Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Ọ̀rọ̀ Jésù Ṣe Lè Sọni Di Aláyọ̀

Bí Ọ̀rọ̀ Jésù Ṣe Lè Sọni Di Aláyọ̀

Bí Ọ̀rọ̀ Jésù Ṣe Lè Sọni Di Aláyọ̀

‘Jésù gòkè lọ sí orí òkè ńlá; àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀; ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn.’—MÁT. 5:1, 2.

1, 2. (a) Àwọn nǹkan wo ló ṣẹlẹ̀ ṣáájú kí Jésù tó ṣe Ìwàásù Lórí Òkè? (b) Báwo ni Jésù ṣe bẹ̀rẹ̀ àsọyé rẹ̀?

 LỌ́DÚN 31 Sànmánì Kristẹni, Jésù dáwọ́ iṣẹ́ ìwàásù tó ń ṣe káàkiri Gálílì dúró díẹ̀ láti ṣe àjọ Ìrékọjá ní Jerúsálẹ́mù. (Jòh. 5:1) Nígbà tó pa dà sí Gálílì, ó gbàdúrà lóru mọ́jú pé kí Ọlọ́run tọ́ òun sọ́nà bóun ṣe fẹ́ yan àpọ́sítélì méjìlá. Lọ́jọ́ kejì, àwọn èrò pé jọ bí Jésù ṣe ń mú aláìsàn lára dá. Lẹ́yìn náà, ó jókòó sí ẹ̀gbẹ́ ibì kan lórí òkè, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àtàwọn èrò tó wà níbẹ̀.—Mát. 4:23–5:2; Lúùkù 6:12-19.

2 Nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ ìwàásù, ìyẹn Ìwàásù Lórí Òkè, ó fi hàn pé àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run ló ń mú kéèyàn jẹ́ aláyọ̀. (Ka Mátíù 5:1-12.) Téèyàn bá láyọ̀ ńṣe ni inú rẹ̀ máa ń dùn, ara rẹ̀ á sì yá gágá. Àwọn nǹkan mẹ́sàn-án tí Jésù sọ pé ó ń fún èèyàn láyọ̀ jẹ́ ká mọ ìdí táwa Kristẹni fi ń láyọ̀, nǹkan wọ̀nyẹn sì wúlò fún wa lónìí bí wọ́n ṣe wúlò ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn. Ẹ jẹ́ ká wá gbé ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ náà yẹ̀ wò lọ́kọ̀ọ̀kan.

“Àwọn Tí Àìní Wọn Nípa Ti Ẹ̀mí Ń Jẹ Lọ́kàn”

3. Àwọn wo ni àìní wọn nípa tẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn?

3 “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn, níwọ̀n bí ìjọba ọ̀run ti jẹ́ tiwọn.” (Mát. 5:3) “Àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn” ni àwọn tó máa ń wá ìtọ́sọ́nà àti àánú Ọlọ́run.

4, 5. (a) Kí nìdí tí àwọn tí àìní wọn nípa tẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn fi máa ń láyọ̀? (b) Báwo la ṣe lè rí ìtọ́sọ́nà àti àánú Ọlọ́run?

4 Àwọn tí àìní wọn nípa tẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn máa ń láyọ̀ “níwọ̀n bí ìjọba ọ̀run ti jẹ́ tiwọn.” Gbígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ gba Jésù ní Mèsáyà mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti dẹni táá lè bá a ṣàkóso nínú Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀run. (Lúùkù 22:28-30) Yálà a ń retí láti jẹ́ ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi ní ọ̀run tàbí a ń retí láti wà láàyè títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, a lè jẹ́ aláyọ̀ tá a bá ń jẹ́ kí àìní wa nípa tẹ̀mí jẹ wá lọ́kàn tá a sì gbà dájúdájú pé a nílò ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run.

5 Kì í ṣe gbogbo èèyàn ló gbà pé àwọn nílò ìtọ́sọ́nà àti àánú Ọlọ́run, nítorí pé ọ̀pọ̀ èèyàn kò nígbàgbọ́, wọn ò sì mọrírì àwọn ohun mímọ́. (2 Tẹs. 3:1, 2; Héb. 12:16) Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lójú méjèèjì, fífi ìtara ṣe iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn àti wíwá sípàdé déédéé jẹ́ ara ọ̀nà tá a ń gbà rí ìtọ́sọ́nà àti àánú Ọlọ́run.—Mát. 28:19, 20; Héb. 10:23-25.

Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀ Tí Wọ́n sì Jẹ́ “Aláyọ̀”

6. Àwọn wo ni “àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀,” kí sì nìdí tí wọ́n fi jẹ́ “aláyọ̀”?

6 “Aláyọ̀ ni àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, níwọ̀n bí a ó ti tù wọ́n nínú.” (Mát. 5:4) Irú èèyàn kan náà ni “àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀” àti “àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” Ọ̀fọ̀ tí wọ́n ń ṣe yìí kì í ṣe ti pé wọ́n ń kẹ́dùn tàbí pé wọ́n ń ráhùn nípa bí nǹkan ṣe rí fún wọn nígbèésí ayé o. Ipò ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n wà àti àkóbá tí àìpé ẹ̀dá ń fà ló ń bà wọ́n nínú jẹ́. Kí wá nìdí tí àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ bẹ́ẹ̀ fi jẹ́ “aláyọ̀”? Ìdí ni pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti Kristi, àjọṣe tó dára tó wà láàárín àwọn àti Jèhófà sì ń tù wọ́n nínú.—Jòh. 3:36.

7. Irú ojú wo ló yẹ ká máa fi wo ayé Sátánì yìí?

7 Ǹjẹ́ àwa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa ń kẹ́dùn nítorí ìwà àìṣòdodo tó kúnnú ayé Sátánì yìí? Kí ni èrò wa nípa jíjẹ adùn ayé yìí? Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé—ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími—kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Baba.” (1 Jòh. 2:16) Àmọ́, kí ló yẹ ká ṣe tá a bá rí i pé “ẹ̀mí ayé,” ìyẹn ẹ̀mí tó ń darí àwọn tó kẹ̀yìn sí Ọlọ́run, ti ń nípa lórí bá a ṣe ń ṣe ìjọsìn wa sí Jèhófà? Ńṣe ló yẹ ká gbàdúrà tọkàntọkàn, ká túbọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ká sì wá ìrànlọ́wọ́ àwọn alàgbà. Ohun yòówù tí ì báà máa dà wá láàmú, a óò “rí ìtùnú” bá a bá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.—1 Kọ́r. 2:12; Sm. 119:52; Ják. 5:14, 15.

Ayọ̀ “Àwọn Onínú Tútù” Mà Pọ̀ O!

8, 9. Tá a bá jẹ́ onínú tútù kí la ó máa ṣe, kí sì nìdí tí àwọn onínú tútù fi jẹ́ aláyọ̀?

8 “Aláyọ̀ ni àwọn onínú tútù, níwọ̀n bí wọn yóò ti jogún ilẹ̀ ayé.” (Mát. 5:5) Ẹni tó ní “inú tútù,” tàbí ọkàn tútù, kì í ṣe ọ̀dẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe ẹni tó ń dọ́gbọ́n ṣe bí èèyàn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́. (1 Tím. 6:11) Tá a bá jẹ́ onínú tútù a ó máa ṣe ìfẹ́ Jèhófà a ó sì máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀, èyí táá fi hàn pé a ní ọkàn tútù. Inú tútù á tún hàn nínú bá a ṣe ń hùwà sáwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ àtàwọn ẹlòmíì. Irú inú tútù bẹ́ẹ̀ sì bá ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá mu.—Ka Róòmù 12:17-19.

9 Kí nìdí tí àwọn onínú tútù fi jẹ́ aláyọ̀? Jésù tó jẹ́ onínú tútù sọ ìdí rẹ̀, ó ní, ‘wọn yóò jogún ayé.’ Jésù gan-an ni olórí ajogún ayé. (Sm. 2:8; Mát. 11:29; Héb. 2:8, 9) Àmọ́, àwọn onínú tútù tí wọ́n jẹ́ “ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi,” náà máa bá a jogún ayé. (Róòmù 8:16, 17) Àwọn ọlọ́kàn tútù yòókù yóò sì gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ Ìjọba Jésù.—Sm. 37:10, 11.

10. Àkóbá wo ni àìní ìwà tútù lè ṣe fún àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì àti àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tá a lè ní nínú ìjọ?

