Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀yìn Òbí—Báwo Lẹ Ṣe Fẹ́ Kí Ọjọ́ Ọ̀la Àwọn Ọmọ Yín Rí?

Ẹ̀yìn Òbí—Báwo Lẹ Ṣe Fẹ́ Kí Ọjọ́ Ọ̀la Àwọn Ọmọ Yín Rí?

Ẹ̀yìn Òbí—Báwo Lẹ Ṣe Fẹ́ Kí Ọjọ́ Ọ̀la Àwọn Ọmọ Yín Rí?

‘Ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin àti ẹ̀yin wúńdíá, ẹ máa yin orúkọ Jèhófà.’—Sáàmù 148:12, 13.

1. Àníyàn wo làwọn òbí máa ń ṣe nípa àwọn ọmọ wọn?

 ÒBÍ wo ni kì í ṣàníyàn nípa ọjọ́ ọ̀la ọmọ rẹ̀? Látìgbà tí wọ́n bá ti bí ọmọ jòjòló kan, tàbí ṣáájú kí wọ́n tó bí i pàápàá làwọn òbí rẹ̀ á ti máa ṣàníyàn nípa bó ṣe máa dáa fún ọmọ náà. Ṣé ara ẹ̀ á le? Ṣé ó máa dàgbà bó ṣe yẹ? Bí ọmọ náà sì ṣe ń dàgbà làníyàn àwọn òbí rẹ̀ á máa pọ̀ sí i. Ní gbogbo ọ̀nà, àwọn òbí máa ń fẹ́ kó dára fáwọn ọmọ wọn.—1 Sámúẹ́lì 1:11, 27, 28; Sáàmù 127:3-5.

2. Kí nìdí tó fi ń wu ọ̀pọ̀ òbí gan-an lónìí pé káyé àwọn ọmọ wọn dára nígbà tí wọ́n bá dàgbà?

2 Àmọ́ láyé òde òní, ó máa ń ṣòro fún àwọn òbí láti ṣe ohun tó dára fún àwọn ọmọ wọn. Ọ̀pọ̀ òbí ló ń fojú winá ọ̀pọ̀ ìṣòro, irú bí ogun, rògbòdìyàn ọ̀ràn ìṣèlú, àìrówóná, ìnira, ìbànújẹ́ ọkàn àtàwọn ìṣòro mìíràn. Gẹ́gẹ́ bó ṣe máa ń rí, àwọn òbí kì í fẹ́ kójú ọmọ wọn rí wàhálà tí àwọn rí. Láwọn orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀, àwọn òbí lè rí i pé ọmọ ẹbí àwọn àtọmọ ọ̀rẹ́ àwọn ń rọ́wọ́ mú nínú iṣẹ́ wọn, ó sì jọ pé nǹkan ń ṣẹnuure fún wọn gan-an. Nítorí ìdí yìí, wọ́n gbà pé ó di dandan káwọn ṣe gbogbo ohun táwọn bá lè ṣe kí ayé àwọn ọmọ tàwọn náà lè dára kí ọkàn wọn sì balẹ̀ nígbà tí wọ́n bá dàgbà.—Oníwàásù 3:13.

Ìgbésí Ayé Tó Dára Làwọn Kristẹni Yàn

3. Kí làwọn Kristẹni pinnu láti fi ìgbésí ayé wọn ṣe?

3 Jíjẹ́ táwọn Kristẹni jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi ti mú kí wọ́n ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jèhófà. Wọ́n fi ọ̀rọ̀ Jésù sọ́kàn pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ níní ara rẹ̀, kí ó sì gbé òpó igi oró rẹ̀ láti ọjọ́ dé ọjọ́, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn nígbà gbogbo.” (Lúùkù 9:23; 14:27) Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn Kristẹni ní láti ní ẹ̀mí ìyọ̀ǹda ara ẹni. Àmọ́ èyí ò túmọ̀ sí pé kí wọ́n máa gbé nínú ìṣẹ́ àti ìyà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìgbésí ayé aláyọ̀ tó sì nítumọ̀ ni wọ́n ń gbé nítorí pé wọ́n ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ pé, “ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.

