Jeremáyà 1:1-19
1 Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ Jeremáyà,* ọmọ Hilikáyà, ọ̀kan lára àwọn àlùfáà tó wà ní Ánátótì,+ ní ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì.
2 Jèhófà bá a sọ̀rọ̀ nígbà ayé Jòsáyà+ ọmọ Ámọ́nì,+ ọba Júdà, ní ọdún kẹtàlá tó ti ń jọba.
3 Ó tún bá a sọ̀rọ̀ nígbà ayé Jèhóákímù+ ọmọ Jòsáyà, ọba Júdà, títí di òpin ọdún kọkànlá ìjọba Sedekáyà,+ ọmọ Jòsáyà, ọba Júdà, títí Jerúsálẹ́mù fi lọ sí ìgbèkùn ní oṣù karùn-ún.+
4 Jèhófà bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:
5 “Kí n tó dá ọ nínú ìyá rẹ ni mo ti mọ̀* ọ́,+Kí wọ́n sì tó bí ọ* ni mo ti sọ ọ́ di mímọ́.*+
Mo fi ọ́ ṣe wòlíì àwọn orílẹ̀-èdè.”
6 Ṣùgbọ́n mo sọ pé: “Áà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ!
Mi ò mọ ọ̀rọ̀ sọ,+ ọmọdé* lásán ni mí.”+
7 Ni Jèhófà bá sọ fún mi pé:
“Má sọ pé ‘ọmọdé lásán’ ni ọ́.
Torí o gbọ́dọ̀ lọ sọ́dọ̀ gbogbo àwọn tí mo bá rán ọ sí,Kí o sì sọ gbogbo ohun tí mo bá pa láṣẹ fún ọ.+
8 Má ṣe jẹ́ kí ìrísí wọn dẹ́rù bà ọ́,+Nítorí ‘mo wà pẹ̀lú rẹ láti gbà ọ́,’+ ni Jèhófà wí.”
9 Jèhófà wá na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi kan ẹnu mi.+ Jèhófà sì sọ fún mi pé: “Mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ẹnu rẹ.+
10 Wò ó, mo ti fàṣẹ yàn ọ́ lónìí lórí àwọn orílẹ̀-èdè àti lórí àwọn ìjọba, láti fà tu àti láti bì wó, láti pa run àti láti ya lulẹ̀, láti kọ́ àti láti gbìn.”+
11 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: “Jeremáyà, kí lo rí?” Mo sọ pé: “Ẹ̀ka igi álímọ́ńdì.”*
12 Jèhófà sọ fún mi pé: “Òótọ́ ni, òun ni, nítorí mo máa ń wà lójúfò láti mú ọ̀rọ̀ mi ṣẹ.”
13 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kejì pé: “Kí lo rí?” Torí náà, mo sọ pé: “Mo rí ìkòkò* tí ohun tó wà nínú rẹ̀ ń hó,* tí wọ́n da ẹnu rẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kí ó lè kọ ìdí sí àríwá.”
14 Ni Jèhófà bá sọ fún mi pé:
“Ìyọnu máa tú jáde láti àríwáSára gbogbo àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà.+
15 Nítorí ‘mò ń pe gbogbo ìdílé àwọn ìjọba àríwá,’ ni Jèhófà wí,+‘Wọ́n á wá, kálukú wọn á sì ṣe ìtẹ́ rẹ̀Sí àwọn ẹnubodè Jerúsálẹ́mù,+Wọ́n á gbé e ti gbogbo ògiri tó yí i káWọ́n á sì gbé e ti gbogbo ìlú tó wà ní Júdà.+
16 Màá kéde ìdájọ́ mi lé wọn lórí nítorí gbogbo ìwà ibi wọn,Torí pé wọ́n ti fi mí sílẹ̀,+Wọ́n ń fi ẹbọ rú èéfín sí àwọn ọlọ́run mìíràn+Wọ́n sì ń forí balẹ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn.’+
17 Àmọ́, gbára dì,*Kí o sì dìde láti bá wọn sọ gbogbo ohun tí mo bá pa láṣẹ fún ọ.
Má ṣe jẹ́ kí ẹ̀rù wọn bà ọ́,+Kí n má bàa jẹ́ kí ẹ̀rù bà ọ́ níwájú wọn.
18 Lónìí, mo ti sọ ọ́ di ìlú olódi,Òpó irin àti ògiri bàbà láti kojú gbogbo ilẹ̀ náà,+Láti kojú àwọn ọba Júdà àti àwọn ìjòyè rẹ̀,Láti kojú àwọn àlùfáà rẹ̀ àti àwọn èèyàn ilẹ̀ náà.+
19 Ó sì dájú pé wọ́n á bá ọ jà,Ṣùgbọ́n wọn kò ní borí* rẹ,Nítorí ‘mo wà pẹ̀lú rẹ + láti gbà ọ́’ ni Jèhófà wí.”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Jèhófà Ń Gbéni Ga.”
^ Ní Héb., “Kí o tó jáde láti inú ilé ọmọ.”
^ Tàbí “yà ọ́ sọ́tọ̀.”
^ Tàbí “yàn.”
^ Tàbí “ọ̀dọ́.”
^ Ní Héb., “ẹni tó ń tètè jí.”
^ Tàbí “ìkòkò ìsebẹ̀ ẹlẹ́nu fífẹ̀.”
^ Ní Héb., “tí wọ́n fẹ́ atẹ́gùn sí,” èyí tó fi hàn pé iná ń jó lala lábẹ́ rẹ̀.
^ Ní Héb., “de àmùrè mọ́ ìbàdí rẹ.”
^ Tàbí “ṣẹ́gun.”