Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà Ń Ṣọ́ Wa fún Ire Wa

Jèhófà Ń Ṣọ́ Wa fún Ire Wa

Jèhófà Ń Ṣọ́ Wa fún Ire Wa

“Ojú [Jèhófà] ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.”—2 KÍRÓ. 16:9.

1. Kí nìdí tí Jèhófà fi ń ṣàyẹ̀wò wa?

 JÈHÓFÀ ni Baba wa tó jẹ́ Bàbá pípé. Ó mọ̀ wá tinú-tòde débi pé ó mọ “ìtẹ̀sí ìrònú” wa. (1 Kíró. 28:9) Ṣùgbọ́n kì í ṣe pé ó ń ṣàyẹ̀wò wa bí ẹni tó ń ṣọ́ wa lọ́wọ́-lẹ́sẹ̀ kó lè ká ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ wa lọ́wọ́. (Sm. 11:4; 130:3) Ńṣe ló fẹ́ máa dáàbò bò wá tìfẹ́tìfẹ́ lọ́wọ́ ohunkóhun tó bá lè ba àjọṣe àwa àtòun jẹ́ tàbí ohun tó bá lè gba ìyè àìnípẹ̀kun lọ́wọ́ wa.—Sm. 25:8-10, 12, 13.

2. Àwọn wo ni Jèhófà ń fi okun rẹ̀ ràn lọ́wọ́?

2 Agbára Jèhófà kò lópin, gbogbo wa pátá ló sì ń rí. Nítorí náà, kò sígbà táwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin bá ké pè é tí kì í lè ràn wọ́n lọ́wọ́, ó sì ṣe tán láti tì wọ́n lẹ́yìn nígbà ìṣòro. Ìwé 2 Kíróníkà 16:9 sọ pé: “Ojú [Jèhófà] ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.” Ṣàkíyèsí pé àwọn tó ń fi ọkàn mímọ́, tó pé pérépéré, tí kò ní àbòsí, sin Jèhófà ló máa ń fi okun tàbí agbára rẹ̀ ràn lọ́wọ́. Kì í ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ fún àwọn tó bá jẹ́ ẹlẹ̀tàn tàbí alágàbàgebè.—Jóṣ. 7:1, 20, 21, 25; Òwe 1:23-33.

Bá Ọlọ́run Rìn

3, 4. Báwo la ṣe lè ‘bá Ọlọ́run rìn,’ àwọn àpẹẹrẹ wo látinú Bíbélì ló sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà yé wa kedere?

3 Ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé Ẹlẹ́dàá ayé àtọ̀run tóbi lọ́ba ju ẹni tó máa gbà kọ́mọ èèyàn lásán-làsàn máa bá òun rìn, kódà lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ pàápàá. Síbẹ̀ ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe gan-an nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, láyé ìgbàanì, Énọ́kù àti Nóà ‘bá Ọlọ́run rìn.’ (Jẹ́n. 5:24; 6:9) Mósè “ń bá a lọ ní fífẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin bí ẹni tí ń rí Ẹni tí a kò lè rí.” (Héb. 11:27) Dáfídì Ọba náà bá Baba rẹ̀ ọ̀run rìn tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀. Ó ní: “Nítorí pé [Jèhófà] wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, a kì yóò mú kí n ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.”—Sm. 16:8.

4 A mọ̀ pé a ò lè rí ọwọ́ Jèhófà gan-an dì mú ká wá jọ máa rìn lọ. Ṣùgbọ́n a lè di ọwọ́ rẹ̀ mú lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Ásáfù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ ìwé Sáàmù sọ pé: “Èmi wà pẹ̀lú rẹ nígbà gbogbo; ìwọ ti di ọwọ́ ọ̀tún mi mú. Ìmọ̀ràn rẹ ni ìwọ yóò fi ṣamọ̀nà mi.” (Sm. 73:23, 24) Èyí fi hàn pé, bá a ṣe lè bá Jèhófà rìn ni pé ká máa tẹ̀ lé gbogbo ìmọ̀ràn rẹ̀, ìyẹn àwọn ìtọ́ni tá à ń gbà látinú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti nípasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.”—Mát. 24:45; 2 Tím. 3:16.

