Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 16

Kọjú Ìjà sí Èṣù Àtàwọn Ọgbọ́n Àlùmọ̀kọ́rọ́yí Rẹ̀

Kọjú Ìjà sí Èṣù Àtàwọn Ọgbọ́n Àlùmọ̀kọ́rọ́yí Rẹ̀

“Ẹ kọ ojú ìjà sí Èṣù, yóò sì sá.”—JÁKỌ́BÙ 4:7.

1, 2. Àwọn wo ló máa ń láyọ̀ nígbà ìrìbọmi?

BÓ O bá ti ń sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún, ó ṣeé ṣe kó o ti gbọ́ ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ìrìbọmi láwọn àpéjọ àyíká àtàwọn àpéjọ àgbègbè wa. Síbẹ̀, bó ti wù kó o ti máa gbọ́rọ̀ ìrìbọmi tó, ó ṣì lè máa ṣe ẹ́ bíi pé o ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ ṣèrìbọmi báwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi bá dìde dúró níbi tí wọ́n jókòó sí ní ìlà iwájú. Bí wọ́n bá ti ń dìde báyìí, inú àwùjọ á dùn, wọ́n á sì bẹ̀rẹ̀ sí pàtẹ́wọ́. Omi lè lé ròrò lójú ẹ, bó o ti ń wo àwùjọ àwọn ẹni ọ̀wọ́n tí wọ́n pinnu láti máa sin Jèhófà yìí. Ó dájú pé a máa ń láyọ̀ gan-an nírú àkókò bẹ́ẹ̀!

2 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè máa ráwọn tó ń ṣèrìbọmi láwọn ìgbà mélòó kan ní àgbègbè ibi tá à ń gbé, àwọn áńgẹ́lì ni wọ́n láǹfààní láti máa rí wọn jù lọ. Ǹjẹ́ o lè ronú bí “ìdùnnú púpọ̀ yóò ṣe wà ní ọ̀run” bí wọ́n ṣe ń rí i tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn kárí ayé ń dara pọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, mọ́ àwọn tó wà nínú apá tó jẹ́ ti ilẹ̀ ayé lára ètò Jèhófà? (Lúùkù 15:7, 10) Kò sí iyè méjì pé inú àwọn áńgẹ́lì pàápàá máa ń dùn láti rí bí ètò Ọlọ́run ṣe ń bí sí i!—Hágáì 2:7.

ÈṢÙ “Ń RÌN KÁÀKIRI BÍ KÌNNÌÚN TÍ Ń KÉ RAMÚRAMÙ”

3. Kí nìdí tí Sátánì fi ń rìn káàkiri “bí kìnnìún tí ń ké ramúramù,” kí ló sì fẹ́ ṣe?

3 Àmọ́ ṣá o, àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí kan wà tí inú máa ń bí tí wọ́n bá ráwọn tó ń ṣèrìbọmi. Ńṣe ni inú Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ máa ń ru fùfù bí wọ́n bá ráwọn tó ń kẹ̀yìn sáyé búburú yìí. Ó ṣe tán, Sátánì ń fọ́nnu pé kò séèyàn kankan tó ń sin Jèhófà torí pé ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ní tòótọ́, àti pé kò sẹ́ni tó máa jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run bó bá dojú kọ ìdánwò tó le koko. (Ka Jóòbù 2:4, 5) Gbogbo ìgbà tí ẹnì kan bá pinnu láti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, ńṣe ló ń mú Sátánì ní onírọ́. Ó sì wá dà bíi pé Sátánì ń gba ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìgbátí lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, títí jálẹ̀ ọdún. Abájọ tó fi “ń rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ”! (1 Pétérù 5:8) “Kìnnìún” yìí ti múra tán láti pa wá jẹ nípa tẹ̀mí, ó fẹ́ ba àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́ tàbí kó tiẹ̀ kẹ̀yìn wa sí Ọlọ́run.—Sáàmù 7:1, 2; 2 Tímótì 3:12.

Ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi tí ẹnì kọ̀ọ̀kan ń ṣe ń mú Sátánì ní onírọ́

4, 5. (a) Àwọn ọ̀nà pàtàkì méjì wo ni Jèhófà gbà pààlà sí agbára tí Sátánì lè ní lórí wa? (b) Kí ló lè dá Kristẹni tòótọ́ lójú?

