Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn | SÁRÀ

“O Jẹ́ Obìnrin Kan Tí Ó Lẹ́wà Ní Ìrísí”

“O Jẹ́ Obìnrin Kan Tí Ó Lẹ́wà Ní Ìrísí”

SÁRÀ dúró sí àárín méjì yàrá, ó ń wò yíká. Fojú inú yàwòrán obìnrin arẹwà kan, tójú rẹ̀ kọrẹ́ lọ́wọ́. Ǹjẹ́ nǹkan kan wà tó lè máa ba obìnrin yìí lọ́kàn jẹ́? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, kó lè ṣòro fún wa láti mọ nǹkan náà. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló ti ṣẹlẹ̀ nínú ilé yìí. Òun àti Ábúráhámù ọkọ rẹ̀ àtàtà ti jọ gbádùn ara wọn nínú ilé yìí. * Wọ́n sì ti jọ pawọ́ pọ̀ sọ ọ́ di ibi tó tura.

Ìlú Úrì ni wọ́n ń gbé. Ìlú tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù ni, àwọn oníṣẹ́-ọwọ́, oníṣẹ́-ọnà àti oníṣòwò sì wà níbẹ̀. Èyí fi hàn pé wọ́n láwọn ohun ìní tó pọ̀. Àmọ́, ilé tí Sárà ń gbé kọjá pé kó kàn ríbi kó ohun ìní rẹ̀ sí o. Nínú ilé yìí, òun àti ọkọ rẹ̀ ti dojú kọ ọ̀pọ̀ nǹkan, wọ́n ti ní àkókò ayọ̀ àti àkókò tí nǹkan ò lọ dáadáa fún wọn. Wọ́n ti gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run wọn lọ́pọ̀ ìgbà. Kò sí àní-àní pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló máa mú kí Sárà fẹ́ràn ibi yìí gan-an.

Síbẹ̀, Sárà múra tán láti fi gbogbo àwọn ohun tó gbádùn mọ́ ọn yìí sílẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ẹni ọgọ́ta [60] ọdún, síbẹ̀ ó máa ní láti rìnrìn-àjò lọ síbi tí kò mọ̀. Yàtọ̀ síyẹ̀n, ìrìn àjò náà tún léwu, ó sì nira, kò sì sírètí pé ọjọ́ báyìí ni wọ́n máa pa dà sílé. Kí ló fa àyípadà òjijì yìí? Kí la sì lè rí kọ́ látinú ìgbàgbọ́ rẹ̀?

“JÁDE KÚRÒ NÍ ILẸ̀ RẸ”

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìlú Úrì ni Sárà dàgbà sí. Ìlú náà sì ti dahoro báyìí. Àmọ́ nígbà ayé Sárà, ọkọ̀ òkun àwọn oníṣòwò máa ń gba orí Odò Yúfírétì kó ẹrù láti ọ̀nà jíjìn wá sí ìlú yìí. Ńṣe làwọn èèyàn má ń wọ́ tìrítìrí láwọn ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀ tó wà nílùú náà, àwọn ọkọ̀ ojú omi tó ń kẹ́rù wá ò lóǹkà, bẹ́ẹ̀ ni ìsọ̀ àwọn oníṣòwò pọ̀ lọ súà. Fọkàn yàwòrán bí Sárà ṣe ń dàgbà nínú ìlú yìí, tó sì mọ àwọn aráàlú náà délédélé. Ó dájú pé wọ́n ò ní gbàgbé òun náà torí pé obìnrin tó rẹwà lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ ni. Ó tún ní mọ̀lẹ́bí tó pọ̀ nílùú náà.

Bíbélì fi hàn pé Sárà ní ìgbágbọ́ tó lágbára, àmọ́ ṣá o, kì í ṣe ìgbàgbọ́ nínú òrìṣà tí wọ́n mọ ilé gogoro fún nílùú Úrì tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń bọ. Kedere ni ẹni tó bá wọ ìlú yìí máa rí ère òrìṣà náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́ ni Sárà ń sìn ní tiẹ̀. Ìwé Mímọ́ kò sọ bí Sárà ṣe dẹni tó nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. Ìgbà kan wà tó jẹ́ pé abọ̀rìṣà ni bàbá ẹ̀. Ṣùgbọ́n, ó fẹ́ Ábúráhámù tó fi nǹkan bí ọdún mẹ́wàá jù ú lọ. * (Jẹ́nẹ́sísì 17:17) Nígbà tó yá, Bíbélì pe Ábúráhámù ní “baba gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́.” (Róòmù 4:11) Àwọn méjèèjì jọ mú kí ìdílé wọn lágbára, wọ́n bọ̀wọ̀ fún ara wọn, wọ́n jọ máa ń sọ̀rọ̀ dáadáa, wọ́n sì jọ máa ń pawọ́ pọ̀ yanjú ìṣòro tó bá jẹ yọ. Èyí tó wá borí gbogbo ẹ̀ ni pé àwọn méjèèjì ló nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run.

