Sí Àwọn Ará Róòmù 16:1-27

  • Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa Fébè tó jẹ́ òjíṣẹ́ (1, 2)

  • Wọ́n ń kí àwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù (3-16)

  • Ìkìlọ̀ pé kí wọ́n yẹra fún ìyapa (17-20)

  • Àwọn tó ń bá Pọ́ọ̀lù ṣiṣẹ́ kí àwọn ará (21-24)

  • A ti wá mọ àṣírí mímọ́ (25-27)

16  Mo fẹ́ kí ẹ mọ* Fébè arábìnrin wa, tó jẹ́ òjíṣẹ́ ní ìjọ tó wà ní Kẹnkíríà,+  kí ẹ lè tẹ́wọ́ gbà á nínú Olúwa lọ́nà tó yẹ àwọn ẹni mímọ́, kí ẹ sì ràn án lọ́wọ́ nínú ohun tó bá nílò,+ torí òun fúnra rẹ̀ ti gbèjà ọ̀pọ̀ èèyàn, títí kan èmi náà.  Ẹ bá mi kí Pírísíkà àti Ákúílà,+ àwọn tí a jọ ń ṣiṣẹ́ Kristi Jésù,  àwọn tí wọ́n fi ẹ̀mí* ara wọn wewu nítorí mi,*+ kì í ṣe èmi nìkan ló ń dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn, gbogbo ìjọ àwọn orílẹ̀-èdè pátá náà ń dúpẹ́.  Bákan náà, ẹ kí ìjọ tó wà ní ilé wọn.+ Ẹ kí Épénétù àyànfẹ́ mi, tó jẹ́ àkọ́so ní Éṣíà fún Kristi.  Ẹ kí Màríà, tó ti ṣiṣẹ́ kára fún yín.  Ẹ kí Andironíkọ́sì àti Júníásì, àwọn ìbátan mi,+ tí a jọ ṣẹ̀wọ̀n, àwọn tí àwọn àpọ́sítélì mọ̀ dáadáa, tí wọ́n sì ti pẹ́ jù mí lọ nínú Kristi.  Ẹ bá mi kí Áńpílíátù, àyànfẹ́ mi nínú Olúwa.  Ẹ kí Úbánọ́sì, tí a jọ ń ṣiṣẹ́ Kristi àti Sítákísì àyànfẹ́ mi. 10  Ẹ kí Ápélésì, ẹni ìtẹ́wọ́gbà nínú Kristi. Ẹ kí àwọn tó wà ní agbo ilé Àrísítóbúlù. 11  Ẹ kí Hẹ́ródíónì, ìbátan mi. Ẹ kí àwọn tó wà nínú Olúwa ní agbo ilé Nákísọ́sì. 12  Ẹ kí Tírífénà àti Tírífósà, àwọn obìnrin tó ń ṣiṣẹ́ kára nínú Olúwa. Ẹ kí Pésísì, àyànfẹ́ wa, torí ó ti ṣiṣẹ́ kára nínú Olúwa. 13  Ẹ kí Rúfọ́ọ̀sì àyànfẹ́ nínú Olúwa àti ìyá rẹ̀, tó tún jẹ́ ìyá mi. 14  Ẹ kí Asinkirítọ́sì, Fílégónì, Hẹ́mísì, Pátíróbásì, Hẹ́másì àti àwọn ará tó wà pẹ̀lú wọn. 15  Ẹ kí Fílólógọ́sì àti Júlíà, Néréúsì àti arábìnrin rẹ̀ àti Òlíńpásì pẹ̀lú gbogbo ẹni mímọ́ tó wà pẹ̀lú wọn. 16  Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín. Gbogbo àwọn ìjọ Kristi kí yín. 17  Ní báyìí, ẹ̀yin ará, mo rọ̀ yín pé kí ẹ máa ṣọ́ àwọn tó ń fa ìyapa àti ìkọ̀sẹ̀ tó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ẹ ti kọ́, kí ẹ sì yẹra fún wọn.+ 18  Nítorí irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ẹrú Olúwa wa Kristi, bí kò ṣe ti ohun tí wọ́n fẹ́ jẹ,* wọ́n máa ń fi ọ̀rọ̀ dídùn àti ọ̀rọ̀ ìpọ́nni fa ọkàn àwọn tí kò fura mọ́ra. 19  Gbogbo èèyàn ti gbọ́ nípa ìgbọràn yín, torí náà, inú mi ń dùn nítorí yín. Àmọ́ mo fẹ́ kí ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ti ohun rere, ṣùgbọ́n aláìmọ̀kan ní ti ohun búburú.+ 20  Ní tirẹ̀, Ọlọ́run tó ń fúnni ní àlàáfíà máa mú kí ẹsẹ̀ yín tẹ Sátánì rẹ́+ láìpẹ́. Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Olúwa wa Jésù wà pẹ̀lú yín. 21  Tímótì, tí a jọ ń ṣiṣẹ́, kí yín, Lúkíọ́sì àti Jásónì pẹ̀lú Sósípátérì, àwọn ìbátan mi+ náà kí yín. 22  Èmi, Tẹ́tíọ́sì, tí mo kọ lẹ́tà yìí, kí yín nínú Olúwa. 23  Gáyọ́sì,+ tó gba èmi àti gbogbo ìjọ lálejò, kí yín. Érásítù, ẹni tó ń bójú tó ìṣúra ìlú,* kí yín, Kúátọ́sì, arákùnrin rẹ̀ náà kí yín. 24 * —— 25  Ní báyìí, Ẹni tó lè fìdí yín múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìhìn rere tí mò ń kéde àti ìwàásù Jésù Kristi, gẹ́gẹ́ bí ìfihàn àṣírí mímọ́+ tí a ti pa mọ́ ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ látọjọ́ pípẹ́, 26  àmọ́ tí a ti fi hàn kedere* ní báyìí, ti a sì jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ ọ́n láàárín gbogbo orílẹ̀-èdè nípasẹ̀ àwọn Ìwé Mímọ́ alásọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Ọlọ́run ayérayé pa pé ká fi ìgbàgbọ́ gbé ìgbọràn ga; 27  Ọlọ́run, ẹnì kan ṣoṣo tí ó gbọ́n,+ ni kí ògo nípasẹ̀ Jésù Kristi jẹ́ tirẹ̀ títí láé. Àmín.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Mo dámọ̀ràn.”
Ní Grk., “ọrùn.”
Tàbí “ọkàn mi.”
Tàbí “ti ikùn wọn.”
Tàbí “ẹni tó jẹ́ ìríjú ìlú.”
Tàbí “tí a ṣí payá.”