Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jẹ́ Adúróṣinṣin, Kó O Sì Máa Dárí Jini Bíi Ti Jèhófà

Jẹ́ Adúróṣinṣin, Kó O Sì Máa Dárí Jini Bíi Ti Jèhófà

“Ẹni rere ni ọ́, Jèhófà, o sì ṣe tán láti dárí jini; Inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí gbogbo àwọn tí ń ké pè ọ́ sì pọ̀ yanturu.”—SM. 86:5.

1, 2. (a) Kí nìdí tá a fi mọyì àwọn ọ̀rẹ́ tó jẹ́ adúróṣinṣin tí wọ́n sì máa ń dárí jini? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa rí ìdáhùn sí?

IRÚ èèyàn wo lo lè pè ní ọ̀rẹ́ tòótọ́? Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Ashley sọ pé: “Ní tèmi, ọ̀rẹ́ gidi ni ẹni tó máa ń dúró tini nígbà ìṣòro, tó sì máa ń dárí jini téèyàn bá ṣẹ̀ ẹ́.” Gbogbo wa la mọyì àwọn ọ̀rẹ́ tó bá jẹ́ adúróṣinṣin tí wọ́n sì máa ń dárí jini. Wọ́n máa ń mú kí ọkàn wa balẹ̀, wọ́n sì máa ń ṣe ohun tó fi hàn pé wọ́n fẹ́ràn wa.—Òwe 17:17.

2 Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rẹ́ tó máa ń dúró tini tó sì máa ń dárí jini, kò sẹ́ni tó dà bí Jèhófà. Bí onísáàmù ṣe sọ ọ́ náà ló rí pé: “Ẹni rere ni ọ́, Jèhófà, o sì ṣe tán láti dárí jini; inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí gbogbo àwọn tí ń ké pè ọ́ sì pọ̀ yanturu.” (Sm. 86:5) Kí ló túmọ̀ sí pé kẹ́nì kan jẹ́ adúrótini tàbí adúróṣinṣin àti ẹni tó máa ń dárí jini? Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń fi àwọn ànímọ́ fífanimọ́ra yìí hàn? Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀? Ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí á mú kí ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà, ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́ túbọ̀ lágbára sí i. Ó sì tún máa mú kí àjọṣe tó wà láàárín àwa àtàwọn míì lágbára sí i.—1 Jòh. 4:7, 8.

JÈHÓFÀ JẸ́ ADÚRÓṢINṢIN

3. Kí ló túmọ̀ sí láti jẹ́ adúróṣinṣin?

3 Ẹni tó jẹ́ adúróṣinṣin máa ń jẹ́ olóòótọ́ sí ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ó máa ń ràn án lọ́wọ́, ó sì máa ń tì í lẹ́yìn. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ á tún jẹ́ adúrótini nígbà ìṣòro. Kò sí àní-àní pé Jèhófà jẹ́ “Ẹni ìdúróṣinṣin” lọ́nà tó ga lọ́lá.—Ìṣí. 16:5.

4, 5. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin? (b) Àǹfààní wo la máa ní tá a ba ń ronú nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ adúróṣinṣin?

4 Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin? Ọ̀nà tó ń gbà fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin ni pé kì í fi àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ sílẹ̀. Dáfídì Ọba tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà jẹ́rìí sí i pé adúróṣinṣin ni Jèhófà. (Ka 2 Sámúẹ́lì 22:26.) Nígbà tí Dáfídì wà nínú ìṣòro tó lágbára, Jèhófà tọ́ ọ sọ́nà, ó dáàbò bò ó, ó sì dá a nídè. (2 Sám. 22:1) Dáfídì mọ̀ pé ìdúróṣinṣin Jèhófà kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu lásán. Kí nìdí tí Jèhófà fi dúró ti Dáfídì? Ìdí ni pé “ẹni ìdúróṣinṣin” ni Dáfídì pẹ̀lú. Jèhófà máa ń mọyì rẹ̀ táwọn èèyàn rẹ̀ bá jẹ́ adúróṣinṣin, òun náà sì máa ń dúró tì wọ́n.—Òwe 2:6-8.