5. Báwo ni Jèhófà ṣe ń ṣọ́ àwọn adúróṣinṣin, irú ẹni wo ló sì yẹ ká ka Jèhófà sí?

5 Nítorí pé Jèhófà fẹ́ràn àwọn tó ń bá a rìn gan-an, ó máa ń ṣọ́ wọn bíi bàbá onífẹ̀ẹ́, ó ń bójú tó wọn, ó ń dàábò bò wọ́n, ó sì ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Ọlọ́run sọ pé: “Èmi yóò mú kí o ní ìjìnlẹ̀ òye, èmi yóò sì fún ọ ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà tí ìwọ yóò máa tọ̀. Dájúdájú, èmi yóò fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.” (Sm. 32:8) O lè bi ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ mò ń fojú inú rí ara mi pé mò ń bá Jèhófà rìn, tí mo di ọwọ́ rẹ̀ mú tá a wá jọ ń rìn lọ, tí mò ń tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó ń bá mi sọ, tí mo sì mọ̀ pé ó ń wò mí tìfẹ́tìfẹ́? Ǹjẹ́ mímọ̀ tí mo mọ̀ pé mò ń bá Ọlọ́run rìn ń mú kí n máa ṣọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi, ìwà mi àtohun tí mò ń rò lọ́kàn? Tí mo bá sì ṣẹ̀, ǹjẹ́ mò ń fi sọ́kàn pé Jèhófà kì í ṣe Ọlọ́run aláìláàánú tó ń hanni léèmọ̀, bí kò ṣe Baba onífẹ̀ẹ́ tó ń ṣíjú àánú wo ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà?’—Sm. 51:17.

6. Kí ni Jèhófà lè ṣe táwọn òbí wa ò lè ṣe?

6 Nígbà míì, Jèhófà lè nawọ́ ìrànwọ́ sí wa ká tiẹ̀ tó dáwọ́ lé ohun tó máa yọrí sí ẹ̀ṣẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó lè kíyè sí i pé ọkàn wa tó ń ṣe àdàkàdekè ti bẹ̀rẹ̀ sí í fà sáwọn ohun tí kò tọ́. (Jer. 17:9) Nírú ìgbà bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa ń dìde ìrànwọ́ ṣáájú àwọn òbí wa pàápàá, nítorí “ojú rẹ̀ títàn yanran” máa ń rí ìsàlẹ̀ ikùn wa lọ́hùn-ún, ó sì lè ṣàyẹ̀wò ohun tá à ń rò. (Sm. 11:4; 139:4; Jer. 17:10) Wo ohun tí Ọlọ́run ṣe nípa ohun kan tó ṣẹlẹ̀ sí Bárúkù tó jẹ́ akọ̀wé àti ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ fún wòlíì Jeremáyà.

Jèhófà Ṣe Baba fún Bárúkù

7, 8. (a) Ta ni Bárúkù, èròkérò wo ló fẹ́ ta gbòǹgbò lọ́kàn rẹ̀? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe bá Bárúkù sọ̀rọ̀ bíi Baba sí ọmọ?

7 Bárúkù jẹ́ akọ̀wé tó mọṣẹ́, ó sì fi gbogbo ọkàn bá Jeremáyà ṣe iṣẹ́ kan tó pa dà wá le gan-an nígbà tó yá, ìyẹn iṣẹ́ pípolongo ìdájọ́ Jèhófà lórí Júdà. (Jer. 1:18, 19) Láàárín ìgbà kan, Bárúkù, tó ṣeé ṣe kó wá láti ìdílé ọlọ́lá, bẹ̀rẹ̀ sí í wá “àwọn ohun ńláńlá” fún ara rẹ̀. Bóyá ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í ro bó ṣe máa di ọlọ́rọ̀ àti èèyàn ńlá. Lọ́rọ̀ kan ṣá, Jèhófà rí i pé èròkérò yìí ti fẹ́ ta gbòǹgbò lọ́kàn Bárúkù. Ni Jèhófà bá gbẹnu Jeremáyà bá Bárúkù sọ̀rọ̀, ó ní: “‘Ìwọ wí pé: ‘Mo gbé wàyí, nítorí pé Jèhófà ti fi ẹ̀dùn-ọkàn kún ìrora mi! Agara ti dá mi nítorí ìmí ẹ̀dùn mi, èmi kò sì rí ibi ìsinmi kankan.’” Ọlọ́run wá sọ fún un pé: “Ìwọ ń wá àwọn ohun ńláńlá fún ara rẹ. Má ṣe wá wọn mọ́.”—Jer. 45:1-5.

