Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 ORÍ 14

Jẹ́ Olóòótọ́ Nínú Ohun Gbogbo

Jẹ́ Olóòótọ́ Nínú Ohun Gbogbo

‘A ń dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.’—HÉBÉRÙ 13:18.

1, 2. Kí nìdí tínú Jèhófà fi máa ń dùn tó bá rí bá a ṣe ń sapá láti jẹ́ olóòótọ́? Ṣàkàwé.

BÍ ỌMỌDÉKÙNRIN kan àti màmá rẹ̀ ṣe ń jáde látinú ṣọ́ọ̀bù kan, ọmọ náà ṣàdédé dúró, ó hàn lójú ẹ̀ pé ẹ̀rù ń bà á. Ó ti mú ọ̀kan lára àwọn bèbí tí wọ́n ń tà nínú ṣọ́ọ̀bù yẹn, ó sì ti gbàgbé láti dá a padà tàbí kó béèrè bóyá màmá ẹ̀ máa rà á fún un. Kò mohun tí ì bá ṣe, ló bá figbe ta. Màmá ẹ̀ fi í lọ́kàn balẹ̀, ó bá mú un padà lọ sínú ṣọ́ọ̀bù yẹn kọ́mọ náà lè dá ohun tó mú padà kó sì tọrọ àforíjì. Inú màmá ọmọdékùnrin náà dùn, ohun tí ọmọ rẹ̀ ṣe sì wú u lórí. Kí nìdí?

2 Kò sóhun tó ń múnú àwọn òbí dùn bíi kí wọ́n máa rí i pé àwọn ọmọ wọn ń fòótọ́ kọ́ra. Bọ́rọ̀ sì ṣe máa ń rí lára Bàbá wa ọ̀run náà nìyẹn, “Ọlọ́run òtítọ́.” (Sáàmù 31:5) Bó ti ń rí i pé àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ túbọ̀ ń dán mọ́rán sí i, inú rẹ̀ ń dùn pé à ń sapá láti jẹ́ olóòótọ́. Torí pé àwa pẹ̀lú fẹ́ dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀, a sì ń fẹ́ máa múnú rẹ̀ dùn, à ń ṣe ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “A [ń] dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.” (Hébérù 13:18) Ẹ jẹ́ ká wá jíròrò oríṣi apá mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí kìí ti í sábà rọrùn láti jẹ́ olóòótọ́ nígbèésí ayé. Lẹ́yìn ìyẹn, a máa jíròrò àwọn àǹfààní tó wà nínú jíjẹ́ olóòótọ́.

MÁ ṢE MÁA TANRA Ẹ JẸ

3-5. (a) Ìkìlọ̀ wo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wa nípa ewu tó wà nínú kéèyàn máa tanra ẹ̀ jẹ? (b) Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ tá ò fi ní máa tanra wa jẹ?

3 Ohun tá a ní láti kọ́kọ́ ṣe ni pé ká má máa tanra wa jẹ. Ó rọrùn gan-an fún wa láti máa tan ara wa jẹ torí a jẹ́ aláìpé.  Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ fáwọn Kristẹni tó wà nílùú Laodíkíà pé wọ́n tan ara wọn jẹ nígbà tí wọ́n ń rò pé àwọn jẹ́ ọlọ́rọ̀, àmọ́ ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, “òtòṣì àti afọ́jú àti ẹni ìhòòhò” nípa tẹ̀mí ni wọ́n. Ó mà ṣe o. (Ìṣípayá 3:17) Ńṣe ni títàn tí wọ́n tanra wọn jẹ túbọ̀ ṣàkóbá fún wọn.

4 O tún lè rántí pé Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yin Jésù kìlọ̀ pé: “Bí ọkùnrin èyíkéyìí lójú ara rẹ̀ bá dà bí olùjọsìn ní irú ọ̀nà kan, síbẹ̀ tí kò kó ahọ́n rẹ̀ níjàánu, ṣùgbọ́n tí ó ń bá a lọ ní títan ọkàn-àyà ara rẹ̀ jẹ, ọ̀nà ìjọsìn ọkùnrin yìí jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.” (Jákọ́bù 1:26) Bá a bá ń rò pé a lè máa fi ahọ́n wa sọ̀sọkúsọ, síbẹ̀ kí Jèhófà ṣì tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa, ńṣe là ń tanra wa jẹ. Ìjọsìn wa sí Jèhófà ò sì ní já mọ́ nǹkan kan. Kí ni ò ní jẹ́ kírú àdánù yìí bá wa?