5 A máa jàǹfààní gan-an tá a bá ń ronú nípa àwọn ọ̀nà tí Jèhófà gbà fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin. Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Reed sọ pé: “Tí mo bá ń kà nípa bí Jèhófà ṣe dúró ti Dáfídì nígbà ìṣòro ó máa ń fún mi lókun gan-an ni. Kódà, nígbà tí Dáfídì ń sá kiri, tó ń sá pa mọ́ sínú àwọn ihò àpáta, Jèhófà kò fi í sílẹ̀. Ìtàn yẹn máa ń fún mi níṣìírí gan-an ni! Ó máa ń rán mi létí pé bó ti wù kí nǹkan le tó, tó sì dà bíi pé kò sí ìrètí kankan mọ́, Jèhófà ò ní fi mí sílẹ̀, bí mo bá ṣáà ti jẹ́ adúróṣinṣin sí i.” Ṣé ìwọ náà gbà pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn?—Róòmù 8:38, 39.

6. Àwọn ọ̀nà míì wo ni Jèhófà tún gbà fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin, báwo ni àwa èèyàn rẹ̀ ṣe lè jàǹfààní látinú èyí?

6 Àwọn ọ̀nà míì wo ni Jèhófà tún gbà fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin? Ìgbà gbogbo ni Jèhófà máa ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà tó fi lélẹ̀. Ó fi dá wa lójú pé: “Àní títí di ọjọ́ ogbó ènìyàn, Ẹnì kan náà ni mí.” (Aísá. 46:4) Orí àwọn ìlànà rẹ̀ ló máa ń gbé àwọn ìpinnu rẹ̀ kà, àwọn ìlànà rẹ̀ kì í sì í yí pa dà. (Mál. 3:6) Awímáyẹhùn tún ni Jèhófà, kì í sọ̀rọ̀ ká má bá a bẹ́ẹ̀, èyí sì fi hàn pé adúróṣinṣin ni. (Aísá. 55:11) Torí náà, gbogbo àwa èèyàn Jèhófà là ń jàǹfààní torí pé ó jẹ́ adúróṣinṣin. Lọ́nà wo? Tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀, ó dá wa lójú pé ó máa bù kún wa gẹ́gẹ́ bó ti ṣèlérí.—Aísá. 48:17, 18.

JẸ́ ADÚRÓṢINṢIN BÍI TI JÈHÓFÀ

7. Ọ̀nà wo la lè gbà jẹ́ adúróṣinṣin bíi ti Jèhófà?

 7 Báwo la ṣe lè jẹ́ adúróṣinṣin bíi ti Jèhófà? Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa ran àwọn tó bá wà nínú ìṣòro lọ́wọ́. (Òwe 3:27) Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ o mọ arákùnrin tàbí arábìnrin kan tó ti rẹ̀wẹ̀sì, bóyá nítorí àìsàn, inúnibíni látọ̀dọ̀ ìdílé, tàbí nítorí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ rẹ̀? Oò ṣe lo ìdánúṣe láti sọ ọ̀rọ̀ ìtùnú fún irú ẹni bẹ́ẹ̀? (Sek. 1:13) * Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe lò ń fi hàn pé adúróṣinṣin àti ọ̀rẹ́ tòótọ́ lo jẹ́. O sì tún jẹ́ ọ̀rẹ́ “tí ń fà mọ́ni tímọ́tímọ́ ju arákùnrin lọ.”—Òwe 18:24.

8. Báwo ni àwọn tọkọtaya ṣe lè jẹ́ adúróṣinṣin bíi ti Jèhófà?

8 A tún lè fi hàn pé a jẹ́ adúróṣinṣin bíi ti Jèhófà tá a bá ń fi òótọ́ bá ọkọ tàbí aya wa lò. (Òwe 5:15-18) A ò gbọ́dọ̀ ṣe ohunkóhun tó lè sún wa dé bèbè panṣágà. (Mát. 5:28) Bákan náà, tá a bá fẹ́ fi hàn pé a jẹ́ adúróṣinṣin sí àwọn ará wa, a ò ní máa sọ̀rọ̀ wọn láìdáa, a ò sí ní máa tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ àìdáa táwọn míì ń sọ nípa wọn.—Òwe 12:18.

