Àkọsílẹ̀ Lúùkù 9:1-62

 • Ó fún àwọn Méjìlá náà ní ìtọ́ni nípa iṣẹ́ ìwàásù (1-6)

 • Ìdààmú bá Hẹ́rọ́dù torí Jésù (7-9)

 • Jésù bọ́ 5,000 èèyàn (10-17)

 • Pétérù pè é ní Kristi (18-20)

 • Àsọtẹ́lẹ̀ nípa ikú Jésù (21, 22)

 • Ojúlówó ọmọ ẹ̀yìn (23-27)

 • A yí Jésù pa dà di ológo (28-36)

 • Ó wo ọmọkùnrin tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu sàn (37-43a)

 • Jésù tún sọ tẹ́lẹ̀ nípa ikú rẹ̀  (43b-45)

 • Àwọn ọmọ ẹ̀yìn ń jiyàn nípa ẹni tó tóbi jù (46-48)

 • Ẹni tí kò bá ta kò wá, tiwa ló ń ṣe (49, 50)

 • Àwọn ará abúlé kan ní Samáríà kọ Jésù (51-56)

 • Bí a ṣe lè tẹ̀ lé Jésù (57-62)

9  Ó wá pe àwọn Méjìlá náà jọ, ó fún wọn ní agbára àti àṣẹ lórí gbogbo ẹ̀mí èṣù,+ kí wọ́n sì máa ṣe ìwòsàn.+  Ó rán wọn jáde láti wàásù Ìjọba Ọlọ́run, kí wọ́n sì máa múni lára dá,  ó sọ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe gbé ohunkóhun dání fún ìrìn àjò náà, ì báà jẹ́ ọ̀pá, àpò oúnjẹ, oúnjẹ tàbí owó;* ẹ má sì mú aṣọ méjì.*+  Àmọ́ ibikíbi tí ẹ bá ti wọ ilé kan, ẹ dúró síbẹ̀, kí ẹ sì lọ láti ibẹ̀.+  Ibikíbi tí àwọn èèyàn ò bá sì ti gbà yín, tí ẹ bá ń kúrò ní ìlú yẹn, ẹ gbọn iyẹ̀pẹ̀ ẹsẹ̀ yín dà nù, kó lè jẹ́ ẹ̀rí lòdì sí wọn.”+  Lẹ́yìn náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í lọ káàkiri agbègbè náà láti abúlé dé abúlé, wọ́n ń kéde ìhìn rere, wọ́n sì ń ṣe ìwòsàn níbi gbogbo.+  Hẹ́rọ́dù* alákòóso agbègbè náà* wá gbọ́ gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ọkàn rẹ̀ ò sì balẹ̀ rárá torí àwọn kan ń sọ pé a ti jí Jòhánù dìde,+  àmọ́ àwọn míì ń sọ pé Èlíjà ti fara hàn, àwọn míì sì ń sọ pé ọ̀kan nínú àwọn wòlíì àtijọ́ ti dìde.+  Hẹ́rọ́dù sọ pé: “Mo ti bẹ́ Jòhánù lórí.+ Ta wá ni ẹni tí mò ń gbọ́ àwọn nǹkan yìí nípa rẹ̀?” Torí náà, ó ń wá bó ṣe máa rí i.+ 10  Nígbà tí àwọn àpọ́sítélì dé, wọ́n ròyìn gbogbo ohun tí wọ́n ṣe fún Jésù.+ Ó wá mú wọn lọ, wọ́n sì kúrò níbẹ̀ láwọn nìkan lọ sí ìlú kan tó ń jẹ́ Bẹtisáídà.+ 11  Àmọ́ nígbà tí àwọn èrò mọ̀ nípa rẹ̀, wọ́n tẹ̀ lé e. Ó gbà wọ́n tinútinú, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í bá wọn sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run, ó sì ṣe ìwòsàn fún àwọn tó nílò ìwòsàn.+ 12  Ọjọ́ ti ń lọ. Àwọn méjìlá náà wá bá a, wọ́n sì sọ fún un pé: “Ní kí àwọn èrò náà máa lọ, kí wọ́n lè lọ sínú àwọn abúlé àti ìgbèríko tó wà ní àyíká, kí wọ́n lè ríbi dé sí, kí wọ́n sì lè rí oúnjẹ tí wọ́n máa jẹ, torí ibi tó dá la wà yìí.”+ 13  Àmọ́ ó sọ fún wọn pé: “Ẹ fún wọn ní nǹkan tí wọ́n máa jẹ.”