Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà Máa Jẹ́ Kí Àwọn Ìpinnu Rẹ Yọrí Sí Rere

Jèhófà Máa Jẹ́ Kí Àwọn Ìpinnu Rẹ Yọrí Sí Rere

“Máa ní inú dídùn kíkọyọyọ nínú Jèhófà, òun yóò sì fún ọ ní àwọn ìbéèrè tí ó ti inú ọkàn-àyà rẹ wá.”​SM. 37:4.

ORIN: 89, 140

1. Kí ni ọ̀dọ́ kan gbọ́dọ̀ pinnu nípa ìgbésí ayé rẹ̀, àmọ́ kí nìdí tí kò fi yẹ kó bẹ̀rù? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

Ó DÁJÚ pé ẹ̀yin ọ̀dọ́ mọ̀ pé kéèyàn tó bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò kan, ó gbọ́dọ̀ pinnu ibi tó ń lọ. Ìgbésí ayé dà bí ìgbà téèyàn ń rìnrìn-àjò, ìgbà tó o sì wà lọ́dọ̀ọ́ ló yẹ kó o pinnu ibi tó o fẹ́ forí lé. Lóòótọ́, kì í rọrùn láti pinnu ohun téèyàn máa fayé rẹ̀ ṣe. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Heather sọ pé: “Ẹ̀rù máa ń bà mí tí n bá ń ronú ohun tí màá fayé mi ṣe.” Àmọ́, má jẹ́ kẹ́rù bà ẹ́. Jèhófà sọ fáwọn èèyàn rẹ̀ pé kí wọ́n má bẹ̀rù, ó wá fi kún un pé, ‘nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Dájúdájú, èmi yóò fi okun fún ọ. Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ti tòótọ́.’​—Aísá. 41:10.

2. Kí ló mú kó dá ẹ lójú pé Jèhófà fẹ́ kó o ṣèpinnu táá jẹ́ kó o láyọ̀?

2 Jèhófà ń rọ̀ ẹ́ pé kó o fọgbọ́n pinnu ohun tó máa jẹ́ kó o gbádùn ọjọ́ ọ̀la rẹ. (Oníw. 12:1; Mát. 6:20) Ó fẹ́ kó o láyọ̀. Àwọn ohun tó dá fún ìgbádùn rẹ fi hàn pé lóòótọ́ ló fẹ́ kó o láyọ̀. Tún ronú nípa bí Jèhófà ṣe ń fìfẹ́ bójú tó ẹ tó sì ń kọ́ ẹ bó o ṣe máa lo ìgbésí ayé rẹ. Jèhófà sọ fáwọn tó fọwọ́ rọ́ ìlànà rẹ̀ sẹ́yìn pé: “Ohun tí èmi kò sì ní inú dídùn sí ni ẹ yàn. . . . Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò yọ̀, ṣùgbọ́n ojú yóò ti ẹ̀yin. Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò fi ìdùnnú ké jáde nítorí ipò rere ọkàn-àyà.” (Aísá. 65:​12-14) Ó ṣe kedere pé inú Jèhófà máa ń dùn táwọn èèyàn rẹ̀ bá ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání.​—Òwe 27:11.

ÀWỌN ÌPINNU TÁÁ JẸ́ KÓ O LÁYỌ̀

3. Ìpinnu wo ni Jèhófà fẹ́ kó o ṣe?

