Ìwé Kìíní sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì 5:1-13

  • Ẹjọ́ ìṣekúṣe tó wáyé (1-5)

  • Ìwúkàrà díẹ̀ ló ń mú gbogbo ìṣùpọ̀ wú (6-8)

  • Ẹ mú ẹni burúkú náà kúrò (9-13)

5  Ní tòótọ́, wọ́n ròyìn ìṣekúṣe*+ tó ṣẹlẹ̀ láàárín yín, irú ìṣekúṣe* bẹ́ẹ̀ kò tiẹ̀ sí láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, pé ọkùnrin kan ń fẹ́* ìyàwó bàbá rẹ̀.+ 2  Ṣé ẹ wá ń fìyẹn yangàn ni? Ṣé kì í ṣe pé ó yẹ kí ẹ máa ṣọ̀fọ̀+ kí a lè mú ọkùnrin tó ṣe nǹkan yìí kúrò láàárín yín?+ 3  Bí mi ò tiẹ̀ sí lọ́dọ̀ yín nípa tara, mo wà lọ́dọ̀ yín nípa tẹ̀mí, mo sì ti ṣèdájọ́ ọkùnrin tó ṣe nǹkan yìí, bíi pé èmi fúnra mi wà lọ́dọ̀ yín. 4  Nígbà tí ẹ bá pé jọ ní orúkọ Olúwa wa Jésù, tí ẹ sì mọ̀ pé mo wà pẹ̀lú yín nípa tẹ̀mí nínú agbára Olúwa wa Jésù, 5  kí ẹ fi irú ẹni bẹ́ẹ̀ lé Sátánì lọ́wọ́+ kí agbára ẹ̀ṣẹ̀ náà lè pa run, kí ipò tẹ̀mí ìjọ lè wà láìyingin ní ọjọ́ Olúwa.+ 6  Bí ẹ ṣe ń fọ́nnu yìí kò dáa. Ṣé ẹ kò mọ̀ pé ìwúkàrà díẹ̀ ló ń mú gbogbo ìṣùpọ̀ wú ni?+ 7  Ẹ mú ìwúkàrà àtijọ́ kúrò, kí ẹ lè di ìṣùpọ̀ tuntun, tí kò bá ti sí amóhunwú nínú yín. Torí, ní tòótọ́, a ti fi Kristi ọ̀dọ́ àgùntàn Ìrékọjá wa+ rúbọ.+ 8  Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká ṣe àjọyọ̀,+ kì í ṣe pẹ̀lú ìwúkàrà àtijọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pẹ̀lú ìwúkàrà ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà burúkú, àmọ́ ká ṣe é pẹ̀lú búrẹ́dì aláìwú ti òótọ́ inú àti ti òtítọ́. 9  Nínú lẹ́tà tí mo kọ sí yín, mo ní kí ẹ jáwọ́ nínú kíkẹ́gbẹ́* pẹ̀lú àwọn oníṣekúṣe,* 10  àmọ́ kì í ṣe gbogbo àwọn oníṣekúṣe* ayé yìí+ tàbí àwọn olójúkòkòrò tàbí àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà tàbí àwọn abọ̀rìṣà ni mò ń sọ. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, á di pé kí ẹ kúrò nínú ayé.+ 11  Ṣùgbọ́n ní báyìí mò ń kọ̀wé sí yín pé kí ẹ jáwọ́ nínú kíkẹ́gbẹ́*+ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí a pè ní arákùnrin, àmọ́ tó jẹ́ oníṣekúṣe* tàbí olójúkòkòrò+ tàbí abọ̀rìṣà tàbí pẹ̀gànpẹ̀gàn* tàbí ọ̀mùtípara+ tàbí alọ́nilọ́wọ́gbà,+ kí ẹ má tiẹ̀ bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹun. 12  Torí kí ló kàn mí pẹ̀lú ṣíṣèdájọ́ àwọn tó wà lóde? Ṣebí àwọn tó wà nínú ìjọ lẹ̀ ń dá lẹ́jọ́, 13  nígbà tí Ọlọ́run ń dá àwọn tó wà lóde lẹ́jọ́?+ “Ẹ mú ẹni burúkú náà kúrò láàárín yín.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

^ Lédè Gíríìkì, por·neiʹa. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Lédè Gíríìkì, por·neiʹa. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “ń gbé pẹ̀lú.”
^ Tàbí “dídarapọ̀.”
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ìṣekúṣe.”
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ìṣekúṣe.”
^ Tàbí “dídarapọ̀.”
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ìṣekúṣe.”
^ Tàbí “ẹlẹ́rẹ̀kẹ́ èébú.”