4. Kí ni Jésù rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa lépa?

4 Nǹkan ṣòro gan-an fáwọn èèyàn nígbà ayé Jésù. Yàtọ̀ sí wíwá oúnjẹ òòjọ́ wọn, wọ́n tún ní láti fara da ìnira àwọn ará Róòmù tó ń ṣàkóso wọn lọ́nà rírorò àti àjàgà àwọn olórí ìsìn tó jẹ́ aláṣehàn láyé ìgbà yẹn. (Mátíù 23:2-4) Síbẹ̀, tayọ̀tayọ̀ lọ̀pọ̀ àwọn tó gbọ́ nípa Jésù fi pa ohun tí wọ́n ń lépa tì, kódà wọ́n pa iṣẹ́ wọn tì, wọ́n sì di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. (Mátíù 4:18-22; 9:9; Kólósè 4:14) Ṣé àwọn ọmọ ẹ̀yìn wọ̀nyẹn kò ro ti ọjọ́ ọ̀la wọn ni? Wo ohun tí Jésù sọ, ó ní: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ti fi àwọn ilé tàbí àwọn arákùnrin tàbí àwọn arábìnrin tàbí baba tàbí ìyá tàbí àwọn ọmọ tàbí àwọn ilẹ̀ sílẹ̀ nítorí orúkọ mi yóò rí gbà ní ìlọ́po-ìlọ́po sí i, yóò sì jogún ìyè àìnípẹ̀kun.” (Mátíù 19:29) Jésù mú un dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lójú pé Bàbá wọn ọ̀run mọ ohun tí wọ́n nílò. Nítorí ìdí yìí, ó rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.”—Mátíù 6:31-33.

5. Kí lèrò àwọn òbí kan nípa bí Jésù ṣe mú un dá wa lójú pé Ọlọ́run á bójú tó àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀?

5 Bákan náà lọ̀rọ̀ rí lónìí. Jèhófà mọ ohun tá a nílò. Àwọn tó fi ire Ìjọba náà sí ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wọn, àgàgà àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún, gbà pé Ọlọ́run yóò tọ́jú àwọn. (Málákì 3:6, 16; 1 Pétérù 5:7) Àmọ́ ṣá o, àwọn òbí kan ń ṣiyè méjì nípa ọ̀rọ̀ yìí. Lọ́nà kan, wọ́n fẹ́ káwọn ọmọ wọn tẹ̀ síwájú nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, bóyá káwọn ọmọ náà tiẹ̀ wọnú iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún tó bá yá. Lọ́nà kejì, wọ́n tún ń ro ti ipò ọrọ̀ ajé àti bí kò ṣe rọrùn láti ríṣẹ́ nínú ayé lónìí. Wọ́n ronú pé ó ṣe pàtàkì káwọn ọ̀dọ́ kọ́kọ́ kàwé dáadáa kí wọ́n bàa lè ní ìmọ̀ tó máa jẹ́ kí wọ́n rí iṣẹ́ tó dára ṣe tàbí kí wọ́n lè rí nǹkan gbára lé tó bá dójú ẹ̀. Irú àwọn òbí bẹ́ẹ̀ lè máa rò pé tọ́mọ ò bá tíì lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga kò tíì kàwé.

Múra Sílẹ̀ De Ọjọ́ Ọ̀la

6. Kí la lo ọ̀rọ̀ náà “ẹ̀kọ́ ilé ìwé gíga” fún nínú àpilẹ̀kọ́ yìí?

6 Ètò ẹ̀kọ́ ní orílẹ̀-èdè kan yàtọ̀ sí ti orílẹ̀-èdè mìíràn. Bí àpẹẹrẹ, ní Nàìjíríà, ọdún méjìlá ni ọmọ fi ń kàwé láti ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ títí tó fi máa jáde ilé ẹ̀kọ́ girama. Lẹ́yìn náà, akẹ́kọ̀ọ́ kan lè yàn láti lọ sí yunifásítì tàbí ilé ẹ̀kọ́ gíga tí yóò ti lo ọdún mẹ́rin tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó lè gba oyè àkọ́kọ́ tàbí kó tún lọ kàwé sí i láti gba oyè kejì nínú ẹ̀kọ́ ìṣègùn, ìmọ̀ òfin, ìmọ̀ ẹ̀rọ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, irú ẹ̀kọ́ báwọ̀nyí la pè ní “ẹ̀kọ́ ilé ìwé gíga.” Ní àfikún sí èyí, àwọn ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti ń kọ́ṣẹ́ ọwọ́ tún wà tí wọ́n ń dáni lẹ́kọ̀ọ́ fún ìgbà kúkúrú tí wọ́n á sì fúnni ní ìwé ẹ̀rí dípúlọ́mà nínú àwọn iṣẹ́ ọwọ́ kan.

7. Kí làwọn tó wà nílé ẹ̀kọ́ girama ń dojú kọ?

7 Ohun tó gbòde kan lónìí ni káwọn ilé ẹ̀kọ́ girama máa múra àwọn ọmọ ilé ìwé wọn sílẹ̀ fún ilé ẹ̀kọ́ gíga. Nítorí náà, ọ̀pọ̀ ilé ẹ̀kọ́ girama ló ń gbájú mọ́ ẹ̀kọ́ tó máa mú káwọn akẹ́kọ̀ọ́ yege dáadáa nínú ìdánwò tí wọ́n ń ṣe wọ ilé ẹ̀kọ́ yunifásítì dípò àwọn ẹ̀kọ́ tó lè mú kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rí iṣẹ́ ṣe. Ohun táwọn olùkọ́ àtàwọn agbaninímọ̀ràn máa ń tẹnu mọ́ ṣáá lónìí ni pé káwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ girama rí i pé àwọn wọ ilé ẹ̀kọ́ yunifásítì tó dára jù lọ, kódà àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn máa ń sọ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. Ibẹ̀ ni wọ́n gbà pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ti lè gba ìwé ẹ̀rí tó máa jẹ́ kí wọ́n ríṣẹ́ àtàtà tó ń mú owó ńlá wá.

