Ìwé Kìíní sí Àwọn Ará Tẹsalóníkà 2:1-20

  • Iṣẹ́ òjíṣẹ́ Pọ́ọ̀lù ní Tẹsalóníkà (1-12)

  • Àwọn ará Tẹsalóníkà gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run (13-16)

  • Àárò àwọn ará Tẹsalóníkà ń sọ Pọ́ọ̀lù (17-20)

2  Ẹ̀yin ará, ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ dájú pé ìbẹ̀wò tí a ṣe sọ́dọ̀ yín kò já sí asán.+  Nítorí bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti kọ́kọ́ jìyà, tí wọ́n sì hùwà àfojúdi sí wa ní ìlú Fílípì,+ bí ẹ̀yin náà ṣe mọ̀, Ọlọ́run wa mú kí a mọ́kàn le* kí a lè sọ ìhìn rere Ọlọ́run+ fún yín lójú ọ̀pọ̀ àtakò.*  Nítorí ọ̀rọ̀ ìyànjú wa kò wá látinú ìṣìnà tàbí látinú ìwà àìmọ́ tàbí pẹ̀lú ẹ̀tàn,  àmọ́ gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe tẹ́wọ́ gbà wá pé kí ìhìn rere wà ní ìkáwọ́ wa, bẹ́ẹ̀ ni à ń sọ̀rọ̀, kì í ṣe torí ká lè wu èèyàn, àmọ́ torí ká lè wu Ọlọ́run, ẹni tó ń yẹ ọkàn wa wò.+  Kódà, ẹ mọ̀ pé kò sí ìgbà kankan tí a sọ ọ̀rọ̀ ìpọ́nni tàbí tí a ṣe ojú ayé nítorí ojúkòkòrò;+ Ọlọ́run ni ẹlẹ́rìí!  Bẹ́ẹ̀ ni a kò máa wá ògo lọ́dọ̀ èèyàn, ì báà jẹ́ lọ́dọ̀ yín tàbí lọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíì, bó tiẹ̀ jẹ́ pé gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Kristi, àwa fúnra wa lè sọ ara wa di ẹrù tó wúwo sí yín lọ́rùn.+  Kàkà bẹ́ẹ̀, a di ẹni jẹ́jẹ́ láàárín yín, bí ìgbà tí abiyamọ ń tọ́jú* àwọn ọmọ rẹ̀.  Torí náà, bí a ṣe ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ sí yín, a ti pinnu* pé kì í ṣe ìhìn rere Ọlọ́run nìkan la máa fún yín, a tún máa fún yín ní ara* wa,+ torí ẹ ti di ẹni ọ̀wọ́n sí wa.+  Ẹ̀yin ará, ó dájú pé ẹ rántí òpò* àti làálàá wa. A ṣiṣẹ́ tọ̀sántòru ká má bàa di ẹrù wọ ìkankan nínú yín lọ́rùn,+ nígbà tí a wàásù ìhìn rere Ọlọ́run fún yín. 10  Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí, Ọlọ́run náà sì jẹ́ ẹlẹ́rìí, bí a ṣe jẹ́ adúróṣinṣin àti olódodo àti aláìlẹ́bi sí ẹ̀yin onígbàgbọ́. 11  Ẹ mọ̀ dáadáa pé ṣe là ń gbà yín níyànjú, tí à ń tù yín nínú, tí a sì ń jẹ́rìí fún ẹnì kọ̀ọ̀kan yín,+ bí bàbá+ ṣe máa ń ṣe fún àwọn ọmọ rẹ̀, 12  kí ẹ lè máa rìn lọ́nà tó yẹ Ọlọ́run,+ ẹni tó ń pè yín sí Ìjọba+ àti ògo rẹ̀.+ 13  Ní tòótọ́, ìdí nìyẹn tí àwa náà fi ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo,+ torí nígbà tí ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tí ẹ gbọ́ lọ́dọ̀ wa, ẹ tẹ́wọ́ gbà á, kì í ṣe bí ọ̀rọ̀ èèyàn, àmọ́ gẹ́gẹ́ bó ṣe jẹ́ lóòótọ́, bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tó tún wà lẹ́nu iṣẹ́ nínú ẹ̀yin onígbàgbọ́. 14  Ẹ̀yin ará ń fara wé àwọn ìjọ Ọlọ́run tó wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù ní Jùdíà, nítorí àwọn ará ìlú yín ń fìyà jẹ yín  + bí àwọn Júù ṣe ń fìyà jẹ àwọn náà, 15  kódà wọ́n pa Jésù Olúwa+ àti àwọn wòlíì, wọ́n sì ṣe inúnibíni sí wa.+ Bákan náà, wọn ò ṣe ohun tó wu Ọlọ́run, wọn ò sì ní ire àwọn èèyàn lọ́kàn, 16  bí wọ́n ṣe ń gbìyànjú láti dí wa lọ́wọ́ ká má lè bá àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè sọ̀rọ̀, kí wọ́n sì rí ìgbàlà.+ Ọ̀nà yìí ni wọ́n gbà ń mú kí ẹ̀ṣẹ̀ wọn pọ̀ sí i. Àmọ́ ìrunú Ọlọ́run ti dé tán sórí wọn.+ 17  Ẹ̀yin ará, nígbà tí wọ́n yà wá kúrò lọ́dọ̀ yín* fún àkókò kúkúrú (nínú ara, tí kì í ṣe nínú ọkàn wa), àárò yín tó ń sọ wá gan-an mú ká sa gbogbo ipá wa láti rí yín lójúkojú.* 18  Torí náà, a fẹ́ wá sọ́dọ̀ yín, bẹ́ẹ̀ ni, èmi Pọ́ọ̀lù, gbìyànjú láti wá, kódà kì í ṣe ẹ̀ẹ̀kan, ẹ̀ẹ̀mejì ni; àmọ́ Sátánì dí wa lọ́nà. 19  Nítorí kí ni ìrètí tàbí ìdùnnú tàbí adé ayọ̀ wa níwájú Jésù Olúwa wa nígbà tó bá wà níhìn-ín? Ní tòótọ́, ṣé kì í ṣe ẹ̀yin ni?+ 20  Dájúdájú, ẹ̀yin ni ògo àti ìdùnnú wa.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “nígboyà.”
Tàbí kó jẹ́, “nínú ọ̀pọ̀ ìjàkadì.”
Tàbí “ṣìkẹ́.”
Ní Grk., “ó dùn mọ́ wa pé.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “iṣẹ́ àṣekára.”
Tàbí “gbà yín kúrò lọ́wọ́ wa.”
Ní Grk., “rí ojú yín.”