10 Ó yẹ ká jẹ́ onínú tútù bíi ti Jésù. Tá a bá jẹ́ aríjàgbá, ńṣe lá mú káwọn èèyàn máa yẹra fún wa, nítorí wọ́n á rí i pé a jẹ́ oníwàhálà àti ẹni líle. Tí àwa arákùnrin tó ń wù láti ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ bá nírú ìwà yìí, a kò ní tóótun láti sìn. (1 Tím. 3:1, 3) Pọ́ọ̀lù sọ fún Títù pé kó máa rán àwọn Kristẹni tó wà ní Kírétè létí “láti má ṣe jẹ́ aríjàgbá, láti jẹ́ afòyebánilò, kí wọ́n máa fi gbogbo ìwà tútù hàn sí ènìyàn gbogbo.” (Títù 3: 1, 2) Ẹ ò rí i pé a máa wúlò gan-an fáwọn èèyàn tá a bá jẹ́ onínú tútù!

Ebi “Òdodo” Ń Pa Wọ́n

11-13. (a) Tí ebi òdodo bá ń pa wá tí òùngbẹ rẹ̀ sì ń gbẹ wá, kí la ó máa ṣe? (b) Báwo la ṣe ń “bọ́” àwọn tí ebi òdodo ń pa tí òùngbẹ rẹ̀ sì ń gbẹ “yó”?

11 “Aláyọ̀ ni àwọn tí ebi ń pa, tí òùngbẹ sì ń gbẹ fún òdodo, níwọ̀n bí a ó ti bọ́ wọn yó.” (Mát. 5:6) “Òdodo” tí Jésù ní lọ́kàn níbí yìí ni pé kéèyàn máa ṣe ohun tó tọ́, ìyẹn ni pé kó máa ṣe ohun tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu kó sì máa tẹ̀ lé àṣẹ rẹ̀. Onísáàmù kan sọ pé ọkàn òun ń yán hànhàn fún àwọn ìpinnu ìdájọ́ Ọlọ́run tó jẹ́ òdodo. (Sm. 119:20) Ǹjẹ́ àwa náà ka òdodo sí iyebíye débi pé ebi rẹ̀ ń pa wá tí òùngbẹ rẹ̀ sì ń gbẹ wá bíi ti onísáàmù yẹn?

12 Jésù sọ pé àwọn tí ebi òdodo ń pa tí òùngbẹ rẹ̀ sì ń gbẹ yóò láyọ̀ nítorí pé a óò “bọ́ wọn yó.” A sì bẹ̀rẹ̀ sí í bọ́ wọn yó lẹ́yìn àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni nítorí ìgbà yẹn ni ẹ̀mí mímọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í “fún ayé ní ẹ̀rí amúnigbàgbọ́ ní ti . . . òdodo.” (Jòh. 16:8) Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ mí sí àwọn èèyàn láti kọ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, tó wúlò gan-an “fún bíbániwí nínú òdodo.” (2 Tím. 3:16) Ẹ̀mí Ọlọ́run tún ń jẹ́ ká lè “gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́.” (Éfé. 4:24) Ǹjẹ́ kò tuni nínú láti mọ̀ pé àwọn tí wọ́n ronú pìwà dà, tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wọn lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù lè dẹni tí Ọlọ́run kà sí olódodo?—Ka Róòmù 3:23, 24.

13 Ní ti àwa tá a nírètí láti jogún ayé lára àwọn tí ebi òdodo ń pa tí òùngbẹ rẹ̀ sì ń gbẹ, ìgbà tá a bá ní ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun tí òdodo ti máa gbilẹ̀ la óò tó yó bámúbámú. Àmọ́ nísinsìnyí ná, ẹ jẹ́ ká pinnu pé a ò ní yà kúrò lórí ìlànà Jèhófà nínú ìgbésí ayé wa. Jésù sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó . . . ní wíwá ìjọba náà àti òdodo [Ọlọ́run] lákọ̀ọ́kọ́.” (Mát. 6:33) Tá a bá ń ṣe èyí, yóò mú kí ọwọ́ wa dí lẹ́nu iṣẹ́ Ọlọ́run, yóò sì mú kí ọkàn wa kún fún ojúlówó ayọ̀.—1 Kọ́r. 15:58.