5 Nínú orí kan náà yẹn, Jákọ́bù fi òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wé dígí. Ó gbà wá nímọ̀ràn pé ká wo inú òfin Ọlọ́run tó jẹ́ pípé, ká sì ṣàwọn àtúnṣe tó bá yẹ. (Ka Jákọ́bù 1:23-25) Bíbélì á ràn wá lọ́wọ́ láti fòótọ́ inú yẹra wa wò, á sì jẹ́ ká rí ohun tá a lè ṣe láti ṣàtúnṣe. (Ìdárò 3:40; Hágáì 1:5) A tún lè gbàdúrà sí Jèhófà pé kó yẹ̀ wá wò, kó ràn wá lọ́wọ́ láti rí àwọn ibi tá a kù sí, ká lè ṣàtúnṣe. (Sáàmù 139:23, 24) Kùdìẹ̀ kudiẹ tó máa ń yọ́ wọlé síni lára kéèyàn tó fura ni àìṣòótọ́ jẹ́, ojú tí Bàbá wa ọ̀run sì fi ń wò ó ló yẹ káwa náà máa fi wò ó. Òwe 3:32 sọ pé: “Oníbékebèke jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà, ṣùgbọ́n ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ Rẹ̀ wà pẹ̀lú àwọn adúróṣánṣán.” Jèhófà lè ràn wá lọ́wọ́ láti nírú ojú ìwòye tó ní, ká sì máa wo ara wa lọ́nà tó ń gbà wò wá. Rántí ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ pé: ‘A ń dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.’ A ò lè jẹ́ ẹni pípé ní báyìí, àmọ́ à ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti jẹ́ olóòótọ́.

JẸ́ OLÓÒÓTỌ́ NÍNÚ ÌDÍLÉ

Bá a bá jẹ́ olóòótọ́, a ò ní máa hùwà tí etí kejì ò gbọ́dọ̀ báni gbọ́

6. Kí nìdí tí tọkọtaya ò fi gbọ́dọ̀ máa purọ́ fúnra wọn, ewu wo ni wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ yẹra fún?

6 Ìṣòtítọ́ gbọ́dọ̀ jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ànímọ́ tá a fi  ń dá ìdílé Kristẹni kan mọ̀ yàtọ̀. Torí náà, ó yẹ kí tọkọtaya máa nà tán, kí wọ́n sì máa bára wọn sọ òótọ́. Nínú ìdílé Kristẹni, kò sáyè fún ìwàkiwà bíi títage pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya ẹni, yíyan àlè yálà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí lílọ́wọ́ sáwọn ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe lọ́nà èyíkéyìí. Àwọn Kristẹni kan tí wọ́n ti ṣègbéyàwó ti lọ́wọ́ sírú àwọn àṣà burúkú wọ̀nyí, tí ọkọ tàbí aya wọn ò sì mọ̀ nípa ẹ̀. Ìwà àìṣòótọ́ nìyẹn. Kíyè si ohun tí Dáfídì Ọbà tó jẹ́ olóòótọ́ sọ pé: “Èmi kò bá àwọn tí kì í sọ òtítọ́ jókòó; àwọn tí ń fi ohun tí wọ́n jẹ́ pa mọ́ ni èmi kì í sì í bá wọlé.” (Sáàmù 26:4) Bó o bá ti ṣègbéyàwó, má ṣe lọ́wọ́ sáwọn àṣà tó lè jẹ́ kó o bẹ̀rẹ̀ sí í fi irú ẹni tó o jẹ́ pa mọ́ fún ọkọ tàbí aya rẹ!

7, 8. Àwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì wo ló lè ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti fòótọ́ kọ́ra?

7 Ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé káwọn òbí lo àwọn àpẹẹrẹ tó wà nínú Bíbélì nígbà tí wọ́n bá ń fòótọ́ kọ́ àwọn ọmọ wọn. Lára àwọn tí kì í ṣe olóòótọ́ nínú Bíbélì ni Ákáánì, ẹni tó jalè tó sì gbìyànjú láti bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀; Géhásì, ẹni tó purọ́ torí owó; àti Júdásì ẹni tó jalè tó sì tún fìwà ẹ̀tàn da Jésù.—Jóṣúà 6:17-19; 7:11-25; 2 Àwọn Ọba 5:14-16, 20-27; Mátíù 26:14, 15; Jòhánù 12:6.