8. Àwọn ìpinnu wo làwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni ní láti ṣe?

8 Kí wá ni àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni yóò ṣe? Ó dájú pé wọ́n á fẹ́ káwọn ọmọ wọn ṣàṣeyọrí nílé ìwé kí wọ́n sì kọ́ ẹ̀kọ́ tó máa mú kí wọ́n lè gbọ́ bùkátà ara wọn lọ́jọ́ iwájú. (Òwe 22:29) Àmọ́, ṣó wá yẹ káwọn òbí jẹ kí ẹ̀mí wíwá ọrọ̀ àti àṣeyọrí lójú méjèèjì máa darí àwọn ọmọ wọn? Irú àwọn nǹkan wo làwọn òbí ń fi síwájú àwọn ọmọ wọn láti máa lé, yálà nípa ọ̀rọ̀ tàbí àpẹẹrẹ tiwọn fúnra wọn? Àwọn òbí kan máa ń ṣiṣẹ́ àṣekára, wọ́n sì máa ń tọ́jú owó pa mọ́ kí wọ́n lè rán àwọn ọmọ wọn lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga tó bá yá. Àwọn mìíràn kò kọ̀ láti jẹ gbèsè nítorí ẹ̀. Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe owó nìkan ni irú ìpinnu bẹ́ẹ̀ máa ń náni. Kí ni lílọ sílé ẹ̀kọ́ gíga lóde òní tún ń náni?—Lúùkù 14:28-33.

Àwọn Ohun Tí Lílọ Sílé Ẹ̀kọ́ Gíga Ń Náni

9. Kí la lè sọ nípa owó tí ilé ẹ̀kọ́ gíga ń náni lóde òní?

9 Bá a bá ń ronú nípa ohun tí lílọ sílé ẹ̀kọ́ gíga ń náni, owó ló sábà máa ń wá síni lọ́kàn. Láwọn orílẹ̀-èdè kan, ìjọba ló máa ń gbọ́ bùkátà ètò ẹ̀kọ́ ilé ìwé gíga, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó bá sì yege láti débẹ̀ kì í sanwó. Àmọ́, ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, ilé ẹ̀kọ́ gíga ń náni lówó gan-an, ńṣe ni iye tó ń náni sì túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Lójú ewé tí wọ́n máa ń kọ èrò àwọn èèyàn sí nínú ìwé ìròyìn New York Times, wọ́n sọ pé: “Ojú táwọn èèyàn fi ń wo ilé ẹ̀kọ́ gíga tẹ́lẹ̀ ni pé ó ń ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀ àǹfààní. Àmọ́ nísinsìnyí ilé ẹ̀kọ́ gíga làwọn èèyàn fi ń mọ̀yàtọ̀ láàárín olówó àtẹni tí kò fi bẹ́ẹ̀ lówó.” Lédè mìíràn, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ àwọn olówó àtàwọn èèyàn pàtàkì nìkan ló ń rán ọmọ wọn lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga tó dára jù lọ káwọn ọmọ náà lè di olówó àtèèyàn pàtàkì nínú ayé yìí. Ǹjẹ́ irú ohun bẹ́ẹ̀ ló yẹ káwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni fi síwájú àwọn ọmọ wọn láti máa lé?—Fílípì 3:7, 8; Jákọ́bù 4:4.

