Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ ÌGBÀGBỌ́ WỌN | ÈLÍJÀ

Ó Fara Dà Á Dé Òpin

Ó Fara Dà Á Dé Òpin

Ìròyìn dé etí Èlíjà pé Ọba Áhábù ti kú. Fojú inú wò ó bí wòlíì àgbàlagbà yìí ṣe ń fọwọ́ pa irùngbọ̀n rẹ̀, tó ń rántí ọ̀pọ̀ ọdún tí òun àti ọba burúkú yẹn ti jọ ń bára wọn pò ó. Ojú Èlíjà rí nǹkan! Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Ọba Áhábù àti Jésíbẹ́lì ìyàwó rẹ̀ halẹ̀ mọ́ ọn, tí wọ́n sì ń lépa ẹ̀ kiri, ṣe ni wọ́n tiẹ̀ fẹ́ gbẹ̀mí ẹ̀. Jésíbẹ́lì pàṣẹ pé kí wọ́n pa ọ̀pọ̀ lára àwọn wòlíì Jèhófà, àmọ́ ọba ò rí nǹkan kan ṣe sí i. Ṣe làwọn méjèèjì jọ pawọ́ pọ̀ láti pa ọkùnrin olódodo kan tí ò mọwọ́ mẹsẹ̀ tórúkọ ẹ̀ ń jẹ́ Nábótì, àtàwọn ọmọkùnrin ẹ̀, bẹ́ẹ̀ Áhábù àti Jésíbẹ́lì gan-an ni olójúkòkòrò. Èyí mú kí Èlíjà kéde ìdájọ́ Jèhófà lórí Áhábù àti ìdílé rẹ̀ tó ń jọba. Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ sì ti ń ṣẹ báyìí. Bí Jèhófà ṣe sọ pé Áhábù máa kú gẹ́lẹ́ ló ṣe kú.—1 Àwọn Ọba 18:4; 21:​1-​26; 22:​37, 38; 2 Àwọn Ọba 9:​26.

Síbẹ̀, Èlíjà mọ̀ pé òun ṣì gbọ́dọ̀ máa fara dà á. Jésíbẹ́lì ò tíì kú, ó ṣì lẹ́nu nínú ìdílé ẹ̀ àti orílẹ̀-èdè náà. Ọ̀pọ̀ ìṣòro míì ni Èlíjà ṣì máa rí, ọ̀pọ̀ nǹkan ló sì máa kọ́ Èlíṣà tó ń bá a ṣiṣẹ́, tó sì máa gbéṣẹ́ náà fún tó bá yá. Ẹ jẹ́ ká wá wo mẹ́ta lára àwọn iṣẹ́ tí Èlíjà ṣe gbẹ̀yìn. Bá a ṣe ń rí bí ìgbàgbọ́ tó ní ṣe ràn án lọ́wọ́ láti fara dà á, a máa rí bí àwa náà ṣe lè jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára lásìkò oníwàhálà tá à ń gbé yìí.

Ó Ṣèdájọ́ Ahasáyà

Ahasáyà, ọmọ Áhábù àti Jésíbẹ́lì ti di ọba ní Ísírẹ́lì báyìí. Dípò kó kẹ́kọ̀ọ́ látinú àṣìṣe àwọn òbí rẹ̀, àpẹẹrẹ burúkú wọn ló tẹ̀ lé. (1 Àwọn Ọba 22:52) Báálì táwọn òbí Ahasáyà sìn lòun náà ń sìn. Ìjọsìn Báálì máa ń mú káwọn èèyàn máa ṣe ohun tó burú, bíi kí wọ́n máa ṣe aṣẹ́wó tẹ́ńpìlì, kódà ó máa ń mú kí wọ́n fi ọmọ rúbọ. Ṣé ohunkóhun máa sún Ahasáyà láti yíwà ẹ̀ pa dà, kó sì ran àwọn èèyàn ilẹ̀ náà lọ́wọ́ kí wọ́n lè jáwọ́ nínú irú ìwà àìṣòótọ́ tó burú jáì tí wọ́n ń hù sí Jèhófà yìí?