8 Àpẹẹrẹ àwọn kan tó jẹ́ olóòótọ́ ni Jékọ́bù, ẹni tó sọ fáwọn ọmọ rẹ̀ pé kí wọ́n dá owó tí wọ́n rí nínú àpò wọn padà torí ó rò pé àwọn ará Íjíbítì ò jẹ́ mọ̀ọ́mọ̀ fi síbẹ̀; Jẹ́fútà àti ọmọbìnrin  rẹ̀, ẹni tó fara mọ́ ẹ̀jẹ́ tí bàbá rẹ̀ jẹ́ nípa yíyọ̀ǹda ara ẹ̀; àti Jésù ẹni tó fira ẹ̀ han àwọn jàǹdùkú tìgboyà tìgboyà kó lè mú àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ, kó sì lè dáàbò bo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 43:12; Àwọn Onídàájọ́ 11:30-40; Jòhánù 18:3-11) Àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ wọ̀nyí lè jẹ́ káwọn òbí mọ̀ nípa àwọn ìsọfúnni àtàtà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fòótọ́ kọ́ àwọn ọmọ wọn.

9. Kí làwọn òbí ò gbọ́dọ̀ máa ṣe bí wọ́n bá fẹ́ fòótọ́ kọ́ àwọn ọmọ wọn nípasẹ̀ àpẹẹrẹ wọn, kí sì nìdí tírú àpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀ fi ṣe pàtàkì?

9 Ojúṣe pàtàkì kan wà tí kíkọ́ àwọn ọmọ lọ́nà yìí gbé lé àwọn òbí lọ́wọ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù béèrè pé: “Bí ó ti wù kí ó rí, ǹjẹ́ ìwọ, ẹni tí ń kọ́ ẹlòmíràn, kò kọ́ ara rẹ? Ìwọ, ẹni tí ń wàásù pé “Má jalè,” ìwọ ha ń jalè bí?” (Róòmù 2:21) Àwọn òbí kan kì í jẹ́ káwọn ọmọ wọn mọ ohun tó yẹ ní ṣíṣe, torí pé wọ́n máa ń kọ́ àwọn ọmọ wọn pé kí wọ́n máa sòótọ́, àmọ́ àwọn fúnra wọn kì í sòótọ́. Wọ́n lè máa dára wọn láre tí wọ́n bá jí àwọn nǹkan kéékèèké tàbí tí wọ́n bá sọ̀rọ̀ tí kì í sòótọ́, wọ́n lè sọ pé, “Kí ló wà níbẹ̀ fún bí wọn ò bá fẹ́ kéèyàn mú un,” tàbí kí wọ́n sọ pé “Irọ́ kékeré lásán nìyẹn, kò sóhun tó burú nínú ẹ̀.” Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, olè lolè ń jẹ́ láìka bí nǹkan tó jí ṣe kéré tó. Bákan náà, irọ́ nirọ́ ń jẹ́, kò ṣáà sí kékeré irọ́.  * (Ka Lúùkù 16:10) Àwọn ọmọdé máa ń tètè mọ̀ téèyàn bá jẹ́ ẹlẹ́nu méjì, èyí sì lè ṣàkóbá fún wọn. (Éfésù 6:4) Àmọ́ tí wọ́n bá fòótọ́ kọ́ra látinú àpẹẹrẹ àwọn òbí wọn, èyí lè jẹ́ kí wọ́n máa fìyìn fún Jèhófà bí wọ́n ti ń dàgbà nínú ayé tí ìwà màgòmágó ti gbilẹ̀ yìí.—Òwe 22:6.

