Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ ÌGBÀGBỌ́ WỌN | JÓNÁTÁNÌ

Jónátánì​—“Kò Sí Ìdílọ́wọ́ fún Jèhófà”

Jónátánì​—“Kò Sí Ìdílọ́wọ́ fún Jèhófà”

Fọkàn yàwòrán ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun Filísínì tó pàgọ́ sẹ́yìn ibùdó ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn. Aṣálẹ̀ ni ibi tí wọ́n wà yẹn, òkè sì pọ̀ níbẹ̀. Ṣàdédé ni wọ́n rí ohun kan tó gbàfiyèsí wọn, tó yàtọ̀ sóhun tí wọ́n ti ń rí tẹ́lẹ̀: Wọ́n rí ọkùnrin méjì tí wọ́n jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì, tí wọ́n dúró níbi tó tẹ́jú lọ́ọ̀ọ́kán. Àfonífojì tóóró kan ló là wọ́n láàárín. Ó pa wọ́n lẹ́rìn-ín pé kí ni ọkùnrin méjì fẹ́ fi àwọn ṣe. Ìdí tó sì fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé ọjọ́ pẹ́ táwọn Filísínì ti ń jẹ gàba lórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, débi pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò lè pọ́n àwọn irinṣẹ́ tí wọ́n ń lò lóko láìjẹ́ pé wọ́n lọ bá àwọn Filísínì kí wọ́n bá wọn pọ́n ọn. Torí ẹ̀ ni wọn ò ṣe fi bẹ́ẹ̀ ní ohun ìjà. Àwọn tí ò fi bẹ́ẹ̀ ní ohun ìjà yìí ò tún wá ju méjì lọ lọ́tẹ̀ yìí tí wọ́n láwọn fẹ́ bá àwọn Filísínì jà! Ẹ gbọ́ ná, bí wọ́n bá tiẹ̀ lóhun ìjà, kí làwọn méjì lè dá ṣe? Abájọ táwọn Filísínì fi wọ́n ṣẹlẹ́yà, tí wọ́n ké sí wọn pé: “Ẹ gòkè tọ̀ wá wá, dájúdájú, àwa yóò sì fojú yín rí nǹkan!”—1 Sámúẹ́lì 13:​19-​23; 14:​11, 12.

Àwọn Filísínì ti rò pé àwọn máa kọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì méjì yẹn lọ́gbọ́n, wọn ò mọ̀ pé àwọn gan-an làwọn máa kọ́gbọ́n. Kíá, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì méjèèjì gba àfonífojì tóóró yẹn sọdá sí òdìkejì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í pọ́n òkè. Òkè náà da gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ débi pé àtọwọ́ àtẹsẹ̀ ni wọ́n fi pọ́n ọn, àmọ́ wọn ò kẹ̀rẹ̀, wọ́n ṣáà ń pọ́n àwọn àpáta yẹn, ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ ogun yẹn ni wọ́n forí lé! (1 Sámúẹ́lì 14:13) Àwọn Filísínì ṣẹ̀ṣẹ̀ wá rí i pé ọkùnrin tó ṣáájú ní ohun ìjà, ẹni tó ń bá a ru ìhámọ́ra ló sì tẹ̀ lé e. Àmọ́ ṣé lóòótọ́ ni ọkùnrin yìí ní in lọ́kàn pé kí àwọn méjì dá lọ gbéjà ko gbogbo àwọn ọmọ ogun tó pàgọ́ sẹ́yìn ibùdó? Ṣé kì í ṣe pé orí ẹ̀ ti yí ṣá?

Orí ẹ̀ ò kúkú yí; ẹni tí ìgbàgbọ́ ẹ̀ lágbára lọkùnrin yìí. Jónátánì lorúkọ ẹ̀, àwa Kristẹni tòótọ́ lóde òní sì lè rí àwọn ẹ̀kọ́ kọ́ látinú ìtàn ẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwa kì í jagun, ọ̀pọ̀ nǹkan la lè kọ́ lára Jónátánì tó bá dọ̀rọ̀ ìgboyà, ìdúróṣinṣin àti àìmọ-tara-ẹni-nìkan tá a nílò kí ìgbàgbọ́ wa lè jinlẹ̀.—Aísáyà 2:4; Mátíù 26:​51, 52.

