Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jésù Kristi—Míṣọ́nnárì Tó Ta Yọ

Jésù Kristi—Míṣọ́nnárì Tó Ta Yọ

Jésù Kristi—Míṣọ́nnárì Tó Ta Yọ

“Mo jẹ́ aṣojú láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, Ẹni yẹn ni ó sì rán mi jáde.”—JÒH. 7:29.

1, 2. Kí ni míṣọ́nnárì túmọ̀ sí, ta sì lẹni tá a lè pè ní Míṣọ́nnárì tó ta yọ?

 KÍ LÓ máa ń wá sí ọ lọ́kàn tó o bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà “míṣọ́nnárì”? Ohun tó máa ń wá sọ́kàn àwọn míì ni àwọn míṣọ́nnárì táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ń rán jáde, tí wọ́n máa ń dá sí ìṣèlú àti ètò ọrọ̀ ajé láwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà. Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ìwọ ti jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ọkàn rẹ lè lọ sọ́dọ̀ àwọn míṣọ́nnárì tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń rán jáde láti lọ wàásù ìhìn rere láwọn ilẹ̀ òkèèrè. (Mát. 24:14) Àwọn míṣọ́nnárì tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń rán yìí ń fi tinútinú lo ara wọn, àkókò wọn àti okun wọn fún iṣẹ́ ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè sún mọ́ Jèhófà Ọlọ́run, kí wọ́n sì ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú rẹ̀.—Ják. 4:8.

2 Kò sí ọ̀rọ̀ náà “míṣọ́nnárì” nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtúmọ̀ Ayé Tuntun láti Jẹ́nẹ́sísì dé Ìṣípayá. Àmọ́, ẹ̀rí fi hàn pé ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “ajíhìnrere” nínú Éfésù 4:11 tún lè túmọ̀ sí “míṣọ́nnárì.” Jèhófà gan-an ni Ọba Ajíhìnrere, ṣùgbọ́n a ò lè pè é ní Míṣọ́nnárì, nítorí pé kò sẹ́ni tó rán an lọ síbì kankan. Nígbà tí Jésù Kristi ń sọ nípa Bàbá rẹ̀ ọ̀run, ó ní: “Mo jẹ́ aṣojú láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, Ẹni yẹn ni ó sì rán mi jáde.” (Jòh. 7:29) Jèhófà rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo wá sáyé nítorí pé ó nífẹ̀ẹ́ aráyé gan-an. (Jòh. 3:16) A lè pe Jésù ní Míṣọ́nnárì tó ta yọ, àní àgbà Míṣọ́nnárì, nítorí ara ìdí tí Jèhófà fi rán an wá sáyé ni láti wá “jẹ́rìí sí òtítọ́.” (Jòh. 18:37) Ó ṣe iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run láṣeyọrí, a ṣì ń jàǹfààní iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ di báyìí. Bí àpẹẹrẹ, bóyá míṣọ́nnárì ni wá tàbí a kì í ṣe míṣọ́nnárì, a lè lo ọ̀nà tí Jésù gbà ń kọ́ni nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.

3. Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò?

3 Níwọ̀n bí Jésù ti jẹ́ oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run tó ta yọ, ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ìbéèrè yìí yẹ̀ wò: Kí lojú Jésù rí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé? Kí ló jẹ́ kí ọ̀nà tó ń gbà kọ́ni múná dóko? Kí ló sì mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ kẹ́sẹ járí?

Ó Múra Tán Láti Ṣe Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ní Ayé

4-6. Àwọn ipò tó yàtọ̀ wo ni Jésù bá pàdé nígbà tí Ọlọ́run rán an wá sáyé?

