Ẹ́kísódù 23:1-33

  • Ìdájọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa tẹ̀ lé (1-19)

    • Nípa ìṣòtítọ́ àti ìwà tó tọ́ (1-9)

    • Nípa sábáàtì àti àwọn àjọyọ̀ (10-19)

  • Áńgẹ́lì yóò máa darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì (20-26)

  • Gbígba ilẹ̀ àti ààlà (27-33)

23   “O ò gbọ́dọ̀ tan ìròyìn èké kálẹ̀.*+ Má ṣe lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú ẹni burúkú láti jẹ́rìí èké.+  O ò gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ọ̀pọ̀ èèyàn láti hùwà ibi, o ò sì gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ọ̀pọ̀ èèyàn láti jẹ́rìí èké* kí o lè yí ìdájọ́ po.  O ò gbọ́dọ̀ ṣe ojúsàájú nínú ẹjọ́ aláìní.+  “Tí o bá rí i tí akọ màlúù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ọ̀tá rẹ ń ṣìnà, kí o dá a pa dà fún un.+  Tí o bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹni tó kórìíra rẹ, tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà ṣubú tí kò sì lè dìde torí ẹrù tó gbé, o ò gbọ́dọ̀ fi sílẹ̀ lọ. Kí o bá a gbé ẹrù náà kúrò.+  “Tí aláìní kan láàárín yín bá ní ẹjọ́, má ṣe yí ìdájọ́ rẹ̀ po.+  “Má ṣe lọ́wọ́ sí ẹ̀sùn èké,* má sì pa aláìṣẹ̀ àti olódodo, torí mi ò ní pe ẹni burúkú ní olódodo.*+  “Má ṣe gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, torí àbẹ̀tẹ́lẹ̀ máa ń dí àwọn tó ríran kedere lójú, ó sì lè mú kí àwọn olódodo yí ọ̀rọ̀ po.+  “O ò gbọ́dọ̀ ni àjèjì lára. Ẹ mọ bó ṣe máa ń rí kéèyàn jẹ́ àjèjì,* torí àjèjì lẹ jẹ́ ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ 10  “Ọdún mẹ́fà ni kí o fi fún irúgbìn sí ilẹ̀ rẹ, kí o sì fi kórè èso rẹ̀.+ 11  Àmọ́ ní ọdún keje, kí o fi ilẹ̀ náà sílẹ̀ láìro, má fi dá oko. Àwọn tó jẹ́ aláìní nínú àwọn èèyàn rẹ yóò jẹ nínú rẹ̀, àwọn ẹran inú igbó yóò sì jẹ ohun tí wọ́n bá ṣẹ́ kù. Ohun tí o máa ṣe sí ọgbà àjàrà rẹ àti àwọn igi ólífì rẹ nìyẹn. 12  “Ọjọ́ mẹ́fà ni kí o máa fi ṣe iṣẹ́ rẹ; àmọ́ ní ọjọ́ keje, kí o ṣíwọ́ iṣẹ́, kí akọ màlúù rẹ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ lè sinmi, kí ara sì lè tu ọmọ ẹrúbìnrin rẹ àti àjèjì.+ 13  “Kí ẹ rí i pé ẹ ṣe gbogbo ohun tí mo sọ fún yín,+ ẹ ò sì gbọ́dọ̀ dárúkọ àwọn ọlọ́run míì; kò gbọ́dọ̀ ti ẹnu* yín jáde.+ 14  “Ẹ̀ẹ̀mẹta lọ́dún ni kí ẹ máa ṣe àjọyọ̀ fún mi.+ 15  Kí ẹ máa ṣe Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú.+ Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi jẹ búrẹ́dì aláìwú ní àkókò rẹ̀ nínú oṣù Ábíbù,*+ bí mo ṣe pa á láṣẹ fún yín, torí ìgbà yẹn lẹ kúrò ní Íjíbítì. Ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ wá síwájú mi lọ́wọ́ òfo.+ 16  Bákan náà, kí ẹ máa ṣe Àjọyọ̀ Ìkórè* àwọn èso oko yín tó kọ́kọ́ pọ́n, èyí tí ẹ ṣiṣẹ́ kára láti gbìn;+ àti Àjọyọ̀ Ìkórèwọlé* níparí ọdún, nígbà tí ẹ bá kórè gbogbo ohun tí ẹ gbìn sí oko.+ 17  Ẹ̀ẹ̀mẹta lọ́dún ni kí gbogbo ọkùnrin* yín wá síwájú Jèhófà, Olúwa tòótọ́.