Ọmọ Tó Jẹ́ Adúróṣinṣin àti Jagunjagun Tó Nígboyà

Ká lè mọ ìdí tí Jónátánì fi lọ gbéjà ko ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun yẹn, ó yẹ ká ṣàyẹ̀wò ibi tó dàgbà sí. Jónátánì ni ọmọ Sọ́ọ̀lù tó dàgbà jù, Sọ́ọ̀lù sì ni ọba àkọ́kọ́ ní Ísírẹ́lì. Nígbà tí Ọlọ́run yan Sọ́ọ̀lù ṣe ọba, Jónátánì kì í ṣe ọmọdé mọ́ nígbà yẹn, ó ṣeé ṣe kó ti tó ọmọ ogún (20) ọdún tàbí kó ti jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó jọ pé Jónátánì àti bàbá ẹ̀ sún mọ́ra gan-an, torí bàbá ẹ̀ sábà máa ń sọ tinú ẹ̀ fún un. Èèyàn gíga ni Sọ́ọ̀lù, ó rẹwà, jagunjagun tó sì nígboyà ni. Jónátánì mọ gbogbo èyí, àmọ́ ohun pàtàkì míì wà tó tún mọ bàbá ẹ̀ mọ́ nígbà yẹn. Ó mọ̀ pé bàbá òun nígbàgbọ́, ó sì nírẹ̀lẹ̀. Jónátánì rí ìdí tí Jèhófà fi yan Sọ́ọ̀lù ṣe ọba. Kódà, wòlíì Sámúẹ́lì sọ pé kò sẹ́ni tó dà bíi Sọ́ọ̀lù ní gbogbo ilẹ̀ náà!—1 Sámúẹ́lì 9:​1, 2, 21; 10:​20-​24; 20:2.

Jónátánì ti gbọ́dọ̀ mọyì àǹfààní tó ní láti bá bàbá ẹ̀ jagun tó fi máa rẹ́yìn àwọn ọ̀tá Jèhófà. Àwọn ogun ìgbà yẹn ò dá bí àwọn ogun táwọn orílẹ̀-èdè ń bára wọn jà lónìí. Nígbà yẹn, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ni Jèhófà yàn pé kí wọ́n máa ṣojú òun, àwọn orílẹ̀-èdè tó ń bọ̀rìṣà sì sábà máa ń gbéjà kò wọ́n ṣáá. Àwọn Filísínì, táwọn náà ń sin òrìṣà bíi Dágónì, sábà ń yọ àwọn èèyàn Jèhófà lẹ́nu, kódà wọ́n tiẹ̀ fẹ́ pa wọ́n run.

Jónátánì gbà pé ọ̀nà tóun fi lè jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà Ọlọ́run ni kóun máa ja irú àwọn ogun yìí. Jèhófà sì bù kún ìsapá rẹ̀. Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Sọ́ọ̀lù di ọba tó fi yan ọmọ rẹ̀ pé kó máa darí ẹgbẹ̀rún kan (1,000) ọmọ ogun, Jónátánì sì kó wọn lọ gbéjà ko ibùdó àwọn ọmọ ogun Filísínì kan ní Gébà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ ogun Jónátánì ò fi bẹ́ẹ̀ ní ohun ìjà, Jèhófà ran Jónátánì lọ́wọ́ tí wọ́n fi borí. Làwọn Filísínì bá lọ kóra wọn wá. Ẹ̀rù ba ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọmọ ogun Sọ́ọ̀lù. Àwọn kan lọ sá pa mọ́, ṣe làwọn kan tiẹ̀ dara pọ̀ mọ́ àwọn Filísínì! Àmọ́ ìgboyà Jónátánì ò yingin.—1 Sámúẹ́lì 13:​2-7; 14:21.

