Àkọsílẹ̀ Mátíù 14:1-36

  • Wọ́n gé orí Jòhánù Arinibọmi (1-12)

  • Jésù bọ́ 5,000 èèyàn (13-21)

  • Jésù rìn lórí omi (22-33)

  • Ó ṣèwòsàn ní Jẹ́nẹ́sárẹ́tì (34-36)

14  Ní àkókò yẹn, Hẹ́rọ́dù, alákòóso agbègbè náà,* gbọ́ ìròyìn nípa Jésù,+  ó sì sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Jòhánù Arinibọmi nìyí. A ti jí i dìde, ìdí sì nìyẹn tó fi lè ṣe àwọn iṣẹ́ agbára yìí.”+  Hẹ́rọ́dù* ti mú Jòhánù, ó dè é, ó sì fi sẹ́wọ̀n torí Hẹrodíà, ìyàwó Fílípì arákùnrin rẹ̀.+  Jòhánù sì ti ń sọ fún un pé: “Kò bófin mu fún ọ láti fẹ́ obìnrin yìí.”+  Àmọ́, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó fẹ́ pa á, ó ń bẹ̀rù àwọn èèyàn, torí pé wòlíì ni wọ́n kà á sí.+  Àmọ́ nígbà tí wọ́n ń ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí+ Hẹ́rọ́dù, ọmọbìnrin Hẹrodíà jó níbi ayẹyẹ náà, ó sì múnú Hẹ́rọ́dù dùn gan-an+  débi pé ó ṣèlérí, ó sì búra pé òun máa fún un ní ohunkóhun tó bá béèrè.  Ìyá ọmọbìnrin náà kọ́ ọ ní ohun tó máa sọ, ó sì sọ pé: “Fún mi ní orí Jòhánù Arinibọmi níbí yìí nínú àwo pẹrẹsẹ.”+  Bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú ọba ò dùn rárá, ó pàṣẹ pé kí wọ́n fún un, torí pé ó ti búra àti torí àwọn tó ń bá a jẹun.* 10  Ó wá ránṣẹ́ pé kí wọ́n lọ bẹ́ orí Jòhánù nínú ẹ̀wọ̀n. 11  Wọ́n gbé orí rẹ̀ wá nínú àwo pẹrẹsẹ, wọ́n sì fún ọmọbìnrin náà, ó wá gbé e wá fún ìyá rẹ̀. 12  Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá gbé òkú rẹ̀ kúrò, wọ́n sì sin ín; wọ́n wá ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ fún Jésù. 13  Nígbà tí Jésù gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, ó wọ ọkọ̀ ojú omi kúrò níbẹ̀ lọ sí ibi tó dá, kó lè dá wà. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn èrò gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n fi ẹsẹ̀ rìn tẹ̀ lé e látinú àwọn ìlú.+ 14  Nígbà tó wá sí etíkun, ó rí èrò rẹpẹtẹ, àánú wọn ṣe é,+ ó sì wo àwọn tó ń ṣàìsàn nínú wọn sàn.+ 15  Àmọ́ nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì sọ pé: “Ibí yìí dá, ọjọ́ sì ti lọ; jẹ́ kí àwọn èèyàn yìí máa lọ, kí wọ́n lè lọ sínú àwọn abúlé, kí wọ́n sì ra ohun tí wọ́n máa jẹ.”+ 16  Ṣùgbọ́n Jésù sọ fún wọn pé: “Wọn ò nílò kí wọ́n lọ; ẹ fún wọn ní nǹkan tí wọ́n máa jẹ.” 17  Wọ́n sọ fún un pé: “A ò ní nǹkan kan níbí àfi búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja méjì.” 18  Ó sọ pé: “Ẹ mú un wá síbí fún mi.” 19  Ó wá sọ fún àwọn èrò náà pé kí wọ́n jókòó* sórí koríko. Lẹ́yìn náà, ó mú búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja méjì náà, ó wo ojú ọ̀run, ó sì súre,+ lẹ́yìn tó bu búrẹ́dì náà, ó fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn sì fún àwọn èrò náà. 20  Gbogbo wọn jẹ, wọ́n yó, wọ́n sì kó èyí tó ṣẹ́ kù jọ, ó kún apẹ̀rẹ̀ méjìlá (12).