Sí Àwọn Ará Fílípì 1:1-30

  • Ìkíni (1, 2)

  • Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run; Àdúrà Pọ́ọ̀lù (3-11)

  • Ìhìn rere ń tẹ̀ síwájú kódà lójú wàhálà (12-20)

  • Ààyè mi jẹ́ ti Kristi, ikú mi jẹ́ èrè (21-26)

  • Ẹ máa hùwà lọ́nà tó yẹ ìhìn rere (27-30)

1  Pọ́ọ̀lù àti Tímótì, àwa ẹrú Kristi Jésù, sí gbogbo ẹni mímọ́ nínú Kristi Jésù, tí wọ́n wà ní ìlú Fílípì,+ pẹ̀lú àwọn alábòójútó àti àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́:+  Kí ẹ ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà látọ̀dọ̀ Baba wa Ọlọ́run àti Jésù Kristi Olúwa.  Mò ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi ní gbogbo ìgbà tí mo bá rántí yín  nínú gbogbo ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ mi lórí gbogbo yín. Inú mi máa ń dùn ní gbogbo ìgbà tí mo bá ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀,+  nítorí ìtìlẹyìn tí ẹ ti ṣe fún* ìhìn rere láti ọjọ́ àkọ́kọ́ títí di àkókò yìí.  Nítorí ohun kan dá mi lójú, pé ẹni tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rere nínú yín á ṣe é parí+ tó bá fi máa di ọjọ́ Kristi Jésù.+  Ó tọ́ tí mo bá ronú lọ́nà yìí nípa gbogbo yín, torí ọ̀rọ̀ yín ń jẹ mí lọ́kàn, ẹ sì jẹ́ alájọpín pẹ̀lú mi nínú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí nínú àwọn ìdè ẹ̀wọ̀n mi+ àti nínú bí a ṣe ń gbèjà ìhìn rere, tí a sì ń fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lọ́nà òfin.+  Mo fi Ọlọ́run ṣe ẹlẹ́rìí pé àárò gbogbo yín ń sọ mí nítorí ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́, irú èyí tí Kristi Jésù ní.  Ohun tí mò ń gbà ládùúrà ni pé kí ìfẹ́ yín lè túbọ̀ pọ̀ gidigidi,+ kí ẹ sì ní ìmọ̀ tó péye+ àti òye tó kún rẹ́rẹ́;+ 10  pé kí ẹ lè máa wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù,+ kí ẹ lè jẹ́ aláìní àbààwọ́n, kí ẹ má sì máa mú àwọn ẹlòmíì kọsẹ̀+ títí di ọjọ́ Kristi; 11  kí èso òdodo tó wá nípasẹ̀ Jésù Kristi lè kún inú yín,+ fún ògo àti ìyìn Ọlọ́run. 12  Ní báyìí, ẹ̀yin ará, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi ti mú kí ìhìn rere tẹ̀ síwájú, 13  tó fi jẹ́ pé gbogbo èèyàn mọ̀+ nípa àwọn ìdè ẹ̀wọ̀n mi+ nítorí Kristi láàárín gbogbo Ẹ̀ṣọ́ Ọba àti gbogbo àwọn yòókù. 