Lọ́jọ́ tá a mẹ́nu bà níbẹ̀rẹ̀ ìtàn yìí, Jónátánì pinnu pé òun máa yọ́ jáde, ẹni tó ń bá a ru ìhámọ́ra rẹ̀ nìkan ló sì mú dání. Bí wọ́n ṣe ń sún mọ́ ibùdó àwọn ọmọ ogun Filísínì tó wà ní Míkímáṣì, Jónátánì sọ ohun tó fẹ́ ṣe fún ẹni tó ń bá a ru ìhámọ́ra. Ó sọ pé àwọn máa fi ara àwọn han àwọn ọmọ ogun Filísínì tó wà lórí òkè. Tí àwọn Filísínì bá sọ pé kí àwọn méjèèjì máa gòkè bọ̀ wá bá àwọn jà, a jẹ́ pé àmì ló jẹ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà pé òun máa ran àwọn ìránṣẹ́ òun lọ́wọ́. Ẹni tó ń bá a ru ìhámọ́ra gbà láìjanpata, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọ̀rọ̀ ìwúrí tí Jónátánì sọ ló fún un lókun. Jónátánì sọ pé: “Kò sí ìdílọ́wọ́ fún Jèhófà láti fi púpọ̀ tàbí díẹ̀ gbà là.” (1 Sámúẹ́lì 14:​6-​10) Kí ló ní lọ́kàn?

Ó ṣe kedere pé Jónátánì mọ Ọlọ́run rẹ̀ dáadáa. Ó dájú pé ó mọ bí Jèhófà ṣe ti ran àwọn èèyàn ẹ̀ lọ́wọ́ nígbà àtijọ́ kí wọ́n lè ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá tó pọ̀ jù wọ́n lọ fíìfíì. Ó tiẹ̀ ti lo ẹnì kan ṣoṣo rí láti ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá. (Onídàájọ́ 3:​31; 4:​1-​23; 16:​23-​30) Torí náà, Jónátánì mọ̀ pé kì í ṣe bí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run bá ṣe pọ̀ tó àbí bí ohun ìjà wọn ṣe lágbára tó ló ṣe pàtàkì; ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní ló ṣe pàtàkì. Ìgbàgbọ́ ló mú kí Jónátánì fi ọ̀rọ̀ lé Jèhófà lọ́wọ́ kó pinnu bóyá kí òun àti ẹni tó ń bá òun ru ìhámọ́ra gbéjà ko àwọn ọmọ ogun Filísínì náà. Ó yan àmì kan tó fi máa mọ̀ bóyá Jèhófà fọwọ́ sí ohun tó fẹ́ ṣe. Nígbà tó sì ti rí i pé Jèhófà fọwọ́ sí i, ṣe ló fìgboyà gbé ìgbésẹ̀.

Kíyè sí ohun méjì nípa ìgbàgbọ́ Jónátánì. Àkọ́kọ́ ni pé ó bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀. Ó mọ̀ pé kì í ṣe agbára èèyàn ni Ọlọ́run Olódùmarè máa ń gbára lé láti fi ṣe ohun tó ní lọ́kàn, síbẹ̀, inú Jèhófà máa ń dùn láti bù kún àwọn olóòótọ́ èèyàn tó ń sìn ín. (2 Kíróníkà 16:9) Ìkejì ni pé, kó tó di pé Jónátánì gbé ìgbésẹ̀, ó wá ẹ̀rí tó máa jẹ́ kó mọ̀ bóyá Jèhófà fọwọ́ sí ohun tó fẹ́ ṣe. Lóde òní, a kì í béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run pé kó fi nǹkan àràmàǹdà hàn wá ká lè mọ̀ bóyá ó fọwọ́ sí ohun tá a fẹ́ ṣe. Níwọ̀n ìgbà tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó mí sí lódindi ti wà lárọ̀ọ́wọ́tó wa, kò sí nǹkan míì tá a tún nílò láti fi mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ká ṣe. (2 Tímótì 3:​16, 17) Ṣé a máa ń fara balẹ̀ wo ohun tí Bíbélì sọ ká tó ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì? Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe là ń ṣe bíi ti Jónátánì, à ń fi hàn pé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe pàtàkì sí wa ju ohun táwa fúnra wa fẹ́ lọ.

