ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ June 2013

Àwọn àpilẹ̀kọ yìí á jẹ́ ká túbọ̀ mọyì àwọn ànímọ́ Jèhófà mìíràn yàtọ̀ sí àwọn tó gbawájú nínú àwọn ànímọ́ rẹ̀.

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Jèhófà Bù Kún Mi Gan-an Torí Pé Mo Ṣègbọràn Sí I

Ka ìrírí arábìnrin Elisa Piccioli. Láìka ìṣòro, àwọn ohun tó ní láti yááf ì àti àwọn ohun tó pàdánù sí, ó pinnu láti ṣe ohun tí ó tọ́.

Túbọ̀ Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Àwọn Ànímọ́ Jèhófà

Kí ló túmọ̀ sí tá a bá sọ pé ẹnì kan ṣeé sún mọ́ àti pé kì í ṣe ojúsàájú? Àpẹẹrẹ Jèhófà máa jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè láwọn ànímọ́ yìí.

Jèhófà Jẹ́ Ọ̀làwọ́ Ó Sì Ń Fòye Báni Lò

Jèhófà lẹni tó lawọ́ tó sì ń fòye báni lò lọ́nà tó ga jù lọ. Tá a bá mọ àwọn ànímọ́ yìí dáadáa, àá lè máa fi ṣèwà hú.

Jẹ́ Adúróṣinṣin, Kó O Sì Máa Dárí Jini Bíi Ti Jèhófà

Àwọn ọ̀rẹ́ gidi máa dúró tini, wọ́n sì máa ń dárí jini. Tá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà, a máa ní àwọn ànímọ́ pàtàkì yìí.

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Àwọn wo ni “àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́ “ àti “àwọn ẹ̀mí nínú ẹ̀wọ̀n” tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn?

Jẹ́ Kí Amọ̀kòkò Tí Kò Lẹ́gbẹ́ Náà Mọ Ẹ́

Jèhófà, “Amọ̀kòkò wa,” ti mọ àwọn èèyàn àtàwọn orílẹ̀-èdè. Kí lèyí kọ́ wa, àǹfààní wo la sì rí látinú bí Jèhófà ṣe ń mọ wá lónìí?

Ẹ̀yin Alàgbà, Ẹ Máa Tu “Ọkàn Tí Àárẹ̀ Mú” Lára

Báwo làwọn alàgbà ṣe lè múra sílẹ̀ kí wọ́n tó lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ará? Wọ́n lè lo Bíbélì láti fún “ọkàn tí àárẹ̀ mú” tàbí ẹni tó rẹ̀wẹ̀sì níṣìírí.

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ṣó o gbádùn kíka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.