Sárà nífẹ̀ẹ́ ọkọ rẹ̀ dénú, àárín àwọn ìbátan wọn ní ìlú Úrì sì ni wọ́n ń gbé. Àmọ́ nǹkan ò lọ dáadáa bí wọ́n ṣe rò. Bíbélì sọ fún wa pé Sárà “jẹ́ àgàn; kò ní ọmọ kankan.” (Jẹ́nẹ́sísì 11:30) Lásìkò yẹn, nǹkan àbùkù gbáà ni kí obìnrin má rọ́mọ bí, torí náà ipò tí Sárà wà kò bára dé rárá. Síbẹ̀, Sárà jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run àti ọkọ rẹ̀. Wọ́n wá gba Lọ́ọ̀tì tó jẹ́ ọmọ ẹ̀gbọ́n Ábúráhámù ṣọmọ, torí pé kò ní bàbá mọ́. Wọ́n sì ń bá ìgbésí ayé wọn lọ, àfi lọ́jọ́ kan tí nǹkan ṣàdédé yí pa dà.

Ábúráhámù sáré wá sọ́dọ̀ Sárà, inú rẹ̀ sì ń dùn. Àfi bí àlá lohun tó ṣẹlẹ̀ rí lójú rẹ̀. Ọlọ́run tòótọ́ tí wọ́n ń sìn ṣẹ̀ṣẹ̀ bá a sọ̀rọ̀ tán ni. Kódà, ńṣe ló fara hàn án nípasẹ̀ ańgẹ́lì kan! Fojú inú wo bí Sára ṣe tẹjú mọ́ ọkọ rẹ̀, tó ń béèrè lemọ́lemọ́ pé: “Kí ló sọ fún yín? Ẹ jọ̀ọ́, ẹ sọ fún mi!” Ó ṣeé ṣe kí Ábúráhámù kọ́kọ́ jọ́kòó ná, kó wá máa ro ibi tó ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó wá sọ ohun tí Jèhófà sọ fún ìyàwó rẹ̀ pé: “Jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ìbátan rẹ, kí o sì wá sí ilẹ̀ tí èmi yóò fi hàn ọ́.” (Ìṣe 7:2, 3) Nígbà tára wọn balẹ̀, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa iṣẹ́ tí Jèhófà gbé síwájú wọn. Wọ́n máa fi ìgbésí ayé gbẹdẹmukẹ tí wọ́n ń gbé sílẹ̀, wọ́n á sì dẹni tó ń ṣí kiri! Báwo lọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára Sárà? Ó dájú pé ńṣe ni Ábúráhámù á tẹ́jú mọ́ Sárà. Á máa ronú pé ṣé ìyàwó mi á gbà tinútinú láti ṣe àyípadà ńlá yìí?

Ìpinnu tí Sárà fẹ́ ṣe yìí lè máa yé wa. A lè máa rò ó pé, ‘Ọlọ́run ò tíì ní kí èmí tàbí ẹnì kejì mi ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀!’ Àmọ́, gbogbo wa la máa ń ṣe irú ìpinnu tó jọ ọ́? Àwọn èèyàn fẹ́ràn kíkó ohun ìní jọ báyìí, èyí sì lè mú kó máa wu àwa náà pé ká gbé ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ, ká ní ohun ìní, kọ́kàn wa sì balẹ̀. Àmọ́ Bíbélì rọ̀ wá pé ká fi àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run ṣáájú àwọn nǹkan yẹn, ìyẹn ni pé ká sapá láti ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ dípò ohun tá a fẹ́. (Mátíù 6:33) Bá a ṣe ń ronú nípa ohun tí Sárà ṣe, a lè bi ara wa pé, ‘Kí ni màá fi sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé mi?’