10. Báwo ni ilé ẹ̀kọ́ gíga ṣe wà lára ohun tó ń ṣètìlẹ́yìn fún ètò nǹkan ìsinsìnyí?

10 Kódà níbi tí ilé ẹ̀kọ́ gíga ti jẹ́ ọ̀fẹ́, àwọn ohun kan ṣì wà tí lílọ síbẹ̀ ń náni. Bí àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn The Wall Street Journal sọ pé lórílẹ̀-èdè kan ní Gúúsù Ìlà Oòrùn Éṣíà, ìjọba ibẹ̀ ṣètò “ẹ̀kọ́ ìwé kan tí wọ́n dìídì fi ń gbé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó bá fakọ yọ sí ipò tó ga jù lọ.” Ohun tí “ipò tó ga jù lọ” yìí túmọ̀ sí ni pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà yóò lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga tó dára jù lọ láyé, ìyẹn Yunifásítì Oxford àti Yunifásítì Cambridge tí wọ́n wà ní England, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àtàwọn Yunifásítì kàǹkà-kàǹkà kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àtàwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga mìíràn. Kí nìdí tí ìjọba orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Éṣíà yẹn fi ṣe irú ètò ẹ̀kọ́ tó kàmàmà bẹ́ẹ̀? Ìròyìn náà sọ pé, “kí wọ́n lè mú kí ọ̀rọ̀ ajé orílẹ̀-èdè yẹn gbèrú sí i ni.” Ẹ̀kọ́ ìwé náà lè jẹ́ ọ̀fẹ́ lóòótọ́, àmọ́ ohun tó máa ná àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ni pé, gbogbo okun àti agbára wọn ni wọn yóò máa fi ṣètìlẹ́yìn fún ètò nǹkan ìsinsìnyí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé irú ìgbésí ayé yẹn làwọn èèyàn ayé ń lé lójú méjèèjì, ṣé ohun táwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni ń fẹ́ fún àwọn ọmọ tiwọn nìyẹn?—Jòhánù 15:19; 1 Jòhánù 2:15-17.

11. Kí ni ìròyìn sọ nípa ọtí àmujù àti ìṣekúṣe láàárín àwọn ọmọ yunifásítì?

11 Ohun mìíràn tó yẹ ká gbé yẹ̀ wò ni ìwà táwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń hù nílé ẹ̀kọ́ gíga. Ìwà burúkú pọ̀ lọ́gbà ilé ẹ̀kọ́ Yunifásítì àtàwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga yòókù, irú àwọn ìwà bíi lílo oògùn olóró, mímu ọtí àmujù, ṣíṣe ìṣekúṣe, ṣíṣe èrú nínú ìdánwò, wíwọ ẹgbẹ́ òkùnkùn, àti ọ̀pọ̀ ìwà abèṣe mìíràn. Ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀ràn ọtí àmujù yẹ̀ wò. Ìwé ìròyìn New Scientist sọ̀rọ̀ nípa ọtí àmujù yìí, ó ní: “Nǹkan bí ìdá mẹ́rìnlélógójì nínú ọgọ́rùn-ún [àwọn ọmọ yunifásítì lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà] ló máa ń mutí yó, ó kéré tán, lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀ méjì.” Ìṣòro kan náà ló ń ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn ọ̀dọ́ nílẹ̀ Ọsirélíà, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Rọ́ṣíà àti láwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. Ní ti ọ̀ràn ìṣekúṣe, ọ̀rọ̀ kan tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga lóde òní ni “àgbésùn” èyí tí ìwé ìròyìn Newsweek sọ pé ó jẹ́ “ìbálòpọ̀ ẹ̀ẹ̀kan péré, ó sì bẹ̀rẹ̀ látorí fífẹnu kora wọn lẹ́nu dórí níní ìbálòpọ̀, tí wọ́n sì lè máà tún bára wọn sọ̀rọ̀ mọ́ lẹ́yìn náà.” Ìwádìí fi hàn pé nínú akẹ́kọ̀ọ́ márùn-ún, mẹ́ta sí mẹ́rin wọn ló ń lọ́wọ́ sí irú ìbálòpọ̀ yìí. Ẹlòmíràn tó ṣe ìwádìí tún sọ pé: “Tó bá jẹ́ pé ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga ni ọ́ lóòótọ́, ìwọ náà á ṣe é.”—1 Kọ́ríńtì 5:11; 6:9, 10.

12. Àwọn ìṣòro wo ló ń dojú kọ àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga?

12 Yàtọ̀ sí ohun búburú tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́gbà ilé ẹ̀kọ́ yunifásítì, nǹkan tún máa ń nira gan-an fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ nítorí iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ àtàwọn ìdánwò tí wọ́n máa ń ṣe. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní láti kàwé gan-an kí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá wọn láti lè yege nínú ìdánwò wọn. Àwọn kan tún ní láti máa ṣe iṣẹ́ ààbọ̀-àkókò nígbà tí wọ́n ṣì wà lẹ́nu ìwé kíkà. Gbogbo ìwọ̀nyí ń gba àkókò àti okun wọn lọ́nà tó bùáyà. Àkókò wo ló máa wá ṣẹ́ kù fún ṣíṣe àwọn nǹkan tẹ̀mí? Tí nǹkan bá le tán, kí ni wọ́n máa ń pa tì? Ṣé ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú Ìjọba Ọlọ́run á ṣì wà ní ipò àkọ́kọ́, àbí wọ́n á pa á tì? (Mátíù 6:33) Bíbélì rọ àwọn Kristẹni pé: “Ẹ máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí ẹ ṣe ń rìn kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n, ní ríra àkókò tí ó rọgbọ padà fún ara yín, nítorí pé àwọn ọjọ́ burú.” (Éfésù 5:15, 16) Ó ṣeni láàánú pé àwọn kan ti kúrò nínú ìgbàgbọ́ nítorí pé ọ̀ràn ẹ̀kọ́ kíkọ́ ti gba àkókò àti okun wọn tàbí nítorí pé wọ́n lọ́wọ́ nínú àwọn ìwà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu nílé ẹ̀kọ́ gíga!

