Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì 6:1-15

  • Wọ́n yan ọkùnrin méje láti máa ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ (1-7)

  • Wọ́n fẹ̀sùn kan Sítéfánù pé ó sọ̀rọ̀ òdì (8-15)

6  Lákòókò yẹn, bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ṣe ń pọ̀ sí i, àwọn Júù tó ń sọ èdè Gíríìkì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàròyé nípa àwọn Júù tó ń sọ èdè Hébérù, nítorí pé àwọn tó ń pín nǹkan lójoojúmọ́ ń gbójú fo àwọn opó wọn.+  Ni àwọn Méjìlá náà bá pe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ẹ̀yìn jọ, wọ́n sì sọ pé: “Kò tọ́ kí a* fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílẹ̀ ká wá máa pín oúnjẹ sórí tábìlì.+  Nítorí náà, ẹ̀yin ará, ẹ yan àwọn ọkùnrin méje láàárín yín tí wọ́n lórúkọ rere,*+ tí wọ́n kún fún ẹ̀mí àti ọgbọ́n,+ kí a lè yàn wọ́n láti máa bójú tó ọ̀ràn tó pọn dandan yìí;+  àmọ́, àwa á gbájú mọ́ àdúrà àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ ọ̀rọ̀ náà.”  Ohun tí wọ́n sọ dùn mọ́ gbogbo àwọn èèyàn náà nínú, wọ́n sì yan Sítéfánù, ọkùnrin tó kún fún ìgbàgbọ́ àti ẹ̀mí mímọ́ pẹ̀lú Fílípì,+ Pírókórọ́sì, Níkánọ̀, Tímónì, Páménásì àti Níkóláósì tó jẹ́ aláwọ̀ṣe* ará Áńtíókù.  Wọ́n mú wọn wá sọ́dọ̀ àwọn àpọ́sítélì, lẹ́yìn tí àwọn àpọ́sítélì gbàdúrà, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn.+  Nítorí náà, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń gbilẹ̀ nìṣó,+ iye àwọn ọmọ ẹ̀yìn sì ń pọ̀ sí i gidigidi+ ní Jerúsálẹ́mù; ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àlùfáà sì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ́wọ́ gba* ìgbàgbọ́ náà.+  Nígbà náà, Sítéfánù, tó kún fún oore Ọlọ́run àti agbára, ń ṣe àwọn ohun ìyanu* ńlá àti àwọn iṣẹ́ àmì láàárín àwọn èèyàn.  Àmọ́ àwọn ọkùnrin kan látinú àwùjọ tí wọ́n ń pè ní Sínágọ́gù Àwọn Olómìnira wá, pẹ̀lú àwọn ará Kírénè àti àwọn ará Alẹkisáńdíríà àti lára àwọn tó wá láti Sìlíṣíà àti Éṣíà, wọ́n wá bá Sítéfánù fa ọ̀rọ̀. 10  Àmọ́ wọn ò lè dúró níwájú rẹ̀ nítorí ọgbọ́n àti ẹ̀mí tó fi ń sọ̀rọ̀.+ 11  Lẹ́yìn náà, wọ́n sún àwọn kan ní bòókẹ́lẹ́ pé kí wọ́n sọ pé: “A gbọ́ tó ń sọ ọ̀rọ̀ òdì sí Mósè àti Ọlọ́run.” 12  Wọ́n ru àwọn èèyàn àti àwọn àgbààgbà pẹ̀lú àwọn akọ̀wé òfin sókè, wọ́n wá bá a lójijì, wọ́n fipá gbá a mú, wọ́n sì mú un lọ sí Sàhẹ́ndìrìn. 13  Wọ́n mú àwọn ẹlẹ́rìí èké wá, tí wọ́n sọ pé: “Ọkùnrin yìí kò jáwọ́ nínú sísọ ọ̀rọ̀ òdì sí ibi mímọ́ yìí àti sí Òfin. 14  Bí àpẹẹrẹ, a gbọ́ tó sọ pé Jésù ará Násárẹ́tì máa wó ibí yìí palẹ̀, á sì yí àwọn àṣà tí Mósè fi lé wa lọ́wọ́ pa dà.” 15  Bí gbogbo àwọn tó jókòó ní Sàhẹ́ndìrìn ṣe tẹjú mọ́ ọn, wọ́n rí i pé ojú rẹ̀ dà bí ojú áńgẹ́lì.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Grk., “Kò dùn mọ́ wa nínú láti.”
Tàbí “àwọn ọkùnrin méje tí wọ́n sọ̀rọ̀ wọn dáadáa.”
Ìyẹn, ẹni tó gba ẹ̀sìn Júù. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “ṣègbọràn sí.”
Tàbí “àwọn àmì.”