+ 21  Àwọn tó jẹun tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé.+ 22  Láìjáfara, ó mú kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ọkọ̀ ojú omi, kí wọ́n sì lọ ṣáájú rẹ̀ sí etíkun tó wà ní òdìkejì, ó sì ní kí àwọn èrò náà máa lọ.+ 23  Lẹ́yìn tó ní kí àwọn èrò náà máa lọ, òun nìkan lọ sórí òkè láti gbàdúrà.+ Nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, òun nìkan ló wà níbẹ̀. 24  Ní àkókò yẹn, ọkọ̀ ojú omi náà ti wà ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìwọ̀n yáàdì* sí orí ilẹ̀, wọ́n ń bá ìgbì òkun fà á, torí pé atẹ́gùn náà ń dà wọ́n láàmú. 25  Àmọ́ ní ìṣọ́ kẹrin òru,* ó wá bá wọn, ó ń rìn lórí òkun. 26  Nígbà tí wọ́n tajú kán rí i tó ń rìn lórí òkun, ọkàn àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ò balẹ̀, wọ́n sọ pé: “Ìran abàmì nìyí!” Wọ́n bá kígbe torí ẹ̀rù bà wọ́n. 27  Àmọ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ mọ́kàn le! Èmi ni; ẹ má bẹ̀rù.”+ 28  Pétérù sọ fún un pé: “Olúwa, tó bá jẹ́ ìwọ ni, pàṣẹ fún mi pé kí n wá bá ọ lórí omi.” 29  Ó sọ pé: “Máa bọ̀!” Pétérù wá jáde nínú ọkọ̀ ojú omi, ó rìn lórí omi, ó sì ń lọ sọ́dọ̀ Jésù. 30  Àmọ́ nígbà tó wo ìjì tó ń jà, ẹ̀rù bà á. Nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í rì, ó ké jáde pé: “Olúwa, gbà mí là!” 31  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jésù na ọwọ́ rẹ̀, ó sì dì í mú, ó sọ fún un pé: “Ìwọ tí ìgbàgbọ́ rẹ kéré, kí ló dé tí o fi ṣiyèméjì?”+ 32  Lẹ́yìn tí wọ́n wọnú ọkọ̀ ojú omi náà, ìjì tó ń jà rọlẹ̀. 33  Àwọn tó wà nínú ọkọ̀ ojú omi náà wá tẹrí ba* fún un, wọ́n sọ pé: “Ọmọ Ọlọ́run ni ọ́ lóòótọ́.” 34  Wọ́n sọdá, wọ́n sì gúnlẹ̀ sí Jẹ́nẹ́sárẹ́tì.+ 35  Nígbà tí àwọn èèyàn ibẹ̀ wá mọ̀ pé òun ni, wọ́n ránṣẹ́ sí gbogbo ìgbèríko tó wà ní àyíká yẹn, àwọn èèyàn sì mú gbogbo àwọn tó ń ṣàìsàn wá sọ́dọ̀ rẹ̀. 36  Wọ́n bẹ̀ ẹ́ pé kí àwọn ṣáà fọwọ́ kan wajawaja tó wà létí aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀,+ ara gbogbo àwọn tó fọwọ́ kàn án sì yá pátápátá.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Grk., “alákòóso ìdá mẹ́rin.”
Ìyẹn, Hẹ́rọ́dù Áńtípà. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “àwọn tó rọ̀gbọ̀kú sídìí tábìlì pẹ̀lú rẹ̀.”
Tàbí “rọ̀gbọ̀kú.”
Ní Grk., “ọ̀pọ̀ sítédíọ̀mù.” Sítédíọ̀mù kan jẹ́ mítà 185 (606.95 ẹsẹ̀ bàtà).
Ìyẹn, nǹkan bí aago mẹ́ta òru títí dìgbà tí ilẹ̀ mọ́ ní nǹkan bí aago mẹ́fà àárọ̀.
Tàbí “forí balẹ̀.”