Bí jagunjagun yìí àti ẹni tó bá a ru ìhámọ́ra ṣe yára gun òkè tó da gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ yẹn nìyẹn, tí wọ́n forí lé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ ogun Filísínì. Nígbà táwọn Filísínì rí i pé wọ́n fẹ́ wá bá àwọn jà lóòótọ́, wọ́n rán àwọn ọmọ ogun lọ bá àwọn méjèèjì jà. Kì í ṣe pé àwọn ọmọ ogun Filísínì pọ̀ ju àwọn méjèèjì lọ nìkan ni, wọ́n tún ń jàǹfààní pé orí òkè làwọn wà, torí náà bí ẹni fẹran jẹ̀kọ ló yẹ kó rí fún wọn láti yanjú àwọn méjì yìí. Àmọ́ ṣe ni Jónátánì ń ṣá wọn balẹ̀ níkọ̀ọ̀kan. Ẹni tó ń bá ru ìhámọ́ra rẹ̀ náà sì ń ṣá wọn balẹ̀ lọ lẹ́yìn rẹ̀. Níbi tí wọ́n rọra dúró sí yẹn, àwọn méjèèjì ti mú ogún (20) balẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun Filísínì! Jèhófà tún wá ṣe nǹkan kan. Bíbélì sọ pé: “Nígbà náà ni ìwárìrì ṣẹlẹ̀ ní ibùdó inú pápá àti láàárín gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà lára ọ̀wọ́ ọmọ ogun ẹ̀yìn ibùdó; agbo ọmọ ogun àwọn akóni-ní-ìkógun sì wárìrì, àní àwọn pàápàá, ilẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí mì tìtì, ó sì di ìwárìrì láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”—1 Sámúẹ́lì 14:15.

Jónátánì mú ẹnì kan ṣoṣo dání lọ gbéjà ko àwọn ọmọ ogun ọ̀tá tó dìhámọ́ra níbi tí wọ́n pabùdó sí

Àti ọ̀ọ́kán ni Sọ́ọ̀lù àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ ti ń wo bí gọngọ ṣe ń sọ nínú ibùdó àwọn Filísínì, tí gbogbo ẹ̀ sì dojú rú fún wọn. Kódà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í dojú idà kọ ara wọn! (1 Sámúẹ́lì 14:​16, 20) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fìgboyà lọ gbéjà kò wọ́n, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ohun ìjà àwọn ọmọ ogun Filísínì tó ti kú ni wọ́n lò. Jèhófà mú kí àwọn èèyàn ẹ̀ ṣẹ́gun gan-an lọ́jọ́ yẹn. Kò sì tíì yí pa dà látìgbà yẹn. Tá a bá nígbàgbọ́ nínú ẹ̀ lónìí, bíi ti Jónátánì àti ẹni tó ń bá a ru ìhámọ́ra àmọ́ tóun ò ní nǹkan ìjà, kò ní sídìí fún wa láé láti kábàámọ̀.—Málákì 3:6; Róòmù 10:11.

