Kíróníkà Kìíní 28:1-21

  • Ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ lórí kíkọ́ tẹ́ńpìlì (1-8)

  • Ó sọ ohun tí Sólómọ́nì máa ṣe; ó fún un ní àwòrán ìkọ́lé (9-21)

28  Nígbà náà, Dáfídì kó gbogbo ìjòyè Ísírẹ́lì jọ sí Jerúsálẹ́mù, àwọn ni: àwọn ìjòyè ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, àwọn olórí àwọn àwùjọ+ tó ń ṣe ìránṣẹ́ fún ọba, àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún,+ àwọn olórí tó ń bójú tó gbogbo ohun ìní àti àwọn ẹran ọ̀sìn ọba+ àti ti àwọn ọmọ rẹ̀+ pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ ààfin àti àwọn ọkùnrin tó jẹ́ akíkanjú àti ọ̀jáfáfá.+  Ìgbà náà ni Ọba Dáfídì dìde dúró, ó sì sọ pé: “Ẹ gbọ́ mi, ẹ̀yin arákùnrin mi àti ẹ̀yin èèyàn mi. Ó jẹ́ ìfẹ́ ọkàn mi láti kọ́ ilé tó máa jẹ́ ibi ìsinmi fún àpótí májẹ̀mú Jèhófà, tí á sì jẹ́ àpótí ìtìsẹ̀ fún Ọlọ́run wa,+ mo sì ti ṣètò sílẹ̀ láti kọ́ ọ.+  Àmọ́ Ọlọ́run tòótọ́ sọ fún mi pé, ‘O ò ní kọ́ ilé fún orúkọ mi,+ nítorí ọkùnrin ogun ni ọ́, o sì ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.’+  Síbẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì yàn mí nínú gbogbo ilé bàbá mi láti di ọba lórí Ísírẹ́lì títí láé,+ nítorí ó yan Júdà ṣe aṣáájú,+ nínú gbogbo ilé Júdà, ó yan ilé bàbá mi,+ nínú gbogbo ọmọ bàbá mi, èmi ni ó fọwọ́ sí, láti fi mí jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì.+  Nínú gbogbo àwọn ọmọ mi, torí àwọn ọmọ tí Jèhófà fún mi pọ̀,+ ó yan Sólómọ́nì+ ọmọ mi láti jókòó sórí ìtẹ́ ìjọba Jèhófà lórí Ísírẹ́lì.+  “Ó sọ fún mi pé, ‘Sólómọ́nì ọmọ rẹ ló máa kọ́ ilé mi àti àwọn àgbàlá mi, nítorí mo ti yàn án ṣe ọmọ mi, màá sì di bàbá rẹ̀.+  Màá fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ títí láé+ tó bá pinnu láti máa pa àwọn àṣẹ mi àti àwọn ìdájọ́+ mi mọ́, bí ó ti ń ṣe lọ́wọ́lọ́wọ́.’  Torí náà, mò ń sọ fún yín lójú gbogbo Ísírẹ́lì, ìyẹn ìjọ Jèhófà àti ní etí Ọlọ́run wa pé: Ẹ rí i pé ẹ mọ gbogbo àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run yín, kí ẹ sì máa pa wọ́n mọ́, kí ilẹ̀ dáradára+ náà lè di tiyín, kí ẹ sì lè fi sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ogún tó máa wà títí láé fún àwọn ọmọ yín.  “Ìwọ Sólómọ́nì ọmọ mi, mọ Ọlọ́run bàbá rẹ, kí o sì fi gbogbo ọkàn*+ àti inú dídùn* sìn ín, nítorí gbogbo ọkàn ni Jèhófà ń wá,+ ó sì ń fi òye mọ gbogbo èrò àti ìfẹ́ ọkàn.+ Tí o bá wá a, á jẹ́ kí o rí òun,+ àmọ́ tí o bá fi í sílẹ̀, á kọ̀ ẹ́ sílẹ̀ títí láé.+ 10  Ní báyìí, wò ó, Jèhófà ti yàn ọ́ láti kọ́ ilé kan tó máa jẹ́ ibi mímọ́. Jẹ́ onígboyà kí o sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́.” 