Ọmọ kékeré onígbèéraga tó pera ẹ̀ ní ọba yìí kan àgbákò. Lọ́jọ́ kan, ó já bọ́ látibi asẹ́ ojú fèrèsé yàrá ẹ̀ tó wà lórí òrùlé, ó sì ṣèṣe gan-an. Pẹ̀lú bí ẹ̀mí ẹ̀ ṣe wà nínú ewu yìí, kò yíjú sí Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́. Dípò ìyẹn, ṣe ló ránṣẹ́ sí Ékírónì, ìlú àwọn Filísínì tó jẹ́ ọ̀tá Jèhófà pé kí wọ́n bá òun wádìí lọ́wọ́ òrìṣà Baali-sébúbù bóyá ara òun máa yá. Ohun tó ṣe yẹn bí Jèhófà nínú gan-an. Ó rán áńgẹ́lì kan sí wòlíì Èlíjà, ó sì sọ fún un pé kó lọ pàdé àwọn ìránṣẹ́ yẹn lọ́nà kí wọ́n tó débi tí wọ́n ń lọ. Wòlíì náà wá rán wọn pa dà lọ bá ọba, ó sì fi ọ̀rọ̀ mímúná rán wọn sí i. Ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì ni Ahasáyà dá, torí ṣe ni ìgbésẹ̀ tó gbé mú kó dà bíi pé Ísírẹ́lì ò ní Ọlọ́run. Jèhófà sì sọ pe Ahasáyà ò ní dìde lórí ìdùbúlẹ̀ àìsàn tó wà.—2 Àwọn Ọba 1:​2-4.

Ahasáyà ò ronú pìwà dà, ṣe ló tún ń bi àwọn ìránṣẹ́ náà pé: “Kí ni ìrísí ọkùnrin náà tí ó gòkè wá pàdé yín, tí ó sì wá sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún yín?” Àwọn ìránṣẹ́ náà sọ bí onítọ̀hún ṣe múra, bíi wòlíì. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Ahasáyà sọ pé: “Èlíjà ni.” (2 Àwọn Ọba 1:​7, 8) Ẹ ò rí i pé ó gbàfiyèsí, pé Èlíjà jẹ́ kí ìwọ̀nba nǹkan díẹ̀ tó ní tẹ́ ẹ lọ́rùn kó lè gbájú mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run, débi pé wọ́n tètè fi aṣọ tó sábà máa ń wọ̀ dá a mọ̀. Àmọ́ ọ̀rọ̀ Ahasáyà àtàwọn òbí ẹ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ ní tiwọn, olójúkòkòrò ni wọ́n, kíkó nǹkan ìní jọ sì ti wọ̀ wọ́n lẹ́wù. Àpẹẹrẹ Èlíjà rán wa létí lónìí pé ká máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù pé ká jẹ́ kí ohun díẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn, ká sì jẹ́ kí ojú wa mú ọ̀nà kan, ìyẹn àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.—Mátíù 6:​22-​24.

Inú bí Ahasáyà, ó fẹ́ gbẹ̀san, ló bá ní kí àádọ́ta (50) ọmọ ogun àti olórí wọn lọ mú Èlíjà. Wọ́n rí Èlíjà tó “jókòó sórí òkè ńlá,” * ni olórí ogun bá ṣàyà gbàǹgbà, ó sì pàṣẹ fún Èlíjà lórúkọ ọba pé kó “sọ̀ kalẹ̀ wá,” ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ṣe ni wọ́n máa lọ pa á. Àbẹ́ ò rí nǹkan! Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ ogun yẹn mọ̀ pé “ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́” ni Èlíjà, wọ́n rò pé àwọn ṣì lè halẹ̀ mọ́ ọn, káwọn sì ṣẹ̀rù bà á. Ìkọjá àyè gbáà! Èlíjà sọ fún olórí ogun náà pé: “Tóò, bí mo bá jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run, kí iná sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run, kí ó sì jẹ ìwọ àti àádọ́ta rẹ run.” Ọlọ́run sì dáhùn lóòótọ́! “Iná sì ti ọ̀run sọ̀ kalẹ̀ wá, ó sì jẹ òun àti àádọ́ta rẹ̀ run.” (2 Àwọn Ọba 1:​9, 10) Ikú oró táwọn ọmọ ogun yẹn kú rán wa létí pé Jèhófà kì í fi àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣeré, ó máa ń fìyà jẹ àwọn tó bá kàn wọ́n lábùkù tàbí tó hùwà àfojúdi sí wọn.—1 Kíróníkà 16:​21, 22.