“Ó Bá Ọlọ́run Ṣiṣẹ́ Pọ̀”

Àmọ́ bí ọ̀rọ̀ ìṣẹ́gun yẹn ṣe rí fún Jónátánì kọ́ ló rí fún Sọ́ọ̀lù. Sọ́ọ̀lù ti ṣe àwọn àṣìṣe kan tó burú gan-an. Ó ṣàìgbọràn sí Sámúẹ́lì, wòlíì tí Jèhófà yàn, ní ti pé ó gba iṣẹ́ wòlíì náà ṣe. Òun ló lọ rúbọ tó yẹ kí wòlíì náà tó jẹ́ ọmọ Léfì rú. Nígbà tí Sámúẹ́lì dé, ó sọ fún Sọ́ọ̀lù pé torí ìwà àìgbọràn tó hù yìí, ìjọba rẹ̀ ò ní wà pẹ́ títí. Nígbà tó yá, tí Sọ́ọ̀lù rán àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lọ jagun, ó kọ́kọ́ mú kí wọ́n ṣe ìbúra kan tí kò mọ́gbọ́n dání, ó sọ pé: “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó bá jẹ oúnjẹ kí ó tó di alẹ́ àti títí èmi yóò fi gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá mi!”—1 Sámúẹ́lì 13:​10-​14; 14:24.

Àwọn ọ̀rọ̀ tí Sọ́ọ̀lù sọ yẹn jẹ́ ká rí i pé ìwà ẹ̀ ti ń yí pa dà sí búburú. Ó jọ pé ọkùnrin onírẹ̀lẹ̀ tó ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run lọ́jọ́ kìíní àná ti ń di agbéraga tó ń wá ipò? Kì í ṣáà ṣe Jèhófà ló sọ fún un pé kó mú kí àwọn ọmọ ogun onígboyà tí wọ́n ṣiṣẹ́ kára yẹn ṣe ìbúra tí kò mọ́gbọ́n dání tó máa ká wọn lọ́wọ́ kò bẹ́ẹ̀. Ẹ tún wo ohun tí Sọ́ọ̀lù sọ, tó ní “títí èmi yóò fi gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá mi.” Ẹ ò rí i pé ó jọ pé Sọ́ọ̀lù ń rò ó pé torí òun ni wọ́n ṣe ń jagun? Àbí ó ti gbàgbé pé ìdájọ́ òdodo tí Jèhófà fẹ́ ṣe fáwọn ọ̀tá rẹ̀ ló ṣe pàtàkì jù, pé kì í ṣe ẹ̀san tóun fẹ́ gbà tàbí ògo àti ìṣẹ́gun tí òun ń wá?

Jónátánì ò mọ nǹkan kan nípa ìbúra tí kò mọ́gbọ́n dání tí bàbá rẹ̀ ní kí àwọn ọmọ ogun ṣe. Ẹni tó ti rẹ̀ tẹnutẹnu torí ojú ogun le lọ́hùn-ún, nígbà tó rí afárá oyin, ṣe ló ki ọ̀pá rẹ̀ bọ̀ ọ́, tó sì lá oyin. Gbàrà tó ṣe bẹ́ẹ̀ ló mọ̀ ọ́n lára pé okun òun pa dà. Ọ̀kan lára àwọn ọmọ ogun rẹ̀ wá sọ fún un nípa ohun tí bàbá rẹ̀ sọ pé àwọn ò gbọ́dọ̀ fi nǹkan kan sẹ́nu. Jónátánì fèsì pé: “Baba mi ti mú ìtanùlẹ́gbẹ́ wá sórí ilẹ̀ yìí. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ wo bí ojú mi ti tàn yanran nítorí pé mo tọ́ oyin díẹ̀ yìí wò. Mélòómélòó ni ì bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ká ní àwọn ènìyàn náà ti jẹ lónìí nínú ohun ìfiṣèjẹ àwọn ọ̀tá wọn tí wọ́n rí! Nítorí ìpakúpa lára àwọn Filísínì kò tíì pọ̀ nísinsìnyí.” (1 Sámúẹ́lì 14:​25-30) Òótọ́ ló kúkú sọ. Adúróṣinṣin ọmọ ni Jónátánì lóòótọ́, àmọ́ ìdúróṣinṣin rẹ̀ sí Ọlọ́run ló kà sí pàtàkì jù. Kì í kàn ṣe gbogbo nǹkan tí bàbá rẹ̀ bá ti sọ ló máa ń gbà láìrò ó, àpẹẹrẹ ìdúróṣinṣin rẹ̀ yẹn sì wú àwọn míì lórí.

