Lẹ́tà sí Àwọn Ará Kólósè 4:1-18

  • Ìmọ̀ràn fún àwọn ọ̀gá (1)

  • “Ẹ tẹra mọ́ àdúrà gbígbà” (2-4)

  • Ẹ máa fi ọgbọ́n bá àwọn tó wà lóde lò (5, 6)

  • Ìkíni tó fi parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ (7-18)

4  Ẹ̀yin ọ̀gá, ẹ máa fi òdodo àti ẹ̀tọ́ bá àwọn ẹrú yín lò, bí ẹ ṣe mọ̀ pé ẹ̀yin náà ní Ọ̀gá kan ní ọ̀run.+  Ẹ tẹra mọ́ àdúrà gbígbà,+ kí ẹ wà lójúfò nínú rẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́.+  Lẹ́sẹ̀ kan náà, ẹ máa gbàdúrà fún wa+ pé kí Ọlọ́run ṣí ilẹ̀kùn fún ọ̀rọ̀ náà, kí a lè kéde àṣírí mímọ́ nípa Kristi, tí mo tìtorí rẹ̀ wà nínú ìdè ẹ̀wọ̀n,+  kí n sì lè kéde rẹ̀ lọ́nà tó ṣe kedere bó ṣe yẹ kí n kéde rẹ̀.  Ẹ máa fi ọgbọ́n bá àwọn tó wà lóde lò, kí ẹ máa lo àkókò yín lọ́nà tó dára jù lọ.*+  Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín máa jẹ́ ọ̀rọ̀ onínúure, tí iyọ̀ dùn,+ kí ẹ lè mọ bó ṣe yẹ kí ẹ dá ẹnì kọ̀ọ̀kan lóhùn.+  Tíkíkù,+ arákùnrin mi ọ̀wọ́n tó jẹ́ òjíṣẹ́ olóòótọ́ àti ẹrú ẹlẹgbẹ́ mi nínú Olúwa, máa ròyìn gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi fún yín.  Mò ń rán an sí yín kí ẹ lè mọ bí a ṣe ń ṣe sí, kí ó sì lè tu ọkàn yín lára.  Ó ń bọ̀ pẹ̀lú Ónísímù,+ arákùnrin mi olóòótọ́ àti olùfẹ́, ẹni tó ti àárín yín wá; wọ́n á sọ gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ níbí fún yín. 10  Àrísítákọ́sì+ tí a jọ wà lẹ́wọ̀n kí yín, Máàkù+ mọ̀lẹ́bí Bánábà náà kí yín, (ẹni tí a sọ fún yín pé kí ẹ gbà tọwọ́tẹsẹ̀  + tó bá wá sọ́dọ̀ yín), 11  pẹ̀lú Jésù tí wọ́n ń pè ní Jọ́sítù, àwọn yìí jẹ́ ara àwọn tó dádọ̀dọ́.* Àwọn yìí nìkan la jọ ń ṣiṣẹ́ fún Ìjọba Ọlọ́run, wọ́n sì ti di orísun ìtùnú* fún mi gan-an. 12  Épáfírásì+ tó ti àárín yín wá, ẹrú Kristi Jésù, kí yín. Ìgbà gbogbo ló ń gbàdúrà lójú méjèèjì nítorí yín, pé níkẹyìn, kí ẹ lè dúró ní pípé, kí ẹ sì ní ìdánilójú nínú gbogbo ìfẹ́ Ọlọ́run. 13  Mo jẹ́rìí rẹ̀ pé ó ń sapá gan-an nítorí yín àti nítorí àwọn tó wà ní Laodíkíà àti ní Hirapólísì. 14  Lúùkù+ oníṣègùn tó jẹ́ olùfẹ́ kí yín, Démà+ náà kí yín. 15  Ẹ bá mi kí àwọn ará ní Laodíkíà, ẹ sì bá mi kí Nímífà àti ìjọ tó wà ní ilé rẹ̀.+ 16  Tí ẹ bá ti ka lẹ́tà yìí láàárín yín, ẹ ṣètò pé kí wọ́n kà á+ nínú ìjọ àwọn ará Laodíkíà, kí ẹ̀yin náà sì ka èyí tó wá láti Laodíkíà. 17  Bákan náà, ẹ sọ fún Ákípọ́sì+ pé: “Máa fiyè sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí o gbà nínú Olúwa, kí o lè ṣe é láṣeyọrí.” 18  Ìkíni èmi Pọ́ọ̀lù nìyí, tí mo fi ọwọ́ ara mi kọ.+ Ẹ máa fi ìdè ẹ̀wọ̀n mi+ sọ́kàn. Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí wà pẹ̀lú yín.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Grk., “máa ra àkókò pa dà.”
Tàbí “kọlà.”
Tàbí “àrànṣe afúnnilókun.”