Àkọsílẹ̀ Máàkù 6:1-56

  • Wọn ò tẹ́wọ́ gba Jésù ní ìlú rẹ̀ (1-6)

  • Ó fún àwọn Méjìlá náà ní ìtọ́ni nípa iṣẹ́ ìwàásù (7-13)

  • Wọ́n pa Jòhánù Onírìbọmi (14-29)

  • Jésù bọ́ 5,000 èèyàn (30-44)

  • Jésù rìn lórí omi (45-52)

  • Ó ṣe ìwòsàn ní Jẹ́nẹ́sárẹ́tì (53-56)

6  Ó kúrò níbẹ̀, ó sì wá sí agbègbè ìlú rẹ̀,+ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì tẹ̀ lé e.  Nígbà tó di Sábáàtì, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ni nínú sínágọ́gù, ẹnu ya ọ̀pọ̀ nínú àwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀, wọ́n sì sọ pé: “Ibo ni ọkùnrin yìí ti rí àwọn nǹkan yìí?+ Kí nìdí tí a fi fún un ní irú ọgbọ́n yìí, tí a sì tipasẹ̀ rẹ̀ ṣe àwọn iṣẹ́ agbára yìí?+  Ṣebí káfíńtà yẹn nìyí,+ ọmọ Màríà,+ tó tún jẹ́ arákùnrin Jémíìsì,+ Jósẹ́fù, Júdásì àti Símónì,+ àbí òun kọ́? Àwọn arábìnrin rẹ̀ sì wà níbí pẹ̀lú wa, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?” Torí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọsẹ̀ nítorí rẹ̀.  Ṣùgbọ́n Jésù sọ fún wọn pé: “Wòlíì máa ń níyì, àmọ́ kì í gbayì ní ìlú rẹ̀, láàárín àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ àti ní ilé òun fúnra rẹ̀.”+  Torí náà, kò lè ṣe iṣẹ́ agbára kankan níbẹ̀, ó kàn gbé ọwọ́ rẹ̀ lé díẹ̀ lára àwọn aláìsàn, ó sì wò wọ́n sàn.  Ó yà á lẹ́nu pé wọn ò nígbàgbọ́. Ó sì lọ yí ká àwọn abúlé náà, ó ń kọ́ni.+  Ó wá pe àwọn Méjìlá náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í rán wọn jáde ní méjì-méjì,+ ó sì fún wọn láṣẹ lórí àwọn ẹ̀mí àìmọ́.+  Ó tún pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe gbé ohunkóhun dání fún ìrìn àjò náà, àfi ọ̀pá, kí wọ́n má ṣe gbé oúnjẹ àti àpò oúnjẹ, kí wọ́n má sì kó owó* sínú àmùrè owó wọn,+  àmọ́ kí wọ́n wọ bàtà, kí wọ́n má sì wọ aṣọ méjì.* 10  Bákan náà, ó sọ fún wọn pé: “Ibikíbi tí ẹ bá ti wọ ilé kan, kí ẹ dúró síbẹ̀ títí ẹ máa fi kúrò níbẹ̀.+ 11  Níbikíbi tí wọn ò bá sì ti gbà yín tàbí fetí sí ọ̀rọ̀ yín, tí ẹ bá ń kúrò níbẹ̀, ẹ gbọn iyẹ̀pẹ̀ tó wà lábẹ́ ẹsẹ̀ yín dà nù, kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún wọn.”+ 12  Torí náà, wọ́n gbéra, wọ́n sì ń wàásù pé kí àwọn èèyàn ronú pìwà dà,+ 13  wọ́n lé ẹ̀mí èṣù púpọ̀ jáde,+ wọ́n fi òróró pa àwọn aláìsàn lára, wọ́n sì wò wọ́n sàn. 14  Ọba Hẹ́rọ́dù wá gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, torí òkìkí orúkọ Jésù ti kàn káàkiri, àwọn èèyàn sì ń sọ pé: “A ti jí Jòhánù Onírìbọmi dìde, ìdí nìyẹn tó fi lè ṣe àwọn iṣẹ́ agbára yìí.”+ 15  Àmọ́ àwọn míì ń sọ pé: “Èlíjà ni.” Síbẹ̀, àwọn míì ń sọ pé: “Ó dà bí ọ̀kan nínú àwọn wòlíì àtijọ́.”+ 16  Àmọ́ nígbà tí Hẹ́rọ́dù gbọ́, ó sọ pé: “Jòhánù tí mo bẹ́ lórí, òun ló ti jíǹde yìí.” 17  Torí Hẹ́rọ́dù fúnra rẹ̀ ti ránṣẹ́ pé kí wọ́n lọ mú Jòhánù, ó sì dè é sínú ẹ̀wọ̀n nítorí Hẹrodíà ìyàwó Fílípì arákùnrin rẹ̀, torí ó ti fẹ́ obìnrin náà.