Ìdí Tí “Àwọn Aláàánú” Fi Jẹ́ Aláyọ̀

14, 15. Báwo la ṣe lè máa ṣàánú àwọn èèyàn, kí sì nìdí tí “àwọn aláàánú” fi jẹ́ aláyọ̀?

14 “Aláyọ̀ ni àwọn aláàánú, níwọ̀n bí a ó ti fi àánú hàn sí wọn.” (Mát. 5:7) “Àwọn aláàánú” máa ń fi ìyọ́nú hàn sáwọn èèyàn, wọ́n sì máa ń ṣàánú wọn. Jésù ṣe iṣẹ́ ìyanu láti fi mú ìtura bá àwọn tójú ń pọ́n nítorí àánú wọn ṣe é. (Mát. 14:14) Ọ̀ràn àánú ṣíṣe tún kan dídáríji àwọn tó ṣẹ̀ wá bí Jèhófà ṣe máa ń ṣàánú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà tó sì ń dárí jì wọ́n. (Ẹ́kís. 34:6, 7; Sm. 103:10) A lè fi àánú hàn lọ́nà yẹn, a sì tún lè fi í hàn nípa jíjẹ́ kí ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa máa mú ìtura bá àwọn tó wà nínú ìṣòro. Ọ̀nà kan tó dára láti gbà ṣàánú àwọn èèyàn ni pé ká máa sọ ọ̀rọ̀ Bíbélì fún wọn. Nígbà tí àánú ogunlọ́gọ̀ èèyàn kan ṣe Jésù, ó “bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn ní ohun púpọ̀.”—Máàkù 6:34.

15 Ìdí pàtàkì wà tó fi yẹ ká gbà pé òótọ́ lọ́rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn aláàánú, níwọ̀n bí a ó ti fi àánú hàn sí wọn.” Tá a bá ń ṣàánú àwọn èèyàn, àwọn náà á máa ṣàánú wa. A ó tún rí i pé nígbà tí Ọlọ́run bá fẹ́ ṣe ìdájọ́ tiwa náà, yóò ro ti àánú tá a ti ṣe fáwọn èèyàn, yóò sì ṣàánú wa. (Ják. 2:13) Àwọn aláàánú nìkan ló máa rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ àti ìyè ayérayé gbà.—Mát. 6:15.

Ìdí Tí “Àwọn Ẹni Mímọ́ Gaara ní Ọkàn-Àyà” Fi Jẹ́ Aláyọ̀

16. Kí ló máa fi hàn pé èèyàn jẹ́ “ẹni mímọ́ gaara ní ọkàn-àyà,” báwo sì ni irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ṣe ń “rí Ọlọ́run”?

16 “Aláyọ̀ ni àwọn ẹni mímọ́ gaara ní ọkàn-àyà, níwọ̀n bí wọn yóò ti rí Ọlọ́run.” (Mát. 5:8) Tá a bá jẹ́ “ẹni mímọ́ gaara ní ọkàn-àyà,” ohun mímọ́ ni ọkàn wa yóò máa fà sí, òun ni yóò máa wù wá, ọkàn mímọ́ la ó sì máa fi ṣe nǹkan. A óò máa fi “ìfẹ́” hàn láti “inú ọkàn-àyà tí ó mọ́.” (1 Tím. 1:5) Nítorí jíjẹ́ tá a jẹ́ ẹni tó mọ́ látọkànwá, a óò “rí Ọlọ́run.” Èyí kò fi dandan túmọ̀ sí pé a ó fi ojúyòójú rí Jèhófà, nítorí “kò sí ènìyàn tí ó lè rí [Ọlọ́run] kí ó sì wà láàyè síbẹ̀.” (Ẹ́kís. 33:20) Ṣùgbọ́n, gbígbé tí Jésù gbé ànímọ́ Ọlọ́run yọ láìkù síbì kan ló mú kó sọ pé: “Ẹni tí ó ti rí mi ti rí Baba pẹ̀lú.” (Jòh. 14:7-9) Àwa tá a jẹ́ olùjọ́sìn Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé ń “rí Ọlọ́run” bá ń ṣe ń rí àwọn ohun tó ń ṣe nítorí tiwa. (Jóòbù 42:5) Ìgbà táwọn Kristẹni ẹni àmì òróró máa rí Ọlọ́run jù lọ ni ìgbà tí wọ́n bá jíǹde gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí tí wọ́n sì ń rí Bàbá wọn ọ̀run ní ojúkojú.—1 Jòh. 3:2.