JẸ́ OLÓÒÓTỌ́ NÍNÚ ÌJỌ

10. Kí ló yẹ ká ṣọ́ra fún, tó bá dọ̀rọ̀ sísọ òótọ́ láàárín àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́?

10 Fífara rora pẹ̀lú àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa máa ń fún  wa láǹfààní tó pọ̀ láti máa fòótọ́ kọ́ra. Gẹ́gẹ́ bá a ti kọ́ ọ ní Orí 12, a ò ní máa ṣọ̀rọ̀ bó bá ṣe wù wá, pàápàá jù lọ láàárín àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wa. Tá ò bá ṣọ́ra, a lè bẹ̀rẹ̀ sí tan òfófó tó ń pani lára, tàbí ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ kálẹ̀! Tá a bá ń sọ ìtàn èké tá ò mọ̀dí ẹ̀ kiri, a lè máa tipa bẹ́ẹ̀ tan irọ́ kálẹ̀, torí náà, ohun tó dára jù lọ ni pé ká máa ṣọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu wa. (Òwe 10:19) Àmọ́ ṣá o, a lè mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ kan lóòótọ́, síbẹ̀ ìyẹn ò ní ká máa sọ ọ́ kiri. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ náà lè má kàn wá, tàbí kó jẹ́ pé kò ní dáa ká máa sọ ọ́ fáwọn ẹlòmíì. (1 Tẹsalóníkà 4:11) Àwọn kan máa ń ṣọ̀rọ̀ ṣàkàṣàkà sáwọn ẹlòmíì tí wọ́n sì máa ń dára wọn láre pé òótọ́ ọ̀rọ̀ làwọ́n ń sọ, ọ̀rọ̀ tiwa gbọ́dọ̀ máa jẹ́ ti onínúure nígbà gbogbo kó sì máa dùn ún gbọ́ létí.—Ka Kólósè 4:6.

11, 12. (a) Báwo làwọn kan tí wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì ṣe ń dá kún ìṣòro ọ̀hún? (b) Àwọn irọ́ wo ni Sátánì ń tàn kálẹ̀ nípa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ búburú jáì, báwo la sì ṣe lè gbéjà ko àwọn irọ́ wọ̀nyí? (d) Báwo la ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ olóòótọ́ sí ètò Jèhófà?

11 Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká máa sòótọ́ fáwọn tó ń múpò iwájú nínú ìjọ. Àwọn kan tí wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì máa ń dá kún ìṣòro ọ̀hún ni ti pé, wọ́n máa ń dọ́gbọ́n bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀, wọ́n sì máa ń purọ́ fáwọn alàgbà nígbà tí wọ́n bá béèrè nípa bọ́rọ̀ náà ṣe rí. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ tiẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí fohun tí wọ́n jẹ́ pa mọ́, wọ́n ń díbọ́n pé àwọn ń jọ́sìn  Jèhófà, wọ́n sì ń yọ́ ẹ̀ṣẹ̀ dá. Bópẹ́ bóyá, irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ á fi irọ́ bara wọn láyé jẹ́. (Sáàmù 12:2) Àwọn míì máa sọ díẹ̀ lára ọ̀rọ̀ náà fáwọn alàgbà tí wọ́n á sì fàwọn òótọ́ tó ṣe pàtàkì kan pa mọ́. (Ìṣe 5:1-11) Wọ́n máa ń hu irú ìwà àìṣòótọ́ bẹ́ẹ̀ torí wọ́n gba àwọn irọ́ kan tí Sátánì ń tàn kálẹ̀ gbọ́.—Wo àpótí náà “ Àwọn Irọ́ Tí Sátánì Ń Pa Nípa Àwọn Ẹ̀ṣẹ̀ Tó Burú Jáì.”

12 Ó tún ṣe pàtàkì pé ká má purọ́ fún ètò Jèhófà bá a bá ní láti kọ àwọn ìsọfúnni kan ránṣẹ́ sí wọn. Bí àpẹẹrẹ, bá a bá ń kọ ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wa sílẹ̀, a máa ń ṣọ́ra láti má ṣe kọ ohun tí a ò ṣe sílẹ̀. Bákan náà, bá a bá ń kọ̀rọ̀ sínú àwọn fọ́ọ̀mù tá a fi ń béèrè fún àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan, a ò gbọ́dọ̀ purọ́ nípa ọ̀ràn ìlera wa, tàbí nípa àwọn ìsọfúnni míì tó yẹ ká kọ nípa ara wa.—Ka Òwe 6:16-19.