3 Ìpinnu wo ni Jèhófà fẹ́ kó o ṣe? Táwa èèyàn bá máa láyọ̀, a gbọ́dọ̀ mọ Jèhófà ká sì jọ́sìn rẹ̀ tọkàntọkàn. (Sm. 128:1; Mát. 5:3) Èyí mú ká yàtọ̀ sáwọn ẹranko torí pé wọn ò mọ̀ ju kí wọ́n jẹun, kí wọ́n sì bímọ. Àmọ́ Jèhófà ò fẹ́ ká gbé ìgbé ayé wa bẹ́ẹ̀, ó fẹ́ ká ṣèpinnu táá mú ká láyọ̀, kí ìgbésí ayé wa sì nítumọ̀. Jèhófà Ẹlẹ́dàá wa jẹ́ “Ọlọ́run ìfẹ́” àti “Ọlọ́run aláyọ̀,” ìdí nìyẹn tó fi dá àwa èèyàn “ní àwòrán rẹ̀.” (2 Kọ́r. 13:11; 1 Tím. 1:11; Jẹ́n. 1:27) Wàá láyọ̀ tó o bá fara wé Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́. Ṣé ìwọ náà gbà pé òótọ́ lohun tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ”? (Ìṣe 20:35) Òótọ́ pọ́ńbélé lèyí. Torí náà, Jèhófà fẹ́ kó o ṣe àwọn ìpinnu táá fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ òun àtàwọn míì.​—Ka Mátíù 22:​36-39.

4, 5. Kí ló fún Jésù láyọ̀?

4 Jésù Kristi fi àpẹẹrẹ pípé lẹ́lẹ̀ fún ẹ̀yin ọ̀dọ́. Nígbà tó wà lọ́mọdé, ó dájú pé ó máa ń ṣeré, ó sì máa ń gbádùn ara rẹ̀. Ó ṣe tán Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé ‘ìgbà rírẹ́rìn-ín wà, ìgbà títọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri sì wà.’ (Oníw. 3:4) Jésù tún máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ sún mọ́ Jèhófà. Nígbà tí Jésù wà lọ́mọ ọdún méjìlá, ẹnu ya àwọn olùkọ́ tó wà nínú tẹ́ńpìlì torí “òye rẹ̀ àti àwọn ìdáhùn rẹ̀” nípa Ìwé Mímọ́.​—Lúùkù 2:​42, 46, 47.

5 Jésù láyọ̀ nígbèésí ayé rẹ̀. Kí ló fún un láyọ̀? Ohun tó fún Jésù láyọ̀ ni pé ó ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, lára ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kó ṣe ni pé kó “polongo ìhìn rere fún àwọn òtòṣì, . . . àti ìtúnríran fún àwọn afọ́jú.” (Lúùkù 4:18) Ó sì dájú pé ohun tó ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn. Sáàmù 40:8 sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára Jésù, ó ní: “Láti ṣe ìfẹ́ rẹ, ìwọ Ọlọ́run mi, ni mo ní inú dídùn sí.” Inú Jésù máa ń dùn láti kọ́ àwọn èèyàn nípa Baba rẹ̀ ọ̀run. (Ka Lúùkù 10:21.) Nígbà kan tí Jésù ń kọ́ obìnrin kan lẹ́kọ̀ọ́ nípa ìjọsìn tòótọ́, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Oúnjẹ mi ni kí n ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi àti láti parí iṣẹ́ rẹ̀.” (Jòh. 4:​31-34) Bí Jésù ṣe nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn èèyàn mú kó láyọ̀. Ìwọ náà máa láyọ̀ tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀.

6. Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé kó o fọ̀rọ̀ lọ àwọn ẹni tẹ̀mí nípa ohun tó o lè fayé rẹ ṣe?

6 Ọ̀pọ̀ Kristẹni ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà nígbà tí wọ́n wà lọ́dọ̀ọ́, ìyẹn sì ń mú kí wọ́n láyọ̀. O ò ṣe bá irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ohun tó o lè fayé rẹ ṣe? Bíbélì sọ pé: “Àwọn ìwéwèé máa ń já sí pàbó níbi tí kò bá ti sí ọ̀rọ̀ ìfinúkonú, ṣùgbọ́n àṣeparí ń bẹ nínú ògìdìgbó àwọn agbani-nímọ̀ràn.” (Òwe 15:22) Àwọn ẹni tẹ̀mí yìí máa jẹ́ kó o mọ̀ pé iṣẹ́ aláyọ̀ ni iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, á sì mú kó o túbọ̀ ní ọgbọ́n táá ṣe ẹ́ láǹfààní jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ. Kódà lẹ́yìn tí Jésù ti kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Jèhófà Baba rẹ̀ ọ̀run, ó tún gba ìmọ̀ kún ìmọ̀ nígbà tó ń ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé. Bí àpẹẹrẹ, òun fúnra rẹ̀ rí i pé ayọ̀ wà nínú bóun ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn nípa Ọlọ́run àti bóun ṣe jẹ́ olóòótọ́ lójú àdánwò. (Ka Aísáyà 50:4; Héb. 5:8; 12:2) Ẹ jẹ́ ká jíròrò mélòó kan lára àwọn iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tó máa fún ẹ láyọ̀.