4 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a dojú kọ ọ̀tá tó jẹ́ òǹrorò, ẹ̀rù ò gbọ́dọ̀ máa bà wá. Kí nìdí? Ìdí ni pé, láwọn ọ̀nà pàtàkì méjì, Jèhófà ti pààlà síbi tí “kìnnìún tí ń ké ramúramù” náà lè nípa lórí wa dé. Àwọn ọ̀nà méjì wo nìyẹn? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Jèhófà ti sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn Kristẹni tòótọ́ tí wọ́n jẹ́ “ogunlọ́gọ̀ ńlá” máa la “ìpọ́njú ńlá” tí ń bọ̀ wá já. (Ìṣípayá 7:9, 14) Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run ò jẹ́ kùnà láé. Nítorí náà, Sátánì pàápàá gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ọwọ́ òun ò lè tó àwọn èèyàn Ọlọ́run lódindi.

5 A lè lóye ọ̀nà kejì tí Ọlọ́run gbà pààlà síbi tágbára rẹ̀ mọ látinú òtítọ́ pọ́ńbélé tí ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin tó jẹ́ adúróṣinṣin nígbà àtijọ́ sọ. Wòlíì Asaráyà sọ fún Ásà Ọba pé: “Jèhófà wà pẹ̀lú yín níwọ̀n ìgbà tí ẹ bá wà pẹ̀lú rẹ̀.” (2 Kíróníkà 15:2; ka 1 Kọ́ríńtì 10:13) Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ tó wà nínú Bíbélì fi hàn pé látijọ́, bí Sátánì ti gbìyànjú léraléra tó láti pa èyíkéyìí lára àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó jẹ́ adúróṣinṣin jẹ tó, ńṣe ló ń kùnà. (Hébérù 11:4-40) Lónìí, ó máa ṣeé ṣe fún Kristẹni tí kò bá jìnnà sí Ọlọ́run láti kọjú ìjà sí Èṣù, kó sì tún ṣẹ́gun rẹ̀ pàápàá. Kódà, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú un dá wa lójú pé: “Ẹ kọ ojú ìjà sí Èṣù, yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín.”—Jákọ́bù 4:7.

“ÀWA NÍ GÍDÍGBÒ KAN . . . LÒDÌ SÍ ÀWỌN AGBO ỌMỌ OGUN Ẹ̀MÍ BURÚKÚ”

6. Báwo ni Sátánì ṣe ń gbéjà ko àwọn Kristẹni lẹ́nì kọ̀ọ̀kan?

6 Sátánì ò lè jàjàṣẹ́gun nínú ogun tẹ̀mí yìí, àmọ́ ó lè mú èyíkéyìí lára wa balẹ̀ bá ò bá wà lójúfò mọ́. Sátánì mọ̀ pé òun lè pa wa run bóun bá lè sọ àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà di ahẹrẹpẹ. Ọ̀nà wo ni Sátánì ń gbà ṣe èyí? Nípa títa kò wá kíkankíkan, lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti nípa lílo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí tí Sátánì ń lò yìí.

7. Kí nìdí tí Sátánì fi ń ṣàtakò kíkankíkan sáwọn èèyàn Jèhófà?

7 Àtakò kíkankíkan. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19) Ìkìlọ̀ wà nínú ọ̀rọ̀ yẹn fún gbogbo Kristẹni tòótọ́. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ní báyìí Sátánì ti kó gbogbo àwọn ẹni ibi tó wà láyé sínú akóló rẹ̀, ó wá lè darí àtakò rẹ̀ sáwọn èèyàn Jèhófà tọ́wọ́ rẹ̀ kò tó látìgbà yìí wá, kó sì máa fínná mọ́ wọn. (Míkà 4:1; Jòhánù 15:19; Ìṣípayá 12:12, 17) Ó ń bínú kíkankíkan, torí ó mọ̀ pé àkókò díẹ̀ ló kù fóun. Ìdí sì nìyẹn tọ́wọ́ ìjà rẹ̀ fi ń le sí i. Lónìí, a dojú kọ ìsapá àṣekágbá Sátánì láti ba àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. Nítorí náà, ju ti ìgbàkígbà rí lọ, a gbọ́dọ̀ máa “fi òye mọ àwọn àkókò láti mọ ohun tí ó yẹ kí [a] ṣe.”—1 Kíróníkà 12:32.

8. Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà to sọ pé a ní “gídígbò kan” lòdì sí àwọn ẹ̀mí burúkú?