+ Wọ́n sọ pé: “A ò ní ju búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja méjì, àfi bóyá tí àwa fúnra wa bá lọ ra oúnjẹ fún gbogbo àwọn èèyàn yìí.” 14  Ní tòótọ́, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin ni wọ́n. Àmọ́ ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ní kí wọ́n jókòó ní àwùjọ-àwùjọ, kí àwùjọ kọ̀ọ̀kan jẹ́ nǹkan bí àádọ́ta (50) èèyàn.” 15  Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n sì ní kí gbogbo wọn jókòó. 16  Lẹ́yìn náà, ó mú búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja méjì náà, ó wo ojú ọ̀run, ó sì súre sórí wọn. Ó wá bù ú sí wẹ́wẹ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn pé kí wọ́n gbé e síwájú àwọn èrò náà. 17  Torí náà, gbogbo wọn jẹ, wọ́n yó, wọ́n sì kó èyí tó ṣẹ́ kù jọ, ó kún apẹ̀rẹ̀ méjìlá (12).+ 18  Lẹ́yìn náà, bó ṣe ń dá gbàdúrà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá bá a, ó sì bi wọ́n pé: “Ta ni àwọn èèyàn ń sọ pé mo jẹ́?”+ 19  Wọ́n fèsì pé: “Jòhánù Arinibọmi, àmọ́ àwọn míì ń sọ pé Èlíjà, àwọn míì sì ń sọ pé ọ̀kan lára àwọn wòlíì àtijọ́ ti dìde.”+ 20  Ó wá bi wọ́n pé: “Ẹ̀yin ńkọ́, ta lẹ sọ pé mo jẹ́?” Pétérù dáhùn pé: “Kristi ti Ọlọ́run.”+ 21  Àmọ́ ó kìlọ̀ fún wọn gidigidi, ó sọ fún wọn pé kí wọ́n má sọ èyí fún ẹnì kankan,+ 22  ó sì sọ pé: “Ọmọ èèyàn gbọ́dọ̀ jìyà púpọ̀, àwọn àgbààgbà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin máa kọ̀ ọ́, wọ́n máa pa á,+ a sì máa jí i dìde ní ọjọ́ kẹta.”+ 23  Ó wá sọ fún gbogbo wọn pé: “Tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ máa tẹ̀ lé mi, kó sẹ́ ara rẹ̀,+ kó máa gbé òpó igi oró* rẹ̀ lójoojúmọ́, kó sì máa tẹ̀ lé mi.+ 24  Torí ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ gba ẹ̀mí* rẹ̀ là máa pàdánù rẹ̀, àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá pàdánù ẹ̀mí* rẹ̀ nítorí mi ni ẹni tó máa gbà á là.+ 25  Lóòótọ́, àǹfààní wo ni èèyàn máa rí tó bá jèrè gbogbo ayé, àmọ́ tó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ tàbí tó pa run?+ 26  Torí ẹnikẹ́ni tó bá tijú èmi àti àwọn ọ̀rọ̀ mi, Ọmọ èèyàn máa tijú ẹni yẹn nígbà tó bá dé nínú ògo rẹ̀ àti ti Baba àti ti àwọn áńgẹ́lì mímọ́.+ 27  Àmọ́ mò ń sọ fún yín ní tòótọ́ pé, àwọn kan wà lára àwọn tó dúró síbí yìí tí kò ní tọ́ ikú wò rárá títí wọ́n á fi kọ́kọ́ rí Ìjọba Ọlọ́run.”+ 28  Lóòótọ́, ní nǹkan bí ọjọ́ mẹ́jọ lẹ́yìn tó sọ ọ̀rọ̀ yìí, ó mú Pétérù, Jòhánù àti Jémíìsì dání, ó sì gun òkè lọ láti gbàdúrà.