Jeremáyà 45:1-5

  • Iṣẹ́ tí Jèhófà rán sí Bárúkù (1-5)

45  Ọ̀rọ̀ tí wòlíì Jeremáyà sọ fún Bárúkù+ ọmọ Neráyà nìyí, nígbà tó ń kọ ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà ń sọ fún un sínú ìwé+ ní ọdún kẹrin Jèhóákímù+ ọmọ Jòsáyà, ọba Júdà:  “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nípa rẹ nìyí, ìwọ Bárúkù,  ‘O sọ pé: “Mo gbé! Nítorí pé Jèhófà ti fi ẹ̀dùn ọkàn kún ìrora mi. Àárẹ̀ mú mi nítorí ìrora mi, mi ò sì rí ibi ìsinmi kankan.”’  “Kí o sọ fún un pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Wò ó! Ohun tí mo ti kọ́ ni màá ya lulẹ̀, ohun tí mo sì ti gbìn ni màá fà tu, ìyẹn gbogbo ilẹ̀ náà.+  Ṣùgbọ́n ìwọ ń wá* àwọn ohun ńlá fún ara rẹ. Má ṣe wá wọn mọ́.”’ “‘Nítorí mo máa tó mú àjálù wá bá gbogbo èèyàn,’*+ ni Jèhófà wí, ‘àmọ́ màá jẹ́ kí o jèrè ẹ̀mí rẹ* ní ibikíbi tí o bá lọ.’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “retí.”
Ní Héb., “ẹlẹ́ran ara.”
Tàbí “màá jẹ́ kí o sá àsálà fún ọkàn rẹ.”