8 Ìjà tó ń bá wa jà lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fáwọn Kristẹni bíi tirẹ̀ pé: “Àwa ní gídígbò kan . . . lòdì sí àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú ní àwọn ibi ọ̀run.” (Éfésù 6:12) Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi lo ọ̀rọ̀ náà “gídígbò”? Èrò tó gbé wá ni tàwọn méjì tí wọ́n sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí, tí wọ́n sì ń bára wọn jìjàkadì. Nítorí náà, Pọ́ọ̀lù lo ọ̀rọ̀ yẹn láti tẹnu mọ́ ọn pé gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ní ìjà tá a máa bá àwọn ẹ̀mí burúkú jà. Yálà ìgbàgbọ́ nínú àwọn ẹ̀mí burúkú gbilẹ̀ lórílẹ̀-èdè tá à ń gbé tàbí kò gbilẹ̀ níbẹ̀, a kò gbọ́dọ̀ gbà gbé pé nígbà tá a ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà ńṣe ló dà bíi pé a bọ́ ságbo ìjàkadì. Ó kéré pin, látìgbà tí Kristẹni kọ̀ọ̀kan bá ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ ló ti bẹ̀rẹ̀ ìjàkadì. Abájọ tó fi pọn dandan fún Pọ́ọ̀lù láti gba àwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù níyànjú nígbà mẹ́ta pé kí wọ́n “dúró gbọn-in gbọn-in”!—Éfésù 6:11, 13, 14.

9. (a) Kí nìdí tí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù fi ń lo onírúurú “ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí”? (b) Kí nìdí tí Sátánì fi ń gbìyànjú láti sọ èrò wa dìbàjẹ́, báwo la sì ṣe lè sọ ìmọ̀ràn rẹ̀ dòfo? (Wo “ Ṣọ́ra Fún Ọgbọ́n Ẹ̀wẹ́ Sátánì!”) (d) Ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí wo la máa jíròrò báyìí?

9 Lílo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́. Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n dúró gbọn-in gbọn-in lòdì sí “àwọn ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí” Sátánì. (Éfésù 6:11, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW) Sì kíyè sí i pé èdè tó ń tọ́ka sí ohun púpọ̀ ni Pọ́ọ̀lù lò. Èyí tó fi hàn pé ọgbọ́n àrékérekè àwọn ẹ̀mí búburú kì í ṣe ọ̀kan ṣoṣo, ó pégba, ó sì nídìí tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́n fẹ́ kó jẹ́ pé bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, àwọn onígbàgbọ́ tó ti wẹ òkun àdánwò kan já, á tún kó sí akóló òmíràn. Ìyẹn ló sì fà á tí Èṣù àtàwọn ẹ̀mí èṣù fi ń ṣọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀, kí wọ́n bàa lè rí ibi tá a kù sí. Wọ́n á wá gba ibi tí wọ́n bá mọ̀ pé a kù sí nípa tẹ̀mí wọlé sí wa lára. Àmọ́, ọpẹ́ ni fún Jèhófà pé ó ṣeé ṣe fún wa láti mọ ọ̀pọ̀ lára ọgbọ́n tí Èṣù ń lò, torí pé ó ṣí wọn payá fún wa nínú Bíbélì. (2 Kọ́ríńtì 2:11) A sì ti kọ́kọ́ jíròrò irú àwọn ìwà àrékérekè bẹ́ẹ̀ nínú ìwé yìí, ìyẹn àwọn ìwà bí ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ àti ìṣekúṣe. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká gbé òmíràn yẹ̀ wò lára àwọn ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí Sátánì, ìyẹn ìbẹ́mìílò.

ÌWÀ Ọ̀DÀLẸ̀ NI ÌBẸ́MÌÍLÒ

10. (a) Kí ni ìbẹ́mìílò? (b) Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo ìbẹ́mìílò, ojú wo nìwọ náà sì fi ń wò ó?

