Àkọsílẹ̀ Máàkù 5:1-43

  • Jésù lé àwọn ẹ̀mí èṣù lọ sínú ẹlẹ́dẹ̀ (1-20)

  • Ọmọbìnrin Jáírù; obìnrin kan fọwọ́ kan aṣọ àwọ̀lékè Jésù (21-43)

5  Lẹ́yìn náà, wọ́n dé òdìkejì òkun, ní agbègbè àwọn ará Gérásà.+  Gbàrà tí Jésù sọ̀ kalẹ̀ nínú ọkọ̀ ojú omi, ọkùnrin kan tí ẹ̀mí àìmọ́ ń dà láàmú wá pàdé rẹ̀ láti àárín àwọn ibojì.*  Àárín àwọn ibojì ló máa ń wà, títí di àkókò yẹn, ẹnì kankan ò lè dè é pinpin, wọn ò lè fi ẹ̀wọ̀n dè é pàápàá.  Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n ti fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ àti ẹ̀wọ̀n dè é, àmọ́ ṣe ló já ẹ̀wọ̀n náà pàrà, tó sì já ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ náà sí wẹ́wẹ́; kò sí ẹni tó lágbára láti kápá rẹ̀.  Tọ̀sántòru ló ń ké ṣáá láwọn ibojì àti àwọn òkè, ó sì máa ń fi àwọn òkúta ya ara rẹ̀ yánnayànna.  Àmọ́ bó ṣe tajú kán rí Jésù ní ọ̀ọ́kán, ó sáré lọ forí balẹ̀ fún un.+  Ó sì ké jáde pé: “Kí ló pa wá pọ̀, Jésù Ọmọ Ọlọ́run Gíga Jù Lọ? Fi Ọlọ́run búra fún mi pé o ò ní dá mi lóró.”+  Torí Jésù ti ń sọ fún un pé: “Jáde nínú ọkùnrin náà, ìwọ ẹ̀mí àìmọ́.”+  Àmọ́ Jésù bi í pé: “Kí ni orúkọ rẹ?” Ó fèsì pé: “Líjíónì lorúkọ mi, torí a pọ̀.” 10  Ó ṣáà ń bẹ Jésù pé kó má ṣe lé àwọn ẹ̀mí náà jáde kúrò ní ilẹ̀ náà.+ 11  Ó ṣẹlẹ̀ pé ọ̀wọ́ àwọn ẹlẹ́dẹ̀+ tó pọ̀ ń jẹun níbẹ̀ níbi òkè.+ 12  Torí náà, àwọn ẹ̀mí náà bẹ̀ ẹ́ pé: “Lé wa lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà, ká lè wọnú wọn.” 13  Torí náà, ó gbà wọ́n láyè. Àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà bá jáde, wọ́n sì wọnú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà, ọ̀wọ́ ẹran náà rọ́ kọjá ní etí òkè* sínú òkun, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ni wọ́n, wọ́n sì kú sínú òkun. 14  Àmọ́ àwọn tó ń dà wọ́n sá lọ, wọ́n sì ròyìn rẹ̀ nínú ìlú àti ní ìgbèríko, àwọn èèyàn sì wá wo ohun tó ṣẹlẹ̀.+ 15  Torí náà, wọ́n wá bá Jésù, wọ́n sì rí ọkùnrin tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu náà, ẹni tí líjíónì wà nínú rẹ̀ tẹ́lẹ̀, ó jókòó, ó ti wọṣọ, orí rẹ̀ sì ti wálé, ni ẹ̀rù bá bẹ̀rẹ̀ sí í bà wọ́n. 16  Bákan náà, àwọn tí wọ́n rí i ròyìn fún wọn nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu náà àti àwọn ẹlẹ́dẹ̀. 17  Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ Jésù pé kó kúrò ní agbègbè wọn.+ 18  Bó ṣe ń wọ ọkọ̀ ojú omi, ọkùnrin tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu tẹ́lẹ̀ náà bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ kí òun tẹ̀ lé e.+ 19  Àmọ́ kò gbà fún un, ṣe ló sọ fún un pé: “Máa lọ sílé lọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ, kí o sì ròyìn fún wọn gbogbo ohun tí Jèhófà* ti ṣe fún ọ àti bó ṣe ṣàánú rẹ. 20  Ọkùnrin náà lọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kéde gbogbo ohun tí Jésù ṣe fún un ní Dekapólì,* ẹnu sì ya gbogbo èèyàn. 21  Lẹ́yìn tí Jésù tún fi ọkọ̀ ojú omi sọdá sí èbúté tó wà ní òdìkejì, èrò rẹpẹtẹ kóra jọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wà létí òkun.+ 22  Ọ̀kan nínú àwọn alága sínágọ́gù, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jáírù wá, nígbà tó sì tajú kán rí i, ó wólẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀.+ 23  Ó bẹ̀ ẹ́ léraléra, ó ní: “Ọmọbìnrin mi kékeré ń ṣàìsàn gidigidi.