17. Tá a bá jẹ́ ọlọ́kàn mímọ́, ipa wo nìyẹn máa ní lórí wa?

17 Nítorí pé ẹni tí ọkàn rẹ̀ mọ́ máa ń hùwà tó mọ́, ó sì máa ń fẹ́ wà ní mímọ́ lójú Ọlọ́run, kì í gba ohun tí Jèhófà kà sí àìmọ́ láyè nínú ọkàn rẹ̀. (1 Kíró. 28:9; Aísá. 52:11) Tí ọkàn wa bá mọ́, ohun tí a ó máa sọ àtohun tí a ó máa ṣe yóò jẹ́ mímọ́, iṣẹ́ ìsìn wa sí Jèhófà kò sì ní jẹ́ àgàbàgebè.

“Àwọn Ẹlẹ́mìí Àlàáfíà” Di Ọmọ Ọlọ́run

18, 19. Irú ìwà wo ni “àwọn ẹlẹ́mìí àlàáfíà” máa ń hù?

18 “Aláyọ̀ ni àwọn ẹlẹ́mìí àlàáfíà, níwọ̀n bí a ó ti pè wọ́n ní ‘ọmọ Ọlọ́run.’” (Mát. 5:9) Ohun tá a fi máa ń dá “àwọn ẹlẹ́mìí àlàáfíà” mọ̀ ni ohun tí wọ́n máa ń ṣe àti ohun tí wọn kì í ṣe. Tá a bá jẹ́ irú àwọn èèyàn tí Jésù sọ yìí, a ó máa wá àlàáfíà, a kò sì ní máa “fi ìṣeniléṣe san ìṣeniléṣe fún ẹnikẹ́ni.” Kàkà bẹ́ẹ̀, a ó ‘máa lépa ohun rere sí àwọn ẹlòmíràn nígbà gbogbo.’—1 Tẹs. 5:15.

19 Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “àwọn ẹlẹ́mìí àlàáfíà” nínú Mátíù 5:9 túmọ̀ sí àwọn tí ń wá àlàáfíà. Láti lè wà lára àwọn ẹlẹ́mìí àlàáfíà, a ní láti máa ṣe ohun tó ń mú kí àlàáfíà wà. Àwọn tó ń wá àlàáfíà kì í ṣe ohun tó “ń ya àwọn tí ó mọ ara wọn dunjú nípa.” (Òwe 16:28) Nítorí pé a jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà, a máa ń sa gbogbo ipá wa láti “lépa àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.”—Héb. 12:14.

20. Àwọn wo ni “ọmọ Ọlọ́run” nísinsìnyí, àwọn wo ló sì máa di ọmọ Ọlọ́run lọ́jọ́ iwájú?

20 Àwọn ẹlẹ́mìí àlàáfíà jẹ́ aláyọ̀ nítorí a ó máa “pè wọ́n ní ‘ọmọ Ọlọ́run.’” Jèhófà sọ àwọn Kristẹni olóòótọ́ tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró dọmọ, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ “ọmọ Ọlọ́run.” Wọ́n ti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọmọ sí baba nísinsìnyí nítorí wọ́n ń lo ìgbàgbọ́ nínú Kristi wọ́n sì ń fi tọkàntọkàn jọ́sìn “Ọlọ́run ìfẹ́ àti àlàáfíà.” (2 Kọ́r. 13:11; Jòh. 1:12) “Àwọn àgùntàn mìíràn” Jésù tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà ńkọ́? Jésù yóò jẹ́ “Baba Ayérayé” fún wọn nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba rẹ̀, àmọ́ ní òpin ìgbà náà Jésù yóò fi ara rẹ̀ sábẹ́ Jèhófà, àwọn àgùntàn mìíràn yóò sì wá di ọmọ Ọlọ́run lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.—Jòh. 10:16; Aísá. 9:6; Róòmù 8:21; 1 Kọ́r. 15:27, 28.

