Ìwé Kejì sí Àwọn Ará Tẹsalóníkà 3:1-18

  • Ẹ máa gbàdúrà (1-5)

  • Ìkìlọ̀ nítorí àwọn tó ń ṣe ségesège (6-15)

  • Ìkíni tó fi parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ (16-18)

3  Lákòótán, ẹ̀yin ará, ẹ máa gbàdúrà fún wa,+ kí ọ̀rọ̀ Jèhófà* lè máa gbilẹ̀ kíákíá,+ kí a sì máa ṣe é lógo, bó ṣe rí lọ́dọ̀ yín,  kí a lè gbà wá lọ́wọ́ àwọn ẹni ibi àti èèyàn burúkú,+ nítorí ìgbàgbọ́ kì í ṣe ohun ìní gbogbo èèyàn.+  Àmọ́ olóòótọ́ ni Olúwa, yóò fún yín lókun, yóò sì dáàbò bò yín kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.  Yàtọ̀ síyẹn, bí a ṣe wà nínú Olúwa, a ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú yín pé ẹ̀ ń ṣe àwọn ohun tí a sọ fún yín, ẹ ó sì máa ṣe wọ́n nìṣó.  Kí Olúwa máa darí ọkàn yín sínú ìfẹ́ Ọlọ́run+ àti sínú ìfaradà+ fún Kristi.  Ní báyìí ẹ̀yin ará, à ń fún yín ní ìtọ́ni ní orúkọ Jésù Kristi Olúwa wa, pé kí ẹ fà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ gbogbo arákùnrin tó ń rìn ségesège,+ tí kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣà* tí ẹ* gbà lọ́dọ̀ wa.+  Nítorí ẹ̀yin fúnra yín mọ bó ṣe yẹ kí ẹ fara wé wa,+ torí a ò ṣe ségesège láàárín yín,  bẹ́ẹ̀ la ò jẹ oúnjẹ ẹnikẹ́ni lọ́fẹ̀ẹ́.*+ Kàkà bẹ́ẹ̀, nínú òpò* àti làálàá, à ń ṣiṣẹ́ tọ̀sántòru kí a má bàa gbé ẹrù tó wúwo wọ ìkankan nínú yín lọ́rùn.+  Kì í ṣe pé a ò ní àṣẹ,+ àmọ́ a fẹ́ fi ara wa ṣe àpẹẹrẹ fún yín kí ẹ lè máa fara wé wa.+ 10  Kódà, nígbà tí a wà lọ́dọ̀ yín, a máa ń pa àṣẹ yìí fún yín pé: “Tí ẹnikẹ́ni ò bá fẹ́ ṣiṣẹ́, kó má jẹun.”+ 11  Nítorí a gbọ́ pé àwọn kan ń rìn ségesège láàárín yín,+ wọn ò ṣiṣẹ́ rárá, ṣe ni wọ́n ń tojú bọ ohun tí kò kàn wọ́n.+ 12  Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni a pa àṣẹ fún, tí a sì gbà níyànjú nínú Jésù Kristi Olúwa pé kí wọ́n gbájú mọ́ iṣẹ́ wọn, kí wọ́n sì máa jẹ oúnjẹ tí àwọn fúnra wọn ṣiṣẹ́ fún.+ 13  Ní tiyín, ẹ̀yin ará, ẹ má ṣe jẹ́ kó sú yín láti máa ṣe rere. 14  Àmọ́ tí ẹnikẹ́ni ò bá ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ tí a sọ nínú lẹ́tà yìí, ẹ sàmì sí ẹni náà, ẹ má sì bá a kẹ́gbẹ́ mọ́,+ kí ojú lè tì í. 15  Síbẹ̀, ẹ má kà á sí ọ̀tá, àmọ́ ẹ máa gbà á níyànjú+ bí arákùnrin. 16  Tóò, kí Olúwa àlàáfíà máa fún yín ní àlàáfíà nígbà gbogbo àti ní gbogbo ọ̀nà.+ Kí Olúwa wà pẹ̀lú gbogbo yín. 17  Ìkíni èmi Pọ́ọ̀lù nìyí, tí mo fi ọwọ́ ara mi kọ,+ ó jẹ́ àmì nínú gbogbo lẹ́tà mi; bí mo ṣe máa ń kọ̀wé nìyí. 18  Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Olúwa wa Jésù Kristi wà pẹ̀lú gbogbo yín.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ìtọ́ni.”
Tàbí kó jẹ́, “wọ́n.”
Tàbí “iṣẹ́ àṣekára.”
Tàbí “láìsanwó.”