ÌDÍ TÍ IṢẸ́ SÍSỌNI DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN FI Ń FÚNNI LÁYỌ̀

7. Kí ló ń mú kí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ gbádùn iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn?

7 Jésù sọ pé: ‘Ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa kọ́ wọn.’ (Mát. 28:​19, 20) Tó o bá pinnu pé iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn lo fẹ́ fayé rẹ ṣe, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ìpinnu tó dáa jù lo ṣe yẹn torí pé á múnú Ọlọ́run dùn. Àmọ́ o, bíi tàwọn iṣẹ́ míì, wàá nílò ìdálẹ́kọ̀ọ́ kó o tó lè di ọ̀jáfáfá. Bí àpẹẹrẹ, Arákùnrin Timothy tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́ sọ pé: “Ohun tó mú kí n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ni pé mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Nígbà tí mo kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, mi ò ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kankan, àmọ́ láàárín oṣù kan péré tí mo lọ sí ìpínlẹ̀ ìwàásù míì, mo ti ń darí ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kódà ọ̀kan lára àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ mi ti ń wá sípàdé. Nígbà tó yá, wọ́n pè mí sí Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì fún Àwọn Àpọ́n, * ẹ̀yìn ìyẹn ni wọ́n rán mi lọ sí ìpínlẹ̀ ìwàásù míì, mo sì ti ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́rin níbẹ̀. Mo gbádùn kí n máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, pàápàá bí mo ṣe ń rí i tí ẹ̀mí mímọ́ ń tún ayé wọn ṣe.”​—1 Tẹs. 2:19.

8. Kí làwọn ọ̀dọ́ kan ṣe kí wọ́n lè túbọ̀ máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn?

8 Àwọn ọ̀dọ́ kan ti kọ́ èdè míì. Bí àpẹẹrẹ, Jacob tó wá láti Amẹ́ríkà sọ pé: “Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méje, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ kíláàsì mi ló jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Vietnam. Ó wù mí gan-an pé kí n wàásù fún wọn, torí náà mo pinnu pé màá kọ́ èdè wọn. Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè náà, mo sábà máa ń fi Ilé Ìṣọ́ èdè òyìnbó wé ti èdè Vietnamese. Mo tún láwọn ọ̀rẹ́ ní ìjọ kan tí kò jìnnà sí wa tí wọ́n ń fi èdè Vietnamese ṣèpàdé. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún méjìdínlógún [18], mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Nígbà tó yá, mo lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì fún Àwọn Àpọ́n. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ yẹn ràn mí lọ́wọ́ gan-an torí pé èmi nìkan ni alàgbà nínú àwùjọ tó ń sọ èdè Vietnamese tí mo wà báyìí. Ẹnu máa ń ya àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Vietnam gan-an pé mo gbọ́ èdè wọn. Wọ́n máa ń gbà mí tọwọ́tẹsẹ̀, ọ̀pọ̀ wọn ló sì gbà kí n máa kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kódà, àwọn kan ti ṣèrìbọmi lára wọn.”​—Fi wé Ìṣe 2:​7, 8.