Nígbà tí Sọ́ọ̀lù mọ̀ pé Jónátánì ti rú òfin tí òun gbé kalẹ̀, kò gbà náà pé òun ti ṣàṣìṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló gbà pé ikú tọ́ sí ọmọ bíbí inú òun! Jónátánì ò bá a jiyàn, kò ní kó má pa òun. Ẹ kíyè sí ohun tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tó sọ. Ó gbà láti fẹ̀mí ara ẹ̀ lélẹ̀, ó ní: “Èmi nìyí! Jẹ́ kí n kú!” Àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò gbà, wọ́n ní: “Jónátánì yóò ha kú, tí ó ti mú ìgbàlà ńláǹlà yìí ṣe ní Ísírẹ́lì? Kò ṣée ronú kàn! Bí Jèhófà ti ń bẹ láàyè, ẹyọ kan nínú irun orí rẹ̀ kì yóò bọ́ sí ilẹ̀; nítorí ó bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́ pọ̀ lónìí yìí.” Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Sọ́ọ̀lù gbà pẹ̀lú wọn. Bíbélì sọ pé: “Pẹ̀lú ìyẹn, àwọn ènìyàn tún Jónátánì rà padà, kò sì kú.”—1 Sámúẹ́lì 14:​43-​45.

“Èmi nìyí! Jẹ́ kí n kú!”

Torí pé Jónátánì nígboyà, ó máa ń ṣiṣẹ́ kára, kò sì mọ tara ẹ̀ nìkan, ó ti ní orúkọ rere lọ́dọ̀ àwọn tó ń rí i. Nígbà tó wà nínú ewu, orúkọ rere tó ti ní ló gbà á sílẹ̀. Ó dáa káwa náà ronú lórí orúkọ tá à ń ṣe fún ara wa lójoojúmọ́. Bíbélì sọ fún wa pé orúkọ rere ṣeyebíye gan-an. (Oníwàásù 7:1) Táwa náà bá ní orúkọ rere lọ́dọ̀ Jèhófà bíi ti Jónátánì, ìṣúra ńlá gbáà ló máa jẹ́.

Sọ́ọ̀lù Di Èèyàn Burúkú

Láìka àwọn àṣìṣe tí Sọ́ọ̀lù ń ṣe, Jónátánì ṣì ń bá a jagun láwọn ọdún yẹn, kò yẹ ìdúróṣinṣin rẹ̀ sí bàbá ẹ̀. Ẹ wo bínú ẹ̀ ṣe máa bà jẹ́ tó bó ṣe ń rí i tí bàbá ẹ̀ ń di aláìgbọràn àti agbéraga. Bàbá ẹ̀ ti ń di èèyàn burúkú, àmọ́ kò sí ohun tí Jónátánì lè ṣe sí i.

Ọ̀rọ̀ náà wá dé góńgó nígbà tí Jèhófà ní kí Sọ́ọ̀lù lọ ba àwọn ọmọ Ámálékì jagun. Ìwà burúkú ló kún ọwọ́ àwọn ọmọ Ámálékì yìí, débi pé àtìgbà ayé Mósè ni Jèhófà ti sọ tẹ́lẹ̀ pé òun máa pa orílẹ̀-èdè náà run. (Ẹ́kísódù 17:14) Jèhófà sọ fún Sọ́ọ̀lù pé kó pa gbogbo nǹkan ọ̀sìn wọn run, kó sì pa Ágágì ọba wọn. Sọ́ọ̀lù ṣẹ́gun lóòótọ́, ó sì dájú pé Jónátánì ọmọ rẹ̀ fìgboyà kún un lọ́wọ́ lójú ogun bó ṣe máa ń ṣe tẹ́lẹ̀. Àmọ́ Sọ́ọ̀lù mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí Jèhófà, ó dá Ágágì sí, kò sì pa ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Ámálékì run. Wòlíì Sámúẹ́lì kéde ìdájọ́ ìkẹyìn tí Jèhófà máa ṣe lórí Sọ́ọ̀lù, ó ní: “Níwọ̀n bí o ti kọ ọ̀rọ̀ Jèhófà, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, òun kọ̀ ọ́ ní ọba.”—1 Sámúẹ́lì 15:​2, 3, 9, 10, 23.