4 Àwọn míṣọ́nnárì òde òní àtàwọn Kristẹni kan tí wọ́n lọ síbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i lè ní láti fara da ipò àwọn nǹkan tó lè má rọrùn bí ibi tí wọ́n ti wá. Àmọ́ ti Jésù tún ṣòro ju ìyẹn lọ torí pé ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ ló wà láàárín ipò tó wà lọ́run níbi tó ti ń gbé lọ́dọ̀ Bàbá rẹ̀ láàárín àwọn áńgẹ́lì tó ń fi ọkàn mímọ́ sin Jèhófà àti ipò tó wà lórí ilẹ̀ ayé. (Jóòbù 38:7) Ẹ ò rí i pé kò ní rọrùn rárá fún Jésù láti wá máa gbé láàárín àwọn ọmọ aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀ nínú ayé tó bà jẹ́ bàlùmọ̀ yìí! (Máàkù 7:20-23) Jésù tún ní láti fara da báwọn ọmọlẹ́yìn tó sún mọ́ ọn jù lọ ṣe ń jowú ara wọn. (Lúùkù 20:46; 22:24) Àmọ́, Jésù mú ara rẹ̀ bá gbogbo ipò tó bá pàdé lórí ilẹ̀ ayé mu.

5 Bákan náà, kì í ṣe pé Jésù dédé bẹ̀rẹ̀ sí í sọ èdè téèyàn ń sọ o, ńṣe ni wọ́n kọ́ ọ díẹ̀díẹ̀ láti kékeré. Ẹ ò rí i pé òdìkejì gbáà léyìí jẹ́ sí ìgbà tó wà lọ́run, tó jẹ́ pé òun ló ń darí àwọn áńgẹ́lì! Ó kéré tán Jésù lo ọ̀kan nínú “ahọ́n ènìyàn,” èyí tó yàtọ̀ pátápátá sí ‘ahọ́n àwọn áńgẹ́lì.’ (1 Kọ́r. 13:1) Síbẹ̀, ní ti sísọ̀rọ̀ tó lárinrin, kò sí ẹ̀dá èèyàn èyíkéyìí tó lè sọ̀rọ̀ bíi ti Jésù.—Lúùkù 4:22.

6 Ẹ jẹ́ ká tún wo àwọn ọ̀nà míì tí nǹkan gbà yàtọ̀ gan-an fún Ọmọ Ọlọ́run nígbà tó wá sáyé. Òótọ́ ni pé Jésù ò jogún ẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ Ádámù, àmọ́, ó di èèyàn bíi táwọn tó wá di “arákùnrin” rẹ̀, ìyẹn àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn. (Ka Hébérù 2:17, 18.) Nígbà tí Jésù nílò ìrànlọ́wọ́ lálẹ́ ọjọ́ tó lò kẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé, kò sọ pé kí Bàbá òun fi “àwọn áńgẹ́lì tí ó ju líjíónì méjìlá” ránṣẹ́ sóun. Bẹ́ẹ̀, ọ̀kẹ́ àìmọye áńgẹ́lì ni Jésù láṣẹ lé lórí nígbà tó wà lọ́run torí òun ni Máíkẹ́lì Olú-áńgẹ́lì! (Mát. 26:53; Júdà 9) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ṣe iṣẹ́ ìyanu nígbà tó wà láyé, síbẹ̀ àwọn ohun tó ṣe lórí ilẹ̀ ayé kéré gan-an sí ohun tí ì bá gbé ṣe tó bá ṣe pé ọ̀run ló wà.

7. Kí ni ìṣarasíhùwà àwọn Júù sí Òfin Mósè?

7 Nígbà tí Jésù jẹ́ “Ọ̀rọ̀,” ìyẹn ṣáájú kí Ọlọ́run tó rán an wá sórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí èèyàn, ó lè jẹ́ pé òun ni Agbọ̀rọ̀sọ fún Ọlọ́run tó ń fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìtọ́ni títí wọ́n fi la aginjù já. (Jòh. 1:1; Ẹ́kís. 23:20-23) Àmọ́, wọ́n “gba Òfin gẹ́gẹ́ bí a ti ta á látaré nípasẹ̀ àwọn áńgẹ́lì ṣùgbọ́n [wọn] kò pa á mọ́.” (Ìṣe 7:53; Héb. 2:2, 3) Àní, àwọn aṣáájú ìsìn Júù ọ̀rúndún kìíní pàápàá kùnà láti fòye mọ ohun tí Òfin Mósè túmọ̀ sí. Àpẹẹrẹ kan ni ti òfin Sábáàtì. (Ka Máàkù 3:4-6.) Àwọn akọ̀wé àtàwọn Farisí ò ka “àwọn ọ̀ràn wíwúwo jù lọ nínú Òfin sí, èyíinì ni, ìdájọ́ òdodo àti àánú àti ìṣòtítọ́.” (Mát. 23:23) Síbẹ̀ Jésù ò wò wọ́n bí ẹni tí ọ̀rọ̀ wọn ti kọjá àtúnṣe, ó sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wọn.

