Ìfihàn Èyí Tí Jòhánù Rí 16:1-21

  • Abọ́ méje ti ìbínú Ọlọ́run (1-21)

    • Wọ́n dà á sórí ayé (2), sínú òkun (3), sínú àwọn odò àti ìsun omi (4-7), sórí oòrùn (8, 9), sórí ìtẹ́ ẹranko náà (10, 11), sínú odò Yúfírétì (12-16) àti sínú afẹ́fẹ́ (17-21)

    • Ogun Ọlọ́run ní Amágẹ́dọ́nì (14, 16)

16  Mo gbọ́ tí ohùn kan dún ketekete látinú ibi mímọ́ náà,+ ó sọ fún àwọn áńgẹ́lì méje náà pé: “Ẹ lọ da abọ́ méje tí ìbínú Ọlọ́run wà nínú rẹ̀ sórí ayé.”+  Àkọ́kọ́ lọ, ó sì da ohun tó wà nínú abọ́ rẹ̀ sórí ayé.+ Egbò tó ń dunni wọra tó sì lè pani+ kọ lu àwọn èèyàn tó ní àmì ẹranko náà,+ tí wọ́n sì ń jọ́sìn ère rẹ̀.+  Ìkejì da ohun tó wà nínú abọ́ rẹ̀ sínú òkun.+ Ó sì di ẹ̀jẹ̀+ bí ẹ̀jẹ̀ ẹni tó ti kú, gbogbo ohun alààyè* kú, àní àwọn ohun tó wà nínú òkun.+  Ìkẹta da ohun tó wà nínú abọ́ rẹ̀ sínú àwọn odò àti àwọn ìsun* omi.+ Wọ́n sì di ẹ̀jẹ̀.+  Mo gbọ́ tí áńgẹ́lì tó wà lórí àwọn omi sọ pé: “Ìwọ, Ẹni tó ti wà tipẹ́, tó sì wà báyìí,+ Ẹni ìdúróṣinṣin,+ jẹ́ olódodo, torí o ti ṣe àwọn ìdájọ́ yìí,+  torí wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹni mímọ́ àti àwọn wòlíì sílẹ̀,+ o sì ti fún wọn ní ẹ̀jẹ̀ mu;+ ó tọ́ sí wọn.”+  Mo sì gbọ́ tí pẹpẹ náà sọ pé: “Jèhófà* Ọlọ́run, Olódùmarè,+ àní òótọ́ àti òdodo ni àwọn ìdájọ́* rẹ.”+  Ìkẹrin da ohun tó wà nínú abọ́ rẹ̀ sórí oòrùn,+ a sì gbà kí oòrùn fi iná jó àwọn èèyàn gbẹ.  Ooru tó gbóná janjan náà sì jó àwọn èèyàn náà gbẹ, àmọ́ wọ́n sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ Ọlọ́run, ẹni tó ní àṣẹ lórí àwọn ìyọnu yìí, wọn ò ronú pìwà dà, wọn ò sì yìn ín lógo. 10  Ìkarùn-ún da ohun tó wà nínú abọ́ rẹ̀ sórí ìtẹ́ ẹranko náà. Ni ìjọba rẹ̀ bá ṣókùnkùn,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í gé ahọ́n wọn jẹ torí ìrora wọn, 11  àmọ́ wọ́n sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run ọ̀run nítorí ìrora wọn àti egbò wọn, wọn ò sì ronú pìwà dà nínú àwọn iṣẹ́ wọn. 12  Ìkẹfà da ohun tó wà nínú abọ́ rẹ̀ sínú odò ńlá Yúfírétì,+ omi rẹ̀ sì gbẹ+ láti palẹ̀ ọ̀nà mọ́ fún àwọn ọba+ láti ibi tí oòrùn ti ń yọ.* 13  Mo sì rí i tí àwọn ọ̀rọ̀ àìmọ́ mẹ́ta tó ní ìmísí,* èyí tó rí bí àkèré jáde láti ẹnu dírágónì+ náà àti láti ẹnu ẹranko náà àti láti ẹnu wòlíì èké náà. 14  Ní tòótọ́, wọ́n jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn ẹ̀mí èṣù mí sí, wọ́n ń ṣe àwọn iṣẹ́ àmì,+ wọ́n sì lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, láti kó wọn jọ sí ogun+ ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè.+ 15  “Wò ó! Mò ń bọ̀ bí olè.+ Aláyọ̀ ni ẹni tó wà lójúfò,+ tó sì wọ aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀,* kó má bàa rìn ní ìhòòhò, kí àwọn èèyàn sì wo ìtìjú rẹ̀.”+ 16  Wọ́n sì kó wọn jọ sí ibi tí wọ́n ń pè ní Amágẹ́dọ́nì*+ lédè Hébérù. 17  Ìkeje sì da ohun tó wà nínú abọ́ rẹ̀ sínú afẹ́fẹ́. Lẹ́yìn náà, ohùn kan dún ketekete látinú ibi mímọ́+ níbi ìtẹ́ náà, ó sọ pé: “Ó ti rí bẹ́ẹ̀!” 18  Mànàmáná kọ yẹ̀rì, a gbọ́ ohùn, ààrá sán, ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára sì ṣẹlẹ̀, irú rẹ̀ kò tíì ṣẹlẹ̀ látìgbà téèyàn ti wà ní ayé,+ ìmìtìtì náà lágbára gan-an ó sì lọ jìnnà. 19  Ìlú ńlá náà+ pín sí mẹ́ta, àwọn ìlú àwọn orílẹ̀-èdè sì ṣubú; a sì rántí Bábílónì Ńlá+ níwájú Ọlọ́run, ká lè fún un ní ife wáìnì tí ìbínú Ọlọ́run ń ru nínú rẹ̀.+ 20  Bákan náà, gbogbo erékùṣù sá lọ, a ò sì rí àwọn òkè.+ 21  Lẹ́yìn náà àwọn òkúta yìnyín ńlá já bọ́ lu àwọn èèyàn láti ọ̀run,+ òkúta kọ̀ọ̀kan fẹ́rẹ̀ẹ́ wúwo tó tálẹ́ńtì* kan, àwọn èèyàn náà sì sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run torí ìyọnu yìnyín náà+ àti pé ìyọnu náà pọ̀ lọ́nà tó kàmàmà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “orísun.”
Tàbí “ìpinnu ìdájọ́.”
Tàbí “láti ìlà oòrùn.”
Ní Grk., “àwọn ẹ̀mí àìmọ́ mẹ́ta.”
Ní Grk., “tó sì pa aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ mọ́.”
Lédè Gíríìkì, Har Ma·ge·donʹ, ó wá látinú ọ̀rọ̀ èdè Hébérù tó túmọ̀ sí “Òkè Mẹ́gídò.”
Tálẹ́ńtì Gíríìkì kan jẹ́ kìlógíráàmù 20.4. Wo Àfikún B14.