21. Tá a bá “wà láàyè nípa ẹ̀mí,” irú ìwà wo la ó máa hù?

21 Tá a bá “wà láàyè nípa ẹ̀mí,” ara ohun táwọn èèyàn máa rí lára wa ni pé a jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà. A ó yẹra fún “ríru ìdíje sókè pẹ̀lú ara wa,” ìyẹn ni pé a ò ní máa “mu ọmọnikeji wa binu.” (Gál. 5:22-26; Bibeli Mimọ) Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe la ó máa sa gbogbo ipá wa láti jẹ́ “ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.”—Róòmù 12:18.

Wọ́n Ń Láyọ̀ Bí Wọ́n Tiẹ̀ Ń Ṣe Inúnibíni sí Wọn!

22-24. (a) Kí ló ń mú kí àwọn tí wọ́n ṣe inúnibíni sí nítorí òdodo jẹ́ aláyọ̀? (b) Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ́ méjì tó tẹ̀ lé èyí?

22 “Aláyọ̀ ni àwọn tí a ti ṣe inúnibíni sí nítorí òdodo, níwọ̀n bí ìjọba ọ̀run ti jẹ́ tiwọn.” (Mát. 5:10) Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà kẹsàn-án téèyàn lè gbà jẹ́ aláyọ̀, ó fi kún un pé: “Aláyọ̀ ni yín nígbà tí àwọn ènìyàn bá gàn yín, tí wọ́n sì ṣe inúnibíni sí yín, tí wọ́n sì fi irọ́ pípa sọ gbogbo onírúurú ohun burúkú sí yín nítorí mi. Ẹ yọ̀, kí ẹ sì fò sókè fún ìdùnnú, níwọ̀n bí èrè yín ti pọ̀ ní ọ̀run; nítorí ní ọ̀nà yẹn ni wọ́n ṣe inúnibíni sí àwọn wòlíì tí ó wà ṣáájú yín.”Mát. 5:11, 12.

23 Bíi ti àwọn wòlíì Ọlọ́run nígbà àtijọ́, àwa Kristẹni retí pé wọ́n á kẹ́gàn wa, wọ́n á ṣe inúnibíni sí wa, wọ́n á sì pa irọ́ mọ́ wa, ‘tìtorí òdodo.’ Àmọ́ tá a bá ń fara da irú àwọn ìdánwò bẹ́ẹ̀ láìbọ́hùn, inú wa yóò dùn pé à ń ṣe ohun tó wu Jèhófà a sì ń gbé e ga. (1 Pét. 2:19-21) Ìyà tó ń jẹ wá kò lè dín ìdùnnú wa nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà kù nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú. Kò lè dín ayọ̀ àwọn tó mọ̀ pé àwọn máa bá Kristi ṣàkóso ní Ìjọba ọ̀run kù, kó sì lè dín ìdùnnú àwọn tó mọ̀ pé àwọn máa ní ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé kù. Irú àwọn ìbùkún bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹ̀rí pé Ọlọ́run jẹ́ olóore, aláàánú àti ọ̀làwọ́.

24 Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ṣì wà tá a lè rí kọ́ nínú Ìwàásù Lórí Òkè. Oríṣiríṣi ẹ̀kọ́ míì látinú ìwàásù náà la óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ́ méjì tó tẹ̀ lé èyí. Ẹ jẹ́ ká wo bá a ṣe lè fi ọ̀rọ̀ Jésù Kristi tó wà níbẹ̀ sílò.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Kí nìdí tí “àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn” fi jẹ́ aláyọ̀?

• Kí nìdí tí “àwọn onínú tútù” fi jẹ́ aláyọ̀?

• Kí nìdí táwa Kristẹni fi ń láyọ̀ bí wọ́n tiẹ̀ ń ṣe inúnibíni sí wa?

• Èwo ló wù ọ́ jù nínú ohun mẹ́sàn-án tí Jésù sọ pé ó ń fúnni láyọ̀?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Àwọn nǹkan mẹ́sàn-án tí Jésù sọ pé ó ń fúnni láyọ̀ wúlò fún wa lónìí bó ṣe wúlò nígbà yẹn lọ́hùn-ún

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Ọ̀nà kan tó dára láti gbà ṣàánú àwọn èèyàn ni pé ká sọ ọ̀rọ̀ Bíbélì fún wọn