Àkọsílẹ̀ Lúùkù 15:1-32

  • Àpèjúwe àgùntàn tó sọ nù (1-7)

  • Àpèjúwe ẹyọ owó tó sọ nù (8-10)

  • Àpèjúwe ọmọ tó sọ nù (11-32)

15  Gbogbo àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń kóra jọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ṣáá kí wọ́n lè gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.+  Àwọn Farisí àti àwọn akọ̀wé òfin sì ń ráhùn ṣáá, pé: “Ọkùnrin yìí ń tẹ́wọ́ gba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ó sì ń bá wọn jẹun.”  Ó wá sọ àpèjúwe yìí fún wọn, ó ní:  “Ọkùnrin wo nínú yín, tó ní ọgọ́rùn-ún (100) àgùntàn, ló jẹ́ pé tí ọ̀kan nínú wọn bá sọ nù, kò ní fi mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99) yòókù sílẹ̀ nínú aginjù, kó sì wá èyí tó sọ nù lọ títí ó fi máa rí i?+  Tó bá sì rí i, ó máa gbé e lé èjìká rẹ̀, inú rẹ̀ sì máa dùn.  Tó bá wá dé ilé, á pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ àti àwọn aládùúgbò rẹ̀ jọ, á sì sọ fún wọn pé, ‘Ẹ bá mi yọ̀, torí mo ti rí àgùntàn mi tó sọ nù.’+  Mò ń sọ fún yín pé, lọ́nà kan náà, inú àwọn tó wà ní ọ̀run máa dùn gan-an torí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tó ronú pìwà dà+ ju olódodo mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99) tí kò nílò ìrònúpìwàdà.  “Àbí obìnrin wo, tó ní ẹyọ owó dírákímà* mẹ́wàá, ló jẹ́ pé tí dírákímà* kan bá sọ nù, kò ní tan fìtílà, kó gbá ilé rẹ̀, kó sì fara balẹ̀ wá a títí ó fi máa rí i?  Tó bá sì rí i, á pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀* àti àwọn aládùúgbò rẹ̀ jọ, á sọ pé, ‘Ẹ bá mi yọ̀, torí mo ti rí ẹyọ owó dírákímà* tí mo sọ nù.’ 10  Mò ń sọ fún yín pé, lọ́nà kan náà, àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run máa ń yọ̀ torí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tó ronú pìwà dà.”+ 11  Lẹ́yìn náà, ó sọ pé: “Ọkùnrin kan ní ọmọkùnrin méjì. 12  Èyí àbúrò sọ fún bàbá rẹ̀ pé, ‘Bàbá, fún mi ní ìpín tó yẹ kó jẹ́ tèmi nínú ohun ìní rẹ.’ Ó wá pín àwọn ohun ìní rẹ̀ fún wọn. 13  Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, èyí àbúrò kó gbogbo ohun tó jẹ́ tirẹ̀ jọ, ó sì rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ tó jìnnà gan-an, ibẹ̀ ló ti ń gbé ìgbésí ayé oníwà pálapàla,* tó sì lo àwọn ohun ìní rẹ̀ nílòkulò. 14  Nígbà tó ti ná gbogbo rẹ̀ tán, ìyàn mú gan-an ní gbogbo ilẹ̀ yẹn, ó sì di aláìní. 