Àkọsílẹ̀ Mátíù 11:1-30

  • Ó yin Jòhánù Arinibọmi (1-15)

  • Ó dẹ́bi fún ìran aláìgbọràn (16-24)

  • Jésù yin Bàbá rẹ̀ torí pé ó ṣojúure sí àwọn tó rẹlẹ̀ (25-27)

  • Àjàgà Jésù ń tuni lára (28-30)

11  Lẹ́yìn tí Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá (12) ní ìtọ́ni, ó gbéra níbẹ̀ láti lọ máa kọ́ni, kó sì máa wàásù nínú àwọn ìlú wọn.+  Àmọ́ nínú ẹ̀wọ̀n tí Jòhánù wà,+ ó gbọ́ nípa àwọn iṣẹ́ Kristi, ó wá rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀+  kí wọ́n lọ bi í pé: “Ṣé ìwọ ni Ẹni Tó Ń Bọ̀, àbí ká máa retí ẹlòmíì?”+  Jésù dá wọn lóhùn pé: “Ẹ lọ ròyìn ohun tí ẹ̀ ń gbọ́ àti ohun tí ẹ̀ ń rí fún Jòhánù:+  Àwọn afọ́jú ti ń ríran báyìí,+ àwọn arọ ń rìn, à ń wẹ àwọn adẹ́tẹ̀+ mọ́, àwọn adití ń gbọ́ràn, à ń jí àwọn òkú dìde, a sì ń sọ ìhìn rere fún àwọn aláìní.+  Aláyọ̀ ni ẹni tí kò rí ohunkóhun tó máa mú kó kọsẹ̀ nínú mi.”+  Nígbà tí àwọn yìí ń lọ, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún àwọn èrò náà nípa Jòhánù pé: “Kí lẹ jáde lọ wò ní aginjù?+ Ṣé esùsú* tí atẹ́gùn ń gbé kiri ni?+  Kí wá lẹ jáde lọ wò? Ṣé ọkùnrin tó wọ aṣọ àtàtà* ni? Ṣebí inú ilé àwọn ọba ni àwọn tó wọ aṣọ àtàtà máa ń wà?  Ká sòótọ́, kí ló wá dé tí ẹ jáde lọ? Ṣé kí ẹ lè rí wòlíì ni? Àní mo sọ fún yín, ó ju wòlíì lọ dáadáa.+ 10  Ẹni yìí la kọ̀wé nípa rẹ̀ pé: ‘Wò ó! Màá rán ìránṣẹ́ mi ṣáájú rẹ,* ẹni tó máa ṣètò ọ̀nà rẹ dè ọ́!’+ 11  Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé, nínú àwọn tí obìnrin bí, kò tíì sí ẹni tó tóbi ju Jòhánù Arinibọmi lọ, àmọ́ ẹni kékeré nínú Ìjọba ọ̀run tóbi jù ú lọ.+ 12  Láti àwọn ọjọ́ Jòhánù Arinibọmi títí di báyìí, Ìjọba ọ̀run ni ohun tí àwọn èèyàn ń fi agbára lépa, ọwọ́ àwọn tó ń sapá gidigidi sì ń tẹ̀ ẹ́.+ 13  Torí pé gbogbo wọn, àwọn Wòlíì àti Òfin, sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ títí dìgbà Jòhánù;+ 14  tí ẹ bá sì fẹ́ gba èyí gbọ́, òun ni ‘Èlíjà tó máa wá.’+ 15  Kí ẹni tó bá ní etí fetí sílẹ̀. 16  “Ta ni màá fi ìran yìí wé?+ Ó dà bí àwọn ọmọ kéékèèké tí wọ́n jókòó nínú ọjà, tí wọ́n ń pe àwọn tí wọ́n jọ ń ṣeré, 17  pé: ‘A fun fèrè fún yín, àmọ́ ẹ ò jó; a pohùn réré ẹkún, àmọ́ ẹ ò kẹ́dùn, kí ẹ sì lu ara yín.’ 18  Bákan náà, Jòhánù wá, kò jẹ, kò sì mu, àmọ́ àwọn èèyàn sọ pé, ‘Ẹlẹ́mìí èṣù ni.’ 19  Ọmọ èèyàn wá, ó ń jẹ, ó sì ń mu,+ àmọ́ àwọn èèyàn sọ pé, ‘Wò ó! Ọkùnrin alájẹkì, ti kò mọ̀ ju kó mu wáìnì lọ, ọ̀rẹ́ àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.’+ Síbẹ̀ náà, a fi ọgbọ́n hàn ní olódodo* nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀.”*+ 20  Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í gan àwọn ìlú tó ti ṣe èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn iṣẹ́ agbára rẹ̀, torí pé wọn ò ronú pìwà dà: 21  “O gbé, ìwọ Kórásínì! O gbé, ìwọ Bẹtisáídà! torí ká ní àwọn iṣẹ́ agbára tó ṣẹlẹ̀ nínú yín bá ṣẹlẹ̀ ní Tírè àti Sídónì ni, tipẹ́tipẹ́ ni wọ́n á ti ronú pìwà dà, nínú aṣọ ọ̀fọ̀* àti eérú.+ 22  Àmọ́ mò ń sọ fún yín pé, Tírè àti Sídónì máa lè fara dà á ní Ọjọ́ Ìdájọ́ jù yín lọ.+ 23  Àti ìwọ, Kápánáúmù,+ ṣé a máa gbé ọ ga dé ọ̀run ni? Inú Isà Òkú* nísàlẹ̀ lo máa lọ;+ torí ká ní àwọn iṣẹ́ agbára tó ṣẹlẹ̀ nínú rẹ bá ṣẹlẹ̀ ní Sódómù ni, ì bá ṣì wà títí dòní yìí. 24  Àmọ́ mo sọ fún yín pé, ilẹ̀ Sódómù máa lè fara dà á ní Ọjọ́ Ìdájọ́ jù yín lọ.”+ 25  Nígbà náà, Jésù sọ pé: “Baba, Olúwa ọ̀run àti ayé, mo yìn ọ́ ní gbangba, torí pé o fi àwọn nǹkan yìí pa mọ́ fún àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn amòye, o sì ti ṣí wọn payá fún àwọn ọmọdé.+ 26  Bẹ́ẹ̀ ni, Baba, torí pé ohun tí o fọwọ́ sí nìyí. 27  Baba mi ti fa ohun gbogbo lé mi lọ́wọ́,+ kò sì sẹ́ni tó mọ Ọmọ délẹ̀délẹ̀ àfi Baba;+ bẹ́ẹ̀ ni kò sẹ́ni tó mọ Baba délẹ̀délẹ̀ àfi Ọmọ àti ẹnikẹ́ni tí Ọmọ bá fẹ́ ṣí i payá fún.+ 28  Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tó ń ṣe làálàá, tí a di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, màá sì tù yín lára. 29  Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, torí oníwà tútù àti ẹni tó rẹlẹ̀ ní ọkàn ni mí,+ ara sì máa tù yín.* 30  Torí àjàgà mi rọrùn,* ẹrù mi sì fúyẹ́.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ìyẹn, koríko etí omi.
Ní Grk., “aṣọ múlọ́múlọ́.”
Ní Grk., “síwájú ojú rẹ.”
Tàbí “a dá ọgbọ́n láre.”
Tàbí “àwọn èso rẹ̀.”
Ní Grk., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
Tàbí “Hédíìsì,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “tu ọkàn yín.”
Tàbí “jẹ́ ti inú rere.”