Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì 18:1-28

  • Iṣẹ́ ìwàásù Pọ́ọ̀lù ní Kọ́ríńtì (1-17)

  • Ó pa dà sí Áńtíókù ti Síríà (18-22)

  • Pọ́ọ̀lù lọ sí Gálátíà àti Fíríjíà (23)

  • Àpólò tó jẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ rí ìrànlọ́wọ́ gbà (24-28)

18  Lẹ́yìn èyí, ó kúrò ní Áténì, ó sì wá sí Kọ́ríńtì.  Ó rí Júù kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ákúílà,+ ọmọ ìbílẹ̀ Pọ́ńtù, tí kò tíì pẹ́ tí òun àti Pírísílà ìyàwó rẹ̀ dé láti Ítálì, torí Kíláúdíù ti pàṣẹ pé kí àwọn Júù kúrò ní Róòmù. Nítorí náà, ó lọ bá wọn,  torí pé iṣẹ́ kan náà ni wọ́n jọ ń ṣe, ó dúró sí ilé wọn, ó sì ń bá wọn ṣiṣẹ́,+ torí iṣẹ́ àgọ́ pípa ni wọ́n ń ṣe.  Ó máa ń sọ àsọyé* nínú sínágọ́gù+ ní gbogbo sábáàtì,+ ó sì máa ń yí àwọn Júù àti Gíríìkì lérò pa dà.  Nígbà tí Sílà+ àti Tímótì+ wá láti Makedóníà, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú kí ọwọ́ Pọ́ọ̀lù dí gan-an, ó ń jẹ́rìí fún àwọn Júù láti fi ẹ̀rí hàn pé Jésù ni Kristi náà.+  Àmọ́ nígbà tí wọn ò yéé ṣàtakò sí i, tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ láìdáa, ó gbọn ẹ̀wù rẹ̀,+ ó sì sọ fún wọn pé: “Kí ẹ̀jẹ̀ yín wà lórí ẹ̀yin fúnra yín.+ Ọrùn mi mọ́.+ Láti ìsinsìnyí lọ, màá lọ máa bá àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè.”+  Torí náà, ó kúrò níbẹ̀,* ó sì lọ sí ilé ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Títíọ́sì Jọ́sítù, olùjọ́sìn Ọlọ́run, tí ilé rẹ̀ wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ sínágọ́gù.  Àmọ́ Kírípọ́sì,+ alága sínágọ́gù, di onígbàgbọ́ nínú Olúwa, òun pẹ̀lú gbogbo agbo ilé rẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn ará Kọ́ríńtì tí wọ́n gbọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í gbà gbọ́, wọ́n sì ṣèrìbọmi.  Síwájú sí i, Olúwa sọ fún Pọ́ọ̀lù ní òru nínú ìran pé: “Má bẹ̀rù, máa sọ̀rọ̀ nìṣó, má sì dákẹ́, 10  torí mo wà pẹ̀lú rẹ,+ ẹnikẹ́ni ò ní kọ lù ọ́ láti ṣe ọ́ léṣe; nítorí mo ní ọ̀pọ̀ èèyàn ní ìlú yìí.” 11  Torí náà, ó lo ọdún kan àti oṣù mẹ́fà níbẹ̀, ó ń kọ́ni ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láàárín wọn. 12  Lásìkò tí Gálíò jẹ́ alákòóso ìbílẹ̀* Ákáyà, àwọn Júù gbìmọ̀ pọ̀, wọ́n dìde sí Pọ́ọ̀lù, wọ́n sì mú un lọ síwájú ìjókòó ìdájọ́, 13  wọ́n sọ pé: “Ọkùnrin yìí ń yí àwọn èèyàn lérò pa dà láti máa sin Ọlọ́run lọ́nà tó ta ko òfin.” 14  Àmọ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀, Gálíò sọ fún àwọn Júù pé: “Ẹ̀yin Júù, tó bá jẹ́ lórí ìwà àìtọ́ tàbí ìwà ọ̀daràn ni, ó máa bọ́gbọ́n mu pé kí n fi sùúrù gbọ́ yín. 15  Ṣùgbọ́n tó bá jẹ́ àríyànjiyàn lórí ọ̀rọ̀ àti àwọn orúkọ àti òfin yín ni,+ ẹ̀yin fúnra yín ni kí ẹ lọ bójú tó o. Mi ò fẹ́ ṣe ìdájọ́ lórí àwọn nǹkan yìí.” 16  Ló bá lé wọn kúrò níbi ìjókòó ìdájọ́. 