Ìwé Kìíní sí Tímótì 1:1-20

  • Ìkíni (1, 2)

  • Ìkìlọ̀ torí àwọn olùkọ́ èké (3-11)

  • Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí a fi hàn sí Pọ́ọ̀lù (12-16)

  • Ọba ayérayé (17)

  • ‘Máa ja ogun rere’ (18-20)

1  Pọ́ọ̀lù, àpọ́sítélì Kristi Jésù nípasẹ̀ àṣẹ Ọlọ́run Olùgbàlà wa àti ti Kristi Jésù, ìrètí wa,+  sí Tímótì,*+ ọmọ gidi+ nínú ìgbàgbọ́: Kí o ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, àánú àti àlàáfíà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ Baba àti Kristi Jésù Olúwa wa.  Bí mo ṣe gbà ọ́ níyànjú nígbà tí mo fẹ́ lọ sí Makedóníà pé kí o dúró ní Éfésù, bẹ́ẹ̀ náà ni mò ń ṣe báyìí, kí o lè pàṣẹ fún àwọn kan pé kí wọ́n má ṣe fi ẹ̀kọ́ tó yàtọ̀ kọ́ni,  kí wọ́n má sì tẹ́tí sí àwọn ìtàn èké+ àti àwọn ìtàn ìdílé. Irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ kò wúlò rárá,+ ṣe ló ń mú káwọn èèyàn máa méfò dípò kó máa fúnni ní ohunkóhun látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ìyẹn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́.  Ní tòótọ́, ìdí tí mo fi ń sọ ìtọ́ni* yìí jẹ́ nítorí ìfẹ́+ látinú ọkàn tó mọ́, látinú ẹ̀rí ọkàn rere àti látinú ìgbàgbọ́+ tí kò ní àgàbàgebè.  Torí àwọn kan ti pa àwọn nǹkan yìí tì, wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ tí kò nítumọ̀.+  Wọ́n fẹ́ di olùkọ́+ òfin, àmọ́ wọn ò lóye àwọn ohun tí wọ́n ń sọ àtàwọn nǹkan tí wọ́n ń tẹnu mọ́ pé ó dá àwọn lójú.  A mọ̀ pé Òfin dáa tí èèyàn bá tẹ̀ lé e bó ṣe yẹ,*  ó yé wa pé torí olódodo kọ́ ni òfin ṣe wà, àmọ́ ó wà torí àwọn arúfin  + àtàwọn ọlọ̀tẹ̀, àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run àtàwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, àwọn aláìṣòótọ́* àti aláìmọ́, àwọn tó ń pa bàbá àti àwọn tó ń pa ìyá, àwọn apààyàn, 10  àwọn oníṣekúṣe,* àwọn ọkùnrin tó ń bá ọkùnrin lò pọ̀,* àwọn ajínigbé, àwọn òpùrọ́, àwọn tó ń parọ́ nílé ẹjọ́* àti torí gbogbo àwọn nǹkan míì tó ta ko ẹ̀kọ́ tó ṣàǹfààní*+ 11  tó bá ìhìn rere ológo ti Ọlọ́run aláyọ̀ mu, èyí tí a fi sí ìkáwọ́ mi.+ 12  Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Kristi Jésù Olúwa wa, tó fún mi lágbára, torí ó kà mí sí olóòótọ́ ní ti pé ó fún mi ní iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan,+ 13  bó tiẹ̀ jẹ́ pé asọ̀rọ̀ òdì ni mí tẹ́lẹ̀, mo máa ń ṣe inúnibíni, mo sì jẹ́ aláfojúdi.+ Síbẹ̀, a fi àánú hàn sí mi, torí àìmọ̀kan ni mo fi hùwà, mi ò sì ní ìgbàgbọ́. 14  Àmọ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Olúwa wa pọ̀ gan-an, bẹ́ẹ̀ sì ni ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ tó wà nínú Kristi Jésù. 15  Ọ̀rọ̀ yìí ṣeé gbára lé, ó sì yẹ ká gbà á délẹ̀délẹ̀, pé: Kristi Jésù wá sí ayé láti gba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ là.+ Èmi sì ni ẹni àkọ́kọ́ lára wọn.+ 16  Síbẹ̀, a fi àánú hàn sí mi, kó lè jẹ́ pé nípasẹ̀ èmi tí mo jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ nínú ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi Jésù máa fi gbogbo sùúrù rẹ̀ hàn, kó lè fi mí ṣe àpẹẹrẹ fún àwọn tó máa gbà á gbọ́ kí wọ́n lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.+ 17  Nítorí náà, kí ọlá àti ògo máa jẹ́ ti Ọba ayérayé,+ ẹni tí kò lè díbàjẹ́,+ tí a kò lè rí,+ Ọlọ́run kan ṣoṣo,+ títí láé àti láéláé. Àmín. 18  Tímótì ọmọ mi, mo fi ìtọ́ni* yìí sí ìkáwọ́ rẹ, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn nǹkan tí a sọ tẹ́lẹ̀ nípa rẹ, pé kí o lè máa fi wọ́n ja ogun rere,+ 19  kí ìgbàgbọ́ rẹ má ṣe yẹ̀, kí o sì máa ní ẹ̀rí ọkàn rere,+ èyí tí àwọn kan ti sọ nù, tó sì ti mú kí ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wọn rì. 20  Híméníọ́sì+ àti Alẹkisáńdà wà lára irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀, mo sì ti fi wọ́n lé Sátánì lọ́wọ́,+ kí a lè fi ìbáwí kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ pé kí wọ́n má sọ̀rọ̀ òdì mọ́.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ó túmọ̀ sí “Ẹni Tó Bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run.”
Tàbí “pa àṣẹ.”
Grk., “bó ṣe bófin mu.”
Tàbí “tí kò ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ìṣekúṣe.”
Tàbí “ọkùnrin tó ń bá ọkùnrin sùn.” Ní Grk., “ọkùnrin tó ń sùn ti ọkùnrin.”
Tàbí “àwọn tó ń búra èké.”
Tàbí “tó ṣeni lóore; tó wúlò.”
Tàbí “àṣẹ.”