9. Báwo ni iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn ṣe máa ń mú kéèyàn túbọ̀ wúlò?

9 Iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn máa ń mú kéèyàn túbọ̀ wúlò gan-an. Bí àpẹẹrẹ, á mú kó o túbọ̀ di ọ̀jáfáfá lẹ́nu iṣẹ́ èyíkéyìí tó o bá ń ṣe, wàá mọ bó o ṣe lè báwọn èèyàn sọ̀rọ̀, á jẹ́ kó o nígboyà, wàá sì mọ bó o ṣe lè fọgbọ́n bá àwọn èèyàn lò. (Òwe 21:5; 2 Tím. 2:24) Àmọ́ ohun táá jẹ́ kó o túbọ̀ láyọ̀ nídìí iṣẹ́ náà ni pé wàá túbọ̀ lóye Ìwé Mímọ́, ìyẹn á sì mú kí ohun tó o gbà gbọ́ túbọ̀ dá ẹ lójú. Yàtọ̀ síyẹn, á mú kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.​—1 Kọ́r. 3:9.

10. Kí lo lè ṣe táá jẹ́ kó o láyọ̀ kódà tí iṣẹ́ rẹ kò bá fi bẹ́ẹ̀ méso jáde?

10 O lè gbádùn iṣẹ́ yìí kódà táwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ kò bá tiẹ̀ tó nǹkan. Ìdí ni pé iṣẹ́ ìwàásù kì í ṣe iṣẹ́ ẹnì kan, gbogbo ìjọ ló ń pawọ́ pọ̀ ṣe é. Ó lè jẹ́ arákùnrin tàbí arábìnrin kan ló kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ títí tónítọ̀hún fi ṣèrìbọmi, síbẹ̀ gbogbo wa là ń láyọ̀ torí pé àjọṣe gbogbo wa ni. Bí àpẹẹrẹ, ọdún mẹ́sàn-án gbáko ni Brandon fi ṣe aṣáájú-ọ̀nà ní ìpínlẹ̀ kan tí kò méso jáde. Ó sọ pé: “Mo gbádùn kí n máa wàásù torí pé ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe nìyẹn. Kò pẹ́ tí mo parí iléèwé ni mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Mo máa ń fún àwọn ọ̀dọ́ tó wà níjọ wa níṣìírí, inú mi sì máa ń dùn bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Lẹ́yìn tí mo lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì fún Àwọn Àpọ́n, wọ́n rán mi lọ sí ìpínlẹ̀ ìwàásù míì. Lóòótọ́ kò tíì sí èyíkéyìí lára àwọn tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ tó ṣèrìbọmi, àmọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ àwọn míì ti ṣèrìbọmi. Mo dúpẹ́ pé iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn ni mò ń fayé mi ṣe.”​—Oníw. 11:6.

ÀWỌN IṢẸ́ ÌSÌN MÍÌ TÍ ỌWỌ́ RẸ LÈ TẸ̀

11. Iṣé ìsìn míì wo lọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ti yọ̀ǹda ara wọn fún?

11 Àwọn apá míì wà tó o ti lè fayé rẹ sin Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló ń yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ ìkọ́lé torí ọ̀pọ̀ ìjọ ló ṣì nílò Gbọ̀ngàn Ìjọba. Tó o bá lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìkọ́lé, iṣẹ́ ìsìn mímọ́ tó ń bọlá fún Jèhófà lò ń ṣe, wàá sì láyọ̀. Bíi tàwọn iṣẹ́ ìsìn míì, á jẹ́ kó o láwọn ọ̀rẹ́ gidi. Iṣẹ́ ìsìn yìí tún máa ṣe ẹ́ láǹfààní, á jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀ràn ààbò, bó o ṣe lè túbọ̀ jáfáfá lẹ́nu iṣẹ́ èyíkéyìí tó o bá ń ṣe àti bó o ṣe lè máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ń múpò iwájú.