17  Nítorí náà, gbogbo wọn gbá Sótínésì,+ alága sínágọ́gù mú, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í lù ú níwájú ìjókòó ìdájọ́. Àmọ́ Gálíò kò dá sí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ rárá. 18  Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù lo ọjọ́ mélòó kan sí i níbẹ̀, ó dágbére fún àwọn ará, ó wọkọ̀ òkun lọ sí Síríà, Pírísílà àti Ákúílà sì bá a lọ. Ó gé irun orí rẹ̀ mọ́lẹ̀ ní Kẹnkíríà,+ torí ó ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ kan. 19  Nígbà tí wọ́n dé Éfésù, ó fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ̀; àmọ́ ó wọ sínágọ́gù, ó sì ń bá àwọn Júù fèròwérò.+ 20  Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń sọ fún un pé kó dúró sí i lọ́dọ̀ àwọn, kò gbà, 21  àmọ́ ó dágbére, ó sì sọ fún wọn pé: “Màá tún pa dà sọ́dọ̀ yín, tí Jèhófà* bá fẹ́.” Ó wá wọkọ̀ òkun láti Éfésù, 22  ó sì wá sí Kesaríà. Ó jáde lọ,* ó sì kí ìjọ, lẹ́yìn náà ó lọ sí Áńtíókù.+ 23  Lẹ́yìn tó lo àkókò díẹ̀ níbẹ̀, ó kúrò, ó sì ń lọ láti ibì kan sí ibòmíì ní ilẹ̀ Gálátíà àti Fíríjíà,+ ó ń fún gbogbo ọmọ ẹ̀yìn lókun.+ 24  Júù kan wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Àpólò,+ ọmọ ìbílẹ̀ Alẹkisáńdíríà, ó dé sí Éfésù; ọkùnrin sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó mọ Ìwé Mímọ́ dunjú ni. 25  Ọkùnrin yìí ti gba ẹ̀kọ́* nípa ọ̀nà Jèhófà,* iná ẹ̀mí sì ń jó nínú rẹ̀, ó ń sọ̀rọ̀, ó sì ń kọ́ni ní àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ Jésù lọ́nà tó péye, àmọ́ ìrìbọmi Jòhánù nìkan ló mọ̀. 26  Ó bẹ̀rẹ̀ sí í fìgboyà sọ̀rọ̀ nínú sínágọ́gù, nígbà tí Pírísílà àti Ákúílà+ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n mú un wọ àwùjọ wọn, wọ́n sì ṣàlàyé ọ̀nà Ọlọ́run fún un lọ́nà tó túbọ̀ péye. 27  Bákan náà, torí pé ó fẹ́ kọjá sí Ákáyà, àwọn ará kọ̀wé sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn, wọ́n rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n gbà á tọwọ́tẹsẹ̀. Torí náà, nígbà tó débẹ̀, ó ṣèrànwọ́ púpọ̀ fún àwọn tó ti di onígbàgbọ́ nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run; 28  ó ń sọ̀rọ̀ ní gbangba pẹ̀lú ìtara, bó ṣe ń fi ẹ̀rí hàn kedere pé àwọn Júù kò tọ̀nà, tó sì ń fi hàn nínú Ìwé Mímọ́ pé Jésù ni Kristi náà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Ó máa ń bá wọn fèròwérò.”
Ìyẹn, sínágọ́gù.
Gómìnà ìjọba Róòmù tó ń ṣàkóso ìpínlẹ̀. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ó jọ pé, sí Jerúsálẹ́mù.
Tàbí “ti kẹ́kọ̀ọ́ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹnu.”