8. Kí nìdí tí Jésù fi lè ràn wá lọ́wọ́?

8 Jésù múra tán láti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Ìfẹ́ tó ní sáwọn èèyàn máa ń mú kó ṣàánú wọn, ó sì máa ń wù ú látọkànwá láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Kò fìgbà kan dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìjíhìnrere. Nítorí pé Jésù jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà nígbà tó wà láyé, ó “di ẹni tí ó ní ẹrù iṣẹ́ fún mímú ìgbàlà àìnípẹ̀kun wá fún gbogbo àwọn tí ń ṣègbọràn sí i.” Láfikún sí i, “níwọ̀n bí òun fúnra rẹ̀ ti jìyà nígbà tí a ń dán an wò, ó lè wá ṣe àrànṣe fún àwọn [bíi tiwa] tí a ń dán wò.”—Héb. 2:18; 5:8, 9.

Olùkọ́ Tó Gba Ìdálẹ́kọ̀ọ́ Dáadáa

9, 10. Irú ìdálẹ́kọ̀ọ́ wo ni Jésù gbà kó tó di pé Jèhófà rán an wá sáyé?

9 Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣètò pé káwọn Kristẹni tí wọ́n ń rán jáde lóde òní gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n tó dẹni tá a rán jáde bíi míṣọ́nnárì. Ǹjẹ́ Jésù Kristi náà tiẹ̀ gba ìdálẹ́kọ̀ọ́? Bẹ́ẹ̀ ni, àmọ́ kò lọ sílé ẹ̀kọ́ àwọn rábì kó tó di pé Ọlọ́run yàn án gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà; kò sì gba ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ gbajúmọ̀ aṣáájú ìsìn èyíkéyìí. (Jòh. 7:15; fi wé Ìṣe 22:3.) Báwo wá ni Jésù ṣe tóótun láti kọ́ni?

10 Lóòótọ́, Jésù kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ Màríà ìyá rẹ̀ àti Jósẹ́fù tó jẹ́ alágbàtọ́ rẹ̀, àmọ́, ọ̀dọ̀ Jèhófà, ẹni tó tóótun jù lọ, ló ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó ṣe pàtàkì fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi sọ pé: “Èmi kò sọ̀rọ̀ láti inú agbára ìsúnniṣe ti ara mi, ṣùgbọ́n Baba fúnra rẹ̀ tí ó rán mi ti fún mi ní àṣẹ kan ní ti ohun tí èmi yóò wí àti ohun tí èmi yóò sọ.” (Jòh. 12:49) Ẹ kíyè sí i pé Jèhófà fún Ọmọ rẹ̀ ní ìtọ́ni nípa àwọn ohun tó máa fi kọ́ni. Kí Jésù tó wá sáyé, ó lo ọ̀pọ̀ àkókò pẹ̀lú Bàbá rẹ̀ láti fi gba ìtọ́ni lọ́dọ̀ rẹ̀. Àbí ẹ̀kọ́ míì wà tó tún jùyẹn lọ?