9, 10. (a) Ta lẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ tó yẹ ká jẹ́ adúróṣinṣin sí? (b) Kí nìdí tó fi jẹ́ pé kì í fìgbà gbogbo rọrùn láti máa ṣègbọràn sí àwọn òfin Jèhófà?

9 Jèhófà lẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ tó yẹ ká jẹ́ adúróṣinṣin sí. Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Ọ̀nà tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan ni káwa náà máa fi wò ó. Ká fẹ́ràn ohun tí Jèhófà fẹ́ràn, ká kórìíra ohun tó kórìíra, ká sì máa gbé ìgbé ayé tó ń múnú Jèhófà dùn. (Ka Sáàmù 97:10.) Tá a bá jẹ́ kó mọ́ wa lára láti máa ronú bí Jèhófà ṣe fẹ́, ó máa rọrùn fún wa láti máa ṣègbọràn sí àwọn òfin rẹ̀.—Sm. 119:104.

10 Àmọ́, kì í fìgbà gbogbo rọrùn láti máa ṣègbọràn sí àwọn òfin Jèhófà. Àfi ká máa sapá gidigidi ká tó lè jẹ́ adúróṣinṣin. Bí àpẹẹrẹ, ó wu àwọn Kristẹni kan láti ṣègbéyàwó, àmọ́ wọn ò tíì rí ẹni tó wù wọ́n láàárín àwọn olùjọ́sìn Jèhófà. (1 Kọ́r. 7:39) Àwọn ará ibiṣẹ́ arábìnrin kan lè máa fi oríṣiríṣi ọkùnrin hàn án, kí wọ́n sì ní kó yan èyí tó máa fi ṣe ọkọ lára wọn. Ó lè ti máa ṣe arábìnrin náà bíi pé kó ti rí ọkùnrin kan tí wọ́n á jọ máa fẹ́ra. Ṣùgbọ́n, ó ti pinnu pé òun ò ní fẹ́ ẹni tí kì í ṣe olùjọsìn Jèhófà rárá. Àpẹẹrẹ àtàtà ni irú àwọn arábìnrin bẹ́ẹ̀ jẹ́, adúróṣinṣin sì ni wọ́n. Ó dájú pé Jèhófà máa san gbogbo àwọn tó bá ń fòótọ́ sìn ín láìka ìṣòro sí lẹ́san rere.—Héb. 11:6.

“Ọ̀rẹ́ kan wà tí ń fà mọ́ni tímọ́tímọ́ ju arákùnrin.”—Òwe 18:24 (Wo  ìpínrọ̀ 7)

‘Ẹ máa dárí ji ara yín fàlàlà.’—Éfé. 4:32 (Wo  ìpínrọ̀ 16)

JÈHÓFÀ MÁA Ń DÁRÍ JINI

11. Kí ló túmọ̀ sí láti máa dárí jini?

11 Jèhófà máa ń dárí jini lọ́pọ̀lọpọ̀, èyí sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ànímọ́ àgbàyanu rẹ̀. Kí ló túmọ̀ sí láti dárí jini? Ó túmọ̀ sí pé kéèyàn ṣe tán láti gbójú fo àṣìṣe tẹ́nì kan bá ṣe, kó má sì ṣe bínú si onítọ̀hún mọ́. Èyí kò túmọ̀ sí pé ńṣe lẹni tó bá lẹ́mìí ìdáríjì ń gba ìgbàkugbà láyè tàbí pé ó ń díbọ́n bíi pé ohun tí ẹnì kan ṣe kò dun òun rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yọ́nú sí ẹni tó ṣẹ̀ ẹ́. Ìwé Mímọ́ sọ pé, Jèhófà ‘ṣe tán láti dárí ji’ àwọn tó bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn.—Sm. 86:5.

12. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń dárí jini? (b) Kí ni Pétérù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé Ọlọ́run máa pa ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn rẹ́?

