Jeremáyà 17:1-27
17 “Ẹ̀ṣẹ̀ Júdà ni a ti fi kálàmù* irin kọ sílẹ̀.
A ti fi ṣóńṣó dáyámọ́ǹdì fín in sára wàláà ọkàn wọnÀti sára àwọn ìwo pẹpẹ wọn,
2 Nígbà tí àwọn ọmọ wọn rántí pẹpẹ wọn àti òpó òrìṣà* wọn+Lẹ́gbẹ̀ẹ́ igi tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀, lórí àwọn ibi tó ga,+
3 Lórí àwọn òkè ní àwọn ìgbèríko tó tẹ́jú.
Àwọn ohun àmúṣọrọ̀ rẹ, gbogbo ìṣúra rẹ ni màá jẹ́ kí wọ́n kó lọ+Títí kan àwọn ibi gíga rẹ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí o dá ní gbogbo ìpínlẹ̀ rẹ.+
4 Ìwọ fúnra rẹ máa yọ̀ǹda ogún tí mo fún ọ.+
Màá sì mú kí o sin àwọn ọ̀tá rẹ ní ilẹ̀ tí o kò mọ̀,+Nítorí o ti mú kí ìbínú mi ràn bí iná.*+
Yóò máa jó títí lọ.”
5 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“Ègún ni fún ọkùnrin* tó gbẹ́kẹ̀ lé èèyàn lásánlàsàn,+Tó gbára lé agbára èèyàn,*+Tí ọkàn rẹ̀ sì pa dà lẹ́yìn Jèhófà.
6 Yóò dà bí igi tó dá wà ní aṣálẹ̀.
Kò ní rí i nígbà tí ohun rere bá dé,Ṣùgbọ́n àwọn ibi tó gbẹ nínú aginjù ni yóò máa gbé,Ní ilẹ̀ iyọ̀ tí kò sí ẹnì kankan tó lè gbé ibẹ̀.
7 Ìbùkún ni fún ọkùnrin* tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà,Ẹni tó fi Jèhófà ṣe ìgbọ́kànlé rẹ̀.+
8 Yóò dà bí igi tí a gbìn sí etí omi,Tó na gbòǹgbò rẹ̀ sínú odò.
Kò ní mọ̀ ọ́n lára nígbà tí ooru bá dé,Ṣùgbọ́n àwọn ewé rẹ̀ yóò máa tutù yọ̀yọ̀ ní gbogbo ìgbà.+
Ní ọdún ọ̀gbẹlẹ̀, kò ní ṣàníyàn,Bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní yéé so èso.
9 Ọkàn ń tanni jẹ* ju ohunkóhun lọ, kò sóhun tí kò lè ṣe.*+
Ta ló lè mọ̀ ọ́n?
10 Èmi, Jèhófà, ń wá inú ọkàn,+Mo sì ń ṣàyẹ̀wò èrò inú,*Kí n lè san èrè fún ẹnì kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀Àti gẹ́gẹ́ bí èso iṣẹ́ rẹ̀.+
11 Bí ẹyẹ àparò tó máa ń sàba lórí ẹyin tí kì í ṣe tirẹ̀,Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tó ń fi èrú* kó ọrọ̀ jọ.+
Wọ́n á fi í sílẹ̀ ní ọ̀sán gangan ayé rẹ̀,Ní ìkẹyìn, á wá hàn pé òmùgọ̀ ni.”
12 Ìtẹ́ ológo tí a gbé ga láti ìbẹ̀rẹ̀,Ni ibi mímọ́ wa jẹ́.+
13 Jèhófà, ìwọ ni ìrètí Ísírẹ́lì,Ojú máa ti gbogbo àwọn tó bá fi ọ́ sílẹ̀.
Àwọn tó bá pẹ̀yìn dà lọ́dọ̀ rẹ* ni a ó kọ orúkọ wọn sórí eruku ilẹ̀,+Torí pé wọ́n ti fi Jèhófà sílẹ̀, ẹni tó jẹ́ orísun omi ìyè.+
14 Wò mí sàn, Jèhófà, ara mi á sì dá.
Gbà mí là, màá sì rí ìgbàlà,+Nítorí ìwọ ni èmi yóò máa yìn.
15 Wò ó! Àwọn kan ń sọ fún mi pé:
“Ọ̀rọ̀ Jèhófà dà?+
Jọ̀wọ́, jẹ́ kó wá!”
16 Ṣùgbọ́n ní tèmi, mi ò sá kúrò lẹ́yìn rẹ bí mo ti ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn,Mi ò sì máa retí pé kí ọjọ́ àjálù dé.
Gbogbo ohun tí mo fi ètè mi sọ lo mọ̀ dáadáa;Ìṣojú rẹ ni gbogbo rẹ̀ wáyé!
17 Má ṣe jẹ́ ohun ẹ̀rù fún mi.
Ìwọ ni ibi ààbò mi ní ọjọ́ àjálù.
