ́run òtítọ́” bíi ti Èlíjà.—Sm. 31:5.

^ ìpínrọ̀ 18 Kò pẹ́ sígbà tá à ń sọ yìí ni Jèhófà ní kí Èlíjà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ Èlíṣà níṣẹ́ tó fi dẹni tí wọ́n mọ̀ sí “ẹni tí ń bu omi sí ọwọ́ Èlíjà.” (2 Ọba 3:11) Èlíṣà di ìránṣẹ́ Èlíjà tó ti dàgbàlagbà, ó ń bá a ṣe àwọn iṣẹ́ tó bá fẹ́ ṣe.