13. Báwo la ṣe lè jẹ́ olóòótọ́ bí iṣẹ́ ajé bá da àwa àtẹni tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ pọ̀?

13 Jíjẹ́ olóòótọ́ nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ tún kan àwọn ọ̀ràn tó jẹ mọ́ iṣẹ́ ajé. Láwọn ìgbà míì, iṣẹ́ ajé máa ń da àwọn ará pọ̀ lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ní láti ṣọ́ra kí wọ́n má ṣe da ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ajé pọ̀ mọ́ ìjọsìn, yálà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí lóde ẹ̀rí. Àjọṣe náà lè jẹ́ ti agbanisíṣẹ́ àti òṣìṣẹ́. Bá a bá gba àwọn arákùnrin tàbí arábìnrin wa síṣẹ́, a gbọ́dọ̀ rí i dájú pé à ń sòótọ́ fún wọn, ká máa san iye owó tá a jọ fẹnu kò lé lórí fún wọn lásìkò, àtàwọn àjẹmọ́nú tó bá a rìn tàbí èyí tí òfin bá béèrè. (1 Tímótì 5:18; Jákọ́bù 5:1-4) Bó bá sì jẹ́ ará lẹni tó gbà wá síṣẹ́, ó yẹ ká ṣiṣẹ́ owó tá a fẹ́ gbà lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. (2 Tẹsalóníkà 3:10) A ò ní máa retí pé kó máa ṣe ojúṣàájú sí wa torí pé a jọ jẹ́ onígbàgbọ́, a ò sì ní máa ṣe bíi pé a lẹ́tọ̀ọ́ láti máa gbàyè lẹ́nu iṣẹ́ bó bá ṣe wù wá, ká máa gba àwọn àjẹmọ́nú tàbí kẹ́ni tó gbà wá síṣẹ́ máa fún wa láwọn àǹfààní míì tí kò fáwọn òṣìṣẹ́ tó kù.—Éfésù 6:5-8.

14. Bí okòwò bá da àwọn Kristẹni pọ̀, kí ló bọ́gbọ́n mu pé kí wọ́n ṣe, kí sì nìdí?

 14 Bí iṣẹ́ ajé ọ̀hún bá wá jẹ́ òwò tẹ́ ẹ pawọ́ pọ̀ ṣe ńkọ́? Bóyá ńṣe lẹ jọ fowó dókòwò tàbí ẹnì kan yáwó lọ́wọ́ ẹlòmíì. Ìlànà tó ṣe pàtàkì tó sì tún wúlò wà nínú Bíbélì lórí ọ̀rọ̀ yìí: Ẹ kọ gbogbo ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú òwò náà sílẹ̀! Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jeremáyà ra ilẹ̀ kékeré kan, ó ṣe ìwé àdéhùn lórí ilẹ̀ ọ̀hún lójú àwọn ẹlẹ́rìí, ó sì fún ẹnì kan ní ẹ̀dà ìwé náà torí ọjọ́ iwájú. (Jeremáyà 32:9-12; tún wo Jẹ́nẹ́sísì 23:16-20.) Bá a bá kọ gbogbo ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú okòwò tó da àwa àtàwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ pọ̀ sórí ìwé, tá a sì buwọ́ lù ú níwájú àwọn ẹlẹ́rìí, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé a ò fọkàn tán ara wa o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe là ń dènà ohun tó lè dá awuyewuye sílẹ̀, tó lè fa ìjákulẹ̀ àti àjàtúká. Gbogbo àwọn Kristẹni tí wọ́n bá jọ dòwò pọ̀ gbọ́dọ̀ máa rántí pé àlàáfíà àti ìṣọ̀kan ìjọ ṣe pàtàkì ju okòwò èyíkéyìí lọ. *1 Kọ́ríńtì 6:1-8.

JẸ́ OLÓÒÓTỌ́ LÁÀÁRÍN ÀWỌN ÈÈYÀN AYÉ

15. Irú ojú wo ni Jèhófà fi ń wo okòwò tó bá ní èrú nínú, kí sì làwa Kristẹni máa ń ṣe lórí ọ̀rọ̀ tó gbòde kan yìí?

15 Jíjẹ́ olóòótọ́ ò wulẹ̀ mọ sínú ìjọ Kristẹni nìkan o. Pọ́ọ̀lù sọ pé: ‘A ń dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.’ (Hébérù 13:18) Tó bá dọ̀rọ̀ iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tó da àwa àtàwọn èèyàn ayé pọ̀, Ẹlẹ́dàá wa ò ní fẹ́ ká figbá kan bọ̀kan nínú. Nínú ìwé Òwe nìkan, ẹsẹ mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló sọ̀rọ̀ nípa ìdí tó fi yẹ ká máa lo òṣùwọ̀n tó pé pérépéré. (Òwe 11:1; 16:11; 20:10, 23) Nígbà àtijọ́, wọ́n sábà máa ń lo síkéèlì àti òṣùwọ̀n lẹ́nu iṣẹ́ ajé wọn láti fi wọn ọjà táwọn èèyàn bá rà àti owó tí wọ́n bá fi rà á. Àwọn oníṣòwò tó máa ń ṣe màgòmágó máa ń lo oríṣi síkéèlì méjì àti òṣùwọ̀n tí kò gún régé láti fi tan àwọn oníbàárà, kí wọ́n sì rẹ́  wọn jẹ. * Jèhófà kórìíra irú àṣà bẹ́ẹ̀! Ká bàa lè dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀, a kì í lọ́wọ́ sí okòwò èyíkéyìí tó bá ní èrú nínú.

