Jeremáyà 38:1-28

  • Wọ́n ju Jeremáyà sínú kòtò omi (1-6)

  • Ebedi-mélékì gba Jeremáyà sílẹ̀ (7-13)

  • Jeremáyà rọ Sedekáyà pé kó juwọ́ sílẹ̀ (14-28)

38  Ìgbà náà ni Ṣẹfatáyà ọmọ Mátánì, Gẹdaláyà ọmọ Páṣúrì, Júkálì+ ọmọ Ṣelemáyà àti Páṣúrì + ọmọ Málíkíjà gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà ń sọ fún gbogbo àwọn èèyàn náà pé:  “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Ẹni tó bá dúró sí ìlú yìí ni idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn* yóò pa.+ Àmọ́, ẹni tó bá fi ara rẹ̀ lé* ọwọ́ àwọn ará Kálídíà á máa wà láàyè, á jèrè ẹ̀mí rẹ̀, á sì wà láàyè.’*+  Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Ó dájú pé ìlú yìí ni a ó fà lé ọwọ́ àwọn ọmọ ogun ọba Bábílónì, yóò sì gbà á.’”+  Àwọn ìjòyè sọ fún ọba pé: “Jọ̀wọ́, ní kí wọ́n pa ọkùnrin yìí,+ torí bó ṣe máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn* àwọn ọmọ ogun tó ṣẹ́ kù nínú ìlú yìí àti gbogbo àwọn èèyàn náà nìyẹn, tó ń sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ fún wọn. Nítorí kì í ṣe àlàáfíà àwọn èèyàn yìí ni ọkùnrin yìí ń wá, bí kò ṣe àjálù wọn.”  Ọba Sedekáyà dáhùn pé: “Ẹ wò ó! Ọwọ́ yín ni ọkùnrin náà wà, torí kò sí nǹkan kan tí ọba lè ṣe láti dá yín dúró.”  Torí náà, wọ́n mú Jeremáyà, wọ́n sì jù ú sínú kòtò omi Málíkíjà ọmọ ọba, èyí tó wà ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́.+ Wọ́n fi okùn sọ Jeremáyà kalẹ̀. Nígbà yẹn, kò sí omi nínú kòtò omi náà, àfi ẹrẹ̀ nìkan, Jeremáyà sì bẹ̀rẹ̀ sí í rì sínú ẹrẹ̀ náà.  Ebedi-mélékì+ ará Etiópíà, tó jẹ́ ìwẹ̀fà* ní ilé* ọba gbọ́ pé wọ́n ti ju Jeremáyà sínú kòtò omi. Lásìkò yìí, ọba wà níbi tó jókòó sí ní Ẹnubodè Bẹ́ńjámínì,+  torí náà, Ebedi-mélékì jáde kúrò ní ilé* ọba, ó sì sọ fún ọba pé:  “Olúwa mi ọba, ìwà ìkà gbáà ni àwọn ọkùnrin yìí hù sí wòlíì Jeremáyà! Wọ́n ti jù ú sínú kòtò omi, ibẹ̀ ló sì máa kú sí nítorí ìyàn, torí kò sí búrẹ́dì mọ́ ní ìlú yìí.”+ 10  Ìgbà náà ni ọba pàṣẹ fún Ebedi-mélékì ará Etiópíà pé: “Mú ọgbọ̀n (30) ọkùnrin pẹ̀lú rẹ láti ibí yìí, kí o sì gbé wòlíì Jeremáyà gòkè láti inú kòtò omi kí ó tó kú.” 11  Torí náà, Ebedi-mélékì kó àwọn ọkùnrin náà, ó sì lọ sí ilé* ọba, sí apá kan lábẹ́ ibi ìṣúra,+ wọ́n sì kó àwọn àkísà àti àwọn àjákù aṣọ níbẹ̀, wọ́n sì fi okùn sọ̀ wọ́n sísàlẹ̀ sí Jeremáyà nínú kòtò omi náà. 12  Ni Ebedi-mélékì ará Etiópíà bá sọ fún Jeremáyà pé: “Jọ̀wọ́, fi àwọn àkísà náà àti àwọn àjákù aṣọ náà tẹ́ abíyá rẹ lórí okùn náà.” Jeremáyà sì ṣe bẹ́ẹ̀, 13  wọ́n fi okùn náà fa Jeremáyà jáde, wọ́n sì gbé e gòkè kúrò nínú kòtò omi náà. Jeremáyà sì wà ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́.