11. Báwo ni Jésù ṣe fara wé Bàbá rẹ̀ tó nínú bó ṣe ń bá àwọn èèyàn lò?

11 Àjọṣe tímọ́tímọ́ wà láàárín Ọlọ́run àti Jésù Ọmọ rẹ̀ látìgbà tó ti dá a. Kó tó di pé Jésù wá sáyé gẹ́gẹ́ bí èèyàn, ó mọ bí Ọlọ́run ṣe ń bá àwọn èèyàn lò nípa wíwo ọwọ́ tí Jèhófà fi mú wọn. Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn gan-an bí Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn, débi pé nígbà tí Bíbélì ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n, ó sọ pé: “Àwọn ohun tí mo . . . ní ìfẹ́ni sí jẹ́ sípa àwọn ọmọ ènìyàn.”—Òwe 8:22, 31.

12, 13. (a) Ọ̀nà wo ni Jésù gbà kẹ́kọ̀ọ́ látinú bí Bàbá rẹ̀ ṣe ń bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò? (b) Báwo ni Jésù ṣe fi ẹ̀kọ́ tó kọ́ sílò?

12 Jésù tún kẹ́kọ̀ọ́ nínú bó ṣe ń rí bí Bàbá rẹ̀ ṣe ń bójú tó onírúurú ìṣòro. Bí àpẹẹrẹ, wo bí Jèhófà ṣe bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì aláìgbọràn lò. Nehemáyà 9:28 sọ pé: “Ní gbàrà tí wọ́n bá ti wà nínú ìsinmi, wọn a tún ṣe ohun tí ó burú níwájú rẹ [Jèhófà], ìwọ a sì fi wọ́n sílẹ̀ sọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn, tí yóò tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọn a padà, wọn a sì ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́, ìwọ alára a sì gbọ́ láti ọ̀run, ìwọ a sì dá wọn nídè ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pọ̀ yanturu àánú rẹ, léraléra.” Bí Jésù ṣe bá Jèhófà ṣiṣẹ́, tó sì kíyè sí bó ṣe ń ṣe nǹkan, mú kí òun náà ṣojú àánú sáwọn èèyàn níbi tó ti ń wàásù, ìyẹn nílẹ̀ Ísírẹ́lì.—Jòh. 5:19.

13 Jésù ò kanra mọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ rárá, èyí sì fi hàn pé ó fi ẹ̀kọ́ tó kọ́ sílò. Lálẹ́ ọjọ́ tó ku ọ̀la kí wọ́n pa á, gbogbo àwọn àpọ́sítélì tó fẹ́ràn gan-an “pa á tì, wọ́n sì sá lọ.” (Mát. 26:56; Jòh. 13:1) Àní, àpọ́sítélì Pétérù tiẹ̀ sẹ́ Kristi lẹ́ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀! Síbẹ̀, Jésù ṣe ohun tí àwọn àpọ́sítélì á fi lè padà sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó sọ fún Pétérù pé: “Ṣùgbọ́n èmi ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ nítorí rẹ, kí ìgbàgbọ́ rẹ má bàa yẹ̀; àti ìwọ, ní gbàrà tí o bá ti padà, fún àwọn arákùnrin rẹ lókun.” (Lúùkù 22:32) “Àwọn àpọ́sítélì àti àwọn wòlíì” ló sì wá di ìpìlẹ̀ Ísírẹ́lì Ọlọ́run, orúkọ àwọn àpọ́sítélì méjìlá ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, Jésù Kristi, sì tún wà lára àwọn òkúta tí wọ́n fi ṣe ìpìlẹ̀ odi tó yí Jerúsálẹ́mù Tuntun ká. Títí dòní, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn, ìyẹn àwọn “àgùntàn mìíràn,” ń ṣàṣeyọrí nínú iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Wọ́n ń ṣe iṣẹ́ náà nípa ọwọ́ agbára ńlá Ọlọ́run àti ìtọ́sọ́nà Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n.—Éfé. 2:20; Jòh. 10:16; Ìṣí. 21:14.

Ọ̀nà Tí Jésù Gbà Kọ́ni

14, 15. Báwo ni ọ̀nà tí Jésù gbà ń kọ́ni ṣe yàtọ̀ sí tàwọn akọ̀wé àtàwọn Farisí?