+ 18  Jòhánù sì ti ń sọ fún Hẹ́rọ́dù pé: “Kò bófin mu fún ọ láti fẹ́ ìyàwó arákùnrin rẹ.”+ 19  Hẹrodíà wá dì í sínú, ó sì fẹ́ pa á, àmọ́ kò rí i ṣe. 20  Hẹ́rọ́dù bẹ̀rù Jòhánù, ó mọ̀ pé olódodo ni, èèyàn mímọ́ sì ni,+ torí náà, ó ń dáàbò bò ó. Lẹ́yìn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, kò mọ ohun tó máa ṣe rárá, síbẹ̀ tayọ̀tayọ̀ ló máa ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. 21  Àmọ́ àyè ṣí sílẹ̀ ní ọjọ́ tí Hẹ́rọ́dù ń ṣe ọjọ́ ìbí rẹ̀.+ Ó se àsè oúnjẹ alẹ́ fún àwọn ìjòyè rẹ̀, àwọn ọ̀gágun àti àwọn ọkùnrin tó gbajúmọ̀ jù ní Gálílì.+ 22  Ọmọbìnrin Hẹrodíà wá wọlé, ó jó, ó sì múnú Hẹ́rọ́dù àti àwọn tó ń bá a jẹun* dùn. Ọba sọ fún ọmọbìnrin náà pé: “Bi mí ní ohunkóhun tí o bá fẹ́, màá sì fún ọ.” 23  Àní, ó búra fún un pé: “Ohunkóhun tí o bá bi mí, màá fún ọ, títí dórí ìdajì ìjọba mi.” 24  Ọmọbìnrin náà wá jáde lọ, ó sì sọ fún ìyá rẹ̀ pé: “Kí ni kí n béèrè?” Ó sọ pé: “Orí Jòhánù Onírìbọmi.” 25  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ọmọbìnrin náà yára wọlé lọ sọ́dọ̀ ọba, ó sì sọ ohun tó fẹ́, ó ní: “Mo fẹ́ kí o fún mi ní orí Jòhánù Arinibọmi nínú àwo pẹrẹsẹ ní báyìí.”+ 26  Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó dun ọba gan-an, kò fẹ́ ṣàìka ohun tó béèrè sí, torí pé ó ti búra àti torí àwọn àlejò rẹ̀.* 27  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ọba rán ẹ̀ṣọ́ kan, ó sì pàṣẹ pé kó lọ gbé orí Jòhánù wá. Torí náà, ó lọ, ó bẹ́ ẹ lórí nínú ẹ̀wọ̀n, 28  ó sì gbé orí rẹ̀ wá nínú àwo pẹrẹsẹ. Ó gbé e fún ọmọbìnrin náà, ọmọbìnrin náà sì gbé e fún ìyá rẹ̀. 29  Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n wá gbé òkú rẹ̀, wọ́n sì tẹ́ ẹ sínú ibojì.* 30  Àwọn àpọ́sítélì kóra jọ yí Jésù ká, wọ́n sì ròyìn gbogbo ohun tí wọ́n ṣe, tí wọ́n sì fi kọ́ni fún un.+ 31  Ó wá sọ fún wọn pé: “Ẹ máa bọ̀, ẹ wá síbi tó dá ní ẹ̀yin nìkan, kí ẹ sì sinmi díẹ̀.”+ Torí ọ̀pọ̀ ló ń wá, tí wọ́n sì ń lọ, wọn ò sì ní àkókò kankan tí ọwọ́ wọn dilẹ̀, kódà, wọn ò ráyè jẹun. 32  Torí náà, wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi lọ síbi tó dá, tí àwọn nìkan máa wà.+ 33  Àmọ́ àwọn èèyàn rí wọn bí wọ́n ṣe ń lọ, ọ̀pọ̀ sì mọ̀ nípa rẹ̀, àwọn èèyàn láti gbogbo ìlú sì fi ẹsẹ̀ sáré dé ibẹ̀ ṣáájú wọn. 34  Nígbà tó jáde, ó rí èrò rẹpẹtẹ, àánú wọn sì ṣe é,+ torí wọ́n dà bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.+ Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn ní ọ̀pọ̀ nǹkan.+ 35  Ọjọ́ ti ń lọ, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sọ pé: “Ibí yìí dá, ọjọ́ sì ti lọ.+ 36  Ní kí wọ́n máa lọ, kí wọ́n lè lọ sí ìgbèríko àti àwọn abúlé tó wà ní àyíká, kí wọ́n sì ra ohun tí wọ́n máa jẹ.”+ 37  Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ fún wọn ní nǹkan tí wọ́n máa jẹ.” Ni wọ́n bá fèsì pé: “Ṣé ká lọ ra búrẹ́dì igba (200) owó dínárì,* ká sì fún àwọn èèyàn yìí jẹ?”