+ 29  Bó ṣe ń gbàdúrà, ìrísí ojú rẹ̀ yí pa dà, aṣọ rẹ̀ sì di funfun, ó ń tàn yinrin. 30  Wò ó! ọkùnrin méjì ń bá a sọ̀rọ̀; Mósè àti Èlíjà ni. 31  Àwọn yìí fara hàn nínú ògo, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ nípa lílọ rẹ̀, èyí tó máa tó mú ṣẹ ní Jerúsálẹ́mù.+ 32  Oorun ń kun Pétérù àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ gidigidi, àmọ́ nígbà tí oorun dá lójú wọn, wọ́n rí ògo rẹ̀+ àti ọkùnrin méjì tó dúró pẹ̀lú rẹ̀. 33  Bí àwọn yìí sì ṣe ń kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, Pétérù sọ fún Jésù pé: “Olùkọ́, ó dáa bí a ṣe wà níbí. Torí náà, jẹ́ ká pa àgọ́ mẹ́ta, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún Mósè àti ọ̀kan fún Èlíjà.” Kò mọ ohun tó ń sọ. 34  Àmọ́ bó ṣe ń sọ àwọn nǹkan yìí, ìkùukùu* kóra jọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣíji bò wọ́n. Bí wọ́n ṣe wọnú ìkùukùu náà, ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí í bà wọ́n. 35  Ohùn kan+ wá dún látinú ìkùukùu náà pé: “Èyí ni Ọmọ mi, ẹni tí mo ti yàn.+ Ẹ fetí sí i.”+ 36  Bí ohùn náà ṣe sọ̀rọ̀, Jésù nìkan ṣoṣo ni wọ́n rí. Àmọ́ wọ́n dákẹ́, wọn ò sì sọ ìkankan nínú àwọn ohun tí wọ́n rí fún ẹnì kankan ní àwọn ọjọ́ yẹn.+ 37  Lọ́jọ́ kejì, nígbà tí wọ́n sọ̀ kalẹ̀ látorí òkè náà, èrò rẹpẹtẹ pàdé rẹ̀.+ 38  Wò ó! ọkùnrin kan ké jáde láti àárín èrò náà pé: “Olùkọ́, mo bẹ̀ ọ́, wo ọmọkùnrin mi, torí òun nìkan ṣoṣo ni mo bí.+ 39  Wò ó! ẹ̀mí kan máa ń gbé e, á sì kígbe lójijì, á fi gìrì mú un, á sì máa yọ ìfófòó lẹ́nu, agbára káká ló fi máa ń fi í sílẹ̀ lẹ́yìn tó bá ti ṣe é léṣe. 40  Mo bẹ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ pé kí wọ́n lé e jáde, àmọ́ wọn ò lè ṣe é.” 41  Jésù fèsì pé: “Ìran aláìnígbàgbọ́ àti oníbékebèke,+ títí dìgbà wo ni màá fi wà pẹ̀lú yín, tí màá sì máa fara dà á fún yín? Mú ọmọkùnrin rẹ wá síbí.”+ 42  Àmọ́ bó ṣe ń sún mọ́ tòsí pàápàá, ẹ̀mí èṣù náà gbé e ṣánlẹ̀, ó sì fi gìrì mú un lọ́nà tó le gan-an. Ṣùgbọ́n Jésù bá ẹ̀mí àìmọ́ náà wí, ó wo ọmọ náà sàn, ó sì dá a pa dà fún bàbá rẹ̀. 43  Ẹnu sì ya gbogbo wọn sí agbára ńlá Ọlọ́run. Bí ẹnu ṣe ń ya gbogbo wọn sí gbogbo ohun tó ń ṣe, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: 44  “Ẹ fetí sílẹ̀ dáadáa, kí ẹ sì máa rántí àwọn ọ̀rọ̀ yìí, torí a máa fi Ọmọ èèyàn lé àwọn èèyàn lọ́wọ́.”+ 45  Àmọ́ ohun tó ń sọ kò yé wọn. Ní tòótọ́, a fi pa mọ́ fún wọn kó má bàa yé wọn, ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti bi í nípa ọ̀rọ̀ yìí. 46  Lẹ́yìn náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bára wọn jiyàn nípa ẹni tó tóbi jù nínú wọn.