WỌ́N “JÁDE KÚRÒ NÍ ILẸ̀” NÁÀ

Bí Sárà ṣe ń di ẹrù rẹ̀, ọkàn rẹ̀ ń ṣe kámi-kàmì-kámi nípa èyí tó máa kó àtèyí tó máa fi sílẹ̀. Ó lè fi àwọn ẹrù tó máa wúwo jù fáwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti ràkúnmí sílẹ̀, àtàwọn tí kò ní wúlò fún wọn bí wọ́n á ṣe máa ṣí láti ibì kan sí ibòmíì. Kò sí àní-àní pé wọ́n máa ní láti ta àwọn kan lára ẹrù wọn, wọ́n á sì fi àwọn míì tọrẹ. Wọ́n tún máa pàdánù àǹfààní tí wọ́n ń rí ní ìgboro, bí ọjà tí wọ́n ti máa ń ra àwọn nǹkan èlò bí ẹran, èso, aṣọ, àwọn nǹkan oníhóró àtàwọn ohun kò-ṣeé-má-nìí míì.

Ìgbàgbọ́ Sárà mú kó fi ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ sílẹ̀

Ó tún ṣeé ṣe kó ṣòro fún Sárà láti fi ilé wọn sílẹ̀. Tí ilé wọn bá rí bí àwọn ilé táwọn awalẹ̀pìtàn wú jáde ní ìlú Úrì, á jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan amáyédẹrùn ni Sárà máa pàdánù. Bí àpẹẹrẹ, yàrá tó wà nínú àwọn ilé kan lé ní méjìlá, wọ́n sì ní omi tó mọ́. Kódà ilé tí ò fi bẹ́ẹ̀ jọjú máa ń ní òrùlé àti ògirí tó lágbára, ilẹ̀kùn wọn sì máa ń ní ohun téèyàn lè fi tì í pa. Ṣé ẹni tó ń gbé inú àgọ́ lè rí irú ààbò bẹ́ẹ̀? Rárá o. Oríṣiríṣi nǹkan ló lè wọlé tọ̀ wọ́n, bí àwọn olè. Àwọn ẹranko ẹhànnà bí kìnnìún, àmọ̀tẹ́kùn, béárì, ìkookò, sì tún pọ̀ lágbègbè náà nígbà yẹn.

Àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ńkọ́? Àwọn wo ni Sárà máa fi sílẹ̀? Ó lè ṣòro fún Sárà láti tẹ̀ lé àṣẹ tí Ọlọ́run pa pé “jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ìbátan rẹ.” Ó dájú pé obìnrin onínuúre, tó sì kóòyàn mọ́ra yìí máa ní láti fi àwọn ẹ̀gbọ́n, àbúrò, àtàwọn mọ̀lẹ́bí míì sílẹ̀, ó sì ṣeé ṣe kó má tún pa dà fojú kàn wọ́n mọ́. Síbẹ̀, Sárà ò lọ́ tìkọ̀, ó ṣáà ń palẹ̀ ẹrù rẹ̀ mọ́.

Láìka gbogbo ìṣòro yìí sí, Sárà di ẹrù rẹ̀, ó sì múra tán láti lọ. Térà tó jẹ́ bàbá àgbà máa tẹ̀ lé Ábúráhámù àti Sárà lọ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti tó ẹni igba [200] ọdún. (Jẹ́nẹ́sísì 11:31) Iṣẹ́ ńlá ló já lé Sárà léjìká yìí o, ìyẹn ni bó ṣe máa bójú tó bàbá àgbàlagbà yìí. Gbogbo wọn tẹ̀ lé ìtọ́ni Jèhófà, wọ́n “jáde kúrò ní ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà,” Lọ́ọ̀tì náà sì bá wọn lọ.Ìṣe 7:4.