8 Lóòótọ́ Jèhófà sọ ojú abẹ níkòó fún Bárúkù, àmọ́ kò fìbínú bá a sọ̀rọ̀. Ọ̀rọ̀ bàbá tó nífẹ̀ẹ́ ọmọ rẹ̀ ló bá a sọ. Láìsí àní-àní, Ọlọ́run ti rí i pé kì í ṣe ọkàn burúkú ló mú kí Bárúkù nírú èrò bẹ́ẹ̀. Jèhófà tún mọ̀ pé Jerúsálẹ́mù àti Júdà máa tó pa run, kò sì fẹ́ kí ohunkóhun mú Bárúkù kọsẹ̀ lásìkò tó ṣe kókó yẹn. Ọlọ́run wá sọ ohun tó lè mú kí Bárúkù ìránṣẹ́ rẹ̀ tún inú rò. Ó rán an létí pé òun máa tó “mú ìyọnu àjálù wá sórí gbogbo ẹran ara,” pé tí Bárúkù bá hùwà ọlọ́gbọ́n, ẹ̀mí rẹ̀ ò ní bá àjálù náà lọ. (Jer. 45:5) Ńṣe ló dà bí ìgbà tí Ọlọ́run ń sọ fún un pé: ‘Bárúkù, ronú ẹ wò dáadáa. Rántí pé Júdà àti Jerúsálẹ́mù máa tó pa run. Máa bá ìṣòtítọ́ rẹ nìṣó, kó o má bàa pàdánù ẹ̀mí ẹ! Màá rí i pé mo dáàbò bò ẹ́.’ Ó hàn gbangba pé Bárúkù gbọ́rọ̀ sí Jèhófà lẹ́nu, torí ó ṣe àyípadà, ó sì la ìparun Jerúsálẹ́mù tó wáyé lọ́dún mẹ́tàdínlógún lẹ́yìn náà já.

9. Kí ni ìdáhùn rẹ sí àwọn ìbéèrè inú ìpínrọ̀ yìí?

9 Bó o ṣe ń ronú lórí ìtàn Bárúkù yìí, wo àwọn ìbéèrè àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó tẹ̀ lé e yìí: Kí ni ọwọ́ tí Jèhófà fi mú Bárúkù fi hàn nípa Jèhófà àti irú ọwọ́ tó fi ń mú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀? (Ka Hébérù 12:9.) Níwọ̀n bí àwa náà ti ń gbé ní àkókò lílekoko báyìí, ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run fún Bárúkù àti nínú ohun tí Bárúkù ṣe nípa ìmọ̀ràn yẹn? (Ka Lúùkù 21:34-36.) Báwo làwọn alàgbà ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jeremáyà, kí wọ́n gbé ẹ̀mí aájò tí Jèhófà ní sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ yọ?—Ka Gálátíà 6:1.

Ọmọ Ọlọ́run Gbé Ìfẹ́ Baba Rẹ̀ Yọ

10. Irú agbára wo ni Ọlọ́run gbé wọ Jésù tó fi lè ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Orí ìjọ Kristẹni?

10 Kí Kristi tó wá sáyé, àwọn wòlíì àtàwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà míì ni Jèhófà ń lò láti fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sáwọn èèyàn rẹ̀. Lóde òní, ẹni tó ń gbé ìfẹ́ rẹ̀ yọ lọ́nà tó ta yọ ti ẹnikẹ́ni, ni Jésù Kristi tó jẹ́ Orí ìjọ Kristẹni. (Éfé. 1:22, 23) Ìdí nìyẹn tí ìwé Ìṣípayá fi fi Jésù wé ọ̀dọ́ àgùntàn tó ní “ojú méje, àwọn ojú tí wọ́n túmọ̀ sí ẹ̀mí méje ti Ọlọ́run tí a ti rán jáde sí gbogbo ilẹ̀ ayé.” (Ìṣí. 5:6) Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára ẹ̀mí mímọ́ wọ Jésù, Jésù ní ìfòyemọ̀ tó pé pérépéré. Ó ń rí ohun tá a jẹ́ nínú, kò sì sí ohun tó fara sin fún un.