11  Lẹ́yìn náà, Dáfídì fún Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ ní àwòrán ìkọ́lé+ ti ibi àbáwọlé*+ àti ti àwọn ilé rẹ̀, àwọn yàrá tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí, àwọn yàrá orí òrùlé, àwọn yàrá inú àti ti ilé ìbòrí ìpẹ̀tù.*+ 12  Ó fún un ní àwòrán ìkọ́lé gbogbo ohun tí a fi hàn án nípa ìmísí* nípa àwọn àgbàlá+ ilé Jèhófà, ti gbogbo àwọn yàrá ìjẹun tó yí i ká, ti àwọn ibi ìṣúra ilé Ọlọ́run tòótọ́ àti ti àwọn ibi ìṣúra tí wọ́n ń kó àwọn ohun tí a sọ di* mímọ́+ sí; 13  bákan náà, ó sọ fún un nípa àwọn àwùjọ àwọn àlùfáà+ àti ti àwọn ọmọ Léfì, gbogbo iṣẹ́ tó jẹ́ iṣẹ́ ìsìn ilé Jèhófà àti gbogbo nǹkan tí wọ́n ń lò fún iṣẹ́ ìsìn ilé Jèhófà; 14  ó tún fún un ní ìwọ̀n wúrà, wúrà gbogbo nǹkan èlò tí wọ́n á fi ṣe oríṣiríṣi iṣẹ́ ìsìn, ìwọ̀n gbogbo nǹkan èlò fàdákà àti gbogbo nǹkan èlò tí wọ́n á fi ṣe oríṣiríṣi iṣẹ́ ìsìn; 15  bákan náà, ó fún un ní ìwọ̀n àwọn ọ̀pá fìtílà wúrà+ àti àwọn fìtílà wúrà wọn, ìwọ̀n oríṣiríṣi ọ̀pá fìtílà àti àwọn fìtílà wọn àti ìwọ̀n àwọn ọ̀pá fìtílà fàdákà, ti ọ̀pá fìtílà kọ̀ọ̀kan àti àwọn fìtílà rẹ̀ bí wọ́n ṣe ń lò wọ́n; 16  ó tún fún un ní ìwọ̀n wúrà àwọn tábìlì búrẹ́dì onípele,*+ ti tábìlì kọ̀ọ̀kan àti fàdákà tí wọ́n á fi ṣe àwọn tábìlì fàdákà, 17  ó fún un ní ìwọ̀n àwọn àmúga, àwọn abọ́, àwọn ṣágo ògidì wúrà àti ìwọ̀n ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn abọ́ kéékèèké wúrà+ àti ìwọ̀n ọ̀kọ̀ọ̀kan abọ́ kéékèèké fàdákà. 18  Ó tún fún un ní ìwọ̀n wúrà tí a yọ́ mọ́ fún pẹpẹ tùràrí+ àti fún àwòrán kẹ̀kẹ́ ẹṣin,+ ìyẹn, àwọn kérúbù+ wúrà tí wọ́n na ìyẹ́ apá wọn bo orí àpótí májẹ̀mú Jèhófà. 19  Dáfídì sọ pé: “Ọwọ́ Jèhófà wà pẹ̀lú mi, ó sì fún mi ní ìjìnlẹ̀ òye kí n lè kọ+ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ àwòrán ìkọ́lé+ náà sílẹ̀.” 20  Lẹ́yìn náà, Dáfídì sọ fún Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ pé: “Jẹ́ onígboyà àti alágbára kí o sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Má bẹ̀rù, má sì jáyà, nítorí Jèhófà Ọlọ́run, Ọlọ́run mi, wà pẹ̀lú rẹ.+ Kò ní fi ọ́ sílẹ̀ tàbí kí ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀,+ àmọ́ ó máa wà pẹ̀lú rẹ títí gbogbo iṣẹ́ tó jẹ́ ti iṣẹ́ ìsìn ilé Jèhófà á fi parí. 21  Àwùjọ àwọn àlùfáà+ àti ti àwọn ọmọ Léfì+ nìyí fún gbogbo iṣẹ́ ìsìn ilé Ọlọ́run tòótọ́. O ní àwọn òṣìṣẹ́ tó ti múra tán, tí wọ́n sì jẹ́ ọ̀jáfáfá láti ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí,+ o tún ní àwọn ìjòyè+ àti gbogbo àwọn èèyàn tó máa ṣe gbogbo ohun tí o bá ní kí wọ́n ṣe.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ọkàn tó pa pọ̀.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”
Tàbí “ìmúratán.”
Tàbí “gọ̀bì.”
Tàbí “ilé ètùtù.”
Ní Héb., “ẹ̀mí.”
Tàbí “yà sí.”
Ìyẹn, búrẹ́dì àfihàn.