15  Ó tiẹ̀ lọ fi ara rẹ̀ sọ́dọ̀ ọ̀kan nínú àwọn aráàlú yẹn, ẹni yẹn sì rán an lọ sínú àwọn pápá rẹ̀ pé kó máa tọ́jú àwọn ẹlẹ́dẹ̀.+ 16  Ó sì máa ń wù ú kó jẹ èèpo èso kárọ́ọ̀bù tí àwọn ẹlẹ́dẹ̀ ń jẹ, àmọ́ ẹnì kankan kì í fún un ní ohunkóhun. 17  “Nígbà tí orí rẹ̀ wálé, ó sọ pé, ‘Àìmọye àwọn alágbàṣe bàbá mi ló ní oúnjẹ ní àníṣẹ́kù, ebi wá ń pa èmi kú lọ níbí! 18  Jẹ́ kí n kúkú dìde, kí n rìnrìn àjò lọ sọ́dọ̀ bàbá mi, kí n sì sọ fún un pé: “Bàbá, mo ti ṣẹ̀ sí ọ̀run, mo sì ti ṣẹ̀ ọ́. 19  Mi ò yẹ lẹ́ni tí o lè pè ní ọmọ rẹ mọ́. Jẹ́ kí n dà bí ọ̀kan lára àwọn alágbàṣe rẹ.”’ 20  Ló bá dìde, ó sì lọ sọ́dọ̀ bàbá rẹ̀. Bó ṣe ń bọ̀ ní òkèèrè ni bàbá rẹ̀ tajú kán rí i, àánú rẹ̀ ṣe é, ó wá sáré lọ dì mọ́ ọn,* ó sì rọra fi ẹnu kò ó lẹ́nu. 21  Ọmọkùnrin náà wá sọ fún un pé, ‘Bàbá, mo ti ṣẹ̀ sí ọ̀run, mo sì ti ṣẹ̀ ọ́.+ Mi ò yẹ lẹ́ni tí o lè pè ní ọmọ rẹ mọ́.’ 22  Àmọ́ bàbá náà sọ fún àwọn ẹrú rẹ̀ pé, ‘Ó yá! ẹ mú aṣọ wá, aṣọ tó dáa jù, kí ẹ wọ̀ ọ́ fún un, kí ẹ fi òrùka sí i lọ́wọ́, kí ẹ sì wọ bàtà sí i lẹ́sẹ̀. 23  Kí ẹ tún mú ọmọ màlúù tó sanra wá, kí ẹ dúńbú rẹ̀, ká jọ jẹun, ká sì yọ̀, 24  torí pé ọmọ mi yìí kú, àmọ́ ó ti pa dà wà láàyè;+ ó sọ nù, a sì rí i.’ Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbádùn ara wọn. 25  “Ọmọkùnrin rẹ̀ àgbà wà nínú pápá, bó sì ṣe dé, tó sún mọ́ ilé, ó gbọ́ orin àti ijó. 26  Torí náà, ó pe ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ sọ́dọ̀, ó sì béèrè ohun tó ń ṣẹlẹ̀. 27  Ìránṣẹ́ náà sọ fún un pé, ‘Àbúrò rẹ ti dé, bàbá rẹ sì dúńbú ọmọ màlúù tó sanra torí ó pa dà rí i ní àlàáfíà.’* 28  Àmọ́ inú bí i, kò sì wọlé. Bàbá rẹ̀ wá jáde, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀ ẹ́. 29  Ó sọ fún bàbá rẹ̀ pé, ‘Wò ó! Ọ̀pọ̀ ọdún yìí ni mo ti ń sìn ọ́, mi ò tàpá sí àṣẹ rẹ rí, síbẹ̀, o ò fún mi ní ọmọ ewúrẹ́ kan rí kí èmi àti àwọn ọ̀rẹ́ mi lè fi gbádùn ara wa. 30  Àmọ́ gbàrà tí ọmọ rẹ yìí dé, ẹni tó lo àwọn ohun ìní rẹ nílòkulò* pẹ̀lú àwọn aṣẹ́wó, o dúńbú ọmọ màlúù tó sanra fún un.’ 31  Bàbá rẹ̀ wá sọ fún un pé, ‘Ọmọ mi, ìgbà gbogbo lo wà lọ́dọ̀ mi, ìwọ lo sì ni gbogbo ohun tó jẹ́ tèmi. 32  Àmọ́ ó yẹ ká yọ̀, kí inú wa sì dùn, torí pé arákùnrin rẹ kú, àmọ́ ó ti wà láàyè; ó sọ nù, a sì rí i.’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ obìnrin.”
Tàbí “onínàákúnàá; aláìníjàánu.”
Ní Grk., “rọ̀ mọ́ ọrùn rẹ̀.”
Tàbí “rí i láyọ̀.”
Ní Grk., “run àwọn ohun ìní rẹ.”