+ 47  Jésù mọ ohun tí wọ́n ń rò lọ́kàn, ó wá mú ọmọ kékeré kan, ó mú un dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara rẹ̀, 48  ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá gba ọmọ kékeré yìí nítorí orúkọ mi gba èmi náà; ẹnikẹ́ni tó bá sì gbà mí gba Ẹni tó rán mi pẹ̀lú.+ Torí ẹni tó bá hùwà bí ẹni tó kéré láàárín gbogbo yín ni ẹni tó tóbi.”+ 49  Jòhánù fèsì pé: “Olùkọ́, a rí ẹnì kan tó ń fi orúkọ rẹ lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, a sì gbìyànjú láti dá a dúró, torí kì í tẹ̀ lé wa.”+ 50  Àmọ́ Jésù sọ fún un pé: “Ẹ má gbìyànjú láti dá a dúró, torí ẹnikẹ́ni tí kò bá ta kò yín, tiyín ló ń ṣe.” 51  Bí àwọn ọjọ́ tí a máa gbé e lọ sókè ṣe ń sún mọ́lé,*+ ó pinnu lọ́kàn rẹ̀ láti lọ sí* Jerúsálẹ́mù. 52  Torí náà, ó ní kí àwọn ìránṣẹ́ lọ ṣáájú rẹ̀. Wọ́n sì lọ, wọ́n wọnú abúlé kan tó jẹ́ ti àwọn ará Samáríà kí wọ́n lè múra sílẹ̀ fún un. 53  Àmọ́ wọn ò tẹ́wọ́ gbà á,+ torí ó ti pinnu* láti lọ sí Jerúsálẹ́mù. 54  Nígbà tí Jémíìsì àti Jòhánù,+ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, rí èyí, wọ́n sọ pé: “Olúwa, ṣé o fẹ́ ká pe iná sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run, kó sì pa wọ́n run?”+ 55  Àmọ́ ó yíjú pa dà, ó sì bá wọn wí. 56  Torí náà, wọ́n lọ sí abúlé míì. 57  Bí wọ́n ṣe ń lọ lójú ọ̀nà, ẹnì kan sọ fún un pé: “Màá tẹ̀ lé ọ lọ ibikíbi tí o bá lọ.” 58  Àmọ́ Jésù sọ fún un pé: “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ìtẹ́, àmọ́ Ọmọ èèyàn kò ní ibì kankan tó máa gbé orí rẹ̀ lé.”+ 59  Lẹ́yìn náà, ó sọ fún ẹlòmíì pé: “Máa tẹ̀ lé mi.” Ọkùnrin náà sọ pé: “Olúwa, gbà mí láyè kí n kọ́kọ́ lọ sìnkú bàbá mi.”+ 60  Àmọ́ ó sọ fún un pé: “Jẹ́ kí àwọn òkú+ máa sin òkú wọn, àmọ́ ìwọ lọ, kí o sì máa kéde Ìjọba Ọlọ́run káàkiri.”+ 61  Ẹlòmíì tún sọ pé: “Màá tẹ̀ lé ọ, Olúwa, àmọ́ kọ́kọ́ gbà mí láyè láti dágbére fún àwọn ará ilé mi pé ó dìgbòóṣe.” 62  Jésù sọ fún un pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá fi ọwọ́ rẹ̀ lé ohun ìtúlẹ̀, tó wá wo àwọn ohun tó wà lẹ́yìn,+ kò yẹ fún Ìjọba Ọlọ́run.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “aṣọ míì.”
Ní Grk., “fàdákà.”
Ìyẹn, Hẹ́rọ́dù Áńtípà. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Grk., “alákòóso ìdá mẹ́rin.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “àwọsánmà.”
Ní Grk., “ṣe ń pé bọ̀.”
Ní Grk., “ó gbé ojú rẹ̀ sọ́nà.”
Ní Grk., “ojú rẹ̀ ti wà lọ́nà.”