Ìwé Kìíní Jòhánù 3:1-24

  • Ọmọ Ọlọ́run ni wá (1-3)

  • Àwọn ọmọ Ọlọ́run yàtọ̀ sí àwọn ọmọ Èṣù (4-12)

    • Jésù máa fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú (8)

  • Ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín (13-18)

  • Ọlọ́run ju ọkàn wa lọ (19-24)

3  Ẹ wo irú ìfẹ́ tí Baba ní sí wa+ tí a fi ń pè wá ní ọmọ Ọlọ́run!+ Ohun tí a sì jẹ́ nìyẹn. Ìdí nìyẹn tí ayé ò fi mọ̀ wá,+ torí kò tíì mọ̀ ọ́n.+  Ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, a ti wá di ọmọ Ọlọ́run,+ àmọ́ a ò tíì fi ohun tí a máa jẹ́ hàn kedere.+ A mọ̀ pé nígbà tí a bá fi í hàn kedere a máa dà bíi rẹ̀, torí a máa rí i bó ṣe rí gẹ́lẹ́.  Gbogbo ẹni tó bá sì ní ìrètí yìí nínú rẹ̀ ń wẹ ara rẹ̀ mọ́+ bí ẹni yẹn ṣe jẹ́ mímọ́.  Gbogbo ẹni tó bá sọ ẹ̀ṣẹ̀ dàṣà ń rú òfin, ẹ̀ṣẹ̀ ni rírú òfin.  Bákan náà, ẹ mọ̀ pé a fi í hàn kedere láti mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa kúrò,+ kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ nínú rẹ̀.  Gbogbo ẹni tó bá wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀ kì í sọ ẹ̀ṣẹ̀ dàṣà;+ ẹnikẹ́ni tó bá sọ ẹ̀ṣẹ̀ dàṣà kò tíì rí i, kò sì tíì mọ̀ ọ́n.  Ẹ̀yin ọmọ kéékèèké, kí ẹnikẹ́ni má ṣì yín lọ́nà; gbogbo ẹni tó bá ń ṣe òdodo jẹ́ olódodo, bí ẹni yẹn ṣe jẹ́ olódodo.  Ẹni tó bá ń sọ ẹ̀ṣẹ̀ dàṣà wá látọ̀dọ̀ Èṣù, torí láti ìbẹ̀rẹ̀* ni Èṣù ti ń dẹ́ṣẹ̀.+ Ìdí tí a ṣe fi Ọmọ Ọlọ́run hàn kedere nìyí, kó lè fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú.*+  Gbogbo ẹni tí a bí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run kì í sọ ẹ̀ṣẹ̀ dàṣà,+ torí irúgbìn* Rẹ̀ wà nínú ẹni náà, kò sì lè sọ ẹ̀ṣẹ̀ dàṣà, torí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run la ti bí i.+ 10  Ohun tí a máa fi dá àwọn ọmọ Ọlọ́run àti àwọn ọmọ Èṣù mọ̀ nìyí: Ẹnikẹ́ni tí kì í ṣe òdodo kò wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀.+ 11  Torí ọ̀rọ̀ tí ẹ ti gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ ni pé ká nífẹ̀ẹ́ ara wa;+ 12  kì í ṣe bíi Kéènì, tó jẹ́ ti ẹni burúkú náà, tó sì pa àbúrò rẹ̀.+ Kí nìdí tó fi pa á? Torí àwọn iṣẹ́ rẹ̀ burú,+ àmọ́ ti àbúrò rẹ̀ jẹ́ òdodo.+ 13  Ẹ̀yin ará, ẹ má ṣe jẹ́ kó yà yín lẹ́nu pé ayé kórìíra yín.+ 14  A mọ̀ pé a ti tinú ikú wá sí ìyè,+ torí pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará.+ Ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ ṣì wà nínú ikú.+ 15  Gbogbo ẹni tó bá kórìíra arákùnrin rẹ̀ jẹ́ apààyàn,+ ẹ sì mọ̀ pé kò sí apààyàn kankan tí ìyè àìnípẹ̀kun ṣì wà nínú rẹ̀.+ 16  Ohun tó jẹ́ ká mọ ìfẹ́ ni pé ẹni yẹn fi ẹ̀mí* rẹ̀ lélẹ̀ fún wa,+ torí náà ó di dandan kí àwa náà fi ẹ̀mí wa* lélẹ̀ fún àwọn ará wa.+ 17  Àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá ní ohun ìní ayé yìí, tó sì rí i pé arákùnrin rẹ̀ ṣaláìní síbẹ̀ tí kò ṣàánú rẹ̀, báwo ni ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe wà nínú rẹ̀?+ 18  Ẹ̀yin ọmọ kéékèèké, kò yẹ kí ìfẹ́ wa jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹnu tàbí ti ahọ́n,+ àmọ́ ó yẹ kó jẹ́ ní ìṣe+ àti òtítọ́.+ 19  Èyí ló máa jẹ́ ká mọ̀ pé a wá látinú òtítọ́, a sì máa jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀* níwájú rẹ̀ 20  nínú ohunkóhun tí ọkàn wa ti lè dá wa lẹ́bi, torí Ọlọ́run ju ọkàn wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo.+ 21  Ẹ̀yin ẹni ọ̀wọ́n, tí ọkàn wa kò bá dá wa lẹ́bi, a lè sọ̀rọ̀ ní fàlàlà níwájú Ọlọ́run;+ 22  a sì ń rí ohunkóhun tí a bá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ gbà,+ torí à ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, a sì ń ṣe àwọn ohun tó dáa lójú rẹ̀. 23  Lóòótọ́, àṣẹ tó pa nìyí pé: ká ní ìgbàgbọ́ nínú orúkọ Ọmọ rẹ̀ Jésù Kristi,+ ká sì nífẹ̀ẹ́ ara wa+ bó ṣe pàṣẹ fún wa gẹ́lẹ́. 24  Bákan náà, ẹni tó bá ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀, ó sì máa wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ẹni náà.+ Ẹ̀mí tó fún wa sì jẹ́ ká mọ̀ pé ó wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú wa.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “látìgbà tí ó ti bẹ̀rẹ̀.”
Tàbí “kó lè run àwọn iṣẹ́ Èṣù.”
Ìyẹn, irúgbìn tó lè méso jáde tàbí kó bí sí i.
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn wa.”
Tàbí “máa yí èrò ọkàn wa pa dà; máa mú kó dá ọkàn wa lójú.”