Ìlú Háránì ni wọ́n kọ́kọ́ forí lé, ìyẹn sì jẹ́ nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kìlómítà ó dín ogójì [960] sí apá àríwá, wọ́n ń tọ ètí Odò Yúfírétì lọ. Nígbà tí wọ́n dé Háránì, ìdílé náà tẹ̀dó síbẹ̀ fúngbà díẹ̀. Ó lè jẹ́ pé Térà ti ń ṣàìsàn débi tí kò fi lè rìnrìn-àjò náa mọ́ lásìkò yìí. Ibẹ̀ ni wọ́n wà títí tó fi kú lẹ́ni igba ọdún ó lé márùn-ún [205]. Láàárín àkókò kan kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ apá kejì ìrìn-àjò náà, Jèhófà tún bá Ábúráhámù sọ̀rọ̀. Ó sọ fún un lẹ́ẹ̀kan sí i pé kó fi ìlú náà sílẹ̀, kó sì máa lọ síbi tí Òun máa fi hàn án. Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, Ọlọ́run fi ìlérí kan kún un fún Ábúráhámù, ó ní: “Èmi yóò sì mú orílẹ̀-èdè ńlá jáde lára rẹ.” (Jẹ́nẹ́sísì 12:2-4) Àmọ́, nígbà tí wọ́n fi máa kúrò nílùú Háránì, Ábúráhámù ti dẹni ọdún márùndínlọ́gọ́rin [75], Sárà sì jẹ́ ẹni ọdún márùnlélọ́gọ́ta [65], wọn ò sì tíì lọ́mọ kankan. Báwo ni orílẹ̀-èdè kan ṣe máa jáde látara Ábúráhámù? Ṣé ó máa fẹ́ ìyàwó míì ni? Nígbà yẹn, àwọn èèyàn sábà máa ń fẹ́ ju ìyàwó kan lọ, torí náà ó ṣeé ṣe kí Sárà náà ti máa rò ó pé àbí ọkọ òun máa fẹ́yàwó míì.

Bó ti wù kó rí, wọ́n fi ìlú Háránì sílẹ̀, wọ́n sì ń bá ìrìn-àjò náà lọ. Kíyè sí àwọn tó wá wà pẹ̀lú wọn báyìí. Àkọsílẹ̀ náà fi hàn pé ìdílé Ábúráhámù kó àwọn ẹrù tí wọ́n ti kó jọ kúrò níbẹ̀ àti “àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ní Háránì.” (Jẹ́nẹ́sísì 12:5, Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní) Àwọn wo làwọn èèyàn yìí? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn ìránṣẹ́. Ṣùgbọ́n, ó dájú pé Ábúráhámù àti Sárà sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fún àwọn tó fẹ́ gbọ́ lára wọn. Ìwé àwọn Júù láyé ìgbàanì tiẹ̀ sọ pé àláwọ̀ṣe làwọn èèyàn tíbí yìí tọ́ka sí, ìyẹn àwọn tó dara pọ̀ mọ́ Ábúráhámù àti Sárà láti máa jọ́sìn Jèhófà. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé ìgbàgbọ́ tó jinlẹ̀ tí Sárà ní máa mú kó fi ìdánilójú sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run rẹ̀ àti ìrètí tó ní fáwọn èèyàn yẹn. Ẹ̀kọ́ pàtàkì lèyí jẹ́ fún wa, torí pé inú ayé tí ìgbàgbọ́ àti ìrètí ò ti tó nǹkan là ń gbé báyìí. Tó o bá kọ́ ohun pàtàkì kan nínú Bíbélì, ǹjẹ́ o lè bá ẹlòmíì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?

“Ọ̀NÀ RẸ̀ SÍ ÍJÍBÍTÌ”

Lẹ́yìn tí wọ́n sọdá Odò Yúfírétì, ní nǹkan bí Nísàn 14, 1943 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, wọ́n gba apá gúúsù wọ ilẹ̀ tí Jèhófà ti ṣèlérí fún wọn. (Ẹ́kísódù 12:40, 41) Fojú inú yàwòrán bí Sárà ṣe ń wọ̀tún wòsì, tí ẹnu sì ń yà á torí bí ìlú náà ṣe lẹ́wà tó, tó ní oríṣiríṣi nǹkan, tójú ọjọ́ ibẹ̀ sì tura. Lẹ́bàá àwọn igi ńlá Mórè, nítòsí Ṣékémù, Jèhófà tún fara han Ábúráhámù lẹ́ẹ̀kàn sí i, lọ́tẹ̀ yìí ó sọ fún un pé: “Irú-ọmọ rẹ ni èmi yóò fi ilẹ̀ yìí fún.” Ó dájú pé Ábúráhámù máa ka gbólóhùn náà “irú-ọmọ” sí pàtàkì gan-an! Ó máa mú kó rántí ọgbà Édẹ́nì, níbí ti Jèhófà ti sọ tẹ́lẹ̀ pé irú-ọmọ kan máa pa Sátánì run. Jèhófà sì ti sọ fún Ábúráhámù tẹ́lẹ̀ pé ipasẹ̀ orílẹ̀-èdè tó ti inú rẹ̀ jáde ni gbogbo èèyàn inú ayé ti máa rí ìbùkún gbà.Jẹ́nẹ́sísì 3:15; 12:2, 3, 6, 7.