13. Àwọn ìbéèrè wo làwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni ní láti gbé yẹ̀ wò?

13 Ká sòótọ́, kì í ṣe ọgbà yunifásítì tàbí àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga mìíràn nìkan ni ìṣekúṣe, ìwà burúkú, àti ìṣòro wà. Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ inú ayé ló tún ka irú àwọn ìwà wọ̀nyẹn sí apá kan ẹ̀kọ́ ìwé, wọ́n sì gbà pé ara ìgbésí ayé inú ọgbà ilé ẹ̀kọ́ gíga ni. Ṣé ó yẹ káwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni mọ̀ọ́mọ̀ fi àwọn ọmọ wọn sínú irú ewu bẹ́ẹ̀ fún ọdún mẹ́rin tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ? (Òwe 22:3; 2 Tímótì 2:22) Ṣé ewu tó wà níbẹ̀ yìí kò wá ju àǹfààní èyíkéyìí táwọn ọ̀dọ́ náà lè rí níbẹ̀ lọ? Ohun tó tún ṣe pàtàkì jù lọ ní pé, kí ni wọ́n ń kọ́ àwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí nílé ẹ̀kọ́ pé kí wọ́n fi sípò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wọn? a (Fílípì 1:10; 1 Tẹsalóníkà 5:21) Àwọn òbí ní láti gbé àwọn ìbéèrè wọ̀nyí yẹ̀ wò dáadáa kí wọ́n sì gbàdúrà nípa rẹ̀, kí wọ́n sì tún ronú nípa ewu tó wà nínú rírán ọmọ wọn lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ní ìlú mìíràn tàbí lórílẹ̀-èdè mìíràn.

Àwọn Ilé Ẹ̀kọ́ Mìíràn Wo Làwọn Ọmọ Lè Lọ?

14, 15. (a) Láìka èrò ọ̀pọ̀ èèyàn sí, ìmọ̀ràn wo ló wà nínú Bíbélì tó yẹ ká mú lò lónìí? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ káwọn ọ̀dọ́ bi ara wọn?

14 Lónìí, èrò ọ̀pọ̀ èèyàn ni pé kí àwọn ọ̀dọ́ tó lè ṣàṣeyọrí, wọ́n ní láti lọ kẹ́kọ̀ọ́ ní yunifásítì. Àmọ́ dípò títẹ̀lé èrò ọ̀pọ̀ èèyàn, ọ̀rọ̀ ìyànjú tó wà nínú Bíbélì làwọn Kristẹni ń tẹ̀ lé, èyí tó sọ pé: “Ẹ . . . jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí, ṣùgbọ́n ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín padà, kí ẹ lè ṣàwárí fúnra yín ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.” (Róòmù 12:2) Kí ni ìfẹ́ Ọlọ́run fáwọn èèyàn rẹ̀ lọ́mọdé lágbà, níwọ̀nba tó kù kí àkókò òpin yìí parí? Pọ́ọ̀lù rọ Tímótì pé: “Máa pa agbára ìmòye rẹ mọ́ nínú ohun gbogbo, jìyà ibi, ṣe iṣẹ́ ajíhìnrere, ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ ní kíkún.” Ó dájú pé ọ̀rọ̀ yìí kan gbogbo wa lónìí.—2 Tímótì 4:5.

15 Dípò ká jẹ́ kí ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì inú ayé yìí kó sí wa lórí, ó yẹ kí gbogbo wa ‘pa agbára ìmòye wa mọ́,’ ìyẹn ojú tá a fi ń wo nǹkan tẹ̀mí. Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, bi ara rẹ léèrè pé: ‘Ǹjẹ́ mò ń sa gbogbo ipá mi láti ‘ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi ní kíkún’ kí n lè di òjíṣẹ́ tó dáńgájíá nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Àwọn ohun wo ni mò ń gbèrò láti ṣe kí n lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi ní “kíkún”? Ǹjẹ́ mo ti ronú láti sọ iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún di iṣẹ́ tí màá fi ìgbèésí ayé mi ṣe?’ Àwọn ìbéèrè wọ̀nyí gbàrònú gidigidi, àgàgà tó o bá rí àwọn ọ̀dọ́ yòókù tí wọ́n ń lépa nǹkan tára wọn, tí wọ́n “ń wá àwọn ohun ńláńlá” tí wọ́n lérò pé á mú káwọn di ọlọ́rọ̀ lọ́jọ́ ọ̀la. (Jeremáyà 45:5) Nítorí náà, ó yẹ káwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni jẹ́ ọlọgbọ́n, kí wọ́n jẹ́ káwọn ọmọ wọn máa bá àwọn tó lè gbé wọn ró, tó sì lè tọ́ wọn sọ́nà nípa tẹ̀mí kẹ́gbẹ́ láti kékeré.—Òwe 22:6; Oníwàásù 12:1; 2 Tímótì 3:14, 15.