Ahasáyà rán olórí ogun míì àti àádọ́ta (50) ọmọ ogun. Olórí ogun kejì yìí tiẹ̀ tún wá bà jẹ́ ju ti àkọ́kọ́ lọ. Kò kẹ́kọ̀ọ́ rárá látinú ikú tó pa àwọn mọ́kànléláàádọ́ta (51) tó kọ́kọ́ wá, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kí eérú wọn ṣì wà nílẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè níbẹ̀. Ohun míì tún ni pé, ńṣe lòun náà ṣàyà gbàǹgbà, ó pàṣẹ fún Èlíjà bíi tẹni àkọ́kọ́ pé kó “sọ̀ kalẹ̀”, àmọ́ òun tiẹ̀ tún wá fi kún un pé kó sọ̀ kalẹ̀ “kíákíá”! Àbẹ́ ò rí i pé ó gọ̀! Bóun àtàwọn ọmọ ogun ẹ̀ ṣe fẹ̀mí wọn ṣòfò bíi tàwọn tó kọ́kọ́ lọ nìyẹn. Ìwà òmùgọ̀ ti ọba tiẹ̀ tún wá ju tiwọn lọ. Ohun tó ti ṣẹlẹ̀ lẹ́ẹ̀mejì yẹn ò tu irun kankan lára ẹ̀, ṣe ló tún rán àwùjọ àwọn ọmọ ogun míì. Àmọ́ a dúpẹ́ pé olórí ogun kẹta yìí gbọ́n ní tiẹ̀. Ṣe ló fìrẹ̀lẹ̀ lọ bá Èlíjà, ó sì bẹ̀ ẹ́ pé kó dá ẹ̀mí òun àtàwọn ọmọ ogun òun sí. Ó dájú pé ṣe ni Èlíjà tó jẹ́ èèyàn Ọlọ́run gbé àánú Jèhófà yọ nígbà tó dá olórí ogun tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ yẹn lóhùn. Áńgẹ́lì Jèhófà sọ fún Èlíjà pé kó tẹ̀ lé àwọn ọmọ ogun yẹn. Èlíjà sì ṣe bẹ́ẹ̀, ó wá tún ohun tí Jèhófà sọ ṣáájú sọ fún ọba burúkú náà. Bí Ọlọ́run sì ṣe sọ ọ́ ló rí, Ahasáyà kú. Kò ju ọdún méjì péré tó fi ṣàkóso.—2 Àwọn Ọba 1:​11-​17.