14  Púpọ̀ lára àwọn ará nínú Olúwa ti ní ìgboyà nítorí àwọn ìdè ẹ̀wọ̀n mi, wọ́n sì túbọ̀ ń fi ìgboyà sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láìbẹ̀rù. 15  Lóòótọ́, àwọn kan ń wàásù Kristi nítorí owú àti ìdíje, àmọ́ àwọn míì ń ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí inú rere. 16  Ìfẹ́ ló ń mú kí àwọn ti ìkẹyìn yìí máa kéde Kristi, torí wọ́n mọ̀ pé a ti yàn mí láti gbèjà ìhìn rere;+ 17  àmọ́ torí àtidá ìjà sílẹ̀ ni àwọn ti ìṣáájú fi ń ṣe bẹ́ẹ̀, kì í ṣe torí pé wọ́n ní èrò tó dáa, ṣe ni wọ́n fẹ́ dá wàhálà sílẹ̀ fún mi nínú àwọn ìdè ẹ̀wọ̀n mi. 18  Kí ló ti wá yọrí sí? Ní gbogbo ọ̀nà, ì báà jẹ́ nínú dídíbọ́n tàbí ní òótọ́, à ń kéde Kristi, èyí sì ń múnú mi dùn. Kódà, ṣe ni inú mi á túbọ̀ máa dùn, 19  torí mo mọ̀ pé èyí máa yọrí sí ìgbàlà mi nípasẹ̀ ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ yín+ àti ìtìlẹyìn ẹ̀mí Jésù Kristi.+ 20  Èyí bá ohun tí mò ń fojú sọ́nà fún, tí mo sì ń retí mu, pé ojú ò ní tì mí lọ́nàkọnà, àmọ́ pé nínú bí mo ṣe lómìnira láti sọ̀rọ̀ fàlàlà, a ó ti ara mi gbé Kristi ga báyìí, bí a ṣe ń gbé e ga tẹ́lẹ̀, ì báà jẹ́ nípasẹ̀ ìyè tàbí nípasẹ̀ ikú.+ 21  Ní tèmi, tí mo bá wà láàyè, mo wà láàyè fún Kristi,+ tí mo bá sì kú, èrè ló jẹ́ fún mi.+ 22  Ní báyìí, tí mo bá máa wà láàyè nìṣó nínú ara, ó jẹ́ èrè iṣẹ́ mi; síbẹ̀, mi ò sọ ohun tí màá yàn fún ẹnikẹ́ni. 23  Mi ò mọ èyí tí màá mú nínú nǹkan méjì tó wà níwájú mi yìí, torí ó wù mí kí n gba ìtúsílẹ̀, kí n sì wà pẹ̀lú Kristi,+ torí ó dájú pé, ìyẹn ló sàn jù.+ 24  Àmọ́ ṣá o, kí n ṣì wà nínú ẹran ara ló máa ṣe yín láǹfààní jù lọ. 25  Nítorí náà, bí èyí ṣe dá mi lójú, mo mọ̀ pé màá dúró, màá sì wà pẹ̀lú gbogbo yín kí ẹ lè tẹ̀ síwájú, kí inú yín sì máa dùn nínú ìgbàgbọ́, 26  kí ayọ̀ yín lè kún nínú Kristi Jésù nítorí mi nígbà tí mo bá tún wà pẹ̀lú yín. 27  Kìkì pé kí ẹ máa hùwà* lọ́nà tó yẹ ìhìn rere nípa Kristi,+ kó lè jẹ́ pé, bóyá mo wá wò yín tàbí mi ò wá, kí n lè máa gbọ́ nípa yín pé ẹ dúró gbọn-in nínú ẹ̀mí kan, pẹ̀lú ọkàn kan,*+ ẹ jọ ń sapá nítorí ìgbàgbọ́ nínú ìhìn rere, 28  ẹ ò sì jẹ́ kí àwọn tó ń ta kò yín kó jìnnìjìnnì bá yín lọ́nàkọnà. Èyí jẹ́ àmì ìparun+ fún wọn, àmọ́ ó jẹ́ ti ìgbàlà fún yín;+ ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló sì ti wá. 29  A ti fún yín ní àǹfààní náà nítorí Kristi, kì í ṣe láti ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ nìkan, àmọ́ láti jìyà nítorí rẹ̀ pẹ̀lú.+ 30  Irú ìjàkadì tí ẹ rí i pé mò ń jà ni ẹ̀yin náà ń jà,+ òun náà lẹ gbọ́ pé mo ṣì wà lẹ́nu rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “nítorí bí ẹ ṣe lọ́wọ́ sí ìtẹ̀síwájú.”
Tàbí “kí ẹ máa ṣe ohun tó fi hàn pé ẹ jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀.”
Tàbí “ní ìṣọ̀kan.”