16, 17. Àwọn ìwà màgòmágó wo ló kúnnú ayé òde òní, kí sì làwa Kristẹni tòótọ́ ti pinnu láti ṣe?

16 Kò yà wá lẹ́nu láti rí i pé ìwà màgòmágó ló kúnnú ayé tá a wà yìí torí pé Sátánì ni alákòóso ayé. A lè máa kojú ìdẹwò láti jẹ́ aláìṣòótọ́ lójoojúmọ́. Nígbà táwọn èèyàn bá ń wáṣẹ́, tí wọ́n sì kọ̀wé tí wọ́n fi máa ń ṣàkópọ̀ àwọn ẹ̀rí tí wọ́n ní láti fi hàn pé àwọn tóótun fún iṣẹ́, wọ́n sábà máa ń purọ́ sínú ìwé náà, wọ́n máa ń ṣe àbùmọ́, wọ́n máa ń ṣe ìwé ẹ̀rí àdàmọ̀dì láti fi hàn pé àwọn tóótun, wọ́n sì máa ń sọ pé àwọn ti ṣe àwọn ohun tí wọn ò ṣe rí. Nígbà táwọn èèyàn bá ń kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù tí wọ́n fẹ́ fi gbàṣẹ láti rìnrìn àjò lọ sí orílẹ̀-èdè míì, èyí tí wọ́n máa fi sanwó orí, ti ìbánigbófò àtàwọn fọ́ọ̀mù míì, wọn kì í sábà kọ òótọ́ ọ̀rọ̀ sínú àwọn fọ́ọ̀mù ọ̀hún torí kọ́wọ́ wọn lè tẹ ohun tí wọ́n fẹ́. Ọ̀pọ̀ ọmọ iléèwé ló máa ń jí ìwé wò nígbà ìdánwò tàbí nígbà tí wọ́n bá gbé àwọn iṣẹ́ míì fún wọn láti iléèwé, wọ́n lè lọ sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, kí wọ́n sì lọ da àwọn ohun tí wọ́n bá rí níbẹ̀ kọ, wọ́n á wá sọ pé àwọn làwọn kọ ọ́. Báwọn èèyàn bá sì fẹ́ nǹkan kan lọ́wọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba kan tó máa ń ṣe màgòmágó, wọ́n máa ń fún irú ẹni bẹ́ẹ̀ ní ẹ̀gúnjẹ kọ́wọ́ wọn lè tẹ ohun tí wọ́n fẹ́. A ò retí ohun tó dínkù sí èyí nínú ayé táwọn èèyàn ti jẹ́ ‘olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, tí wọ́n sì jẹ́ aláìní ìfẹ́ ohun rere’ yìí.—2 Tímótì 3:1-5.

17 Àwa Kristẹni tòótọ́ ti pinnu pé a ò ní lọ́wọ́ sírú àwọn àṣà wọ̀nyẹn. Ohun kan tó máa ń jẹ́ kó ṣòro láti jẹ́ olóòótọ́ ni pé, ńṣe ló máa ń dà bí i pé àwọn tó ń ṣe màgòmágó ló ń rọ́wọ́ mú, tí nǹkan sì ń ṣẹnuure fún jù lọ nínú ayé tá a wà yìí. (Sáàmù 73:1-8) Ní báyìí ná, àwọn Kristẹni lè máà  lówó lọ́wọ́ torí wọ́n fẹ́ jẹ́ olóòótọ́ “nínú ohun gbogbo.” Ṣó tó ká yááfì ohun tó tóyẹn torí pé a kò fẹ́ figbá kan bọ̀kan nínú? Bẹ́ẹ̀ ni, ó tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ! Àmọ́ kí nìdí tá a fi ní láti yááfì ohun tó tóyẹn? Àwọn àǹfààní wo ló wà nínu jíjẹ́ olóòótọ́?

