Ìwé Kìíní Jòhánù 1:1-10

  • Ọ̀rọ̀ ìyè (1-4)

  • Ká máa rìn nínú ìmọ́lẹ̀ (5-7)

  • Ìdí tó fi yẹ ká máa jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa (8-10)

1  Ohun tó wà láti ìbẹ̀rẹ̀, tí a gbọ́, tí a fi ojú wa rí, tí a kíyè sí, tí a sì fọwọ́ bà, nípa ọ̀rọ̀ ìyè,+  (òótọ́ ni, a fi ìyè náà hàn kedere, a ti rí ìyè àìnípẹ̀kun+ tó wà pẹ̀lú Baba, tí a fi hàn kedere fún wa, à ń jẹ́rìí fún yín nípa rẹ̀,+ a sì ń ròyìn rẹ̀ fún yín),  a tún ń sọ àwọn ohun tí a ti gbọ́ tí a sì ti rí fún yín,+ kí ẹ̀yin náà lè ní àjọṣe* pẹ̀lú wa. Àwa àti Baba pẹ̀lú Ọmọ rẹ̀ Jésù Kristi la jọ ní àjọṣe yìí.+  A sì ń kọ àwọn nǹkan yìí kí ayọ̀ wa lè kún rẹ́rẹ́.  Ohun tí a gbọ́ látọ̀dọ̀ rẹ̀, tí a sì ń sọ fún yín ni pé: Ọlọ́run jẹ́ ìmọ́lẹ̀,+ kò sì sí òkùnkùn kankan nínú rẹ̀* rárá.  Tí a bá sọ pé, “A ní àjọṣe pẹ̀lú rẹ̀,” síbẹ̀ tí à ń rìn nínú òkùnkùn, irọ́ ni à ń pa, a ò sì sọ òótọ́.+  Àmọ́, tí a bá ń rìn nínú ìmọ́lẹ̀ bí òun fúnra rẹ̀ ṣe wà nínú ìmọ́lẹ̀, a ní àjọṣe pẹ̀lú ara wa, ẹ̀jẹ̀ Jésù Ọmọ rẹ̀ sì ń wẹ̀ wá mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀.+  Tí a bá sọ pé, “A ò ní ẹ̀ṣẹ̀,” à ń tan ara wa,+ òótọ́ ò sì sí nínú wa.  Tí a bá jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, ó máa dárí jì wá, ó sì máa wẹ̀ wá mọ́ kúrò nínú gbogbo àìṣòdodo torí olóòótọ́ àti olódodo ni.+ 10  Tí a bá sọ pé, “A ò dẹ́ṣẹ̀,” à ń sọ ọ́ di òpùrọ́, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì sí nínú wa.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “lè ṣàjọpín.”
Tàbí “ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.”