10 Ńṣe lẹni tó ń bẹ́mìí lò ń ní àjọṣe tààràtà pẹ̀lú àwọn ẹ̀mí búburú. Lára àwọn àṣà ìbẹ́mìílò sì ni iṣẹ́ wíwò, iṣẹ́ oṣó, èèdì àti bíbá òkú sọ̀rọ̀. A sì mọ̀ dáadáa pé, ńṣe ni Jèhófà ń wo ìbẹ́mìílò bí “ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí.” (Diutarónómì 18:10-12; Ìṣípayá 21:8) Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé àwa pẹ̀lú gbọ́dọ̀ “fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ohun burúkú,” a kò gbọ́dọ̀ ní àjọṣe kankan pẹ̀lú àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú. (Róòmù 12:9) Ìwà ọ̀dàlẹ̀ tí ń kóni nírìíra gbáà nìyẹn máa jẹ́ sí Baba wa ọ̀run, Jèhófà!

11. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé pàkúté Sátánì ti ré bó bá lè tan ẹnikẹ́ni nínú wa wọnú àṣà ìbẹ́mìílò? Ṣàkàwé.

11 Ti pé ẹní bá ń lọ́wọ́ sí ìbẹ́mìílò ń hùwà àrékérekè tó burú jáì sí Jèhófà gan-an ló fà á tí Sátánì fi ń fẹ́ ká lọ́wọ́ sí i. Inú Sátánì sì máa ń dùn ní gbogbo ìgbà tó bá ti kọwọ́ Kristẹni èyíkéyìí bọnú àṣà ìbẹ́mìílò, torí pé pàkúté rẹ̀ tún ré nìyẹn. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ronú nípa àkàwé yìí: Bó bá ṣeé ṣe káwọn ọmọ ogun kan tan ọ̀kan lára àwọn ọmọ ogun ọ̀tá wọnú ẹgbẹ́ tiwọn, ó dájú pé inú olórí wọn á dùn gan-an. Ó tiẹ̀ lè máa fi ọ̀dàlẹ̀ tí wọ́n fẹ̀tàn mú náà yangàn bí àmì ẹ̀yẹ, kó bàa lè fi í yán ọ̀gá rẹ̀ tẹ́lẹ̀ lójú. Bákan náà, bí Kristẹni kan bá ń bẹ́mìí lò, a jẹ́ pé ńṣe ló ń mọ̀ọ́mọ̀ kọ Jèhófà sílẹ̀ tó sì ń fi ara rẹ̀ sábẹ́ ìdarí Sátánì. Wá wo bí inú Sátánì á ti dùn tó láti máa fi irú ọ̀dàlẹ̀ bẹ́ẹ̀ yangàn bí àmì ẹ̀yẹ tó kó ti ogun bọ̀! Ta ni nínú wa táá fẹ́ kí Èṣù fòun yangàn lọ́nà yẹn? Ká má ri! Àwa kì í ṣe ọ̀dàlẹ̀.

BÓ ṢE Ń LO ÌBÉÈRÈ LÁTI MÚ WA ṢIYÈ MÉJÌ

12. Ọgbọ́n wo ni Sátánì máa ń lò láti yí ojú tá a fi ń wo ìbẹ́mìílò padà?

12 Bá a bá ń bá a nìṣó láti máa kórìíra ìbẹ́mìílò, Sátánì ò ní lè fi fà wá sínú pàkúté rẹ̀. Ó ti wá rí i pé àfi kóun yí èrò wa padà. Lọ́nà wo? Ó ń wá oríṣiríṣi ọ̀nà tó máa gbà kó ìdààmú bá àwọn Kristẹni débi táwọn kan lára wọn á fi máa ronú pé “ohun tí ó dára burú àti pé ohun tí ó burú dára.” (Aísáyà 5:20) Kí Sátánì bàa lè ṣe èyí, ọgbọ́n kan tí kì í bà á tì tó ti máa ń lò tipẹ́tipẹ́ ló máa ń dá, ìyẹn ni lílo ìbéèrè láti mú kéèyàn máa ṣiyè méjì.

13. Ọ̀nà wo ni Sátánì gbà ń lo ìbéèrè láti dá iyè méjì sílẹ̀?