14 Báwo ni Jésù ṣe fi ohun tó ti kọ́ sílò nígbà tó ń kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀? Tá a bá fi ọ̀nà tí Jésù gbà ń kọ́ àwọn èèyàn wé tàwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù, kedere la óò rí i pé ọ̀nà tí Jésù gbà kọ́ àwọn èèyàn ta yọ. Àwọn akọ̀wé àtàwọn Farisí “sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di aláìlẹ́sẹ̀nílẹ̀ nítorí òfin àtọwọ́dọ́wọ́ [wọn].” Àmọ́ ti Jésù yàtọ̀, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló fi ń kọ́ni, kì í ṣe ọ̀rọ̀ tara rẹ̀. (Mát. 15:6; Jòh. 14:10) Ohun tó yẹ káwa náà máa ṣe nìyẹn.

15 Ohun míì tún wà tó mú kí Jésù yàtọ̀ pátápátá sáwọn aṣáájú ẹ̀sìn. Ó sọ nípa àwọn akọ̀wé àtàwọn Farisí pé: “Gbogbo ohun tí wọ́n bá sọ fún yín, ni kí ẹ ṣe kí ẹ sì pa mọ́, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe gẹ́gẹ́ bí àwọn ìṣe wọn, nítorí wọn a máa wí, ṣùgbọ́n wọn kì í ṣe.” (Mát. 23:3) Ohun tí Jésù fi kọ́ni ló ń hù níwà. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan to fi hàn pé òótọ́ lohun tá a sọ yìí.

16. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Jésù ṣe ohun tó sọ nínú Mátíù 6:19-21?

16 Jésù rọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n “to ìṣúra jọ pa mọ́ . . . ní ọ̀run.” (Ka Mátíù 6:19-21.) Ǹjẹ́ Jésù fúnra rẹ̀ ṣe ohun tó sọ yìí? Bẹ́ẹ̀ ni, torí ó sọ gbangba gbàǹgbà nípa ara rẹ̀ pé: “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ibi wíwọ̀sí, ṣùgbọ́n Ọmọ ènìyàn kò ní ibì kankan láti gbé orí rẹ̀ lé.” (Lúùkù 9:58) Jésù ò kó ọrọ̀ jọ. Iṣẹ́ kíkéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ló gbájú mọ́, ọ̀nà tó sì gbà gbé ìgbésí ayé rẹ̀ jẹ́ ká mọ béèyàn ṣe lè bọ́ lọ́wọ́ àníyàn tó ń báni téèyàn bá ń to ọrọ̀ jọ sórí ilẹ̀ ayé. Jésù sọ bó ṣe ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn to ìṣúra pa mọ́ sí ọ̀run, “níbi tí òólá tàbí ìpẹtà kò lè jẹ nǹkan run, àti níbi tí àwọn olè kò lè fọ́lé, kí wọ́n sì jalè.” Ǹjẹ́ ò ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù pé kó o to ìṣúra pa mọ́ sí ọ̀run?

Àwọn Ànímọ́ Tó Mú Káwọn Èèyàn Sún Mọ́ Jésù

17. Àwọn ànímọ́ wo ló mú kí Jésù jẹ́ ajíhìnrere tó ta yọ?

17 Àwọn ànímọ́ wo ló mú kí Jésù jẹ́ ajíhìnrere tó ta yọ? Ọ̀kan nínú rẹ̀ ni bó ṣe hùwà sáwọn tó ràn lọ́wọ́. Ìrẹ̀lẹ̀, ìfẹ́ àti àánú wà lára àwọn ànímọ́ Jèhófà tí Jésù ní. Wo báwọn ànímọ́ dáadáa wọ̀nyí ṣe jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn sún mọ́ Jésù.

18. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Jésù lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀?