16. Ọ̀nà wo làwọn Kristẹni òbí tó jẹ́ ọlọgbọ́n lè gbà mú kí àwọn ọmọ wọn máa bá àwọn tó lè gbé wọn ró nípa tẹ̀mí kẹ́gbẹ́?

16 Nínú ìdílé kan tí màmá wọn ti jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún fún ọ̀pọ̀ ọdún, èyí tó dàgbà jù nínú àwọn ọmọkùnrin mẹ́ta inú ìdílé náà sọ pé: “Màmá mi máa ń ṣọ́ àwọn tá à ń bá kẹ́gbẹ́. A kì í bá àwọn ọmọ iléèwé wa kẹ́gbẹ́, àwọn tó wà nínú ìjọ tí wọ́n jẹ́ ẹni tẹ̀mí là ń bá kẹ́gbẹ́. Ìyá wa sì máa ń pe àwọn tó wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún wá sílé wa ká lè jùmọ̀ sọ̀rọ̀, ìyẹn àwọn míṣọ́nnárì, àwọn alábòójútó àyíká, àwọn tó wà ní Bẹ́tẹ́lì àtàwọn aṣáájú-ọ̀nà. Gbígbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu wọn àti rírí i bí wọ́n ṣe ń láyọ̀ ló gbin ìfẹ́ iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún sí wa lọ́kàn.” Ẹ wo bó ti múni láyọ̀ tó pé lónìí àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí wà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún! Ọ̀kan ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì, ọ̀kan ti jáde Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́, ọ̀kan yòókù ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà.

17. Ìtọ́sọ́nà wo làwọn òbí lè fún àwọn ọmọ wọn nígbà tí wọ́n bá fẹ́ yan ẹ̀kọ́ tí wọ́n fẹ́ kọ́ nílé ẹ̀kọ́ àti iṣẹ́ ọwọ́ tí wọ́n fẹ́ kọ́? (Wo àpótí tó wà ní ojú ìwé 29.)

17 Yàtọ̀ sí jíjẹ́ káwọn ọmọ máa bá àwọn tó lè gbé wọn ró dáadáa nípa tẹ̀mí kẹ́gbẹ́, ó tún yẹ káwọn òbí tètè tọ́ àwọn ọmọ wọn sọ́nà dáadáa nípa ẹ̀kọ́ tí wọ́n fẹ́ kọ́ nílé ẹ̀kọ́ àti iṣẹ́ ọwọ́ tí wọ́n fẹ́ kọ́. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń sìn nísinsìnyí ní Bẹ́tẹ́lì sọ pé: “Àwọn òbí mi ti ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà kí wọ́n tó ṣègbéyàwó, wọ́n tún ń bá iṣẹ́ náà lọ lẹ́yìn ìgbéyàwó wọn, wọ́n sa gbogbo ipá wọn láti gbin ìfẹ́ ṣíṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà sínú ọkàn gbogbo àwa tá a wà nínú ìdílé wa. Nígbà tá a bá fẹ́ yan ẹ̀kọ́ tá a fẹ́ kọ́ nílé ẹ̀kọ́ tàbí nígbà tá a bá ń ṣèpinnu tí yóò kan ọjọ́ ọ̀la wa, wọ́n máa ń gbà wá níyànjú nígbà gbogbo pé ká yan ohun tó máa fún wa láǹfààní dáadáa láti rí iṣẹ́ ààbọ̀-àkókò ṣe ká lè ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà.” Dípò táwọn ọmọ á fi yan àwọn ẹ̀kọ́ tó máa gba pé kí wọ́n lọ sí yunifásítì, ó yẹ káwọn òbí àtàwọn ọmọ ronú nípa àwọn ẹ̀kọ́ tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lè ṣe iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. b