13 Kíyè sí bí Sátánì ṣe lo ọgbọ́n yẹn nígbà pípẹ́ sẹ́yìn. Nínú ọgbà Édẹ́nì, ó bi Éfà pé: “Ṣé bẹ́ẹ̀ ni ní tòótọ́, pé Ọlọ́run sọ pé ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú gbogbo igi ọgbà?” Nígbà tí Jóòbù wà lórí ilẹ̀ ayé, táwọn áńgẹ́lì sì pé jọ pọ̀ lókè ọ̀run, Sátánì béèrè pé: “Lásán ha ni Jóòbù ń bẹ̀rù Ọlọ́run bí?” Nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, Sátánì pè é níjà nípa sísọ pé: “Bí ìwọ bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, sọ fún àwọn òkúta wọ̀nyí pé kí wọ́n di àwọn ìṣù búrẹ́dì.” Ẹ̀gbin gbùn-ún-ùn, Sátánì tiẹ̀ dá yẹ̀yẹ́ Jèhófà nípa lílo ọ̀rọ̀ kan náà tí Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ ní nǹkan bí ọ̀sẹ̀ mẹ́fà sẹ́yìn pé: “Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà”!—Jẹ́nẹ́sísì 3:1; Jóòbù 1:9; Mátíù 3:17; 4:3.

14. (a) Báwo ni Sátánì ṣe ń lo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ láti dá iyè méjì sílẹ̀ lórí ọ̀ràn ìbẹ́mìílò? (b) Kí la máa gbé yẹ̀ wò báyìí?

14 Irú ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ kan náà ni Èṣù ń lò lónìí, kó bàa lè mú káwọn èèyàn máa ṣe kámi-kàmì-kámi nípa bí ìbẹ́mìílò ṣe burú tó. Ó bani nínú jẹ́ pé, ó ti kẹ́sẹ járí láti mú káwọn kan tó jẹ́ onígbàgbọ́ máa ṣiyè méjì. Wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí béèrè pé ṣé lóòótọ́ nírú àwọn ìbẹ́mìílò kan burú tó bí wọ́n ṣe ń sọ. Lédè kan, wọ́n ń ronú pé, ‘Ṣé bẹ́ẹ̀ ni ní tòótọ́?’ (2 Kọ́ríńtì 11:3) Báwo la ṣe lè ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ láti yí èrò wọn padà? Báwo la ṣe lè rí i dájú pé ìwà àrékérekè Sátánì kò nípa lórí wa? Láti dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká gbé apá méjì yẹ̀ wò nínú ìgbésí ayé ẹ̀dá èyí tí Sátánì ti ta àbààwọ́n ìbẹ́mìílò sí lára. Àwọn ni eré ìnàjú àti ìtọ́jú ara.

BÓ ṢE Ń FI ÌFẸ́ ỌKÀN WA ÀTÀWỌN OHUN TÁ A NÍLÒ TÀN WÁ JẸ

15. (a) Ojú wo lọ̀pọ̀ èèyàn fi ń wo ìbẹ́mìílò nílẹ̀ Yúróòpù àti Amẹ́ríkà? (b) Ọ̀nà wo ni ojú táráyé fi ń wo ìbẹ́mìílò ń gbà nípa lórí àwọn Kristẹni kan?

15 Pàápàá jù lọ nílẹ̀ Yúróòpù àti Amẹ́ríkà, ńṣe làwọn èèyàn túbọ̀ ń fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú ọ̀rọ̀ iṣẹ́ òkùnkùn, iṣẹ́ àjẹ́ àti irú àwọn ìbẹ́mìílò mìíràn. Àwọn fíìmù, ìwé, ètò orí tẹlifíṣọ̀n àtàwọn eré orí kọ̀ǹpútà túbọ̀ ń gbé ìwà ìbẹ́mìílò lárugẹ, wọ́n sì ń jẹ́ káwọn èèyàn rí wọn bí ohun ṣeréṣeré, ohun tó dáa, àti ohun tí kò léwu. Àwọn fíìmù àtàwọn ìwé kan tó dá lórí iṣẹ́ òkùnkùn tiẹ̀ ti wá gbajúmọ̀ bí ìṣáná ẹlẹ́ẹ́ta báyìí débi pé àwọn tó fẹ́ràn rẹ̀ ti dá ẹgbẹ́ sílẹ̀. Ó ṣe kedere pé àwọn ẹ̀mí èṣù ti kẹ́sẹ járí láti mú káwọn èèyàn fojú tín-ín-rín ewu tó wà nínú iṣẹ́ òkùnkùn. Àbí ìwà ká máa fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú ọ̀rọ̀ ìbẹ́mìílò yìí náà ti ń nípa lórí àwọn Kristẹni? Dájúdájú, ó ti nípa lórí èrò àwọn kan. Lọ́nà wo? Àpẹẹrẹ kan nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé lẹ́yìn tí Kristẹni kan ti wo fíìmù kan tó dá lórí iṣẹ́ òkùnkùn, ó sọ pé, “Mo wo fíìmù náà, àmọ́ mi ò lọ́wọ́ sí ìbẹ́mìílò.” Kí nìdí tírú èrò yẹn fi léwu?