Àmọ́ ṣá o, ìṣòro tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń dojú kọ kò yọ ìdílé yìí sílẹ̀ o. Ìyàn ńlá bẹ́ sílẹ̀ nílùú Kénáánì, Ábúráhámù sì pinnu láti kó ìdílé rẹ̀ lọ sí Íjíbítì. Ṣùgbọ́n, ó kíyè sí i pé àgbègbè yìí léwu. Torí náà, ó sọ fún Sárà pé: “Wàyí o, jọ̀wọ́! Mo mọ̀ dáadáa pé o jẹ́ obìnrin kan tí ó lẹ́wà ní ìrísí. Nítorí náà, ó dájú pé yóò ṣẹlẹ̀ pé àwọn ará Íjíbítì yóò rí ọ, wọn yóò sì wí pé, ‘Aya rẹ̀ nìyí.’ Dájúdájú, wọn yóò sì pa mi, ṣùgbọ́n ìwọ ni wọn yóò pa mọ́ láàyè. Jọ̀wọ́, sọ pé arábìnrin mi ni ọ́, kí ó bàa lè lọ dáadáa fún mi ní tìtorí rẹ, ó sì dájú pé ọkàn mi yóò wà láàyè nítorí rẹ.” (Jẹ́nẹ́sísì 12:10-13) Kí nìdí tí Ábúráhámù fí ní kí Sárà ṣe bẹ́ẹ̀?

Ábúráhámù kì í ṣe òpùrọ́, kì í sì í ṣe ojo báwọn kan ṣe sọ. Àbúrò rẹ̀ ni Sárà jẹ́ lóòótọ́. Ó sì dáa gan-an bí Ábúráhámù ṣe kíyè sára. Ábúráhámù àti Sárà mọ̀ pé kò sí nǹkan míì tó tún ṣe pàtàkì bí ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé Ábúráhámù máa bí ọmọ kan tó máa di orílẹ̀-èdè ńlá, torí náà ìwàláàyè Ábúráhámù ṣe pàtàkì gan-an. Láfikún sí i, àwọn awalẹ̀pìtàn ti rí ẹ̀rí tó fi hàn pé àwọn alágbára nílẹ̀ Íjíbítì máa ń gba ìyàwó oníyàwó, tí wọ́n á sì pa ọkọ rẹ̀. Torí náà, ìwà ọgbọ́n ni Ábúráhámù hù, Sárà náà sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.

Kò pẹ́ tí ohun tí Ábúráhámù rò fi já sí òótọ́, àwọn kan lára àwọn ìjòye Fáráò rí i pé Sárà lẹ́wà tó kọ yọyọ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti dàgbà. Wọ́n sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún Fáráò, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n lọ mú un wá! Ó dájú pé ńṣe ni ìbànújẹ́ á sorí Ábúráhámù kodò, ẹ̀rù á sì máa bá Sárà gan-an. Àmọ́, ó jọ pé wọn ò ṣe é bí ẹrù, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ni wọ́n ń kẹ́ ẹ bí àlejò pàtàkì. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni Fáráò fẹ́ kọnu ìfẹ́ sí i, kó sì fi àwọn ohun ìní rẹ̀ fà á lójú mọ́ra, lẹ́yìn náà kó wá lọ san nǹkan ìdána fún Ábúráhámì “ẹ̀gbọ́n” rẹ̀, kó lè fi í ṣaya.Jẹ́nẹ́sísì 12:14-16.

