Ìwé Kìíní Pétérù 5:1-14

  • Ẹ máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run (1-4)

  • Ẹ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, kí ẹ sì wà lójúfò (5-11)

    • Ẹ máa kó gbogbo àníyàn yín lé Ọlọ́run (7)

    • Èṣù dà bíi kìnnìún tó ń ké ramúramù (8)

  • Ọ̀rọ̀ ìparí (12-14)

5  Torí náà, bí èmi náà ti jẹ́ alàgbà, tí mo fojú ara mi rí àwọn ìyà tí Kristi jẹ, tí mo sì máa pín nínú ògo tí a máa ṣí payá,+ mò ń rọ àwọn alàgbà tó wà láàárín yín* pé:  Ẹ máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run+ tó wà níkàáwọ́ yín, kí ẹ máa ṣe alábòójútó,* kì í ṣe tipátipá àmọ́ kó jẹ́ tinútinú níwájú Ọlọ́run;  + kó má ṣe jẹ́ nítorí èrè tí kò tọ́,+ àmọ́ kí ẹ máa fi ìtara ṣe é látọkàn wá;  ẹ má ṣe jẹ ọ̀gá lórí àwọn tó jẹ́ ogún Ọlọ́run,+ àmọ́ kí ẹ jẹ́ àpẹẹrẹ fún agbo.+  Tí a bá sì fi olórí olùṣọ́ àgùntàn+ hàn kedere, ẹ máa gba adé ògo tí kì í ṣá.+  Bákan náà, kí ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin máa tẹrí ba fún àwọn àgbà ọkùnrin.*+ Àmọ́ kí gbogbo yín gbé ìrẹ̀lẹ̀* wọ̀* nínú àjọṣe yín, torí Ọlọ́run dojú ìjà kọ àwọn agbéraga, àmọ́ ó ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí àwọn onírẹ̀lẹ̀.+  Torí náà, ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára Ọlọ́run, kó lè gbé yín ga ní àkókò tó yẹ,+  ẹ máa kó gbogbo àníyàn* yín lọ sọ́dọ̀ rẹ̀,+ torí ó ń bójú tó yín.*+  Ẹ máa ronú bó ṣe tọ́, ẹ wà lójúfò!+ Èṣù tó jẹ́ ọ̀tá yín ń rìn káàkiri bíi kìnnìún tó ń ké ramúramù, ó ń wá bó ṣe máa pani jẹ.*+  Àmọ́ ẹ kọjú ìjà sí i,+ kí ẹ dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́, ẹ mọ̀ pé irú ìyà kan náà ló ń jẹ gbogbo àwọn ará yín* nínú ayé.+ 10  Àmọ́ lẹ́yìn tí ẹ bá ti jìyà fún ìgbà díẹ̀, Ọlọ́run onínúure àìlẹ́tọ̀ọ́sí gbogbo, ẹni tó pè yín sí ògo àìlópin rẹ̀+ ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi, máa fúnra rẹ̀ parí ìdálẹ́kọ̀ọ́ yín. Ó máa fún yín lókun,+ ó máa sọ yín di alágbára,+ ó sì máa fẹsẹ̀ yín múlẹ̀ gbọn-in. 11  Kí agbára jẹ́ tirẹ̀ títí láé. Àmín. 12  Mo fi ọ̀rọ̀ díẹ̀ tí mo kọ yìí ránṣẹ́ sí yín nípasẹ̀ Sílífánù,*+ arákùnrin olóòótọ́, kí n lè fún yín níṣìírí, kí n sì lè jẹ́rìí taratara pé inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tòótọ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run nìyí. Ẹ dúró gbọn-in nínú rẹ̀. 13  Obìnrin tó wà ní Bábílónì, tó jẹ́ àyànfẹ́ bíi tiyín ń kí yín. Máàkù+ ọmọ mi náà ń kí yín. 14  Ẹ fi ìfẹnukonu ìfẹ́ kí ara yín. Kí gbogbo ẹ̀yin tí ẹ wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi ní àlàáfíà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “gba àwọn alàgbà tó wà láàárín yín níyànjú.”
Tàbí “ẹ máa tọ́jú wọn dáadáa.”
Tàbí “àwọn alàgbà.”
Tàbí “ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn.”
Tàbí “fi ìrẹ̀lẹ̀ di ara yín lámùrè.”
Tàbí “ohun tó ń jẹ yín lọ́kàn; ìdààmú.”
Tàbí “ó bìkítà fún yín.”
Tàbí “ó ń wá ẹni tó máa pa jẹ.”
Ní Grk., “ẹgbẹ́ àwọn ará yín.”
Wọ́n tún ń pè é ní Sílà.