18. Irú àwọn iṣẹ́ wo làwọn ọ̀dọ́ lè ṣe?

18 Ìwádìí fi hàn pé ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwọn tó ń gbani síṣẹ́ ò wá àwọn tó ní ìwé ẹ̀rí yunifásítì, àwọn tó mọ iṣẹ́ ọwọ́ ni wọ́n ń wá gan-an báyìí. Ìwé ìròyìn USA Today sọ pé “lógún ọdún sígbà tá a wà yìí, òṣìṣẹ́ méje nínú mẹ́wàá ni kò ní nílò ìwé ẹ̀rí téèyàn ń gbà lẹ́yìn tó bá lo ọdún mẹ́rin nílé ẹ̀kọ́ gíga, kàkà bẹ́ẹ̀ ìwé ẹ̀rí tí kò tó èyí tí wọ́n ń gbà láwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga ló máa wúlò tàbí ìwé ẹ̀rí téèyàn ń gbà nílé ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti ń kọ́ṣẹ́ ọwọ́.” Ọ̀pọ̀ ilé ẹ̀kọ́ tí kò tó ilé ẹ̀kọ́ gíga wọ̀nyí máa ń kọ́ni ní onírúurú iṣẹ́ tí kò gba àkókò gígùn, irú bí iṣẹ́ akọ̀wé, iṣẹ́ atọ́kọ̀ṣe, iṣẹ́ atún-kọ̀ǹpútà-ṣe, iṣẹ́ púlọ́ńbà (ìyẹn àwọn tó ń fami sílé), iṣẹ́ aṣerunlóge àti ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ọwọ́ mìíràn. Ṣé àwọn iṣẹ́ wọ̀nyẹn dára? Bẹ́ẹ̀ ni! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn iṣẹ́ yìí lè má gbayì lójú àwọn èèyàn kan, síbẹ̀ wọ́n tó láti gbọ́ bùkátà fún àwọn tó fẹ́ fi ìgbésí ayé wọn ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, yóò sì tún jẹ́ kí wọ́n lè ṣètò àkókò wọn bí wọ́n ṣe fẹ́.—2 Tẹsalóníkà 3:8.

19. Ọ̀nà tó dájú wo ni ayé ẹni fi lè láyọ̀ kó sì lárinrin?

19 Bíbélì rọ̀ wá pé, ‘Ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin àti ẹ̀yin wúńdíá, ẹ máa yin orúkọ Jèhófà, nítorí pé orúkọ rẹ̀ nìkan ṣoṣo ni ó ga ré kọjá ibi tí ó ṣeé dé. Iyì rẹ̀ ń bẹ lókè ilẹ̀ ayé àti ọ̀run.’ (Sáàmù 148:12, 13) Tá a bá ní ká fi ipò àti èrè táwọn iṣẹ́ ayé ń fúnni wé ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún sí Jèhófà, iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún ni ọ̀nà tó dára jù lọ táyé ẹni lè gbà láyọ̀ kó sì lárinrin. Má ṣe gbàgbé ọ̀rọ̀ tó ń fọkàn ẹni balẹ̀ tí Bíbélì sọ, pé: “Ìbùkún Jèhófà—èyíinì ni ohun tí ń sọni di ọlọ́rọ̀, kì í sì í fi ìrora kún un.”—Òwe 10:22.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Láti lè mọ̀ nípa àwọn tó mọyì ẹ̀kọ́ ìjọba Ọlọ́run ju ẹ̀kọ́ yunifásítì lọ, wo Ile-Iṣọ Naa, November 1, 1982, ojú ìwé 3 sí 6; October 15, 1979, ojú ìwé 15 sí 20; Jí! February 8, 1979, ojú ìwé 24; àti August 8, 1974, ojú ìwé 3 sí 7 (Gẹ̀ẹ́sì).

b Wo Jí! October 8, 1998, “Wíwá Ìgbésí Ayé Aláàbò Kiri,” ojú ìwé 4 sí 6, àti November 8, 1989, “Iṣẹ́-Ìgbésí-Ayé Wo Ni Mo Nilati Yàn?” ojú ìwé 12 sí 14.

Ṣé O Lè Ṣàlàyé?

• Ta làwọn Kristẹni gbẹ́kẹ̀ lé tí wọ́n fi gbà pé ọjọ́ ọ̀la àwọn á dára?

• Àwọn ìṣòro wo ló ń dojú kọ àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni nípa ọjọ́ ọ̀la àwọn ọmọ wọn?

• Kí ló yẹ ká gbé yẹ̀ wò nígbà tá a bá ń ronú nípa àwọn ohun tí lílọ silé ẹ̀kọ́ gíga ń náni?

• Báwo làwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 29]

Báwo Ni Ilé Ẹ̀kọ́ Gíga Ṣe Wúlò Tó?

Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó ń wọ ilé ẹ̀kọ́ yunifásítì ló ń retí àtigba oyè tó máa jẹ́ kí wọ́n rí iṣẹ́ àtàtà tó ń mówó ńlá wá. Àmọ́, ohun tí ìjọba orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ ni pé ìdá kan nínú mẹ́rin àwọn tó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ yunifásítì ló ń gboyè jáde láàárín ọdún mẹ́fà, èyí tó fi hàn pé àṣeyọrí ibẹ̀ kò tó nǹkan. Ǹjẹ́ àwọn díẹ̀ tó tiẹ̀ rí oyè ọ̀hún gbà rí iṣẹ́ àtàtà fi ṣe? Gbọ́ ohun táwọn ìwádìí àti àyẹ̀wò kan tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn.

