Ìwé Kìíní sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì 13:1-13

  • Ìfẹ́ jẹ́ ọ̀nà tó ta yọ (1-13)

13  Tí mo bá ń fi èdè* èèyàn àti ti àwọn áńgẹ́lì sọ̀rọ̀ àmọ́ tí mi ò ní ìfẹ́, mo ti di abala idẹ tó ń dún tàbí síńbálì* olóhùn gooro.  Tí mo bá sì ní ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀, tí mo lóye gbogbo àṣírí mímọ́ àti gbogbo ìmọ̀,+ tí mo ní gbogbo ìgbàgbọ́ láti ṣí àwọn òkè nípò pa dà,* àmọ́ tí mi ò ní ìfẹ́, mi ò já mọ́ nǹkan kan.*+  Tí mo bá yọ̀ǹda gbogbo nǹkan tí mo ní láti bọ́ àwọn ẹlòmíì,+ tí mo sì fi ara mi lélẹ̀ kí n lè máa yangàn, àmọ́ tí mi ò ní ìfẹ́,+ kò ṣe mí láǹfààní kankan.  Ìfẹ́+ máa ń ní sùúrù*+ àti inú rere.+ Ìfẹ́ kì í jowú,+ kì í fọ́nnu, kì í gbéra ga,+  kì í hùwà tí kò bójú mu,*+ kì í wá ire tirẹ̀ nìkan,+ kì í tètè bínú.+ Kì í di èèyàn sínú.*+  Kì í yọ̀ lórí àìṣòdodo,+ àmọ́ ó máa ń yọ̀ lórí òtítọ́.  Ó máa ń mú ohun gbogbo mọ́ra,+ ó máa ń gba ohun gbogbo gbọ́,+ ó máa ń retí ohun gbogbo,+ ó máa ń fara da ohun gbogbo.+  Ìfẹ́ kì í yẹ̀ láé. Àmọ́ tí ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀ bá wà, yóò dópin; tí àwọn ahọ́n àjèjì bá wà,* wọ́n á ṣíwọ́; tí ìmọ̀ bá wà, yóò dópin.  Nítorí a ní ìmọ̀ dé àyè kan,+ a sì ń sọ tẹ́lẹ̀ dé àyè kan, 10  àmọ́ nígbà tí èyí tó pé bá dé, èyí tó dé àyè kan yóò dópin. 11  Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, mo máa ń sọ̀rọ̀ bí ọmọdé, mò ń ronú bí ọmọdé, mo sì ń gbèrò bí ọmọdé; àmọ́ ní báyìí tí mo ti di ọkùnrin, mo ti fòpin sí àwọn ìwà ọmọdé. 12  Ní báyìí à ń ríran fírífírí* nínú dígí onírin, àmọ́ nígbà yẹn yóò jẹ́ kedere ní ojúkojú. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, mo ní ìmọ̀ dé àyè kan, àmọ́ nígbà yẹn màá ní ìmọ̀ tó péye,* bí Ọlọ́run ṣe mọ̀ mí lọ́nà tó péye. 13  Tóò, àwọn mẹ́ta tó ṣì wà nìyí: ìgbàgbọ́, ìrètí àti ìfẹ́; àmọ́ èyí tó tóbi jù lọ nínú wọn ni ìfẹ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Grk., “ahọ́n.”
Tàbí “aro.”
Tàbí “kúrò lọ sí ibòmíì.”
Tàbí “wúlò.”
Tàbí “ìpamọ́ra.”
Tàbí “Kì í kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe.”
Tàbí “ṣe ọ̀yájú.”
Ìyẹn, kéèyàn máa fi iṣẹ́ ìyanu sọ àwọn èdè míì.
Tàbí “bàìbàì.”
Tàbí “tó kún rẹ́rẹ́.”