18 Jẹ́ kí ojú ti àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí mi,+Àmọ́ má ṣe jẹ́ kí ojú tì mí.
Jẹ́ kí jìnnìjìnnì bá wọn,Àmọ́ má ṣe jẹ́ kí jìnnìjìnnì bá mi.
Mú kí ọjọ́ àjálù dé bá wọn,+Fọ́ wọn túútúú, kí o sì pa wọ́n run pátápátá.*
19 Ohun tí Jèhófà sọ fún mi nìyí: “Lọ, kí o sì dúró ní ẹnubodè àwọn ọmọ èèyàn náà, èyí tí àwọn ọba Júdà ń gbà wọlé, tí wọ́n sì ń gbà jáde àti ní gbogbo ẹnubodè Jerúsálẹ́mù.+
20 Sọ fún wọn pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹ̀yin ọba Júdà àti gbogbo ẹ̀yin èèyàn Júdà pẹ̀lú gbogbo ẹ̀yin tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù, tí ẹ̀ ń gba àwọn ẹnubodè yìí wọlé.
21 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ẹ ṣọ́ ara* yín, ẹ má sì ru ẹrù èyíkéyìí ní ọjọ́ Sábáàtì tàbí kí ẹ gbé e gba àwọn ẹnubodè Jerúsálẹ́mù wọlé.+
22 Ẹ kò gbọ́dọ̀ gbé ẹrù kankan jáde láti inú ilé yín ní ọjọ́ Sábáàtì, ẹ kò sì gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan.+ Ẹ jẹ́ kí ọjọ́ Sábáàtì máa jẹ́ mímọ́, gẹ́gẹ́ bí mo ṣe pa á láṣẹ fún àwọn baba ńlá yín.+
23 Ṣùgbọ́n wọn kò tẹ́tí sí mi, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fetí sílẹ̀, wọ́n ya alágídí* kí wọ́n má bàa ṣègbọràn, kí wọ́n má sì gba ìbáwí.”’+
24 “‘“Àmọ́, bí ẹ bá ṣègbọràn sí mi délẹ̀délẹ̀,” ni Jèhófà wí, “tí ẹ kò gbé ẹrù kankan gba àwọn ẹnubodè ìlú yìí wọlé ní ọjọ́ Sábáàtì, tí ẹ sì jẹ́ kí ọjọ́ Sábáàtì máa jẹ́ mímọ́ ní ti pé ẹ kò ṣe iṣẹ́ kankan lọ́jọ́ náà,+
25 nígbà náà, àwọn ọba àti àwọn ìjòyè, tí wọ́n jókòó lórí ìtẹ́ Dáfídì,+ tí wọ́n gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti àwọn ẹṣin, àwọn àti àwọn ìjòyè wọn, àwọn èèyàn Júdà àti àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù, máa gba àwọn ẹnubodè ìlú yìí wọlé,+ àwọn èèyàn á sì máa gbé inú ìlú yìí títí láé.
26 Àwọn èèyàn á sì wá láti àwọn ìlú Júdà àti láti àyíká Jerúsálẹ́mù àti láti ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì+ àti láti pẹ̀tẹ́lẹ̀ + àti láti àwọn agbègbè olókè àti láti Négébù.* Wọ́n á máa mú odindi ẹbọ sísun + àti ẹbọ+ àti ọrẹ ọkà+ àti oje igi tùràrí wá, wọ́n á sì máa mú ẹbọ ìdúpẹ́ wá sínú ilé Jèhófà.+
27 “‘“Ṣùgbọ́n bí ẹ kò bá ṣègbọràn sí àṣẹ tí mo pa pé kí ẹ jẹ́ kí ọjọ́ Sábáàtì máa jẹ́ mímọ́, tí ẹ̀ ń ru ẹrù, tí ẹ sì ń gbé e gba àwọn ẹnubodè Jerúsálẹ́mù ní ọjọ́ Sábáàtì, ṣe ni màá sọ iná sí àwọn ẹnubodè rẹ̀, ó sì dájú pé á jó àwọn ilé gogoro tó láàbò ní Jerúsálẹ́mù run,+ a kò sì ní pa iná náà.”’”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “gègé.”
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí kó jẹ́, “Nítorí ìbínú mi ti mú kí ẹ ràn bí iná.”
^ Ní Héb., “tó fi ẹlẹ́ran ara ṣe apá rẹ̀.”
^ Tàbí “ọkùnrin alágbára.”
^ Tàbí “ọkùnrin alágbára.”
^ Tàbí “ṣe békebèke.”
^ Tàbí kó jẹ́, “kò ṣeé wò sàn.”
^ Tàbí “inú lọ́hùn-ún.” Ní Héb., “kíndìnrín.”
^ Tàbí “ìwà àìtọ́.”
^ Ní Héb., “lọ́dọ̀ mi,” ó jọ pé Jèhófà ló ń tọ́ka sí.
^ Tàbí “pa wọ́n ní àpatúnpa.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Ní Héb., “wọ́n mú ọrùn wọn le.”
^ Tàbí “gúúsù.”