16. Kí nìdí tó fi léwu pé kéèyàn yan eré ìnàjú tó dá lórí iṣẹ́ òkùnkùn láàyò?

16 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyàtọ̀ wà láàárín kéèyàn máa bẹ́mìí lò àti kéèyàn máa wo àwọn tó ń bẹ́mìí lò, ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé kò séwu nínú kéèyàn máa wo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ òkùnkùn. Kí nìdí? Gba èyí yẹ̀ wò: Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi hàn pé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù ò lágbára láti mọ ohun tá à ń rò. * Torí náà, bá a ṣe sọ ṣáájú, káwọn ẹ̀mí búburú bàa lè mọ ohun tá à ń rò, kí wọ́n sì rí ibi tá a kù sí nípa tẹ̀mí, wọ́n máa ń ṣọ́ wa lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀, wọ́n sì tún máa ń kíyè sí irú eré ìnàjú tá a fẹ́ràn. Bí ìwà Kristẹni kan bá wá fi hàn pé ó fẹ́ràn fíìmù tàbí àwọn ìwé tó dá lórí àwọn abẹ́mìílò, sísa oògùn síni, kéèyàn máa ṣe bí ẹni tí ẹ̀mí gbé, tàbí àwọn nǹkan míì tó dá lórí àwọn ẹ̀mí èṣù, ńṣe ló ń sọ irú ẹni tóun jẹ́ fún wọn. Ìyẹn ni pé, ó ń fi ibi tí òun kù sí hàn wọ́n! Báwọn náà bá sì ti rí i, wọ́n lè koná mọ́ gídígbò tí wọ́n ń bá irú Kristẹni bẹ́ẹ̀ jà kí wọ́n bàa lè fẹ̀yìn rẹ̀ balẹ̀. Kódà, àwọn kan tó jẹ́ pé eré ìnàjú tó ń gbé iṣẹ́ òkùnkùn lárugẹ ló kọ́kọ́ mú kí ọkàn wọn máa fà sí ìbẹ́mìílò ti wá ń lọ́wọ́ nínú ìbẹ́mìílò báyìí.—Ka Gálátíà 6:7.

Jàǹfààní ìtìlẹ́yìn Jèhófà nígbà tó o bá ń ṣàìsàn

17. Ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí wo ni Sátánì lè lò láti tan àwọn tára wọn ò yá sínú pàkúté rẹ̀?

17 Kì í ṣe wíwù tó máa ń wù wá láti ṣeré ìnàjú nìkan ni Sátánì máa ń lò, àmọ́ ó tún máa ń lo àwọn ọ̀ràn tó jẹ mọ́ gbígba ìtọ́jú láti tàn wá sínú pàkúté rẹ̀. Lọ́nà wo? Nǹkan lè tojú sú Kristẹni kan tí ara rẹ̀ kò yá bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti sapá lọ́pọ̀lọpọ̀ láti tọ́jú ara rẹ̀. (Máàkù 5:25, 26) Ìyẹn lè fún Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù ní àǹfààní tí wọ́n ti ń wá kọ́wọ́ ṣìnkún wọn lè tẹ̀ ẹ́. Wọ́n kúkú mọ̀ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kìlọ̀ fún wa pé ká má máa wá “ìrànwọ́ àwọn aṣenilọ́ṣẹ́.” (Aísáyà 31:2) Kí wọ́n lè mú kí Kristẹni kan kọ̀ láti fi ìkìlọ̀ yẹn sílò, wọ́n á tàn án títí tí wàhálà tó ń bá a fínra á fi mú kó gbékútà kó sì lọ gba ìtọ́jú tó la lílo “agbára abàmì,” tàbí ìbẹ́mìílò lọ. Ẹ ò rí i pé àgbákò ńlá nìyẹn! Bí ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí àwọn ẹ̀mí èṣù bá kẹ́sẹ járí, ó lè ba àjọṣe tí aláìlera náà ní pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. Lọ́nà wo?