12. Báwo ni iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ṣe lè mú kọ́wọ́ rẹ tẹ àwọn iṣẹ́ ìsìn míì?

12 Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Kevin sọ pé: “Àtikékeré ló ti máa ń wù mí pé kí n fayé mi ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Nígbà ti mo pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19], mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Kí n lè gbọ́ bùkátà ara mi, mo máa ń bá arákùnrin kan tó jẹ́ kọ́lékọ́lé ṣiṣẹ́ fún ọjọ́ mélòó kan lọ́sẹ̀. Mo kọ́ béèyàn ṣe ń kan òrùlé, wíńdò àti ilẹ̀kùn. Nígbà tó yá, mo dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ń ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù bá, odindi ọdún méjì ni mo sì lò pẹ̀lú wọn, tá à ń tún àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àti ilé àwọn ará ṣe. Nígbà tí mo gbọ́ nípa iṣẹ́ ìkọ́lé tó ń lọ lórílẹ̀-èdè South Africa, mo sọ fún ètò Ọlọ́run pé mo fẹ́ dara pọ̀, wọ́n sì gbà pé kí n lọ. Tá a bá ti parí Gbọ̀ngàn Ìjọba kan láàárín ọ̀sẹ̀ mélòó kan, àá tún kọjá sí òmíì. Bí ọmọ ìyá làwa tá a jọ ń ṣiṣẹ́ ìkọ́lé náà ṣe rí. A jọ ń jẹ, a jọ ń mu, a jọ ń ṣiṣẹ́, a sì jọ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pọ̀. Mo tún gbádùn kí n máa bá àwọn ará ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ohun tí mo yàn látìgbà ọmọdé mi ti mú kí n láyọ̀ gan-an, kódà ayọ̀ náà kọjá sísọ.”

Àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún máa ń rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà (Wo ìpínrọ̀ 11 sí 13)

13. Báwo ni iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì ṣe ń fún àwọn ọ̀dọ́ láyọ̀?

13 Àwọn ọ̀dọ́ kan tó yàn láti fayé wọn sin Jèhófà ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Iṣẹ́ aláyọ̀ ni iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì torí pé iṣẹ́ yòówù kó o máa ṣe níbẹ̀, Jèhófà lò ń ṣe é fún. Bẹ́tẹ́lì làwọn oúnjẹ tẹ̀mí ti ń wá. Arákùnrin Dustin tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì sọ pé: “Ìgbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́sàn-án ni mo ti pinnu pé iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ni màá fayé mi ṣe, nígbà tí mo sì parí iléèwé, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Lẹ́yìn ọdún kan àtààbọ̀, wọ́n pè mí sí Bẹ́tẹ́lì. Wọ́n kọ́ mi béèyàn ṣe ń lo ẹ̀rọ ìtẹ̀wé, lẹ́yìn náà ni mo tún ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń ṣe ètò orí kọ̀ǹpútà. Inú mi máa ń dùn nígbàkigbà tí wọ́n bá ṣèfilọ̀ ní Bẹ́tẹ́lì nípa bí iṣẹ́ ìwàásù náà ṣe ń lọ jákèjádò ayé. Mo láyọ̀ gan-an pé mo wà ní Bẹ́tẹ́lì torí pé ohun tá à ń ṣe níbí ń mú káwọn èèyàn sún mọ́ Jèhófà.”

KÍ LO MÁA FI ỌJỌ́ Ọ̀LA RẸ ṢE?

14. Kí lo lè ṣe táá jẹ́ kọ́wọ́ rẹ tẹ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún?

14 Àwọn nǹkan wo lo lè ṣe báyìí táá jẹ́ kọ́wọ́ rẹ tẹ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, á dáa kí òtítọ́ túbọ̀ jinlẹ̀ lọ́kàn rẹ torí pé ìyẹn láá jẹ́ kó o lè fayé rẹ sin Jèhófà. Torí náà, máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, máa ronú lórí ohun tó ò ń kọ́, kó o sì máa ṣe ohun táá gbé àwọn míì ró nípàdé. Tó bá jẹ́ pé o ṣì wà níléèwé, lo àǹfààní yẹn láti kọ́ ara rẹ kó o lè túbọ̀ jáfáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, máa fọgbọ́n bi wọ́n ní ìbéèrè kó o lè mọ ohun tó wà lọ́kàn wọn, kó o sì rí i pé o tẹ́tí sí ìdáhùn wọn. Bákan náà, máa yọ̀ǹda ara rẹ tí ìjọ bá níṣẹ́. O lè yọ̀ǹda láti máa bójú tó Gbọ̀ngàn Ìjọba. Rántí pé àwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ tí wọ́n sì yọ̀ǹda ara wọn ni Jèhófà máa ń lò. (Ka Sáàmù 110:3; Ìṣe 6:​1-3) Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní kí Tímótì dara pọ̀ mọ́ òun nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì torí pé àwọn arákùnrin “ròyìn rẹ̀ dáadáa.”​—Ìṣe 16:​1-5.