11. Ipa wo ni Kristi ń kó, báwo sì ni ìṣe rẹ̀ sí wa ṣe ń gbé ìfẹ́ Baba rẹ̀ yọ?

11 Àmọ́ ṣá, ìṣe Jésù kò yàtọ̀ sí ti Jèhófà. Kì í ṣe bí ọlọ́pàá tó ń ṣọ́ wa lọ́wọ́-lẹ́sẹ̀ látọ̀run. Ojú Baba onífẹ̀ẹ́ ló fi ń wò wá. Ọ̀kan lára orúkọ oyè Jésù, ìyẹn “Baba Ayérayé,” ń mú wa rántí ipa tí yóò kó nínú bí gbogbo àwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ yóò ṣe rí ìyè àìnípẹ̀kun. (Aísá. 9:6) Yàtọ̀ síyẹn, nítorí pé Kristi ni Orí ìjọ Kristẹni, ó lè mú káwọn Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn, tí wọ́n lẹ́mìí ìrannilọ́wọ́, pàápàá àwọn alàgbà, pèsè ìtùnú àti ìmọ̀ràn fáwọn tó nílò rẹ̀.—1 Tẹs. 5:14; 2 Tím. 4:1, 2.

12. (a) Kí làwọn ìwé tí Jésù kọ sí ìjọ méje tó wà ní Éṣíà Kékeré fi hàn nípa Jésù? (b) Báwo làwọn alàgbà ṣe ń fi ọwọ́ tí Kristi fi mú ìjọ hàn?

12 Ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí Kristi ní sí ìjọ hàn nínú àwọn ìwé tó ní kí Jòhánù kọ sáwọn alàgbà ìjọ méje tó wà ní àgbègbè Éṣíà Kékeré. (Ìṣí. 2:1–3:22) Jésù fi hàn nínú àwọn ìwé náà pé òun mọ ohun tó ń lọ nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan àti ohun tó ń jẹ àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun lọ́kàn. Irú ọwọ́ tí Jésù fi mú ìjọ lóde òní náà nìyẹn, ó tiẹ̀ tún jù bẹ́ẹ̀ lọ pàápàá, nítorí pé “Ọjọ́ Olúwa” la wà yìí, nígbà tí ìran inú ìwé Ìṣípayá ń ní ìmúṣẹ. a (Ìṣí. 1:10) Ipasẹ̀ àwọn alàgbà tó ń ṣe iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn nínú ìjọ ni Kristi gbà ń fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí ìjọ. Ó lè mú káwọn alàgbà tí í ṣe “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” pèsè ìtùnú, ìṣírí tàbí ìmọ̀ràn fáwọn ará lákòókò tí wọ́n nílò rẹ̀ gẹ́lẹ́. (Éfé. 4:8; Ìṣe 20:28; ka Aísáyà 32:1, 2.) Ǹjẹ́ o máa ń ka akitiyan wọn lórí rẹ sí ọ̀nà tí Kristi gbà ń fìfẹ́ hàn sí ọ ní tààràtà?

Ìrànlọ́wọ́ Lákòókò Tó Yẹ

13-15. Ọ̀nà wo ni Ọlọ́run lè gbà dáhùn àdúrà wa? Sọ àwọn àpẹẹrẹ kan.

13 Ǹjẹ́ o ti gbàdúrà kíkankíkan fún ìrànlọ́wọ́ rí, tí Ọlọ́run sì dáhùn rẹ̀ nípa mímú kí Kristẹni kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ kó sì fún ọ níṣìírí? (Ják. 5:14-16) Ó sì tún lè jẹ́ pé ọ̀rọ̀ kan lo máa gbọ́ nínú ìpàdé ìjọ tàbí ohun kan lo máa kà nínú ìtẹ̀jáde wa tó máa ràn ọ́ lọ́wọ́. Jèhófà sábà máa ń gba ọ̀nà wọ̀nyẹn dáhùn àdúrà. Wo àpẹẹrẹ yìí: Lẹ́yìn tí alàgbà kan sọ àsọyé kan tán, arábìnrin kan tí wọ́n yàn jẹ lọ́nà tó burú jáì lọ́sẹ̀ díẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn tọ̀ ọ́ wá. Dípò tí arábìnrin yìí á fi kó ẹjọ́ palẹ̀ nípa gbogbo bí wọ́n ṣe rẹ́ ẹ jẹ, ńṣe ló dúpẹ́ gan-an fáwọn kókó kan látinú Bíbélì tó gbọ́ nínú àsọyé náà. Wọ́n bá ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i mu gan-an ni, wọ́n sì tù ú nínú gidigidi. Inú arábìnrin náà dùn gan-an ni pé òun wà ní ìpàdé yẹn!