Ohun tí Èlíjà ṣe fún olórí ogun tó nírẹ̀lẹ̀ yẹn fi àánú Jèhófà hàn

Kí ló jẹ́ kí Èlíjà lè fara dà á, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn alágídí àtàwọn ọlọ̀tẹ̀ ló yí i ká? Ó yẹ káwa tá à ń gbé lóde òní mọ ìdáhùn ìbéèrè yẹn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ṣó ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí pé o gba ẹnì kan tó o fẹ́ràn nímọ̀ràn tó dáa, àmọ́ tó fàáké kọ́rí, tó ní ohun tí ò dáa lòun fẹ́ ṣe dandan, tíyẹn sì mú kí nǹkan sú ẹ. Kí ló lè jẹ́ ká fara dà á tí wọ́n bá já wa kulẹ̀ lọ́nà yẹn? A lè kọ́ ohun kan látinú ibi tí àwọn ọmọ ogun náà ti rí Èlíjà, ìyẹn ní “orí òkè.” A ò lè fi gbogbo ẹnu sọ ìdí tí Èlíjà fi wà níbẹ̀, àmọ́ torí pé Èlíjà máa ń gbàdúrà gan-an, ó dá wa lójú pé bí ibẹ̀ yẹn ṣe pa rọ́rọ́ máa fún un láǹfààní láti túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run rẹ̀ ọ̀wọ́n. (Jákọ́bù 5:​16-​18) Àwa náà lè wá ààyè déédéé láti máa bá Jèhófà sọ̀rọ̀, ká ké pè é, ká sì sọ gbogbo ìṣòrò àti ohun tó ń dùn wá lọ́kàn fún un. Ìyẹn máa jẹ́ ká lè túbọ̀ fara dà á táwọn tó yí wa ká bá ń ṣe ohun tí ò dáa, tó sì léwu.

Ó Fún Un ní Ẹ̀wù Oyè

Àkókò ti wá tó báyìí kí Èlíjà faṣẹ́ lé ẹlòmíì lọ́wọ́. Kíyè sí ohun tó ṣe. Bí òun àti Èlíṣà ṣe ń kúrò nílùú Gílígálì, Èlíjà rọ Èlíṣà pé kó dúró síbẹ̀, pé òun nìkan fẹ́ lọ sí Bẹ́tẹ́lì tó jìn tó nǹkan bíi kìlómítà mọ́kànlá (11). Àmọ́ Èlíṣà ò fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, ó ní: “Bí Jèhófà ti ń bẹ, àti bí ọkàn rẹ ti ń bẹ, èmi kí yóò fi ọ́ sílẹ̀.” Nígbà táwọn méjèèjì dé Bẹ́tẹ́lì, Èlíjà sọ fún Èlíṣà pé òun fẹ́ dá rìnrìn àjò lọ sí Jẹ́ríkò, nǹkan bíi kìlómítà méjìlélógún (22) sí ibi tí wọ́n wà. Àmọ́ Èlíṣà ò yẹhùn, èsì kan náà ló tún fún ọ̀gá rẹ̀. Nígbà tí wọ́n tún dé Jẹ́ríkò, ohun kan náà ló ṣẹlẹ̀ kí wọ́n tó dé Odò Jọ́dánì tó wà ní nǹkan bíi kìlómítà mẹ́jọ síwájú. Èlíṣà ṣì dúró lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀ náà. Ó ní òun ò ní fi Èlíjà sílẹ̀!—2 Àwọn Ọba 2:​1-6.

Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ni Èlíṣà fi hàn yìí. Irú ìfẹ́ yìí ni Rúùtù ní sí Náómì, ìfẹ́ tó máa ń rọ̀ mọ́ ohun kan, tí kì í sì í dẹ̀yìn lẹ́yìn ohun náà. (Rúùtù 1:​15, 16) Gbogbo àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run la nílò ànímọ́ yẹn pàápàá lóde òní. Èlíṣà rí i pé ànímọ́ yẹn ṣe pàtàkì gan-an. Ṣé àwa náà rí i bẹ́ẹ̀?