Ronú nípa bí Sárà, ṣe ń wo ilẹ̀ Íjíbítì tó lọ salalu látojú fèrèsé. Báwo ló ṣe rí lára ẹ̀, kó tún dẹ́ni tó ń gbénú ilé, tó ní òrùlé pẹ̀lú àwọn oúnjẹ aṣaralóore? Ṣé irú ìgbésí ayé yọ̀tọ̀mì yìí wọ̀ ọ́ lójú? Ìyẹn ìgbésí ayé ọlọ́lá tó sàn ju èyí tó gbé nígbà tó wà nílùú Úrì. Inú Sátánì ì bá dùn gan-an ká ní Sárà gbà láti fi Ábúráhámù sílẹ̀, kó sì di ìyàwó Fáráò! Àmọ́ Sárà kò ṣe bẹ́ẹ̀. Ó jẹ́ adúróṣinṣin sí ọkọ rẹ̀, ìdílé rẹ̀ àti Ọlọ́run rẹ̀. Ó máa dáa gan-an tí àwọn tó ti gbéyàwó nínú ayé tí ìṣekúṣe kúnnú rẹ̀ yìí bá lè fi ìwà ìdúróṣinṣin bẹ́ẹ̀ hàn! Ǹjẹ́ o lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Sárà, kí ìwọ náà jẹ́ adúróṣinṣin sí ọkọ tàbí aya rẹ àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ?

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fi gbogbo nǹkan tẹ́ Sárà lọ́rùn láàfin Fáráò, síbẹ̀ ó jẹ́ adúróṣinṣin sí ọkọ rẹ̀

Jèhófà dá sí ọ̀rọ̀ náà, ó rán àjàkálẹ̀ àrùn sí Fáráò àti agbo ilé rẹ̀, ó sì yọ Sárà nínú ewu. Nígbà tí Fáráò mọ̀ pé ìyàwó Ábúráhámù ni Sárà, kíá ló dá a pa dà fún ọkọ rẹ̀, ó sì ní kí gbogbo wọn kúrò nílẹ̀ Íjíbítì. (Jẹ́nẹ́sísì 12:17-20) Inú Ábúráhámù dùn gan-an nígbà tí ìyàwó rẹ̀ pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀! Má gbàgbé pé ó ti sọ fún un tẹ́lẹ̀ pé: “Mo mọ̀ dáadáa pé o jẹ́ obìnrin kan tí ó lẹ́wà ní ìrísí” èyí sì fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n, ó tún mọyì ẹwà míì tí Sárà ní, ìyẹn ẹwà inú lọ́hùn-ún tó jinlẹ̀ ju ẹwà ojú lásán lọ. Sárà ní ẹwà inú, èyí tí Jèhófà mọyì gidigidi. (1 Pétérù 3:1-5) Irú ẹwà tó yẹ kí gbogbo wa sapá láti ní nìyẹn. Tá a bá fi àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run ṣáájú ohun ìní wa, tá à ń sọ ohun tá a mọ̀ nípa Ọlọ́run fáwọn míì, tá a sì ń tẹ̀ lé ìlànà ìwà rere tí Ọlọ́run fi lélẹ̀ láìka àdánwò sí, ńṣe là ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Sárà.

^ ìpínrọ̀ 3 Lákọ̀ọ́kọ́, Ábúrámù àti Sáráì lorúkọ wọn, àmọ́ orúkọ tí Jèhófà sọ wọ́n ló wá mọ́ wọn lórí.Jẹ́nẹ́sísì 17:5, 15.

^ ìpínrọ̀ 8 Ọbàkan Ábúráhámù ni Sárà. Térà ló bí àwọn méjèèjì, àmọ́ wọn kì í ṣọmọ ìyá kan náà. (Jẹ́nẹ́sísì 20:12) Irú ìgbéyàwó yìí kò bẹ́tọ̀ọ́ mu lóde òní, àmọ́ ó yẹ ká rántí pé nǹkan ò rí bó ṣe rí báyìí nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Ìdí ni pé àwọn èèyàn ṣì ní ìlera tó jí pépé, irú èyí tí Ádámù àti Éfà gbádùn àmọ́ tí wọ́n gbé sọnù. Fún àwọn èèyàn tó ní ìlera tó jí pépé, ìgbéyàwó láàárín ìbátan kò lè fa ìṣòro àìlera fáwọn ọmọ wọn. Àmọ́ ní nǹkan bí irínwó [400] ọdún lẹ́yìn náà, ẹ̀mí àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í kúrú bíi tiwa lóde òní. Torí náà, òfin tí Ọlọ́run fún Mósè nígbà yẹn kò fàyè gba ìbálòpọ̀ láàárín ìbátan.Léfítíkù 18:6.