14 Ní ti pé kí Ọlọ́run gbọ́ àdúrà ẹni, wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ẹlẹ́wọ̀n mẹ́ta kan tó jẹ́ pé inú ọgbà ẹ̀wọ̀n ni wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tí wọ́n sì di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi. Wàhálà kan táwọn kan fà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n náà mú káwọn aláṣẹ fi àwọn àǹfààní kan du gbogbo ẹlẹ́wọ̀n tó wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n yẹn. Làwọn ẹlẹ́wọ̀n bá bẹ̀rẹ̀ sí í fi ẹ̀hónú hàn. Wọ́n wá fẹnu kò pé lẹ́yìn oúnjẹ àárọ̀ wọn lọ́jọ́ kejì ńṣe ni kí gbogbo àwọn kọ̀ láti dá abọ́ oúnjẹ àwọn pa dà. Nìṣòro bá délẹ̀ fáwọn akéde mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí kò tíì ṣèrìbọmi yẹn. Tí wọ́n bá bá wọn lọ́wọ́ sí ọ̀tẹ̀ yẹn, a jẹ́ pé wọn ò tẹ̀ lé ìtọ́ni Jèhófà tó wà nínú Róòmù 13:1. Tí wọ́n ò bá sì lọ́wọ́ sí i, ńṣe làwọn ẹlẹ́wọ̀n yòókù máa fàbọ̀ sórí wọn.

15 Nígbà tí kò ṣeé ṣe fáwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta láti bára wọn sọ̀rọ̀, kálukú wọn gbàdúrà fún ọgbọ́n látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Nígbà tó sì máa dàárọ̀ ọjọ́ kejì, wọ́n rí i pé ìpinnu kan náà làwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ṣe, ìyẹn ni pé àwọn ò wúlẹ̀ ní gba oúnjẹ àárọ̀ ọjọ́ náà. Nígbà táwọn wọ́dà wá dé láti gba abọ́, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kò ní abọ́ kankan lọ́wọ́ tó yẹ kí wọ́n dá pa dà. Inú wọn mà dún o pé “Olùgbọ́ àdúrà” gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn!—Sm. 65:2.

Má Bẹ̀rù Ọjọ́ Ọ̀la

16. Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù ṣe ń fi hàn pé Jèhófà bìkítà nípa àwọn ẹni bí àgùntàn?

16 Iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé jẹ́ ọ̀nà míì tí Jèhófà gbà ń fi hàn pé òun bìkítà nípa àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́, níbikíbi tí wọ́n bá ń gbé. (Jẹ́n. 18:25) Lọ́pọ̀ ìgbà, Jèhófà máa ń tipasẹ̀ àwọn áńgẹ́lì darí wa lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹni bí àgùntàn, kódà kó jẹ́ ibi tí ìhìn rere ò tíì dé ni wọ́n ń gbé. (Ìṣí. 14:6, 7) Àpẹẹrẹ kan ni bí Ọlọ́run ṣe mú kí áńgẹ́lì kan darí Fílípì, ajíhìnrere kan ní ọ̀rúndún kìíní, lọ pàdé ìwẹ̀fà ará Etiópíà láti ṣàlàyé Ìwé Mímọ́ fún un. Bí ọkùnrin náà ṣe tẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà nìyẹn tó sì di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. bJòh. 10:14; Ìṣe 8:26-39.

17. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa dààmú jù nítorí ọjọ́ ọ̀la?

17 Bí ètò nǹkan ìsinsìnyí ṣe ń lọ sópin, ńṣe ni “ìroragógó wàhálà” tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ yóò máa bá a nìṣó. (Mát. 24:8) Bí àpẹẹrẹ, oúnjẹ lè di ọ̀wọ́n gógó nítorí àìtó oúnjẹ, nítorí ojú ọjọ́ tí kò bára dé, tàbí ipò ọrọ̀ ajé tó túbọ̀ ń burú sí i. Iṣẹ́ lè túbọ̀ ṣòro láti rí, ó sì lè wá di dandan pé káwọn òṣìṣẹ́ máa ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó. Ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, kò sídìí tó fi yẹ káwọn tó bá fiṣẹ́ ìsìn Jèhófà sípò kìíní, tí wọ́n sì jẹ́ kí ‘ojú wọn mú ọ̀nà kan,’ máa dààmú jù. Wọ́n mọ̀ pé Ọlọ́run fẹ́ràn àwọn àti pé yóò bójú tó àwọn. (Mát. 6:22-34) Bí àpẹẹrẹ, wo bí Jèhófà ṣe bójú tó Jeremáyà nígbà hílàhílo tó yọrí sí ìparun Jerúsálẹ́mù lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni.