+ 14  Ọba Sedekáyà ránṣẹ́ sí wòlíì Jeremáyà pé kó wá sọ́dọ̀ òun ní àbáwọlé kẹta, tó wà ní ilé Jèhófà, ọba sì sọ fún Jeremáyà pé: “Ohun kan wà tí mo fẹ́ bi ọ́. Má fi ohunkóhun pa mọ́ fún mi.” 15  Jeremáyà wá sọ fún Sedekáyà pé: “Tí mo bá sọ fún ọ, ó dájú pé wàá pa mí. Tí mo bá sì fún ọ nímọ̀ràn, o ò ní fetí sí mi.” 16  Torí náà, Ọba Sedekáyà búra ní bòókẹ́lẹ́ fún Jeremáyà pé: “Bí Jèhófà ti wà láàyè, ẹni tó fún wa ní ẹ̀mí wa,* mi ò ní pa ọ́, mi ò sì ní fà ọ́ lé ọwọ́ àwọn èèyàn tó fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ.”* 17  Jeremáyà wá sọ fún Sedekáyà pé: “Ohun tí Jèhófà, Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Bí o bá fi ara rẹ lé* àwọn ìjòyè ọba Bábílónì lọ́wọ́, wọ́n á dá ẹ̀mí rẹ sí,* wọn kò ní dáná sun ìlú yìí, wọn kò sì ní pa ìwọ àti agbo ilé rẹ.+ 18  Àmọ́, bí o kò bá fi ara rẹ lé* àwọn ìjòyè ọba Bábílónì lọ́wọ́, a ó fa ìlú yìí lé àwọn ará Kálídíà lọ́wọ́, wọ́n á dáná sun ún,+ o ò sì ní lè sá mọ́ wọn lọ́wọ́.’”+ 19  Ìgbà náà ni Ọba Sedekáyà sọ fún Jeremáyà pé: “Ẹ̀rù àwọn Júù tí wọ́n ti sá lọ sọ́dọ̀ àwọn ará Kálídíà ń bà mí, nítorí tí wọ́n bá fà mí lé wọn lọ́wọ́, wọ́n lè ṣe mí ṣúkaṣùka.” 20  Ṣùgbọ́n Jeremáyà sọ pé: “Wọn kò ní fà ọ́ lé wọn lọ́wọ́. Jọ̀wọ́, ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà lórí ohun tí mò ń sọ fún ọ, nǹkan á lọ dáadáa fún ọ, wàá* sì máa wà láàyè. 21  Àmọ́, bí o bá kọ̀ láti fi ara rẹ lé* wọn lọ́wọ́, ohun tí Jèhófà fi hàn mí nìyí: 22  Wò ó! Gbogbo obìnrin tó ṣẹ́ kù sí ilé* ọba Júdà ni a mú jáde wá sọ́dọ̀ àwọn ìjòyè ọba Bábílónì,+ wọ́n sì ń sọ pé,‘Àwọn ọkùnrin tí o fọkàn tán* ti tàn ọ́ jẹ, wọ́n sì ti borí rẹ.+ Wọ́n ti mú kí ẹsẹ̀ rẹ rì sínú ẹrọ̀fọ̀. Ní báyìí, wọ́n ti sá pa dà lẹ́yìn rẹ.’ 23  Gbogbo ìyàwó rẹ àti àwọn ọmọ rẹ ni wọ́n á kó wá fún àwọn ará Kálídíà, o ò sì ní lè sá mọ́ wọn lọ́wọ́, àmọ́ ọba Bábílónì+ máa mú ọ, nítorí rẹ sì ni wọ́n á fi dáná sun ìlú yìí.”+ 24  Sedekáyà sì sọ fún Jeremáyà pé: “Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀ nípa àwọn nǹkan yìí, kí o má bàa kú. 25  Tí àwọn ìjòyè bá sì gbọ́ pé mo bá ọ sọ̀rọ̀, tí wọ́n wá bá ọ, tí wọ́n sì sọ fún ọ pé, ‘Jọ̀wọ́, sọ fún wa, ohun tí o bá ọba sọ. Má fi ohunkóhun pa mọ́ fún wa, a ò ní pa ọ́.+ Kí ni ọba sọ fún ọ?’ 26  kí o fún wọn lésì pé, ‘Ṣe ni mò ń bẹ ọba pé kó má ṣe dá mi pa dà sí ilé Jèhónátánì láti kú sí ibẹ̀.’”+ 27  Nígbà tó yá, gbogbo àwọn ìjòyè wọlé wá bá Jeremáyà, wọ́n sì bi í ní ìbéèrè. Ó sọ gbogbo ohun tí ọba pa láṣẹ fún un pé kó sọ fún wọn. Torí náà, wọn kò bá a sọ̀rọ̀ mọ́, nítorí ẹnikẹ́ni kò mọ ohun tí òun àti ọba jọ sọ. 28  Jeremáyà kò kúrò ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́+ títí di ọjọ́ tí wọ́n gba Jerúsálẹ́mù; ibẹ̀ ló ṣì wà nígbà tí wọ́n gba Jerúsálẹ́mù.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “àìsàn.”
Ní Héb., “jáde sí.”
Tàbí “á sì sá àsálà fún ọkàn rẹ̀.”
Ní Héb., “ọwọ́.”
Tàbí “òṣìṣẹ́ láàfin.”
Tàbí “ààfin.”
Tàbí “ààfin.”
Tàbí “ààfin.”
Tàbí “tó ń lépa ọkàn rẹ.”
Tàbí “ẹni tó dá ọkàn yìí fún wa.”
Ní Héb., “jáde sí.”
Tàbí “ọkàn rẹ yóò máa wà láàyè.”
Ní Héb., “jáde sí.”
Tàbí “ọkàn rẹ.”
Ní Héb., “jáde sí.”
Ní Héb., “Àwọn ọkùnrin tó wà ní àlàáfíà pẹ̀lú rẹ.”
Tàbí “ààfin.”