18. Irú àwọn ìtọ́jú wo ni Kristẹni kan gbọ́dọ̀ kọ̀, kí sì nìdí?

18 Jèhófà kìlọ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n ń lo “agbára abàmì” pé: “Nígbà tí ẹ bá sì tẹ́ àtẹ́lẹwọ́ yín, èmi yóò fi ojú mi pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ yín. Bí ẹ tilẹ̀ gba àdúrà púpọ̀, èmi kò ní fetí sílẹ̀.” (Aísáyà 1:13, 15) Látàrí èyí, gbogbo ìgbà la máa ń fẹ́ láti yẹra fún ohunkóhun tó lè dènà àdúrà wa tó sì tún lè dín ìtìlẹ́yìn tá à ń rí gbà lọ́dọ̀ Jèhófà kù, pàápàá jù lọ nígbà tá a bá ń ṣàìsàn. (Sáàmù 41:3) Torí náà, bí Kristẹni tòótọ́ kan bá rí àpẹẹrẹ pé ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣàyẹ̀wò àìsàn kan tàbí irú ìtọ́jú tí wọ́n ń lò jẹ mọ́ ìbẹ́mìílò, ó gbọ́dọ̀ kọ̀ ọ́. * (Mátíù 6:13) Lọ́nà yẹn nìkan ló fi lè dá a lójú pé òun á máa rí ìtìlẹ́yìn Jèhófà. Wo àpótí náà,  “Ṣé Ìbẹ́mìílò Ni Lóòótọ́?” lójú ìwé 194.

BÓ BÁ DI PÉ ÌRÒYÌN NÍPA ÀWỌN Ẹ̀MÍ ÈṢÙ GBILẸ̀?

19. (a) Ìgbàgbọ́ wo ni Èṣù ti fẹ̀tàn mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn ní nípa agbára rẹ̀? (b) Irú àwọn ìtàn wo ló yẹ káwọn Kristẹni tòótọ́ máa yẹra fún?

19 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn nílẹ̀ Yúróòpù àti Amẹ́ríkà ń fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú bí agbára Sátánì ṣe léwu tó, bọ́rọ̀ ṣe rí láwọn ilẹ̀ mìíràn tún yàtọ̀. Láwọn ilẹ̀ wọ̀nyí, Èṣù ti tan àwọn èèyàn láti mú kí wọ́n nígbàgbọ́ pé agbára òun pọ̀ ju bó ṣe mọ ní tòótọ́. Àwọn èèyàn kan wà tí wọ́n ń gbé nínú ìbẹ̀rù, tí wọ́n ń jẹ nínú ìbẹ̀rù, tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ nínú ìbẹ̀rù, tí wọ́n sì ń sùn nínú ìbẹ̀rù nítorí àwọn ẹ̀mí burúkú. Ọ̀pọ̀ ìtàn làwọn èèyàn máa ń sọ nípa bí agbára àwọn ẹ̀mí èṣù ṣe pọ̀ tó. Ńṣe lara àwọn èèyàn máa ń wà lọ́nà láti gbọ́ irú àwọn ìtàn bẹ́ẹ̀ torí pé ó máa ń dùn mọ́ wọn gan-an ni. Ṣó yẹ káwa náà máa bá wọn tan irú ìtàn bẹ́ẹ̀ kálẹ̀? Rárá o, ìdí pàtàkì méjì ló sì wà táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kì í fi í ṣe bẹ́ẹ̀.

20. Ọ̀nà wo lẹnì kan lè gbà máa bá Sátánì tan èké kálẹ̀ láìmọ̀?

20 Ìdí àkọ́kọ́ ni pé bá a bá ń tan ìròyìn kálẹ̀ nípa itú táwọn ẹ̀mí èṣù ń pa, ńṣe là ń gbé akitiyan Sátánì lárugẹ. Lọ́nà wo? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú un dá wa lójú pé Sátánì lè ṣe àwọn iṣẹ́ agbára, àmọ́ ó tún kìlọ̀ fún wa pé ó máa ń lo ‘àwọn iṣẹ́ àmì irọ́’ àti “ẹ̀tàn.” (2 Tẹsalóníkà 2:9, 10) Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé Sátánì ni olórí ẹlẹ̀tàn, ó mọ bóun ṣe lè fẹ̀tàn yí ọkàn àwọn tó bá fẹ́ràn ìbẹ́mìílò po àti bó ṣe lè mú kí wọ́n gba àwọn ohun tí kì í ṣe òtítọ́ gbọ́. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè gbà gbọ́ pé òótọ́ ni ohun táwọn rí àti ohun táwọn gbọ́, kí wọ́n sì máa sọ bó ṣe rí lára wọn fáwọn ẹlòmíì. Bó bá sì di pé wọ́n ń sọ ìtàn náà ní àsọtúnsọ, wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í fi tiwọn kún un. Bí Kristẹni kan bá ní láti máa tan irú àwọn ìtàn bẹ́ẹ̀ kálẹ̀, a jẹ́ pé ó ń ṣe ohun tí Èṣù, “baba irọ́” fẹ́ kó máa ṣe nìyẹn. Òun náà á dẹni tó ń bá Sátánì tan èké kálẹ̀.—Jòhánù 8:44; 2 Tímótì 2:16.