12 Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń dárí jini? Bí Jèhófà bá dárí jini, ó máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ “lọ́nà títóbi”; ńṣe ló máa ń dárí jini pátápátá. (Aísá. 55:7) Báwo la ṣe mọ̀ pé ńṣe ni Jèhófà máa ń dárí jini pátápátá? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Pétérù sọ nípa èyí nínú Ìṣe 3:19. (Kà á.) Àpọ́sítélì Pétérù rọ àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ẹ ronú pìwà dà, kí ẹ sì yí padà.” Bí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn, ńṣe ni onítọ̀hún kábàámọ̀ gidigidi nípa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ó sì tún pinnu pé òun ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́. (2 Kọ́r. 7:10, 11) Ẹni tó bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn máa “yí padà,” ìyẹn ni pé á jáwọ́ nínú gbogbo ìwà burúkú tó ń hù, á sì máa ṣe ohun tó ń múnú Ọlọ́run dùn. Tí àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Pétérù lọ́jọ́ yẹn bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn, kí ló máa ṣẹlẹ̀? Pétérù sọ pé Ọlọ́run máa “pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ [wọn] rẹ́.” Gbólóhùn náà ‘pa rẹ́’ ni a tú látinú ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì kan tó túmọ̀ sí pé kéèyàn pa ohun tí a kọ rẹ́, tàbí kéèyàn nu nǹkan kúrò. Torí náà, tí Jèhófà bá dárí jì ńṣe ló pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa rẹ́ pátápátá.—Héb. 10:22; 1 Jòh. 1:7.

13. Kí ni gbólóhùn náà, “ẹ̀ṣẹ̀ wọn ni èmi kì yóò sì rántí mọ́” mú kó dá wa lójú?

13 Báwo la ṣe mọ̀ pé tí Jèhófà bá ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini, ńṣe ló máa ń gbàgbé rẹ̀ pátápátá? Ká lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká wo àsọtẹ́lẹ̀ Jeremáyà nípa májẹ̀mú tuntun tí Jèhófà bá àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró dá, èyí tó máa mú kí àwọn tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wọn gbà. (Ka Jeremáyà 31:34.) Jèhófà sọ pé: “Èmi yóò dárí ìṣìnà wọn jì, ẹ̀ṣẹ̀ wọn ni èmi kì yóò sì rántí mọ́.” Ńṣe ni Jèhófà ń fi dá wa lójú pé, bí òun bá ti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, òun ò tún ní fìyà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ náà jẹ wá mọ́. Lédè míì, kì í tún fi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ náà bi wá mọ́ tàbí kó máa wá fìyà ẹ̀ṣẹ̀ náà jẹ wá títí lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Jèhófà máa ń gbàgbé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yẹn pátápátá, kò sì ní kà á sí wa lọ́rùn mọ́.—Róòmù 4:7, 8.