Ó dájú pé ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí ọ̀dọ́ tó jẹ́ ìránṣẹ́ Èlíjà ní yìí wú Èlíjà lórí gan-an. Torí ẹ̀ ni Èlíṣà ṣe láǹfààní láti rí iṣẹ́ ìyanu tó gbẹ̀yìn tí Èlíjà ṣe. Nígbà tí wọ́n dé etí Odò Jọ́dánì, tó sábà máa ń yára ṣàn, tómi rẹ̀ sì jìn láwọn ibì kan, Èlíjà fi ẹ̀wù oyè rẹ̀ lu omi náà. Ni omi ọ̀hún bá pínyà! Àwọn méjèèjì nìkan kọ́ ló rí iṣẹ́ ìyanu yìí, “àádọ́ta ọkùnrin lára àwọn ọmọ àwọn wòlíì” náà rí i, ẹ̀rí fi hàn pé àwọn ọkùnrin yìí wà lára àwọn tí wọ́n ń dá lẹ́kọ̀ọ́ láti múpò iwájú nínú ìjọsìn mímọ́ nílẹ̀ náà. (2 Àwọn Ọba 2:​7, 8) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ Èlíjà ló ń bójú tó ìdálẹ́kọ̀ọ́ wọn. Ìgbà kan wà lọ́dún mélòó kan ṣáájú àkókò yẹn tí Èlíjà rò pé òun nìkan ni ọkùnrin olóòótọ́ tó ṣẹ́ kù nílẹ̀ náà. Àmọ́ látìgbà yẹn, Jèhófà bù kún Èlíjà torí ìfaradà tó ní, Ó jẹ́ kí ìtẹ̀síwájú tó gadabú tó ń wáyé láàárín àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ ṣojú Èlíjà.—1 Àwọn Ọba 19:10.

Lẹ́yìn tí wọ́n sọdá Odò Jọ́dánì, Èlíjà sọ fún Èlíṣà pé: “Béèrè ohun tí èmi yóò ṣe fún ọ kí a tó mú mi kúrò lọ́dọ̀ rẹ.” Èlíjà mọ̀ pé àkókò ti tó fún òun láti lọ. Kò wò ó pé ṣe ni ìránṣẹ́ òun fẹ́ gbapò mọ́ òun lọ́wọ́, tó sì fẹ́ gba àwọn àǹfààní tóun ní mọ́ òun lára. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yá Èlíjà lára láti ràn án lọ́wọ́ lọ́nàkọnà. Ohun kan tí Èlíṣà sọ ò ju pé: “Jọ̀wọ́, kí ipa méjì nínú ẹ̀mí rẹ lè bà lé mi.” (2 Àwọn Ọba 2:9) Kì í ṣe ohun tó ń sọ ni pé òun fẹ́ gba ìlọ́po méjì ẹ̀mí mímọ́ tó wà lára Èlíjà. Kàkà bẹ́ẹ̀, irú ogún tó máa ń jẹ́ ti àkọ́bí ni Èlíṣà ń béèrè, torí lábẹ́ òfin, àkọ́bí ọmọkùnrin ló máa ń gba ìpín tó pọ̀ jù tàbí ìlọ́po méjì tàwọn ìyókù kó lè tó ojúṣe ẹ̀ ṣe gẹ́gẹ́ bí olórí ẹbí. (Diutarónómì 21:17) Nígbà tó sì jẹ́ pé Èlíṣà ni àrólé Èlíjà nípa tẹ̀mí, ó ṣe kedere pé ó rí i pé ó yẹ kóun ní ẹ̀mí ìgboyà tí Èlíjà ní kóun lè ṣiṣẹ́ náà yọrí.

Tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ ni Èlíjà fi ọ̀rọ̀ náà lé Jèhófà lọ́wọ́. Tí Jèhófà bá ti lè jẹ́ kí Èlíṣà rí wòlíì Èlíjà nígbà tó bá mú Èlíjà lọ, a jẹ́ pé Ọlọ́run máa fún Èlíṣà ní ohun tó béèrè fún. Ká tó wí, ká tó fọ̀, bí àwọn ọ̀rẹ́ méjèèjì tó ti ń bára wọn bọ̀ tipẹ́ yìí ṣe ń rìn lọ, “tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ bí wọ́n ti ń rìn,” ohun àgbàyanu kan ṣẹlẹ̀!—2 Àwọn Ọba 2:​10, 11.