+ 18  “O ò gbọ́dọ̀ fi ẹ̀jẹ̀ rúbọ sí mi pa pọ̀ pẹ̀lú ohun tó ní ìwúkàrà. Ọ̀rá tí o bá fi rúbọ níbi àwọn àjọyọ̀ mi ò sì gbọ́dọ̀ ṣẹ́ kù di àárọ̀ ọjọ́ kejì. 19  “Kí o mú èyí tó dáa jù nínú àwọn èso tó kọ́kọ́ pọ́n ní ilẹ̀ rẹ wá sí ilé Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+ “O ò gbọ́dọ̀ se ọmọ ewúrẹ́ nínú wàrà ìyá rẹ̀.+ 20  “Màá rán áńgẹ́lì kan ṣáájú yín+ kó lè dáàbò bò yín lójú ọ̀nà, kó sì mú yín wá síbi tí mo ti ṣètò sílẹ̀.+ 21  Kí ẹ fetí sí i, kí ẹ sì ṣègbọràn sí ohùn rẹ̀. Ẹ má ṣọ̀tẹ̀ sí i, torí kò ní dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì,+ torí pé orúkọ mi wà lára rẹ̀. 22  Àmọ́, tí ẹ bá ṣègbọràn délẹ̀délẹ̀ sí ohùn rẹ̀, tí ẹ sì ṣe gbogbo ohun tí mo sọ, màá bá àwọn ọ̀tá yín jà, màá sì gbógun ti àwọn tó ń gbógun tì yín. 23  Torí áńgẹ́lì mi yóò ṣáájú yín, yóò sì mú yín wá sọ́dọ̀ àwọn Ámórì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Pérísì, àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì, màá sì pa wọ́n run.+ 24  Ẹ ò gbọ́dọ̀ forí balẹ̀ fún àwọn ọlọ́run wọn, ẹ má sì jẹ́ kí wọ́n mú kí ẹ sìn wọ́n, ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe àwọn ohun tí wọ́n ń ṣe.+ Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni kí ẹ wó wọn palẹ̀, kí ẹ sì run àwọn ọwọ̀n òrìṣà wọn.+ 25  Jèhófà Ọlọ́run yín ni ẹ gbọ́dọ̀ máa sìn,+ yóò sì bù kún oúnjẹ àti omi yín.+ Èmi yóò mú àìsàn kúrò láàárín yín.+ 26  Oyún kò ní bà jẹ́ lára àwọn obìnrin ilẹ̀ yín, wọn ò sì ní yàgàn.+ Màá jẹ́ kí ẹ̀mí yín gùn dáadáa.* 27  “Màá mú kí àwọn èèyàn máa bẹ̀rù mi kí ẹ tó dé ọ̀dọ̀ wọn,+ màá sì da àárín gbogbo àwọn tí ẹ bá pàdé rú. Màá mú kí ẹ ṣẹ́gun gbogbo ọ̀tá yín, wọ́n á sì sá lọ.*+ 28  Màá mú kí àwọn èèyàn rẹ̀wẹ̀sì* kí ẹ tó dé ọ̀dọ̀ wọn,+ ìrẹ̀wẹ̀sì náà yóò sì lé àwọn Hífì, àwọn ọmọ Kénáánì àti àwọn ọmọ Hétì kúrò níwájú yín.+ 29  Mi ò ní lé wọn kúrò níwájú yín láàárín ọdún kan, kí ilẹ̀ náà má bàa di ahoro, kí àwọn ẹranko búburú má bàa pọ̀ níbẹ̀ kí wọ́n sì ṣe yín lọ́ṣẹ́.+ 30  Díẹ̀díẹ̀ ni màá lé wọn kúrò níwájú yín, títí ẹ ó fi bí àwọn ọmọ, tí ẹ ó sì gba ilẹ̀ náà.+ 31  “Màá pààlà fún yín láti Òkun Pupa dé òkun àwọn Filísínì àti láti aginjù dé Odò;*+ torí màá mú kí ọwọ́ yín tẹ àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà, ẹ ó sì lé wọn kúrò níwájú yín.+ 32  Ẹ ò gbọ́dọ̀ bá àwọn èèyàn náà tàbí àwọn ọlọ́run wọn dá májẹ̀mú.+ 33  Kí wọ́n má ṣe gbé ní ilẹ̀ yín, kí wọ́n má bàa mú kí ẹ ṣẹ̀ mí. Tí ẹ bá lọ sin àwọn ọlọ́run wọn, ó dájú pé yóò di ìdẹkùn fún yín.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “gbé ìròyìn èké kiri.”
Tàbí “bá wọn jẹ́rìí èké tí ọ̀pọ̀ èèyàn fara mọ́.”
Ní Héb., “ọ̀rọ̀ èké.”
Tàbí “dá ẹni burúkú láre.”
àbí “Ẹ mọ bí ẹ̀mí (ọkàn) àjèjì ṣe máa ń rí.”
Tàbí “ètè.”
Wọ́n tún máa ń pè é ní Àjọyọ̀ Àtíbàbà (Àgọ́ Ìjọsìn).
Wọ́n tún máa ń pè é ní Àjọyọ̀ Àwọn Ọ̀sẹ̀ tàbí Pẹ́ńtíkọ́sì.
Tàbí “akọ.”
Tàbí “Màá mú kí ọjọ́ ayé yín kún.”
Tàbí “Màá mú kí gbogbo ọ̀tá yín yísẹ̀ pa dà lọ́dọ̀ yín.”
Tàbí kó jẹ́, “bẹ̀rù; wárìrì.”
Ìyẹn, odò Yúfírétì.