+ 38  Ó sọ fún wọn pé: “Búrẹ́dì mélòó lẹ ní? Ẹ lọ wò ó!” Lẹ́yìn tí wọ́n wò ó, wọ́n sọ pé: “Márùn-ún, pẹ̀lú ẹja méjì.”+ 39  Ó wá sọ fún gbogbo àwọn èèyàn náà pé kí wọ́n jókòó* sórí koríko tútù ní àwùjọ-àwùjọ.+ 40  Torí náà, wọ́n jókòó* ní àwùjọ ọgọ́rọ̀ọ̀rún àti àràádọ́ta. 41  Ó wá mú búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja méjì náà, ó wo ojú ọ̀run, ó sì súre.+ Lẹ́yìn náà, ó bu àwọn búrẹ́dì náà sí wẹ́wẹ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí í fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn pé kí wọ́n gbé e síwájú àwọn èèyàn náà, ó sì pín ẹja méjì náà fún gbogbo wọn. 42  Gbogbo wọn jẹ, wọ́n yó, 43  wọ́n sì kó èyí tó ṣẹ́ kù jọ, ó kún apẹ̀rẹ̀ méjìlá (12), yàtọ̀ sí àwọn ẹja náà.+ 44  Àwọn tó jẹ búrẹ́dì náà jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin. 45  Láìjáfara, ó mú kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ọkọ̀ ojú omi, kí wọ́n sì ṣáájú rẹ̀ lọ sí etíkun tó wà ní òdìkejì lápá Bẹtisáídà, òun fúnra rẹ̀ sì ní kí àwọn èrò náà máa lọ.+ 46  Lẹ́yìn tó kí wọn pé ó dàbọ̀, ó lọ sórí òkè lọ gbàdúrà.+ 47  Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, ọkọ̀ ojú omi náà ti wà ní àárín òkun, àmọ́ òun nìkan ló wà lórí ilẹ̀.+ 48  Nígbà tó rí i bí wọ́n ṣe ń tiraka láti tukọ̀, torí atẹ́gùn ń dà wọ́n láàmú, ní nǹkan bí ìṣọ́ kẹrin òru,* ó wá sápá ọ̀dọ̀ wọn, ó ń rìn lórí òkun; àmọ́ ó fẹ́* gba ẹ̀gbẹ́ wọn kọjá. 49  Nígbà tí wọ́n tajú kán rí i tó ń rìn lórí òkun, wọ́n rò pé: “Ìran abàmì ni!” Wọ́n bá kígbe. 50  Torí gbogbo wọn rí i, ọkàn wọn ò balẹ̀. Àmọ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ mọ́kàn le! Èmi ni; ẹ má bẹ̀rù.”+ 51  Ó wá wọnú ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú wọn, atẹ́gùn náà sì rọlẹ̀. Èyí yà wọ́n lẹ́nu gan-an, 52  torí wọn ò tíì mọ ohun tí búrẹ́dì náà túmọ̀ sí, ọkàn wọn ò sì tíì ní òye. 53  Nígbà tí wọ́n sọdá sórí ilẹ̀, wọ́n dé Jẹ́nẹ́sárẹ́tì, wọ́n sì dá ọkọ̀ náà ró sí tòsí.+ 54  Àmọ́ gbàrà tí wọ́n jáde nínú ọkọ̀ ojú omi náà, àwọn èèyàn dá a mọ̀. 55  Wọ́n sáré yí ká gbogbo agbègbè yẹn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé àwọn tó ń ṣàìsàn wá lórí ibùsùn síbi tí wọ́n gbọ́ pé ó wà. 56  Níbikíbi tó bá sì ti wọ àwọn abúlé, ìlú tàbí ìgbèríko, wọ́n máa gbé àwọn aláìsàn sí àwọn ibi tí wọ́n ti ń tajà, wọ́n á sì bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ kí wọ́n fọwọ́ kan wajawaja etí aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ lásán.+ Ara gbogbo àwọn tó fọwọ́ kàn án sì yá.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Grk., “bàbà.”
Tàbí “aṣọ míì.”
Tàbí “àwọn tó jókòó sídìí tábìlì pẹ̀lú rẹ̀.”
Tàbí “àwọn tó jókòó nídìí tábìlì.”
Tàbí “ibojì ìrántí.”
Tàbí “rọ̀gbọ̀kú.”
Tàbí “rọ̀gbọ̀kú.”
Ìyẹn, nǹkan bí aago mẹ́ta òru títí dìgbà tí ilẹ̀ mọ́ ní nǹkan bí aago mẹ́fà àárọ̀.
Tàbí “ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́.”