Ó dájú pé ọ̀rẹ́ tí Èlíjà àti Èlíṣà ń bára wọn ṣe ran àwọn méjèèjì lọ́wọ́ láti fara da àkókò tó nira

Ìmọ́lẹ̀ kan ṣàdédé yọ lójú ọ̀run, ló bá ń bọ̀ wálẹ̀ ṣòòròṣò. Fojú inú wò ó bí ìjì ẹlẹ́fùúfù ṣe bẹ̀rẹ̀ lójijì, tó ń pariwo, tó sì ń hó yee lẹ́gbẹ̀ẹ́ kiní kan tó mọ́lẹ̀ yòò, tó ń yára bọ̀ lọ́dọ̀ àwọn ọkùnrin méjì náà, tó sì pín wọn níyà. Ó ṣeé ṣe kí nǹkan ọ̀hún dẹ́rù bà wọ́n bí wọ́n ṣe ń yà fún un. Kí ni wọ́n rí ná? Kẹ̀kẹ́ ẹṣin ni, ló ń ràn yòò bíi pé iná ni wọ́n fi ṣe é. Èlíjà mọ̀ pé àsìkò òun ti tó. Ṣé ó wá gun kẹ̀kẹ́ ọ̀hún ni? Bíbélì ò sọ. Èyí ó wù kó jẹ́, ó ṣáà mọ̀ pé kẹ̀kẹ́ ọ̀hún gbé òun lọ sókè réré nínú ìjì ẹlẹ́fùúfù yẹn, ó sì gbé òun lọ!

Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún Èlíṣà. Torí ohun àràmàǹdà tó rí yìí, ó mọ̀ pé Jèhófà máa fún òun ní “ipa méjì” ẹ̀mí ìgboyà tí Èlíjà ní. Àmọ́ ìyẹn kọ́ ló tiẹ̀ bá Èlíṣà báyìí. Inú ẹ̀ ò dùn rárá. Kò mọ ibi tí ọ̀rẹ́ ẹ̀ àgbà yìí ń lọ, kò dájú pé ó retí pé òun ṣì tún máa pa dà fojú kan Èlíjà. Ṣe ló ké jáde pé: “Baba mi, baba mi, kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun Ísírẹ́lì àti àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀!” Ó ń wò ó bí ọ̀gá rẹ̀ ọ̀wọ́n tó jẹ́ àwòkọ́ṣe fún un ṣe ń lọ lọ́ọ̀ọ́kán títí kò fi rí i mọ́, inú ẹ̀ bà jẹ́, ló bá fa aṣọ ara ẹ̀ ya.—2 Àwọn Ọba 2:​12.

Bí Èlíjà ṣe ń wọnú òfuurufú lọ, ṣé ó gbọ́ igbe ọ̀rẹ́ rẹ̀ yìí, tí omijé sì bọ́ lójú tiẹ̀ náà? Èyí ó wù kó jẹ́, ó dájú pé ó mọ̀ pé bí òun ṣe ní irú Èlíṣà lọ́rẹ̀ẹ́ ran òun lọ́wọ́ láti fara da àwọn àkókò kan tó nira. Ó yẹ káwa náà kẹ́kọ̀ọ́ látinú àpẹẹrẹ Èlíjà, kó sì jẹ́ pé àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, tí wọ́n sì fẹ́ ṣẹ̀ ìfẹ́ rẹ̀ la mú lọ́rẹ̀ẹ́!