14. Báwo la ṣe lè rí ìtùnú gbà tá a bá ń ṣàṣàrò lórí bí Jèhófà ṣe máa ń dárí jini? Sọ àpẹẹrẹ kan.

14 Ó máa tù wá nínú gan-an tá a bá ń ṣàṣàrò lórí bí Jèhófà ṣe máa ń dárí jini. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan. Nígbà kan, wọ́n yọ arábìnrin kan lẹ́gbẹ́. Ọdún bíi mélòó kan lẹ́yìn náà ló tó pa dà sínú ètò. Arábìnrin yẹn wá sọ pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo gbà pé Jèhófà ti dárí jì mí, tí mo sì máa ń sọ bẹ́ẹ̀ fáwọn èèyàn, ó ṣì máa ń ṣe mí bíi pé Jèhófà sún mọ́ àwọn ẹlòmíì ó sí jẹ́ ẹni gidi sí wọn, àmọ́ ní tèmi, ó dá bíi pé ó jìnnà sí mi.” Kí wá ló ran arábìnrin yìí lọ́wọ́ tó fi ní èrò tó tọ́? Ohun tó ṣe ni pé, tó bá ń ka Bíbélì, ó máa ń fara balẹ̀ ṣàṣàrò lórí ọ̀nà tí Ìwé Mímọ́ gbà ṣàlàyé bí Jèhófà ṣe máa ń dárí jini, èyí sì tù ú nínú gan-an. Ó sọ pé: “Èyí ti wá jẹ́ kí n ní ojú ìwòye tó yàtọ̀ pátápátá nípa irú ẹni tí Jèhófà jẹ́. Mo ti wá rí i pé ó fẹ́ràn mi, ó sì máa ń bá mi kẹ́dùn.” Arábìnrin yìí tún kà nínú ìtẹ̀jáde wa kan pé: “Nígbà tí Jèhófà bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, kò sídìí fún rírò pé àbààwọ́n ẹ̀ṣẹ̀ yẹn á ṣì wà lára wa jálẹ̀ ìgbésí ayé wa.” * Ọ̀rọ̀ yìí wọ arábìnrin náà lọ́kàn gan-an, ó wá sọ pé: “Tẹ́lẹ̀, mi ò gbà gbọ́ pé Jèhófà lè dárí jì mí pátápátá, èrò mi ni pé ńṣe ni màá máa bá ẹ̀dùn ọkàn yẹn yí títí màá fi kú. Àmọ́ ní báyìí, mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í rí i pé mo lè sún mọ́ Jèhófà ní ti gidi, ó wá dà bíi pé ńṣe ni wọ́n gbé ẹrù kan tó wúwo kúrò lórí mi.” Inú wa mà dùn o, pé Ọlọ́run tó nífẹ̀ẹ́ tó sì máa ń dárí jini là ń sìn!—Sm. 103:9.

MÁA DÁRÍ JINI BÍI TI JÈHÓFÀ

15. Báwo la ṣe lè máa dárí jini bíi ti Jèhófà?

15 Tá a bá fẹ́ fìwà jọ Jèhófà, a gbọ́dọ̀ múra tán láti máa dárí ji àwọn ẹlòmíì. (Ka Lúùkù 17:3, 4.) Ká máa rántí pé tí Jèhófà bá ti dárí jì wá, ńṣe ló máa ń gbàgbé ẹ̀ṣẹ̀ náà, kò sì ní fi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ náà bi wá mọ́. Lọ́nà kan náà, táwọn èèyàn bá ṣẹ̀ wá, ká dárí jì wọ́n tọkàntọkàn, ká jẹ́ kọ́rọ̀ náà tán síbẹ̀, ká má sì tún máa mẹ́nu kan ọ̀rọ̀ náà mọ́.

16. (a) Kí ló túmọ̀ sí láti dárí àṣìṣe àwọn ẹlòmíì jì wọ́n? Kí ni èyí kò túmọ̀ sí? (b) Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá?

 16 Tá a bá ń dárí ji àwọn ẹlòmíì kò túmọ̀ sí pé ńṣe là ń gba ìgbàkugbà láyè tàbí pé à ń jẹ́ káwọn èèyàn rẹ́ wa jẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe la gbé ìbínú kúrò lọ́kàn tá a sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà tán nínú wa. Torí náà, tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run dárí jì wá, àwa náà gbọ́dọ̀ fìwà jọ ọ́, ká máa dárí ji àwọn ẹlòmíì. (Mát. 6:14, 15) Ó ṣe tán, Jèhófà máa ń rántí pé “erùpẹ̀ ni wá.” (Sm. 103:14) Torí náà, táwọn míì bá ṣe ohun tó dùn wá tàbí tí wọ́n sọ ọ̀rọ̀ kan tó dùn wá, ó yẹ ká máa rántí pé aláìpé bíi ti wa làwọn náà, ká sì dárí jì wọ́n látọkàn wá.—Éfé. 4:32; Kól. 3:13.