18. Báwo ni Jèhófà ṣe dúró ti Jeremáyà lákòókò táwọn ará Bábílónì sàga ti Jerúsálẹ́mù?

18 Lápá ìgbẹ̀yìn àkókò táwọn ará Bábílónì sàga ti Jerúsálẹ́mù, inú àtìmọ́lé ni Jeremáyà wà ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́. Báwo ló ṣe wá ń rí oúnjẹ jẹ? Ká ní kò sí látìmọ́lé ni, ṣebí ì bá máa wá oúnjẹ kiri. Àmọ́ ní báyìí, kò sọ́nà tó lè gbà róúnjẹ àyàfi táwọn tó wà láyìíká rẹ̀ bá fún un, àwọn tó kórìíra rẹ̀ ló sì pọ̀ jù níbẹ̀! Síbẹ̀, Ọlọ́run ni Jeremáyà gbẹ́kẹ̀ lé, kò gbẹ́kẹ̀ léèyàn, torí Ọlọ́run ti ṣèlérí pé òun máa bójú tó o. Ǹjẹ́ Jèhófà mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ? Ó mú un ṣẹ! Ó rí i dájú pé Jeremáyà ń rí “ìṣù búrẹ́dì ribiti kan” gbà lójoojúmọ́ “títí gbogbo búrẹ́dì ìlú ńlá náà fi tán pátápátá.” (Jer. 37:21) Ní kúkúrú, Ọlọ́run dá ẹ̀mí Jeremáyà, Bárúkù, Ebedi-mélékì àtàwọn míì bẹ́ẹ̀ sí nígbà ìyàn, àrùn àti ikú yẹn.—Jer. 38:2; 39:15-18.

19. Kí ló yẹ ká fi ṣe ìpinnu wa nípa ọjọ́ iwájú?

19 Dájúdájú, “ojú Jèhófà ń bẹ lára àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn.” (1 Pét. 3:12) Ǹjẹ́ inú rẹ kì í dùn pé Baba rẹ̀ ọ̀run ń ṣọ́ ọ? Ṣé ọkàn rẹ balẹ̀ pẹ̀sẹ̀, ṣé ara sì tù ọ́ bó o ṣe mọ̀ pé Jèhófà ń ṣọ́ ọ fún ire rẹ? Nígbà náà, fi ṣe ìpinnu rẹ pé, àní sẹ́, bíná ń jó, bíjì ń jà, Ọlọ́run ni wàá máa bá rìn títí láé. Ó dájú pé bíi baba ni Jèhófà yóò ṣe máa fìṣọ́ ṣọ́ gbogbo àwọn adúróṣinṣin.—Sm. 32:8; ka Aísáyà 41:13.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹni àmì òróró ni Kristi dìídì sọ ọ̀rọ̀ inú ìwé wọ̀nyẹn fún, gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni ìlànà inú rẹ̀ kàn.

b Àpẹẹrẹ míì nípa bí Ọlọ́run ṣe darí àwọn oníwàásù wà nínú Ìṣe 16:6-10. A rí i kà níbẹ̀ pé “ẹ̀mí mímọ́ ka sísọ ọ̀rọ̀ náà ní àgbègbè Éṣíà [àti Bítíníà] léèwọ̀” fún Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ ń wàásù. Wọ́n wá gba ìtọ́ni pé ìlú Makedóníà ni kí wọ́n ti lọ wàásù, tí ọ̀pọ̀ ọlọ́kàn tútù èèyàn sì gba ìhìn rere náà gbọ́.

Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?

• Báwo la ṣe lè fi hàn pé à ń ‘bá Ọlọ́run rìn’?

• Báwo ni Jèhófà ṣe fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí Bárúkù?

• Báwo ni Jésù tó jẹ́ Orí ìjọ Kristẹni ṣe gbé àwọn ànímọ́ Baba rẹ̀ yọ?

• Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run lákòókò lílekoko yìí?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Bí Jèhófà ṣe tipasẹ̀ Jeremáyà ran Bárúkù lọ́wọ́, ló ṣe ń lo àwọn alàgbà láti ràn wá lọ́wọ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ọ̀nà wo ni Jèhófà lè gbà pèsè ìrànlọ́wọ́ fún wa lákòókò tó yẹ?