Kò pẹ́ sígbà yẹn tí Jèhófà gba ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ kúrò lára Sọ́ọ̀lù. Torí pé ẹ̀mí Jèhófà ò sí lára Sọ́ọ̀lù mọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kanra lódìlódì, ìbínú ẹ̀ wá le gan-an, ẹ̀rù sì máa ń bà á. Ṣe ló dà bí ìgbà tí ẹ̀mí burúkú látọ̀dọ̀ Ọlọ́run rọ́pò èyí tó dáa tó wà lára Sọ́ọ̀lù tẹ́lẹ̀. (1 Sámúẹ́lì 16:14; 18:​10-​12) Ẹ wo bí ìdààmú ṣe máa bá Jónátánì tó pé bàbá òun tó jẹ́ èèyàn dáadáa nígbà kan ti wá dìdàkudà! Síbẹ̀, Jónátánì ò yéé jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Ó ti bàbá rẹ̀ lẹ́yìn débi tí agbára ẹ̀ gbé e dé, kódà, ó máa ń bá bàbá ẹ̀ sọ òótọ́ ọ̀rọ̀ nígbà míì, àmọ́ kò fìgbà kan gbọ́kàn kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Baba rẹ̀ tí kì í yí pa dà.—1 Sámúẹ́lì 19:​4, 5.

Ṣé ó ti ṣe yín rí, kẹ́ ẹ rí i tí ẹnì kan tẹ́ ẹ nífẹ̀ẹ́, bóyá mọ̀lẹ́bí kan tẹ́ ẹ sún mọ́ra, tó jẹ́ èèyàn dáadáa tẹ́lẹ̀ wá dìdàkudà? Ó máa ń dunni wọra. Àpẹẹrẹ Jónátánì rán wa létí ohun tí onísáàmù pa dà kọ, tó ní: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé baba mi àti ìyá mi fi mí sílẹ̀, àní Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò tẹ́wọ́ gbà mí.” (Sáàmù 27:10) Olóòótọ́ ni Jèhófà. Ohun yòówù kí èèyàn aláìpé ṣe fún ẹ tó dùn ẹ́ tàbí tí wọ́n fi já ẹ kulẹ̀, Jèhófà máa tẹ́wọ́ gba ìwọ náà, á sì ṣe Bàbá fún ẹ ju bó o ṣe rò lọ.

Ó ṣeé ṣe kí Jónátánì mọ̀ pé Jèhófà máa gba ìjọba kúrò lọ́wọ́ Sọ́ọ̀lù. Kí ló wá ṣe? Àbí ó tiẹ̀ ń rò ó pé ọba rere lòun máa jẹ́ ní tòun? Ṣé ó rò ó pé tóun bá di ọba, òun á lè ṣàtúnṣe àwọn àìdáa tí bàbá òun ti ṣe, tóun á sì jẹ́ àpẹẹrẹ ìdúróṣinṣin àti ìgbọràn fáwọn míì. A ò mọ ohun tó rò lọ́kàn, àmọ́ a mọ̀ pé tó bá ro irú ẹ̀, kò lè ṣẹlẹ̀. Ṣó wá túmọ̀ sí pé Jèhófà ti pa ọkùnrin olóòótọ́ yẹn tì ni? Rárá o, ṣe ló lo Jónátánì láti kọ́ wa ní àpẹẹrẹ ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ tó jẹ́ jù nínú Bíbélì! Ọ̀rọ̀ nípa òun àti ẹni tó bá ṣọ̀rẹ́ la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ míì tó dá lórí Jónátánì.