“Gbígboyè jáde láwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga tó dára jù lọ, ìyẹn Yunifásítì Harvard tàbí Yunifásítì Duke lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kò sọ pé kéèyàn rí iṣẹ́ tó dáa táá ti máa gba owó ńlá. . . . Àwọn ilé iṣẹ́ kì í fẹ́ gba àwọn ọ̀dọ́ tó ń wá iṣẹ́. Oyè kàǹkà-kàǹkà téèyàn gbà láti àwọn ilé ẹ̀kọ́ yunifásítì tó lórúkọ lè níyì lóòótọ́. Àmọ́ ohun téèyàn mọ̀ ọ́n ṣe làwọn agbanisíṣẹ́ máa ń kà sí pàtàkì jù lọ.”—Ìwé ìròyìn Newsweek, November 1, 1999.

“Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn iṣẹ́ tó wà níta báyìí gba kéèyàn mọṣẹ́ náà dáadáa ju ti ìgbà àtijọ́ lọ . . . , ìmọ̀ téèyàn nílò fáwọn iṣẹ́ wọ̀nyí ni ìmọ̀ tó jíire téèyàn ti ní lọ́dún kẹta nílé ẹ̀kọ́ girama, ìyẹn ìmọ̀ ìṣirò, ìwé kíkà, àti ìwé kíkọ . . . , kì í ṣe ìmọ̀ ilé ẹ̀kọ́ gíga. . . . Kò dìgbà táwọn akẹ́kọ̀ọ́ bá lọ sílé ẹ̀kọ́ yunifásítì kí wọ́n tó lè rí iṣẹ́ àtàtà, àmọ́ ó ṣe pàtàkì kí wọ́n ní ìmọ̀ tó jinlẹ̀ nílé ẹ̀kọ́ girama.”—Ìwé ìròyìn American Educator, Spring 2004.

“Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga lohun tí wọ́n ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kò bá bóde ṣe rí mu nítorí pé wọn kì í múra àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀ láti ríṣẹ́ ṣe lẹ́yìn tí wọ́n bá gboyè jáde. Àwọn ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti ń kọ́ṣẹ́ ọwọ́ . . . ti wá ń gbajúmọ̀ gan-an nísinsìnyí. Iye àwọn èèyàn tó ń wọ ibẹ̀ ti fi ìdá méjìdínláàádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún ròkè láti ọdún 1996 sí ọdún 2000. . . . Nígbà tó jẹ́ pé àwọn ìwé ẹ̀rí ilé ẹ̀kọ́ gíga tó ń náni lówó tó sì tún ń gba àkókò ẹni kò fi bẹ́ẹ̀ níye lórí bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́.”—Ìwé ìròyìn Time, January 24, 2005.

“Ohun tí Ẹ̀ka Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Àwọn Òṣìṣẹ́ ní Ilẹ̀ Amẹ́ríkà sọ nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ láàárín ọdún 2005 bani lẹ́rù. Wọ́n ní ó kéré tán, ẹnì kan nínú mẹ́ta àwọn tó fi ọdún mẹ́rin kàwé gboyè jáde nílé ẹ̀kọ́ gíga kò ní rí iṣẹ́ tó dára tó ìwé ẹ̀rí tí wọ́n gbà.”—Ìwé ìròyìn The Futurist, July/August 2000.

Gbogbo ohun tá a ti sọ yìí fi hàn pé, ńṣe làwọn onímọ̀ ẹ̀kọ́ tó ń ṣiyè méjì gan-an nípa ìwúlò ilé ẹ̀kọ́ gíga tòde òní túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Ìwé ìròyìn Futurist kédàárò pé: “Ẹ̀kọ́ tá à ń kọ́ àwọn èèyàn kò ṣe wọ́n láǹfààní lẹ́yìn tí wọ́n bá jáde níléèwé.” Àmọ́ kíyè sí ohun tí Bíbélì sọ nípa Ọlọ́run, ó ní: “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn. Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fetí sí àwọn àṣẹ mi ní tòótọ́! Nígbà náà, àlàáfíà rẹ ì bá dà bí odò, òdodo rẹ ì bá sì dà bí ìgbì òkun.”—Aísáyà 48:17, 18.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Wọ́n pa iṣẹ́ wọn tì, wọ́n sì tẹ̀ lé Jésù

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Ó yẹ káwọn Kristẹni òbí tó jẹ́ ọlọgbọ́n máa jẹ́ káwọn ọmọ wọn bá àwọn tó lè gbé wọn ró dáadáa nípa tẹ̀mí kẹ́gbẹ́ láti kékeré