ÀWỌN ÀǸFÀÀNÍ TÓ WÀ NÍNÚ JÍJẸ́ OLÓÒÓTỌ́

18. Àǹfààní wo ló wà nínú jíjẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ wá sólóòótọ́?

18 Kò sóhun tó dà bíi káwọn èèyàn mọ̀ọ̀yàn sí olóòótọ́, ẹni tó ṣeé fọkàn tán. (Wo àpótí náà  “Báwo Ni Mo Ṣe Jẹ́ Olóòótọ́ Tó?” lójú ìwé 167.) Ǹjẹ́ o mọ̀ pé kò sẹ́ni táwọn èèyàn ò lè mọ̀ sólóòótọ́? Kì í ṣe ẹ̀bùn àbínibí tó o ní, owó, ìrísí, ibi tí wọ́n ti tọ́ ẹ dàgbà tàbí nǹkan míì kan tápá ẹ ò lè ká ló máa pinnu bóyá wà á jẹ́ olóòótọ́. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ti kùnà láti lórúkọ rere. Orúkọ rere wá ṣọ̀wọ́n. (Míkà 7:2) Àwọn kan lè máa fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé o jẹ́ olóòótọ́, àmọ́ àwọn ẹlòmíì máa mọyì rẹ, wọ́n á bọ̀wọ̀ fún ẹ, wọ́n á sì fọkàn tán ẹ. Ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló sì ti rí i pé jíjẹ́ táwọn jẹ́ olóòótọ́ ti jẹ́ káwọn rówó gbọ́ bùkátà. Wọn ò dá wọn dúró lẹ́nu iṣẹ́ nígbà tí wọ́n ń dá àwọn òṣìṣẹ́ tó jẹ́ aláìṣòótọ́ dúró, àwọn míì lára wọn sì ti ríṣẹ́ síbi tí wọ́n ti ń wá òṣìṣẹ́ tó jólóòótọ́ lójú méjèèjì.

19. Ipa wo ni jíjẹ́ olóòótọ́ lè ní lórí ẹ̀rí ọkàn wa àti àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà?

19 Yálà o nírú àǹfààní yìí tàbí o ò ní i, wà á rí i pé àǹfààní tó wà nínú jíjẹ́ olóòótọ́ ò kéré rárá. Wàá lẹ́rìí ọkàn tó mọ́. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé a ní ẹ̀rí-ọkàn aláìlábòsí.” (Hébérù 13:18) Síwájú sí i, kedere ni Bàbá wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́, ẹni tó fẹ́ràn àwọn olóòótọ́ èèyàn ń rí akitiyan rẹ láti jólóòótọ́. (Ka Sáàmù 15:1, 2; Òwe 22:1) Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé, jíjẹ́ olóòótọ́ máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, kò tún sí àǹfààní míì tó jùyẹn lọ. Jẹ́ ká wá ṣàyẹ̀wò kókó ọ̀rọ̀ míì tó tan mọ́ jíjẹ́ olóòótọ́, ìyẹn ojú tí Jèhófà fi ń wo iṣẹ́ ṣíṣe.

^ ìpínrọ̀ 9 Nínu ìjọ, bí ẹnì kan bá ń mọ̀ọ́mọ̀ parọ́ láti fi ba ẹlòmíì lórúkọ jẹ́, ìyẹn lè mú káwọn alàgbà bá onítọ̀hùn wí.

^ ìpínrọ̀ 14 Ohun tó yẹ kó o ṣe bí èdèkòyédè bá wáyé láàárín ìwọ àtẹni tẹ́ ẹ jọ dòwò pọ̀ wà nínú Àfikún lójú ìwé 222 àti 223.

^ ìpínrọ̀ 15 Ọ̀tọ̀ ni síkéèlì tí wọ́n fi ń wọn ọjà kí wọ́n tó rà á, ọ̀tọ̀ sì lèyí tí wọ́n fi ń wọ̀n ọ́n tí wọ́n bá fẹ́ tà á, nítorí àtijèrè àbòsí. Wọ́n tún lè lo òṣùwọ̀n tó gùn lápá kan tàbí èyí tí apá ẹ̀ kan wúwo ju ìkejì lọ láti fi rẹ́ àwọn oníbàárà wọn jẹ.