21. Orí kí ni ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tá a bá ń bá àwọn ẹlòmíì sọ máa dá lé?

21 Ìdí kejì ni pé, báwọn ẹ̀mí èṣù bá tiẹ̀ ti yọ Kristẹni kan lẹ́nu rí nígbà kan sẹ́yìn, àfi kó yáa jáwọ́ nínú fífi ìtàn nípa irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ dá àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni lára yá. Kí nìdí? A gbà wá níyànjú pé: “Tẹjú mọ́ Olórí Aṣojú àti Aláṣepé ìgbàgbọ́ wa, Jésù. (Hébérù 12:2) Bẹ́ẹ̀ ni, orí Kristi ló yẹ kí ìjíròrò wa máa dá lé, kì í ṣe Sátánì. Ó tún yẹ ká kíyè sí i pé nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé kò fi ìtàn nípa àwọn ẹ̀mí búburú dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lára yá, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó mọ̀, ó sì lè sọ púpọ̀ nípa ohun tí Sátánì lè ṣe àti ohun tí kò lè ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, orí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ni ọ̀rọ̀ Jésù máa ń dá lé. Nítorí náà, ní àfarawé Jésù àtàwọn àpọ́sítélì, ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tá a bá ń bá àwọn ẹlòmíì sọ máa dá lórí “àwọn ohun ọlá ńlá Ọlọ́run.”—Ìṣe 2:11; Lúùkù 8:1; Róòmù 1:11, 12.

22. Báwo la ṣe lè mú kí “ìdùnnú púpọ̀ [máa] wà ní ọ̀run”?

22 Òótọ́ ni pé Sátánì máa ń lo onírúurú ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí, tó fi mọ́ ìbẹ́mìílò, láti fi wá bó ṣe máa ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Àmọ́ ṣá o, bá a bá kórìíra ohun burúkú, tá a sì rọ̀ mọ́ ohun rere, Èṣù ò ní ráyè wọlé sí wa lára, débi táá fi ba ìpinnu wa láti sá fún onírúurú ìbẹ́mìílò jẹ́. (Ka Éfésù 4:27) Sì fojú inú wo bí “ìdùnnú púpọ̀ yóò ṣe wà ní ọ̀run” bá a bá ń bá a nìṣó láti “dúró gbọn-in gbọn-in lòdì sí [àwọn ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí] Èṣù,” títí tí àfẹ́kù á fi bá òun fúnra rẹ̀!— Éfésù 6:11, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW.

^ ìpínrọ̀ 16 Àwọn orúkọ tó ṣàpèjúwe irú ẹni tí Sátánì jẹ́ (Alátakò, Abanijẹ́, Atannijẹ, Adánniwò, Òpùrọ́) kò fi hàn pé ó lágbára láti ṣàwárí ohun tó wà nínú ọkàn àti àyà wa. Àmọ́, ti Jèhófà yàtọ̀, torí Bíbélì ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “olùṣàyẹ̀wò àwọn ọkàn-àyà,” ó sì pe Jésù ní ẹni tó “ń wá inú kíndìnrín àti ọkàn-àyà.”—Òwe 17:3; Ìṣípayá 2:23.

^ ìpínrọ̀ 18 Bó o bá ń fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i, wo àpilẹ̀kọ náà “Àyẹ̀wò Ìlera Kan fún Ọ Ha Ni Bí?” nínú Ilé-Ìṣọ́nà December 15, 1994, ojú ìwé 19 sí 22 àti àpilẹ̀kọ náà, “Ǹjẹ́ Irú Ìtọ́jú Tóo Yàn Ṣe Pàtàkì?” nínú Ilé Ìṣọ́ February 15, 2001, ojú ìwé 30 àti 31.