18 Nígbà tí Jésù fẹ́ wá ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an láyé, ó “sọ ara rẹ̀ di òfìfo, ó sì gbé ìrísí ẹrú wọ̀, ó sì wá wà ní ìrí ènìyàn.” (Fílí. 2:7) Ìyẹn fi hàn pé ó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Jésù ò tún fojú pa àwọn èèyàn rẹ́. Kì í sọ pé: ‘Ọ̀run ni mo ti wá, ẹ gbọ́dọ̀ gbọ́ tèmi.’ Jésù ò dà bí àwọn èké èèyàn tó ń pe ara wọn ní Mèsáyà, kò polongo ara rẹ̀ pé òun ni Mèsáyà tòótọ́. Nígbà míì, ó máa ń sọ fáwọn èèyàn pé kí wọ́n má sọ ẹni tóun jẹ́ àti ohun tí òun ṣe. (Mát. 12:15-21) Jésù fẹ́ kó jẹ́ pé ohun táwọn èèyàn bá fojú ara wọn rí ló máa jẹ́ kí wọ́n pinnu láti máa tọ òun lẹ́yìn. Jésù ò retí pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun dà bí àwọn áńgẹ́lì pípé tí wọ́n jọ ń gbé lọ́run. Ẹ ò rí i pé ìyẹn máa fún wọn níṣìírí gan-an!

19, 20. Báwo ni ìfẹ́ àti àánú ṣe mú kí Jésù ran àwọn èèyàn lọ́wọ́?

19 Jésù Kristi tún fi ìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, ìyẹn sì ni ànímọ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ tí Bàbá rẹ̀ ọ̀run ní. (1 Jòh. 4:8) Jésù kọ́ àwọn èèyàn nítorí ìfẹ́ tó ní sí wọn. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo ọwọ́ tó fi mú ọ̀dọ́ kan tó jẹ́ alákòóso. (Ka Máàkù 10:17-22.) Jésù “ní ìfẹ́ fún un” ó sì fẹ́ ràn án lọ́wọ́, àmọ́, ọ̀dọ́ tó jẹ́ alákòóso yìí kò fi ọ̀pọ̀ ohun ìní tó ní sílẹ̀ kó lè di ọmọ ẹ̀yìn Kristi.

20 Àánú tún wà lára àwọn ànímọ́ tó mú káwọn èèyàn sún mọ́ Jésù. Gbogbo èèyàn aláìpé ló níṣòro, nítorí náà, àwọn tó kọbi ara sí ẹ̀kọ́ Jésù náà níṣòro tiwọn. Níwọ̀n bí Jésù sì ti mọ èyí, ó lo ìyọ́nú àti àánú nígbà tó ń kọ́ wọn. Àpẹẹrẹ kan rèé: Lọ́jọ́ kan, ọwọ́ Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ dí débi pé àyè oúnjẹ ò yọ rárá. Àmọ́, kí ni Jésù ṣe nígbà tó rí ogunlọ́gọ̀ èèyàn tó ń dúró dè é? “Àánú wọ́n ṣe é, nítorí wọ́n dà bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn ní ohun púpọ̀.” (Máàkù 6:34) Jésù kíyè sí ipò tó ń ṣeni láàánú táwọn èèyàn níbi tó ti ń wàásù wà, ìyẹn jẹ́ kó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti kọ́ wọn, ó sì tún ṣe iṣẹ́ ìyanu nítorí tiwọn. Àwọn ànímọ́ dáadáa tó ní fa àwọn kan sún mọ́ ọn, ọ̀rọ̀ tó sọ wọ̀ wọ́n lọ́kàn, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ di ọmọlẹ́yìn rẹ̀.

21. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí?

21 Ọ̀pọ̀ nǹkan ṣì wà tá a lè kọ́ látinú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù lórí ilẹ̀ ayé bá a ṣe máa rí i nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí. Àwọn ọ̀nà míì wo la tún lè gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù Kristi, Míṣọ́nnárì tó ta yọ?

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Ìdálẹ́kọ̀ọ́ wo ni Jésù gbà kó tó wá sáyé?

• Báwo ni ọ̀nà tí Jésù gbà ń kọ́ àwọn èèyàn ṣe ta yọ tàwọn akọ̀wé àtàwọn Farisí?

• Àwọn ànímọ́ wo ló mú káwọn èèyàn sún mọ́ Jésù?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Báwo ni Jésù ṣe kọ́ ogunlọ́gọ̀ èèyàn?