* Jọ̀ọ́, wá gbé ọwọ́ rẹ lé e+ kí ara rẹ̀ lè yá, kó má sì kú.” 24  Jésù wá tẹ̀ lé e, èrò rẹpẹtẹ sì ń rọ́ tẹ̀ lé e, wọ́n fún mọ́ ọn. 25  Obìnrin kan wà tó ti ní ìsun ẹ̀jẹ̀+ fún ọdún méjìlá (12).+ 26  Ó ti jìyà gan-an* lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ oníṣègùn, ó sì ti ná gbogbo ohun tó ní, àmọ́ kàkà kí ara rẹ̀ yá, ṣe ló ń burú sí i. 27  Nígbà tó gbọ́ ìròyìn nípa Jésù, ó gba àárín èrò wá sí ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì fọwọ́ kan aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀,+ 28  torí ó ń sọ ṣáá pé: “Tí mo bá fọwọ́ kan aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ lásán, ara mi á yá.”+ 29  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ gbẹ láú, ó sì mọ̀ nínú ara rẹ̀ pé àìsàn burúkú tó ń ṣe òun ti lọ. 30  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jésù mọ̀ ọ́n lára pé agbára+ ti jáde lára òun, ó wá yíjú pa dà láàárín èrò náà, ó sì béèrè pé: “Ta ló fọwọ́ kan aṣọ àwọ̀lékè mi?”+ 31  Àmọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé: “O rí i tí èrò ń fún mọ́ ọ, o wá ń béèrè pé, ‘Ta ló fọwọ́ kàn mí?’” 32  Ṣùgbọ́n ó ń wò yí ká kó lè rí ẹni tó fọwọ́ kàn án. 33  Ẹ̀rù ba obìnrin náà, jìnnìjìnnì sì bò ó, torí ó ti mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí òun, ó wá wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì sọ gbogbo òótọ́ ọ̀rọ̀ náà fún un. 34  Ó dá a lóhùn pé: “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá. Máa lọ ní àlàáfíà,+ kí àìsàn burúkú tó ń ṣe ọ́ sì lọ.”+ 35  Bó ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, àwọn ọkùnrin kan láti ilé alága sínágọ́gù wá, wọ́n sì sọ pé: “Ọmọbìnrin rẹ ti kú! Kí ló dé tí o ṣì ń yọ Olùkọ́ lẹ́nu?”+ 36  Àmọ́ Jésù fetí kọ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ, ó sì sọ fún alága sínágọ́gù náà pé: “Má bẹ̀rù,* ṣáà ti ní ìgbàgbọ́.”+ 37  Kò jẹ́ kí ẹnì kankan tẹ̀ lé òun, àfi Pétérù, Jémíìsì àti Jòhánù arákùnrin Jémíìsì.+ 38  Wọ́n sì dé ilé alága sínágọ́gù náà, ó rí i tí ariwo ń sọ, tí àwọn èèyàn ń sunkún, tí wọ́n sì ń pohùn réré ẹkún gidigidi,+ 39  Lẹ́yìn tó wọlé, ó sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń sunkún, tí ẹ sì ń pariwo báyìí? Ọmọ náà ò tíì kú, ó ń sùn ni.”+ 40  Ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ́rìn-ín, wọ́n sì ń fi ṣẹlẹ́yà. Àmọ́ lẹ́yìn tó ní kí gbogbo wọn bọ́ síta, ó mú bàbá àti ìyá ọmọ náà àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì wọlé síbi tí ọmọ náà wà. 41  Ó wá di ọwọ́ ọmọ náà mú, ó sì sọ fún un pé: “Tàlítà kumì,” tó túmọ̀ sí: “Ọmọbìnrin, mo sọ fún ọ, dìde!”+ 42  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ọmọbìnrin náà dìde, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rìn. (Ọmọ ọdún méjìlá [12] ni.) Lójú ẹsẹ̀, ṣe ni inú wọn bẹ̀rẹ̀ sí í dùn gidigidi. 43  Àmọ́ ó kìlọ̀ fún wọn léraléra* pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí ẹnì kankan mọ ohun tó ṣẹlẹ̀,+ ó sì ní kí wọ́n fún ọmọbìnrin náà ní nǹkan tó máa jẹ.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “àwọn ibojì ìrántí.”
Tàbí “gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́.”
Tàbí “Agbègbè Tó Ní Ìlú Mẹ́wàá.”
Tàbí “ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú.”
Tàbí “jẹ̀rora gan-an.”
Tàbí “Má fòyà mọ́.”
Tàbí “ó tẹ̀ ẹ́ mọ́ wọn létí.”