Tá a bá ń gbàdúrà fún ìdáríjì, kí ó jẹ́ látọkàn wá (Wo  ìpínrọ̀ 17)

17. Tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá ṣẹ̀ wá, kí ló máa jẹ́ ká lè dárí jì í?

 17 Ká sòótọ́, kì í fìgbà gbogbo rọrùn láti dárí jini. Kódà, ní ọ̀rúndún kìíní, kò rọrùn fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró kan láti yanjú èdèkòyédè tó wà láàárín wọn. (Fílí. 4:2) Tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá ṣẹ̀ wá, kí ló máa jẹ́ ká lè dárí jì í? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù. Ọ̀rẹ́ Jóòbù ni Élífásì, Bílídádì, àti Sófárì pe ara wọn. Ṣùgbọ́n, wọ́n kàn án lábùkù, wọ́n sì fẹ̀sùn èké kàn án. (Jóòbù 10:1; 19:2) Àmọ́ nígbà tó yá, Jèhófà bá àwọn ọkùnrin mẹ́ta yẹn wí. Ó ní kí wọ́n lọ ba Jóòbù, kí wọ́n sì rú ẹbọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. (Jóòbù 42:7-9) Jèhófà wá ní kí Jóòbù alára ṣe ohun kan. Kí lohun náà? Jèhófà sọ pé kí Jóòbù gbàdúrà nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́ta yìí. Jóòbù ṣe ohun tí Jèhófà sọ fún un, Jèhófà sì san án lẹ́san rere fún bó ṣe dárí ji àwọn ọkùnrin mẹ́ta náà. (Ka Jóòbù 42:10, 12, 16, 17.) Kí la rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí? Bí ẹnì kan bá ṣẹ̀ wá, tá a bá gbàdúrà àtọkànwá nítorí onítọ̀hún, ìyẹn lè mú ká gbé ìbínú náà kúrò lọ́kàn.

TÚBỌ̀ MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍPA ÀWỌN ÀNÍMỌ́ JÈHÓFÀ, KÓ O SÌ MÁA FARA WÉ E

18, 19. Kí la lè ṣe ká lè túbọ̀ máa mọyì àwọn ànímọ́ àgbàyanu Jèhófà?

18 Ó dájú pé a gbádùn bá a ṣe jíròrò oríṣiríṣi àwọn ànímọ́ àgbàyanu tí Jèhófà ní. A ti rí i pé, ó ṣeé sún mọ́, kì í ṣe ojúsàájú, ọ̀làwọ́ ni, ó máa fòye báni lò, adúróṣinṣin ni, ó sì máa ń dárí jini. Àmọ́, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ nǹkan ṣì wà tá a lè kọ́ nípa Jèhófà. Àǹfààní ṣì wà fún wa láti ní ayọ̀ tó máa wá látinú kéèyàn kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà títí ayérayé. (Oníw. 3:11) A gbà pẹ̀lú àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó sọ pé: “Ìjìnlẹ̀ àwọn ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run mà pọ̀ o.” Ó dájú pé àwa náà lè sọ irú ọ̀rọ̀ yìí nípa ìfẹ́ Ọlọ́run àtàwọn ànímọ́ rẹ̀ mẹ́fà tá a ti jíròrò nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí.—Róòmù 11:33.

19 Ẹ jẹ́ kí gbogbo wa túbọ̀ máa fi hàn pé a mọyì àwọn ànímọ́ àgbàyanu Jèhófà ká sì máa fara wé e. Ọnà tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká túbọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ànímọ́ rẹ̀, ká máa ṣàṣàrò lórí wọn, ká sì máa fi àwọn ànímọ́ yìí sílò nígbèésí ayé wa. (Éfé. 5:1) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé àwa náà á gbà pẹ̀lú onísáàmù náà tó sọ pé: “Ní tèmi, sísúnmọ́ Ọlọ́run dára fún mi.”—Sm. 73:28.

^ ìpínrọ̀ 7 Àwọn àbá tó gbéṣẹ́ nípa bó o ṣe lè fún àwọn míì níṣìírí wà nínú àpilẹ̀kọ náà, “O Ha Ti Fún Ẹnikẹ́ni Ní Ìṣírí Láìpẹ́ Yìí bí?” nínú Ilé Ìṣọ́ January 15, 1995, àti “Ẹ Máa Ru Ara Yín Lọ́kàn Sókè sí Ìfẹ́ àti Sí Àwọn Iṣẹ́ Àtàtà—Báwo?” nínú Ilé Ìṣọ́ April 1, 1995.

^ ìpínrọ̀ 14 Wo orí 26 ìpínrọ̀ kẹwàá nínú ìwé Sún Mọ́ Jèhófà.