15. Kí lo lè ṣe tó o bá fẹ́ yan iṣẹ́ táá jẹ́ kó o ráyè ṣe aṣáájú-ọ̀nà?

15 Àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún nílò owó tí wọ́n á fi gbọ́ bùkátà ara wọn. (Ìṣe 18:​2, 3) O ò ṣe wá iṣẹ́ kan kọ́ táá fún ẹ láyè, tí wàá sì lè fi gbọ́ bùkátà ara rẹ. Bó o ṣe ń ronú ohun tó o máa fayé rẹ ṣe, bá alábòójútó àyíká àtàwọn aṣáájú-ọ̀nà tó wà láyìíká yín sọ̀rọ̀. Ní kí wọ́n sọ àwọn iṣẹ́ tó o lè ṣe táá jẹ́ kó o lè ráyè ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Má sì gbàgbé ohun tí Bíbélì sọ pé, “yí àwọn iṣẹ́ rẹ lọ sọ́dọ̀ Jèhófà tìkára rẹ̀, a ó sì fìdí àwọn ìwéwèé rẹ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.”​—Òwe 16:3; 20:18.

16. Báwo ni iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ nígbèésí ayé rẹ?

16 Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà fẹ́ kí ayé rẹ ládùn kó lóyin. (Ka 1 Tímótì 6:​18, 19.) Iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún máa jẹ́ kó o láwọn ọ̀rẹ́ táwọn náà jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, ìyẹn á sì jẹ́ kó o túbọ̀ dàgbà dénú. Àwọn tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà nígbà ọ̀dọ́ rí i pé iṣẹ́ náà mú kí ìgbéyàwó àwọn lárinrin. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó fẹ́ra wọn jọ máa ń gbádùn iṣẹ́ náà lọ lẹ́yìn ìgbéyàwó wọn.​—Róòmù 16:​3, 4.

17, 18. Kí nìdí tí ohun tó wà lọ́kàn rẹ fi ṣe pàtàkì?

17 Ohun tó wà lọ́kàn rẹ ló máa pinnu bí wàá ṣe lo ayé rẹ. Sáàmù 20:4 sọ nípa Jèhófà pé: “Kí ó fi fún ọ ní ìbámu pẹ̀lú ọkàn-àyà rẹ, kí ó sì mú gbogbo ète rẹ ṣẹ.” Torí náà, ronú ohun tó o fẹ́ fayé rẹ ṣe. Fara balẹ̀ kíyè sí ohun tí Jèhófà ń ṣe lásìkò wa yìí, kó o sì ronú bíwọ náà ṣe lè kọ́wọ́ ti iṣẹ́ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, pinnu pé wàá ṣe ohun táá múnú rẹ̀ dùn.

18 Tó o bá fayé rẹ sin Jèhófà, ìgbésí ayé rẹ máa nítumọ̀ torí pé ohun tó ń múnú Ọlọ́run dùn lò ń ṣe. Bíbélì rọ̀ ẹ́ pé: “Máa ní inú dídùn kíkọyọyọ nínú Jèhófà, òun yóò sì fún ọ ní àwọn ìbéèrè tí ó ti inú ọkàn-àyà rẹ wá.”​—Sm. 37:4.

^ ìpínrọ̀ 7 Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run là ń ṣe dípò rẹ̀ báyìí.