Sí Àwọn Ará Éfésù 2:1-22

  • Ọlọ́run sọ wọ́n di ààyè pẹ̀lú Kristi (1-10)

  • A wó ògiri tó pààlà (11-22)

2  Síwájú sí i, Ọlọ́run sọ yín di ààyè, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ ti kú nínú àṣemáṣe àti ẹ̀ṣẹ̀ yín,+  nínú èyí tí ẹ ti rìn nígbà kan rí lọ́nà ti ètò àwọn nǹkan* ayé yìí,+ lọ́nà ti ẹni tó ń darí àṣẹ afẹ́fẹ́,+ ẹ̀mí+ tó ń ṣiṣẹ́ nísinsìnyí nínú àwọn ọmọ aláìgbọràn.  Òótọ́ ni pé gbogbo wa ti wà láàárín wọn rí, tí à ń hùwà lọ́nà ti ara wa,+ tí à ń ṣe ohun tí ara wa fẹ́ àti èyí tí ọkàn wa rò,+ a sì jẹ́ ọmọ ìrunú+ bíi ti àwọn yòókù látìgbà tí wọ́n ti bí wa.  Àmọ́ Ọlọ́run, tí àánú rẹ̀ pọ̀,+ nítorí ìfẹ́ ńlá tó ní sí wa,+  sọ wá di ààyè pẹ̀lú Kristi, kódà nígbà tí a kú nínú àwọn àṣemáṣe wa,+ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ mú kí ẹ rí ìgbàlà.  Yàtọ̀ síyẹn, ó gbé wa dìde pa pọ̀, ó sì mú wa jókòó pa pọ̀ ní àwọn ibi ọ̀run ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù,+  pé nínú àwọn ètò àwọn nǹkan* tó ń bọ̀, kó lè fi ọrọ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ tí ó ta yọ hàn nínú oore ọ̀fẹ́* rẹ̀ sí wa nínú Kristi Jésù.  Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí yìí ti mú kí ẹ rí ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́,+ èyí kì í ṣe nípa agbára yín; ẹ̀bùn Ọlọ́run ni.  Bẹ́ẹ̀ ni, kì í ṣe nípa iṣẹ́,+ kí ẹnì kankan má bàa ní ìdí láti máa yangàn. 10  Iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọ́run ni wá,* ó dá wa+ ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù+ ká lè ṣe àwọn iṣẹ́ rere, tí Ọlọ́run ti ṣètò sílẹ̀ fún wa láti máa ṣe. 11  Nítorí náà, ẹ rántí pé nígbà kan, ẹ̀yin tí ẹ wá látinú àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè, ẹ̀yin ni àwọn tó dádọ̀dọ́* nínú ara látọwọ́ èèyàn ń pè ní aláìdádọ̀dọ́.* 12  Lákòókò yẹn, ẹ ò ní Kristi, ẹ sì jẹ́ àjèjì sí àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Ísírẹ́lì, ẹ tún jẹ́ àjèjì sí àwọn májẹ̀mú ìlérí náà;+ ẹ ò nírètí, ẹ ò sì ní Ọlọ́run nínú ayé.+ 13  Àmọ́ ní báyìí, tí ẹ wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù, ẹ̀yin tí ẹ ti fìgbà kan jìnnà réré ti wá wà nítòsí nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Kristi. 14  Nítorí òun ni àlàáfíà wa,+ ẹni tó ṣe àwùjọ méjèèjì ní ọ̀kan,+ tó sì wó ògiri tó pààlà sáàárín wọn.+ 15  Ó lo ẹran ara rẹ̀ láti fòpin sí ọ̀tá náà, ìyẹn, Òfin tí àwọn àṣẹ àti ìlànà wà nínú rẹ̀, kí ó lè mú kí àwùjọ méjèèjì ṣọ̀kan pẹ̀lú ara rẹ̀, kí wọ́n lè di ẹni tuntun kan,+ kí ó sì mú àlàáfíà wá 16  àti pé kí ó lè mú àwùjọ méjèèjì wá sínú ara kan láti pa dà bá Ọlọ́run rẹ́ ní kíkún nípasẹ̀ òpó igi oró,*+ nítorí ó ti fúnra rẹ̀ pa ọ̀tá náà.+ 17  Ó sì wá kéde ìhìn rere àlàáfíà fún ẹ̀yin tí ẹ jìnnà réré àti àlàáfíà fún àwọn tó wà nítòsí, 18  torí ipasẹ̀ rẹ̀ ni àwa àwùjọ méjèèjì fi lè wọlé sọ́dọ̀ Baba nípasẹ̀ ẹ̀mí kan. 19  Nítorí náà, ẹ kì í ṣe àjèjì tàbí ọmọ ilẹ̀ òkèèrè mọ́,+ àmọ́ ẹ jẹ́ aráàlú+ pẹ̀lú àwọn ẹni mímọ́, ẹ sì jẹ́ ara agbo ilé Ọlọ́run,+ 20  a sì ti kọ́ yín sórí ìpìlẹ̀ àwọn àpọ́sítélì àti àwọn wòlíì,+ nígbà tí Kristi Jésù fúnra rẹ̀ jẹ́ òkúta ìpìlẹ̀ igun ilé.+ 21  Ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀, gbogbo ilé náà, bó ṣe so pọ̀ di ọ̀kan,+ ń dàgbà di tẹ́ńpìlì mímọ́ fún Jèhófà.*+ 22  Ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀, à ń kọ́ ẹ̀yin náà pa pọ̀ láti di ibi tí Ọlọ́run á máa gbé nípasẹ̀ ẹ̀mí.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ipa ọ̀nà.”
Tàbí “àwọn àsìkò.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “inú rere.”
Tàbí “Àwa jẹ́ iṣẹ́ Rẹ̀.”
Tàbí “kọlà.”
Tàbí “aláìkọlà.”