Ìwé Kejì sí Àwọn Ará Tẹsalóníkà 2:1-17

  • Ọkùnrin arúfin (1-12)

  • Ó gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n dúró gbọn-in (13-17)

2  Àmọ́, ẹ̀yin ará, ní ti wíwàníhìn-ín Olúwa wa Jésù Kristi+ àti kíkó wa jọ sọ́dọ̀ rẹ̀,+ a rọ̀ yín  kí ọkàn yín má tètè mì tàbí kí ó dà rú nítorí ọ̀rọ̀ onímìísí*+ tàbí nítorí iṣẹ́ tí a fẹnu jẹ́ tàbí nítorí lẹ́tà kan tó dà bíi pé ó wá látọ̀dọ̀ wa, tó ń sọ pé ọjọ́ Jèhófà*+ ti dé.  Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnì kankan kó yín ṣìnà* lọ́nàkọnà, nítorí kò ní dé láìjẹ́ pé ìpẹ̀yìndà+ kọ́kọ́ dé, tí a sì fi ọkùnrin arúfin+ hàn, ìyẹn ọmọ ìparun.+  Alátakò ni, ó sì gbé ara rẹ̀ lékè gbogbo àwọn tí wọ́n ń pè ní ọlọ́run tàbí ohun ìjọsìn,* tó fi jẹ́ pé ó jókòó nínú tẹ́ńpìlì Ọlọ́run, ó sì ń fi ara rẹ̀ hàn ní gbangba pé òun jẹ́ ọlọ́run.  Ṣé ẹ rántí pé nígbà tí mo ṣì wà pẹ̀lú yín, mo máa ń sọ àwọn nǹkan yìí fún yín?  Ní báyìí, ẹ mọ ohun tó ń ṣèdíwọ́ kó má bàa fara hàn ṣáájú àkókò rẹ̀.  Lóòótọ́, àṣírí ìwà ìkà yìí ti wà lẹ́nu iṣẹ́,+ àmọ́ ó dìgbà tí ẹni tó ń ṣèdíwọ́ ní báyìí bá kúrò lọ́nà.  Lẹ́yìn náà, a ó fi arúfin náà hàn, ẹni tí Jésù Olúwa máa fi ẹ̀mí ẹnu rẹ̀ pa,+ tí á sì sọ di asán nígbà tó bá ṣe kedere+ pé ó ti wà níhìn-ín.  Àmọ́ ohun tó mú kí arúfin náà wà níhìn-ín jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ Sátánì+ pẹ̀lú gbogbo iṣẹ́ agbára àti àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu* tó jẹ́ irọ́ + 10  pẹ̀lú gbogbo ẹ̀tàn àìṣòdodo  + fún àwọn tó ń ṣègbé, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀san iṣẹ́ wọn nítorí pé wọn ò gba ìfẹ́ òtítọ́ kí wọ́n lè rí ìgbàlà. 11  Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi jẹ́ kí ohun tó ń ṣiṣẹ́ ẹ̀tàn kó wọn ṣìnà, kí wọ́n lè gba irọ́ gbọ́,+ 12  kí a lè dá gbogbo wọn lẹ́jọ́ torí pé wọn ò gba òtítọ́ gbọ́, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ni wọ́n ń fi àìṣòdodo ṣayọ̀. 13  Síbẹ̀, ó di dandan fún wa láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo nítorí yín, ẹ̀yin ará tí Jèhófà* nífẹ̀ẹ́, torí pé àtìbẹ̀rẹ̀ ni Ọlọ́run ti yàn yín+ fún ìgbàlà nípa fifi ẹ̀mí rẹ̀ sọ yín di mímọ́+ àti nípa ìgbàgbọ́ yín nínú òtítọ́. 14  Ó tipasẹ̀ ìhìn rere tí à ń kéde pè yín sí èyí, kí ẹ lè ní ògo Olúwa wa Jésù Kristi.+ 15  Nítorí náà, ẹ̀yin ará, ẹ dúró gbọn-in,+ kí ẹ sì di àwọn àṣà tí a fi kọ́ yín mú ṣinṣin,+ ì báà jẹ́ nípasẹ̀ iṣẹ́ tí a fẹnu jẹ́ tàbí nípasẹ̀ lẹ́tà látọ̀dọ̀ wa. 16  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, kí Olúwa wa Jésù Kristi fúnra rẹ̀ àti Ọlọ́run, Baba wa, ẹni tó nífẹ̀ẹ́ wa,+ tó sì fún wa ní ìtùnú ayérayé àti ìrètí rere+ nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, 17  tu ọkàn yín lára, kó sì fìdí yín múlẹ̀ gbọn-in* nínú gbogbo iṣẹ́ rere àti ọ̀rọ̀ rere.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “torí ẹ̀mí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ẹ̀mí.”
Tàbí “sún yín dẹ́ṣẹ̀.”
Tàbí “ọ̀wọ̀.”
Tàbí “àwọn àmì.”
Tàbí “fún yín lókun.”