Jèhófà gbé Èlíjà lọ síbòmíì láti lọ bójú tó iṣẹ́ míì

Iṣẹ́ Tó Gbẹ̀yìn

Ibo ni Èlíjà wá lọ lẹ́yìn náà? Ohun táwọn ẹ̀sìn kan fi kọ́ àwọn èèyàn ni pé ṣe la mú un lọ sí ọ̀run lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Àmọ́ ìyẹn ò ṣeé ṣe. Ìdí ni pé, ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn náà, Jésù Kristi sọ pé kò sẹ́ni tó lọ sọ́run rí ṣáájú kóun tó wá sáyé. (Jòhánù 3:​13) Torí náà, nígbà tá a kà á nínú Bíbélì pé “Èlíjà . . . gòkè re ọ̀run nínú ìjì ẹlẹ́fùúùfù,” ìbéèrè tó yẹ ká béèrè ni pé, ọ̀run wo? (2 Àwọn Ọba 2:​11) Tí Bíbélì bá lo ọ̀rọ̀ náà “ọ̀run”, kì í ṣe ibi tí Jèhófà ń gbé nìkan ló máa ń tọ́ka sí, ó tún máa ń tọ́ka sí ojú sánmà tó wà lápá òkè ayé wa yìí, ìyẹn níbi tí ìkùukùu máa ń wà, táwọn ẹyẹ sì ti máa ń fò. (Sáàmù 147:8) Ọ̀run yẹn, tàbí ká kúkú sọ pé òfuurufú, ni Èlíjà gòkè lọ. Kí ló wá ṣẹlẹ̀?

Ṣe ni Jèhófà gbé wòlíì rere yìí lọ síbòmíì, tó sì yanṣẹ́ míì fún un níbẹ̀. Ìjọba Júdà ni Jèhófà mú un lọ. Àkọsílẹ̀ tó wà nínú Bíbélì jẹ́ ká rí i pé Èlíjà ń báṣẹ́ lọ níbẹ̀, ó ṣeé ṣe kó ti lé ní ọdún méje lẹ́yìn náà. Jèhórámù ọba búburú ló ń jọba ní Júdà nígbà yẹn. Ọmọ Áhábù àti Jésíbẹ́lì ló fẹ́, torí náà, iná ò tíì tán láṣọ. Jèhófà sọ fún Èlíjà pé kó kọ lẹ́tà láti kéde ìdájọ́ lórí Jèhórámù. Bí Èlíjà sì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ikú ẹ̀sín ni Jèhórámù kú. Ibi tó wá burú sí ni pé Bíbélì parí ìtàn ẹ̀ báyìí pé: “Níkẹyìn, ó lọ láìdunni.”—2 Kíróníkà 21:​12-​20.

Ẹ ò rí i pé ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ ló wà láàárín ọkùnrin burúkú yẹn àti Èlíjà. A ò mọ ìgbà tí Èlíjà kú àtohun tó pa á. Àmọ́ a mọ̀ pé òun ò kú ikú ẹ̀sín bíi ti Jèhórámù. Ikú tiẹ̀ máa dun àwọn èèyàn. Àárò ẹ̀ sọ Èlíjà. Ó sì dájú pé àárò ẹ̀ sọ àwọn wòlíì olóòótọ́ yòókù náà. Kódà, Jèhófà fúnra ẹ̀ ṣì ka Èlíjà sí iyebíye, torí ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún (1, 000) ọdún kan lẹ́yìn náà, ó fi àwòrán wòlíì dáadáa yẹn hàn nínú ìran táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù rí nígbà ìyípadà ológo. (Mátíù 17:​1-9) Ṣé wàá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ lára Èlíjà, kó o sì mú kí ìgbàgbọ́ ẹ lágbára kó o lè fara dà á bí ìṣòro bá tiẹ̀ yọjú? Yáa má gbàgbé pé, àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ló yẹ kó o máa bá ṣọ̀rẹ́, pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run, kó o sì máa gbàdúrà déédéé látọkàn wá. Bíi ti Èlíjà, Jèhófà á fi ìwọ náà sọ́kàn, kò ní gbàgbé ẹ láé!

^ ìpínrọ̀ 6 Ohun táwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kan sọ ni pé Òkè Kámẹ́lì ni òkè tí Bíbélì mẹ́nu bà yìí, tí Ọlọ́run ti fún Èlíjà lágbára láti ṣẹ́gun àwọn wòlíì Báálì lọ́dún mélòó kan ṣáájú. Àmọ́ Bíbélì ò dárúkọ òkè yẹn.